-
Kí Ni “Òpin” Túmọ̀ Sí?Ilé Ìṣọ́—2015 | May 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ÒPIN TI SÚN MỌ́LÉ
Kí Ni “Òpin” Túmọ̀ Sí?
Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ pé “Òpin ti sún mọ́lé?” Ṣé kì í ṣe oníwàásù kan tó ń sọ̀rọ̀ fatafata látorí àga ìwàásù pẹ̀lú Bíbélì rẹ̀ lọ́wọ́, tó sì ń fara ṣàpèjúwe ló máa wá sí ẹ lọ́kàn? Àbí bàbá àgbàlagbà onírùngbọ̀n yẹ́bútú kan tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, tó wọṣọ gbàgẹ̀rẹ̀ tó wá gbé àmì kan tó kọ ọ̀rọ̀ nípa òpin ayé sí tàbí tí àmùrè wà ní ìgbáròkó rẹ̀, tó wá ń kéde pé: “Ẹ yí pa dà, ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀!” Ká sòótọ́, irú èyí lè dáyà já àwọn kan tàbí kó mú àwọn míì máa ṣiyèméjì tàbí kó tiẹ̀ dẹ́rìn-ín pa wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Bíbélì sọ pé: “Òpin yóò sì dè.” (Mátíù 24:14) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan náà là ń pè ní “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run” àti “Amágẹ́dọ́nì.” (Ìṣípayá 16:14, 16) Lóòótọ́, ẹ̀kọ́ ìsìn ti mú kí ọ̀rọ̀ náà ta kora, torí kò yé àwọn fúnra wọn, wọ́n sì ń gbin ọ̀pọ̀ èrò tó ń bani lẹ́rù sọ́kàn àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé Bíbélì ò fi wá sínú òkùnkùn, ó tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí ká lè mọ ohun tó jóòótọ́ nípa òpin. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ bóyá òpin ti sún mọ́lé. Paríparí rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè làájá! Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo èrò òdì tí àwọ́n èèyàn ní nípa òpin àti ohun tó túmọ̀ sí. Kí tiẹ̀ ni Bíbélì pè ní “òpin”?
ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́ NÍPA ÒPIN
ÒPIN KÌ Í ṢE PÉ ỌLỌ́RUN FẸ́ FI INÁ PA AYÉ RUN.
Bíbélì sọ pé: “Ó [Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí àtàwọn míì ti jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ò ní pa ayé rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kò ní fàyè gba àwọn èèyàn pé kí wọ́n pa á run.—Oníwàásù 1:4; Aísáyà 45:18.
ÒPIN KÒ NÍ ṢÀDÉDÉ WÁYÉ.
Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run ti dá ọjọ́ tí òpin máa dé, ó sì ti ṣètò àkókò tí yóò jẹ́. Ó ní: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba. Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́.” (Máàkù 13:32, 33) Torí náà, Ọlọ́run, ìyẹn “Baba” ti dá ọjọ́ tàbí ṣètò “àkókò tí ó yàn kalẹ̀” tí òpin máa dé.
. ÒPIN KÌ Í ṢE LÁTỌWỌ́ ÈÈYÀN TÀBÍ NÍPASẸ̀ ÀWỌN ÒKÚTA INÁ TÓ Ń JÁBỌ́ LÁTỌ̀RUN.
Kí ló máa mú òpin wá? Ìṣípayá 19:11 sọ pé: “Mo sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó! ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a ń pè ní Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́.” Ẹsẹ 19 wá sọ pé: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà náà àti àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn tí wọ́n kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.” (Ìṣípayá 19:11-21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ èdè ìṣàpẹẹrẹ, ohun tí ó fẹ́ ká lóye ni pé: Ọlọ́run máa rán agbo ọmọ ogun àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run.
Ìròyìn ayọ̀ lohun tí Bíbélì sọ nípa òpin kì í ṣe ìròyìn búburú
ÈRÒ TÓ TỌ́ NÍPA ÒPIN
ÒPIN MÁA DÉ BÁ ÌJỌBA ÈÈYÀN.
Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tá à ń jíròrò kókó kẹta, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa pa “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” wọn run torí wọ́n “kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.”—Ìṣípayá 19:19.
OGUN, ÌWÀ IPÁ ÀTI ÌRẸ́JẸ MÁA DÓPIN.
“[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) “Nítorí àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.” (Òwe 2:21, 22) “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5.
ÒPIN Á DÉ BÁ ÌSÌN TÍ KÒ ṢÈFẸ́ ỌLỌ́RUN TÓ SÌ Ń MÚ ÀWỌN ÈÈYÀN ṢÌNÀ.
‘Àwọn wòlíì pàápàá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní ti gidi; àti ní ti àwọn àlùfáà, wọ́n ń tẹni lórí ba ní ìbámu pẹ̀lú agbára wọn . . . kí sì ni ẹ ó ṣe ní òpin rẹ̀?’ (Jeremáyà 5:31) “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: ‘Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin!’”—Mátíù 7:21-23.
ÒPIN MÁA DÉ BÁ ÀWỌN TÓ Ń DA AYÉ RÚ.
Jésù Kristi sọ pé: “Wàyí o, èyí ni ìpìlẹ̀ fún ìdájọ́, pé ìmọ́lẹ̀ ti wá sí ayé ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ti nífẹ̀ẹ́ òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, nítorí pé àwọn iṣẹ́ wọn burú.” (Jòhánù 3:19) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìparun tó wáyé nígbà kan tó sì kárí ayé, ìyẹn jẹ́ nígbà ayé ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Nóà. “Ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:5-7.
Kíyè sí pé Bíbélì fi “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun” wé ìparun “ayé” ìgbà Nóà. Ayé wo ló pa run nígbà yẹn? Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ló “jìyà ìparun,” ìyẹn “àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Kì í ṣe ilẹ̀ ayé yìí ló pa run. Bákan náà, bí “ọjọ́ ìdájọ́” bá dé, àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run máa pa run. Àmọ́ Ọlọ́run máa dá àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ nídè bíi ti ọjọ́ Nóà.—Mátíù 24:37-42.
Wo bí ilẹ̀ ayé yìí ṣe máa rí nígbà tí gbogbo àwọn ẹni ibi bá pa run! Ẹ ò rí i pé ìròyìn ayọ̀ lohun tí Bíbélì sọ nípa òpin kì í ṣe ìròyìn búburú. Síbẹ̀, o lè máa ronú pé: ‘Ǹjẹ́ Bíbélì sọ ìgbà tí òpin máa dé? Báwo ló ṣe sún mọ́lé tó? Báwo ni mo ṣe lè làájá?’
-
-
Ǹjẹ́ Òpin Ti Sún Mọ́lé?Ilé Ìṣọ́—2015 | May 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Ǹjẹ́ Òpin Ti Sún Mọ́lé?
Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa fàyè gba àwọn èèyàn láti máa jẹ gàba lórí ara wọn, kí wọ́n sì máa ba ayé yìí jẹ́ nìṣó? Rárá o, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé láìpẹ́, òun á sì fòpin sí ìṣẹ́ àti ìnira. A dúpẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká mọ ìgbà tí òun máa gbé ìgbésẹ̀ náà. Àmọ́ báwo ló ṣe jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì yìí?
Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o fẹ́ rìnrìn àjò lọ síbì kan tóò dé rí, ó dájú pé wàá béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹni tó mọ̀nà. Bó o ṣe ń lọ lọ́nà, tó o sì ń rí àwọn àmì tẹ́ni náà júwe fún ẹ ni ọkàn rẹ á túbọ̀ balẹ̀ pé oò ṣìnà, á sì tún dá ẹ lójú pé o ti sún mọ́ ibi tí ò ń lọ. Bákan náà, Ọlọ́run fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé ṣe bá àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn mu gẹ́lẹ́. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì tó ń wáyé yìí sì jẹ́ àmì tó dájú pé àkókò tí à ń gbé yìí ló kángun sí ìgbà tí òpin máa dé.
Bíbélì fi hàn pé bí ayé yìí ṣe ń bá a lọ, a máa dé sáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan tó máa sàmì sí àkókò òpin gan-an. Lákòókò yẹn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá ò rírú rẹ̀ rí nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn àti ipò tí kò bára dé máa wáyé. Díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ pé ó máa wáyé rèé.
1. ÌDÀRÚDÀPỌ̀ MÁA GBAYÉ KAN Ìwé Mátíù orí kẹrìnlélógún [24] sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan á wáyé tó máa fi hàn pé a ti wà ní ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà para pọ̀ jẹ́ àmì kan, wọ́n sì sàmì sí “ìparí ètò àwọn nǹkan,” tó máa jẹ́ ká mọ ìgbà tí ‘òpin yóò dé.’ (Ẹsẹ 3 àti 14) Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn ogun tó mi ayé tìtì, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, ìwà àìlófin tó gbòde kan àti àìsí ìfẹ́. Kódà, ó tún sọ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì á máa fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tú àwọn ọmọ ìjọ jẹ bí iṣu. (Ẹsẹ 6-26) Lóòótọ́, dé ìwọ̀n àyè kan, irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ń wáyé láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn. Àmọ́, bí òpin ṣe ń sún mọ́lé, gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà á máa wáyé lákòókò kan náà tí aráyé wà nínú hílàhílo tó bùáyà. Ohun mẹ́ta tá a máa sọ tẹ̀ lé èyí tún jẹ́ ìkìlọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé.
2. ÌWÀ ÀWỌN ÈÈYÀN MÁA BURÚ SÍ I Bíbélì sọ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò tó sàmì sí òpin, àwọn èèyàn á máa hùwà tó burú jáì. Ó ní: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1-4) Bí àwa náà bá wò ó, ìwà àìnáání ara ẹni lẹ́nì-kìíní-kejì ti wà ọjọ́ pẹ́, àmọ́ ìwà tí àwọn èèyàn á máa hù sí ara wọn ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí máa lékenkà débí tí a fi lè pe sáà yìí ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Àbí ìwọ náà ò rí i pé ìwà àwọn èèyàn túbọ̀ ń burú sí i ni?
3. ÀWỌN ÈÈYÀN Á MÁA BA ILẸ̀ AYÉ JẸ́ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Kí la rí tá a fi sọ pé àwọn èèyàn ń run ilẹ̀ ayé tàbí bà á jẹ́? Bíbélì sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nípa ìgbà ayé Nóà, ó ní: “Ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá. Nítorí náà, Ọlọ́run rí ilẹ̀ ayé, sì wò ó! ó bàjẹ́.” Ọlọ́run wá sọ nígbà yẹn pé: “Èmi yóò run wọ́n,” ìyẹn àwọn èèyàn burúkú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11-13) Ǹjẹ́ ìwọ náà ò kíyè sí pé ìwà ipá kún inú ayé lónìí? Ní ti gidi, a wà ní sáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn aráyé. Àwọn tó ń ba ayé jẹ́ ti gbèrú nínú ìwà burúkú wọn débi pé wọ́n lágbára tó lè pa gbogbo èèyàn run láìkù kan. Àwọn ohun ìjà tí wọ́n lè fi ṣọṣẹ́ burúkú yìí sì wà níkàáwọ́ wọn. Ọ̀nà míì tún wà tí àwọn èèyàn gbà ń ba ayé yìí jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tó ń gbé ìwàláàyè ró bí afẹ́fẹ́ tá à ń mí, ewéko àtàwọn ẹranko, òkun àtàwọn ohun abẹ̀mí inú rẹ̀ làwọn ọmọ aráyé ti bà jẹ́.
Ẹ gbọ́ ná, ‘ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ǹjẹ́ ọmọ aráyé tiẹ̀ lálàá pé àwọn máa ṣe ohun ìjà tó lágbára láti pa gbogbo ohun alààyè inú ayé yìí run bí?’ Àmọ́, ẹ wo bí wọ́n ṣe ń kó àwọn ohun ìjà olóró jọ, tí wọ́n sì fi ń run àyíká. Àti pé bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe ń tẹ̀ síwájú yìí, bóyá lagbára ẹ̀dá èèyàn á lè ká àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ń gbé jáde. Bákan náà, wọn ò mọ bí ọṣẹ́ tó máa ṣe á ṣe rinlẹ̀ tó. Bó ti wù kó rí, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé yìí lọ́jọ́ iwájú kọjá òye wa, kò sì sí níkàáwọ́ ẹ̀dá èèyàn. Ọlọ́run ti sọ pé kí ọmọ aráyé tó ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe, òun máa dá sí ọ̀rọ̀ náà, òun á sì run àwọn tó ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Asọ̀rọ̀mátàsé sì ni Ẹlẹ́dàá wa!
4. IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ MÁA KÁRÍ AYÉ Nǹkan míì tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé ni iṣẹ́ kan tí kò láfiwé tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Iṣẹ́ ìwàásù yìí máa yàtọ̀ gédégbé sí ìwàásù táwọn onísìn ń sọ pé àwọn ń ṣe kiri láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” ló máa jẹ́ lájorí ìwàásù tá à ń sọ náà. Ìsìn wo ni ìwọ mọ̀ tó ń sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn? Ká tiẹ̀ sọ pé àwọn kan ní àwọn ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ṣé wọ́n kàn ń ṣe é ládùúgbò ni àbí ibi gbogbo ni wọ́n ti mọ̀ wọ́n pé àwọn ni wọ́n ń wàásù ìhìn rere náà “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè”?
À ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè
“Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” ni ìkànnì www.jw.org ń gbé lárugẹ. Àwọn ìwé ìròyìn tó wà lórí ìkànnì yìí ń ṣàlàyé ìhìn rere Ìjọba náà ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700]. Ǹjẹ́ ohun míì wà táwọn èèyàn ti ṣe láti fi kéde Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé? Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà làwọn èèyàn ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí akínkanjú tó ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kódà, láti ọdún 1939 ni ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ wa ti ń ní àkọlé náà tó sọ pé “Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.” Ìwé kan tí wọ́n fi ń ṣàlàyé nípa àwọn ẹ̀sìn sọ pé: “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹ̀sìn tó lè wàásù lọ́nà tó jinlẹ̀ tó sì gbòòrò” tó ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Iṣẹ́ ìwàásù yìí ni wọ́n fi ń kéde pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run á gbé ìgbésẹ̀, “òpin yóò sì dé.”
ÀKÓKÒ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀ NÍNÚ ÌTÀN ARÁYÉ
Ṣé o ti wá rí bí mẹ́rin lára àwọn àmì tí Bíbélì fi kìlọ̀ nípa òpin ṣe ń wáyé lákòókò tá a wà yìí? Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí ìwé ìròyìn yìí ti ń fún wa ní ìsọfúnni tó ṣe ṣàkó nípa ohun tó ń lọ láyé, èyí sì ń jẹ́ ká mọ̀ pé a ti sún mọ́ òpin ayé. Síbẹ̀, ńṣe làwọn kan ń jiyàn pé àwọn ẹ̀rí wọ̀nyẹn ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, pé ńṣe la dọ́gbọ́n hùmọ̀ rẹ̀ fúnra wa. Wọ́n ní torí pé ètò ìbánisọ̀rọ̀ túbọ̀ ń gbèrú sí i ló ṣe dà bíi pé nǹkan ń burú sí i. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn ń rí nísinsìnyí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé à ń gbé ní ìparí sáà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn ìran èèyàn.
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé bí nǹkan ṣe ń lọ yìí, gudugbẹ̀ ńlá kan ò ní pẹ́ já, tí á sì mú ìyípadà ńláǹlà bá ilẹ̀ ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2014, ìgbìmọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ààbò tó ń tẹ ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists, sọ fún ẹ̀ka tó ń dáàbò bo Ìgbìmọ̀ Ààbò fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pé kí wọ́n múra kí àwọn àjálù ńlá tó lè run aráyé má bàa ṣẹlẹ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yẹn sọ pé: “Nígbà tá a gbé àwọn ẹ̀rí tá a ní yẹ̀ wò, ibi tí a parí èrò sí ni pé apá tí ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìṣe ìgbàlódé lásán máa kó nínú ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí máa fa ewu tó lékenkà fún aráyé.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá gbà lóòótọ́ pé a ti wà ní sáà kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn ìran aráyé. Àmọ́ ó dá àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn yìí àtàwọn tó ń kà á lójú pé sáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tá à ń sọ yìí ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àti pé òpin ti sún mọ́lé gan-an. Ṣùgbọ́n, dípò kó o máa bẹ̀rù torí pé oò mọ̀la, máa yọ̀ nítorí pé ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú máa já sí ayọ̀ nígbẹ̀yìn. Ki nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Torí pé ìwọ náà lè la òpin tó ń bọ̀ já!
-
-
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Máa La Òpin Já Ìwọ Náà Lè LàájáIlé Ìṣọ́—2015 | May 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ǸJẸ́ ÒPIN TI SÚN MỌ́LÉ
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Máa La Òpin Já Ìwọ Náà Lè Làájá
Bíbélì sọ pé òpin tó ń bọ̀ máa mú ìparun wá, ó sọ pé: “Ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí . . . láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là.” (Mátíù 24:21, 22) Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò làájá, ó sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ . . . , ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
Bó o bá fẹ́ la ayé tó ń kọjá lọ yìí já, tó o sì fẹ́ wà láàyè títí láé, kí ló yẹ kó o ṣe? Àbí, ṣé ohun tó kàn ni pé kó o máa kó àwọn nǹkan ìní jọ pelemọ tàbí kó o máa gbara dì lójú méjèèjì? Rárá. Bíbélì sọ ohun tó fẹ́ ká fi sí ipò àkọ́kọ́. Ó ní: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà.” (2 Pétérù 3:10-12) Àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé àwọn alákòóso inú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí àti gbogbo àwọn tó fara mọ́ ìṣàkóso èèyàn dípò Ọlọ́run ló dúró fún “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” tí yóò di yíyọ́. Ká sòótọ́, tó bá jẹ́ àwọn nǹkan ìní tara là ń tọ́jú pamọ́, ìyẹn kò ní lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ìparun tó ń bọ̀.
Tá a bá fẹ́ là á já, a ní láti fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà Ọlọ́run, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ ká lè mọ àwọn ìwà àti ìṣe tó máa dùn mọ́ ọn nínú. (Sefanáyà 2:3) Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a ‘fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,’ a ní láti yẹra fún ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ ká sì fọkàn sí àwọn àmì tó fi hàn pé àkókò tí kò lẹ́gbẹ́ là ń gbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fi ohun tí Bíbélì sọ hàn ẹ́, kó o lè mọ bí wà á ṣe la òpin tó ń bọ̀ já.
-