ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

      Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ikú?

      Àwọn àgbà àtọmọdé dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ pósí kan níbi tí wọ́n ti fẹ́ sìnkú

      “Ibi mẹ́ta ni mo rò pé èèyàn lè lọ lẹ́yìn tó bá kú, nínú kó lọ sí ọ̀run tàbí ọ̀run àpáàdì tàbí kó lọ sí pọ́gátórì. Mi ò rò pé ìwà mi dáa tó kí n rí ọ̀run wọ̀, àmọ́ kò burú débi tí máa fi lọ sí ọ̀run àpáàdì. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní pọ́gátórì kò sì yé mi rárá. Ẹnu àwọn èèyàn ni mo kúkú ti gbọ́ ọ, kò sí èyí tí mo rí nínú Bíbélì níbẹ̀.”​—Lionel.

      “Ohun tí wọ́n kọ́ mi ni pé, ọ̀run ni gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú, àmọ́ mi ò gbà gbọ́. Ohun témi rò ni pé ikú lòpin ohun gbogbo, kò sì sí ìrètí kankan fáwọn tó ti kú.”​—Fernando.

      Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé: ‘Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú? Ṣé àwọn èèyàn wa tó ti kú ń jìyà níbì kan? Ṣé a tún lè pa dà rí wọn? Kí ló máa jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè rí wọn?’ Ó máa dáa ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì fi ikú wé. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ìrètí tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó wà fún àwọn tó ti kú.

      Ipò wo làwọn òkú wà?

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn. Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [tàbí Sàréè], ibi tí ìwọ ń lọ.”a​—Oníwàásù 9:​5, 10.

      Ṣìọ́ọ̀lù ìyẹn Sàréè ni ibi tí gbogbo èèyàn ń lọ lẹ́yìn ikú; ó sì ń ṣàpẹẹrẹ ipò tí èèyàn kò ti mọ nǹkan kan mọ́, téèyàn ò sì lè ṣe ohunkóhun. Kí ni ohun tí Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà rò nípa Ṣìọ́ọ̀lù? Ọjọ́ kan ṣoṣo ni Jóòbù pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, ni eéwo bá tún so sí gbogbo ara rẹ̀ látorí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Ó wá bẹ Ọlọ́run pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [“ní ọ̀run àpáàdì,” Bíbélì Catholic Douay Version], pé ìwọ yóò pa mí mọ́.” (Jóòbù 1:​13-19; 2:7; 14:13) Ó dájú pé Jóòbù kò gbà pé Ṣìọ́ọ̀lù ìyẹn Sàréè jẹ́ ibi tí èèyàn ti ń joró nínú iná, níbi tí ìyà rẹ̀ ti máa pọ̀ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà pé ibẹ̀ ni òun ti máa rí ìtura.

      Ọ̀nà míì wà tá a tún lè gbà mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú. A lè ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn mẹ́jọ tí wọ́n jíǹde.​—Wo àpótí náà “Àjíǹde Mẹ́jọ Tí Bíbélì Mẹ́nu Kàn.”

      Kò sí ọ̀kan nínú àwọn mẹ́jọ yìí tó sọ bóyá òun lọ gbádùn tàbí pé òun joró nígbà tí òun kú. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wọ́n á sọ bí ọ̀hún ṣe rí fún àwọn míì. Tí wọ́n bá sì sọ ọ́, ǹjẹ́ irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní sí nínú Bíbélì fún wa? Àmọ́, kò sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Àwọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ kò sọ nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn kò mọ nǹkan kan nígbà tí wọ́n kú, àfi bí ẹni tó sun oorun àsùnwọra. Kódà, Bíbélì sábà máa ń fi ikú wé oorun. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Dáfídì àti Sítéfánù “sùn nínú ikú.”​—Ìṣe 7:60; 13:36.

      Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fún àwọn tó ti kú? Ṣé wọ́n lè jí lójú oorun yìí?

      a Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Ṣìọ́ọ̀lù” àti ti Gíríìkì náà “Hédíìsì” túmọ̀ sí “Sàréè.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì pè é ní “ọ̀run àpáàdì,” àmọ́ ẹ̀kọ́ pé èèyàn máa ń joró nínú ọ̀run àpáàdì kò bá Bíbélì mu.

      ÀJÍǸDE MẸ́JỌ TÍ BÍBÉLÌ MẸ́NU KÀNb

      Ọmọ opó kan Wòlíì Èlíjà jí ọmọ opó kan dìde. Ìlú Sáréfátì tó wà ní àríwá Ísírẹ́lì ni opó náà ń gbé.​—1 Àwọn Ọba 17:​17-24.

      Ọmọkùnrin kan ní Ṣúnémù Wòlíì Èlíṣà tí Èlíjà fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́ jí ọmọkùnrin kan dìde ní ìlú Ṣúnẹ́mù, ó sì fà á lé àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́.​—2 Àwọn Ọba 4:​32-37.

      Òkú ọkùnrin kan nínú ibojì Wọ́n ju òkú ọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú síbi tí wọ́n sin òkú Èlíṣà sí. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan eegun òkú wòlíì Èlíṣà, ọkùnrin náà jí dìde.​—2 Àwọn Ọba 13:​20, 21.

      Ọmọkùnrin òpó tó wá láti Náínì Nígbà tí wọ́n fẹ́ lọ sin òkú ọ̀dọ́kùnrin kan sí ẹ̀yìn odi ìlú Náínì, Jésù jí ọmọ náà dìde ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́.​—Lúùkù 7:​11-15.

      Ọmọbìnrin Jáírù Jáírù tó jẹ́ ọkàn lára àwọn òṣìṣẹ́ sínágọ́gù bẹ Jésù pé kó wá bá òun wo ọmọbìnrin òun tó ń ṣàìsàn. Jésù jí ọmọ náà dìde kété lẹ́yìn tó kú.​—Lúùkù 8:​41, 42, 49-56.

      Lásárù, ọ̀rẹ́ Jésù àtàtà Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú, Jésù jí i dìde níṣojú gbogbo àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀.​—Jòhánù 11:​38-44.

      Dọ̀káàsì Àpọ́sítélì Pétérù jí obìnrin ọ̀wọ́n yìí dìde. Aláàánú èèyàn ni wọ́n mọ obìnrin yìí sí.​—Ìṣe 9:​36-42.

      Yútíkọ́sì Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì kú nígbà tó jábọ́ látojú wíńdò; àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì jí i dìde.​—Ìṣe 20:​7-12.

      b Àjíǹde tó ṣe pàtàkì jù ni ti Jésù Kristi fúnra rẹ̀. Àjíǹde tirẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo àwọn mẹ́jọ tá a sọ yìí. A máa rí bó ṣe jẹ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

  • Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

      Ǹjẹ́ Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Ti Kú?

      Ṣé àwọn òkú lè jíǹde?

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”​—Jòhánù 5:​28, 29.

      Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé Sàréè máa ṣófo lábẹ́ Ìjọba òun lọ́jọ́ iwájú. Fernando tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Ẹnu yà mí nígbà àkọ́kọ́ tí mo ka Jòhánù 5:​28, 29, ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kí n ní ìrètí, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”

      Láyé ìgbàanì, ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù ní ìrètí pé Ọlọ́run máa jí òun dìde tí òun bá kú. Jóòbù béèrè pé: ‘Bí ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?’ Òun fúnra rẹ̀ wá fi ìdánilójú dáhùn pé: “Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo [nínú Sàréè] ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé. Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.”​—Jóòbù 14:​14, 15.

      Lásárù gbá arábìnrin rẹ̀ mọ́ra lẹ́yìn tó jíǹde

      Àjíǹde Lásárù jẹ́ ká ní ìrètí pé àwọn òkú máa jíǹde

      Ọ̀rọ̀ àjíǹde kì í ṣe nǹkan tuntun sí Màtá arábìnrin Lásárù. Nígbà tí Lásárù kú, Jésù sọ fún un pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Màtá dáhùn pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Jésù wá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:​23-25) Lẹ́yìn náà, Jésù jí Lásárù dìde. Ìtàn yìí jẹ́ ká mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Fojú inú wo bó ṣe máa rí nígbà tí Jésù bá jí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kú dìde!

      Ṣé àwọn kan máa jíǹde sí ọ̀run?

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àjíǹde Jésù yàtọ̀ sí tàwọn mẹ́jọ yòókù tó wà nínú Bíbélì. Àwọn mẹ́jọ yìí jíǹde pa dà sáyé. Àmọ́ ní ti àjíǹde Jésù, Bíbélì sọ pé: “Jésù Kristi . . . wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, nítorí tí ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀run.” (1 Pétérù 3:​21, 22) Ṣé Jésù nìkan ló máa jíǹde sí ọ̀run? Ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.”​—Jòhánù 14:3.

      Kristi lọ sí ọ̀run láti lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún díẹ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó ń bọ̀. Iye àwọn tó máa jíǹde sí ọ̀run jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. (Ìṣípayá 14:​1, 3) Ṣùgbọ́n, kí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù yìí fẹ́ máa ṣe lọ́run?

      Iṣẹ́ ńlá ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe! Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ àti mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní; ikú kejì kò ní àṣẹ kankan lórí àwọn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6) Àwọn tó máa jíǹde sí ọ̀run máa jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi, wọ́n sì máa ṣàkóso ayé.

      Àwọn wo ló máa jíǹde lẹ́yìn náà?

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú Bíbélì pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìrètí tí àwọn ọkùnrin yìí pẹ̀lú ní, pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”​—Ìṣe 24:15.

      Nínú párádísè ọjọ́ iwájú, obìnrin kan gbá ọmọ tó ṣẹ̀sẹ̀ jíǹde mọ́ra

      Bíbélì jẹ́ kó dáwa lójú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti kú máa jíǹde

      Àwọn wo ló máa wà lára “àwọn olódodo” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Dáníẹ́lì ọkùnrin olóòótọ́ kú, áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún un pé: “Ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:13) Ibo ni Dáníẹ́lì máa jíǹde sí? Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:⁠5) Dáníẹ́lì àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì máa gbébẹ̀ títí láé.

      Àwọn wo ló máa wà lára “àwọn aláìṣòdodo” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn? Àwọn ni ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọn ò láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà láàyè. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n á láǹfààní láti mọ Jèhófàa àti Jésù, kí wọ́n sì fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run làwọn máa sẹ. (Jòhánù 17:3) Àwọn tó bá yàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà títí lọ kánrin lórí ilẹ̀ ayé, bí Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣe wà títí láé.

      Àwọn tó bá yàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà títí lọ kánrin lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n máa láyọ̀, ìlera wọn sì máa dáa

      Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé?

      OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) “Wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.”​—Aísáyà 65:21.

      Fojú inú wo bó ṣe máa dùn tó kó o máa gbé ní irú ipò yìí pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n ti jíǹde! Àmọ́, ìbéèrè kan ni pé, Kí ló máa mú kó dá ọ lójú pé àjíǹde máa wáyé lóòótọ́?

      a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

  • Bó Ṣe Lè Dá Ẹ Lójú Pé Àwọn Òkú Máa Jíǹde
    Ilé Ìṣọ́—2015 | August 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

      Bó Ṣe Lè Dá Ẹ Lójú Pé Àwọn Òkú Máa Jíǹde

      Ṣé àsọdùn ni kéèyàn sọ pé àwọn òkú máa jíǹde? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò gbà pé àsọdùn ni ọ̀rọ̀ yẹn. Ọlọ́run mí sí i láti sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ni ó yẹ láti káàánú jù lọ nínú gbogbo ènìyàn. Àmọ́ ṣá o, nísinsìnyí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” (1 Kọ́ríńtì 15:​19, 20) Jésù fúnra rẹ̀ jíǹde, èyí sì mù kó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé àjíǹde àwọn òkú máa wáyé.a (Ìṣe 17:31) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi pe Jésù ní “àkọ́so”​—nítorí pé òun lẹni àkọ́kọ́ tó jíǹde sí ìyè ayérayé. Tí Jésù bá jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó jíǹde sí ọ̀run, á jẹ́ pé àwọn míì ṣì wà tó máa jíǹde.

      Obìnrin kan ṣí Bíbélì sọ́wọ́, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ bó ṣe ń wo ọ̀ọ́kán

      Jóòbù sọ fún Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”​—Jóòbù 14:​14,15

      Ẹ̀rí míì tún wà tá á mú kó dáwa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde. Ìyẹn ni pé Ọlọ́run òtítọ́ ni Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” (Títù 1:⁠2) Jèhófà kò purọ́ ri, kò sì le purọ́ láé. Ó tiẹ̀ tún fi hàn wá pé òun lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé Ọlọ́run máa wá ṣe ìlérí pé òun máa jí àwọn òkú dìde, kó má sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀!

      Kí nìdí tí Jèhófà fi pinnu láti jí àwọn òkú dìde? Ó jẹ́ nítorí ìfẹ́ tó ní fún wa. Jóòbù béèrè pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Jóòbù fúnra rẹ̀ wá dáhùn pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:​14, 15) Ó dá Jóòbù lójú pé ó wu Bàbá wa ọ̀run láti jí òun dìde. Ṣé Ọlọ́run ti wá yí pa dà ni? Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn òkú jíǹde, kí wọ́n ní ìlera tó dáa, kí wọ́n sì láyọ̀. Bó ṣe máa wu òbí tó pàdánù ọmọ rẹ̀ láti rí ọmọ náà pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń wu Ọlọ́run láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé Ọlọ́run ní agbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́.​—Sáàmù 135:6.

      Ikú ń hàn wá léèmọ̀, àmọ́ Ọlọ́run máa tó mú un kúrò

      Jèhófà máa fún Jésù lágbára láti mú ayọ̀ wá fún gbogbo àwọn tó ti pàdánù èèyàn wọn. Báwo ni ọ̀rọ̀ àjíǹde ṣe rí lára Jésù? Ṣáájú kó tó jí Lásárù dìde, ó rí ìbànújẹ́ tó bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Lásárù, èyí sì mú kó sunkún. (Jòhánù 11:35) Nígbà kan, Jésù pàdé opó Náínì tó pàdánù ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí. “Àánú rẹ̀ ṣe [Jésù], ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’” Lẹ́yìn náà, ó jí ọmọ rẹ̀ dìde. (Lúùkù 7:13) Èyí fi hàn pé ó máa ń dun Jésù láti rí ìbànújẹ́ tí ikú ń fà. Ẹ ò rí i pé inú rẹ̀ máa dùn púpọ̀ nígbà tó bá sọ ìbànújẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn di ayọ̀!

      Ọkùnrin kan gbá ọmọbìnrin rẹ̀ mọ́ra

      Ǹjẹ́ o ti pàdánù èèyàn rẹ kan rí? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò ní rí ẹni náà mọ́. Ṣùgbọ́n jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa lo Ọmọ rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde. Ó fẹ́ kó o rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú, kó o sì wà níbẹ̀ láti kí wọn nígbà tí wọ́n bá jíǹde. Fojú inú wo bí ìgbà yẹn ṣe máa dùn tó fún ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ láìbẹ̀rù pé ikú lè mú ẹnikẹ́ni lọ!

      Lionel, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Nígbà tó yá, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àjíǹde. Mi ò kọ́kọ́ gbà gbọ́ pé àjíǹde máa wà, mo tiẹ̀ rò pé ẹni tó ń kọ́ mi fẹ́ ṣì mí lọ́nà ni. Àmọ́, ìgbà tí mo rí i nínú Bíbélì ni mo tó gbà pé òótọ́ ni. Ní báyìí, mò ń fojú sọ́nà láti rí bàbá ìyá mi lẹ́ẹ̀kan sí i.”

      Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti fi hàn ẹ́ nínú Bíbélì rẹ ìdí tá a fi gbà pé àjíǹde máa wà lọ́jọ́ iwájú.b

      a Fún àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù jíǹde, wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 2013, ojú ìwé 3-6. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

      b Wo orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́