ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ogunlọ́gọ̀ Ńlá
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 22. Ìsọfúnni síwájú sí i wo ni Jòhánù rí gbà nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá?

      22 Ọlọ́run lo ọ̀nà tó ń gbà fi ìran han Jòhánù láti fún un ní ìsọfúnni síwájú sí i nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí: “Ó [ìyẹn alàgbà náà] sì wí fún mi pé: ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ó jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà, wọ́n sì ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀; Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ yóò sì na àgọ́ rẹ̀ bò wọ́n.’”—Ìṣípayá 7:14b, 15.

  • Ogunlọ́gọ̀ Ńlá
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    • 25. (a) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún Jèhófà “tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀”? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe “na àgọ́ rẹ̀” bo ogunlọ́gọ̀ ńlá náà?

      25 Síwájú sí i, wọ́n ti di ẹlẹ́rìí onítara fún Jèhófà, “wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” Ṣé ọ̀kan lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ti ya ara wọn sí mímọ́ yìí ni ìwọ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún ọ láti máa sin Jèhófà nìṣó nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé. Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà lábẹ́ ìdarí àwọn ẹni àmì òróró. Láìka wíwá àtijẹ àtimu sí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára wọn ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nípa sísìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́, yálà o wà lára wọn tàbí o kò sí níbẹ̀, yíyà tó o ti ya ara ẹ sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó ohun tó lè mú kó o máa yọ̀ pé nítorí ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́ rẹ, a polongo rẹ ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run a sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlejò nínú àgọ́ rẹ̀. (Sáàmù 15:1-5; Jákọ́bù 2:21-26) Ìdí ẹ̀ nìyẹn tí Jèhófà fi “na àgọ́ rẹ̀” bo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé, gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò rere, ó ń dáàbò bò wọ́n.—Òwe 18:10.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́