Orin 138
Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Ọlọ́run alààyè— - Ọlọ́run ohun gbogbo - Láti ìran dé ìran— - Jèhófà loókọ rẹ. - O dá wa lọ́lá gan-an - A ń yọ̀ p’a jẹ́ èèyàn rẹ. - À ń kéde ògo rẹ fún, - Ẹ̀yà orílẹ̀èdè. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, Jèhófà, - Kò s’Ọlọ́run bí ‘rẹ. - Kò sẹ́lòmíì lọ́run bí ‘rẹ - Tàbí láyé níbí. - Ìwọ ni Olódùmarè, - Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀. - Jèhófà, Jèhófà, - Ìwọ nìkan l’Ọlọ́run wa. 
- Ìwọ mú kí a di - Ohunkóhun tí o fẹ́, - Ka lè ṣohun tí o fẹ́— - Jèhófà loókọ rẹ. - Nítorí àánú rẹ - O pè wá l’Ẹ́lẹ́rìí rẹ. - O dá wa lọ́lá torí— - À ń jẹ́ orúkọ rẹ. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, Jèhófà, - Kò s’Ọlọ́run bí ‘rẹ. - Kò sẹ́lòmíì lọ́run bí ‘rẹ - Tàbí láyé níbí. - Ìwọ ni Olódùmarè, - Aráyé gbọ́dọ̀ mọ̀. - Jèhófà, Jèhófà, - Ìwọ nìkan l’Ọlọ́run wa. 
(Tún wo 2 Kíró. 6:14; Sm. 72:19; Aísá. 42:8.)