-
Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún ÌgbàlàIlé Ìṣọ́—1999 | February 15
-
-
fún ìràpadà náà? Ní gẹ́rẹ́ kí wọ́n tó mú Jésù, ó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” (Jòhánù 14:23) “Ọ̀rọ̀” Jésù wé mọ́ àṣẹ rẹ̀, pé ká máa fi ìtara nípìn-ín nínú ṣíṣe iṣẹ́ tó fi rán wa, pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mátíù 28:19) Ìgbọràn sí Jésù tún ń béèrè pé ká fìfẹ́ hàn sí àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí.—Jòhánù 13:34, 35.
21. Èé ṣe tó fi yẹ ká wà níbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní April 1?
21 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ táa lè gbà fi ìmọrírì hàn fún ìràpadà náà ni nípa wíwà níbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, tí a ó ṣe ní April 1 lọ́dún yìí.a Èyí pẹ̀lú jẹ́ ara “ọ̀rọ̀” Jésù, torí pé nígbà tó ń dá ayẹyẹ yìí sílẹ̀, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Báa bá wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí, tí a sì fiyè sí gbogbo ohun tí Kristi pa láṣẹ kínníkínní, a ó fi hàn pé lóòótọ́ ló dá wa lójú hán-ún-hán-ún pé ìràpadà Jésù ni ọ̀nà tí Ọlọ́run là sílẹ̀ fún ìgbàlà. Lóòótọ́, “kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.”—Ìṣe 4:12.
-
-
Ọ̀nà Ìfẹ́ Kì í Kùnà LáéIlé Ìṣọ́—1999 | February 15
-
-
Ọ̀nà Ìfẹ́ Kì í Kùnà Láé
“Ẹ máa fi tìtara-tìtara wá àwọn ẹ̀bùn títóbi jù. Síbẹ̀, èmi fi ọ̀nà títayọ ré kọjá hàn yín.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 12:31.
1-3. (a) Báwo ni kíkọ́ láti fìfẹ́ hàn ṣe dà bí kíkọ́ èdè tuntun? (b) Kí ni àwọn nǹkan tó lè mú kí kíkọ́ láti fìfẹ́ hàn ṣòro?
OHA ti gbìyànjú láti kọ́ èdè tuntun rí? Ìpèníjà ńlá ni, ká má sọ ọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ṣùgbọ́n o, ọmọdé tètè máa ń gbọ́ èdè bó bá wà lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ ọ́. Kíá ni ọpọlọ rẹ̀ yóò ti mòye àwọn ìró àti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀, tí yóò fi jẹ́ pé láìpẹ́ láìjìnnà, ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ ti mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ, ó ti ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuru. Àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún àgbàlagbà. Lemọ́lemọ́ la óò máa ṣí ìwé atúmọ̀ èdè, ká sáà lè rántí gbólóhùn díẹ̀ tó ṣe kókó nínú èdè àjèjì. Àmọ́ ṣá o, tó bá wá pẹ́ táa ti ń kọ́ èdè ọ̀hún, a óò wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú lọ́nà tó bá èdè tuntun náà mu, yóò sì wá túbọ̀ rọrùn láti sọ.
2 Kíkọ́ báa ṣe ń fìfẹ́ hàn kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí kíkọ́ èdè tuntun. Òtítọ́ ni pé Ọlọ́run dá ànímọ́ yìí mọ́ ènìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; fi wé 1 Jòhánù 4:8.) Síbẹ̀síbẹ̀, kíkọ́ láti fìfẹ́ hàn tún gba àkànṣe ìsapá—pàápàá lónìí, tí ìfẹ́ni àdánidá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì. (2 Tímótì 3:1-5) Nígbà mìíràn, bọ́ràn ṣe máa ń rí nìyẹn nínú ìdílé pàápàá. Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ ló ń dàgbà nínú àyíká tí ń dáni lágara, níbi tó jẹ́ pé níjọ́kanlọ́gbọ̀n ni wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́—ìyẹn bí wọ́n bá tilẹ̀ gbọ́ ọ rárá. (Éfésù 4:29-31; 6:4) Báwo wá ni a ṣe lè mọ báa ṣe ń fìfẹ́ hàn—bó tilẹ̀ jẹ́ pé
-