-
Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà Apá KìíníIlé Ìṣọ́—2015 | June 15
-
-
Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà Apá Kìíní
“Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—MÁT. 6:9.
1. Báwo la ṣe lè lo àdúrà tó wà nínú Mátíù 6:9-13 lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló lè ka Àdúrà Olúwa láìwo ìwé. Nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, a sábà máa ń tọ́ka sí àdúrà yìí káwọn èèyàn lè mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ṣe é fọkàn tán, òun ló sì máa mú àyípadà rere bá ilẹ̀ ayé. Nígbà míì sì rèé, a lè tọ́ka sí apá àkọ́kọ́ nínú àdúrà náà ká lè fi hàn pé Ọlọ́run ní orúkọ kan, èyí tó yẹ kó di mímọ́, a ò sì gbọ́dọ̀ tàbùkù sí i.—Mát. 6:9.
2. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò ní in lọ́kàn pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ àdúrà àwòṣe náà léraléra ní gbogbo ìgbà tá a bá ń gbàdúrà?
2 Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé ká máa sọ ọ̀rọ̀ inú àdúrà yìí léraléra ní gbogbo ìgbà tá a bá ti ń gbàdúrà, bí ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń ṣe lónìí? Rárá o. Ṣáájú kí Jésù tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní àdúrà àwòṣe yìí, ó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mát. 6:7) Ní àkókò mìíràn, Jésù tún gba àdúrà yìí, àmọ́ ó lo àwọn ọ̀rọ̀ míì. (Lúùkù 11:1-4) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ àwọn ohun tá a lè béèrè nínú àdúrà wa, ká sì mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù. Torí náà, àdúrà àwòṣe gan-an ló yẹ ká máa pè é.
3. Àwọn ìbéèrè wo la lè ronú lé lórí bá a ṣe ń jíròrò àdúrà àwòṣe náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò àdúrà àwòṣe náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni àdúrà àwòṣe yìí ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ kí àdúrà tèmi náà lè sunwọ̀n sí i? Ní pàtàkì, ǹjẹ́ mo tiẹ̀ ń gbé ìgbé ayé mi lọ́nà tó bá àdúrà náà mu?’
“BABA WA TÍ Ń BẸ NÍ Ọ̀RUN”
4. Kí ni gbólóhùn náà “Baba wa” rán wa létí, ọ̀nà wo sì ni Jèhófà gbà jẹ́ “Baba” fún àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé?
4 Jésù kò sọ pé “Baba mi,” àmọ́ ó sọ pé “Baba wa.” Èyí rán wa létí pé a jẹ́ apá kan “ẹgbẹ́ àwọn ará,” tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (1 Pét. 2:17) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́! Ó tọ́ ní ti gidi bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe pe Jèhófà ní “Baba” wọn torí pé Ọlọ́run ti gbà wọ́n ṣọmọ, wọ́n sì nírètí láti lọ gbé ní ọ̀run. (Róòmù 8:15-17) Bákan náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé náà lè pe Jèhófà ní “Baba.” Òun ni Olùfúnni-ní-ìyè wọn, ó sì máa ń fìfẹ́ pèsè ohun tí gbogbo àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn rẹ̀ nílò fún wọn. Àwọn tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò di ọmọ Ọlọ́run ní ti gidi lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá di ẹ̀dá pípé, tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò ìkẹyìn.—Róòmù 8:21; Ìṣí. 20:7, 8.
5, 6. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye wo ni àwọn òbí lè fún àwọn ọmọ wọn, báwo ló sì ṣe yẹ kí ọmọ kọ̀ọ̀kan lo ẹ̀bùn náà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
5 Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye làwọn òbí ń fún àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi Baba wọn ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Arákùnrin kan tó ti wá di alábòójútó àyíká báyìí ní orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Láti ọjọ́ tá a ti bí àwọn ọmọbìnrin wa la ti máa ń gbàdúrà pa pọ̀ ní alaalẹ́ àyàfi ọjọ́ tí mi ò bá sí nílé. Àwọn ọmọ wa sábà máa ń sọ pé àwọn ò rántí àwọn ọ̀rọ̀ pàtó tí à ń sọ nínú àdúrà alaalẹ́ náà. Àmọ́, wọn ò gbàgbé bó ṣe máa ń rí, bí àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà, Baba wa ṣe jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀ tó àti bí ara ṣe máa ń tù wọ́n tí ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀. Gbàrà tí wọ́n ti lè gbàdúrà ni mo ti máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà sókè kí n lè gbọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èrò ọkàn wọn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn fún Jèhófà. Àǹfààní ńlá lèyí jẹ́ fún mi kí n lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Lẹ́yìn náà, mo lè wá máa fọgbọ́n kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fi àwọn ohun pàtàkì látinú àdúrà àwòṣe náà kún àdúrà wọn kí wọ́n lè ti kékeré mọ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà tó nítumọ̀.”
6 Abájọ tí àwọn ọmọ arákùnrin náà fi tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí. Wọ́n ti lọ sílé ọkọ báyìí, wọ́n ń láyọ̀, àwọn àtàwọn ọkọ wọn sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ẹ̀yin òbí, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tẹ́ ẹ lè fún àwọn ọmọ yín ni pé kẹ́ ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ọwọ́ olúkúlùkù wọn ló wá kù sí láti máa ṣìkẹ́ àjọṣe iyebíye tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà yìí. Èyí ní nínú kíkọ́ wọn bí wọ́n á ṣe nífẹ̀ẹ́ orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un.—Sm. 5:11, 12; 91:14.
“KÍ ORÚKỌ RẸ DI SÍSỌ DI MÍMỌ́”
7. Àǹfààní wo làwa èèyàn Ọlọ́run ní, àmọ́ kí ló gba pé ká ṣe?
7 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa pé a ò kàn mọ orúkọ Ọlọ́run nìkan, a tún ń jẹ́ orúkọ náà gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 15:14; Aísá. 43:10) À ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run pé: “Kí orúkọ [rẹ̀] di sísọ di mímọ́.” Ẹ̀bẹ̀ yìí lè mú kó o sọ fún Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o máa bàa sọ tàbí ṣe ohunkóhun tó máa tàbùkù sí orúkọ rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́. A ò fẹ́ dà bí àwọn kan ní ọ̀rúndún kìíní tí ìwà wọn yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n ń wàásù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé: “Orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”—Róòmù 2:21-24.
8, 9. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.
8 A fẹ́ sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọkọ arábìnrin kan kú lójijì lórílẹ̀-èdè Norway, arábìnrin náà ní láti máa dá tọ́ ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún méjì. Ó sọ pé: “Nǹkan nira fún mi gan-an lákòókò yẹn. Mò ń gbàdúrà lójoojúmọ́, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé wákàtí wákàtí ni mò ń gbàdúrà torí pé mi ò fẹ́ ṣe ohun tó máa fún Sátánì láyè láti ṣáátá Jèhófà, torí náà, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun kí n lè ronú lọ́nà tó tọ́, kí n má bàa ṣe ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání tàbí kí n hùwà àìṣòótọ́. Mo fẹ́ sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, mo sì fẹ́ kí ọmọ mi rí bàbá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i nínú Párádísè.”—Òwe 27:11.
9 Arábìnrin yìí fi hàn nínú àdúrà rẹ̀ pé òun fi ti Jèhófà ṣáájú. Ǹjẹ́ Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ó rí ìrànlọ́wọ́ gbà bó ṣe ń péjọ déédéé pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ó fẹ́ alàgbà kan. Ọmọkùnrin rẹ̀ ti pé ọmọ ogún ọdún báyìí, ó sì ti ṣèrìbọmi. Arábìnrin náà sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé ọkọ mi kà á sí ọmọ rẹ̀ gan-an, ó sì bá mi tọ́ ọ.”
10. Kí la nílò kí orúkọ Ọlọ́run tó lè di mímọ́ pátápátá?
10 Kí la nílò kí orúkọ Ọlọ́run tó lè di mímọ́ pátápátá, tí kò sì ní sí ẹ̀gàn kankan lórí orúkọ rẹ̀ mọ́? Kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀, ó pọn dandan pé kí Jèhófà mú gbogbo àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ kẹ̀yìn sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ kúrò. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:22, 23.) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, aráyé yóò di ẹ̀dá pípé. À ń fojú sọ́nà fún àkókò kan tí gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì yóò máa ṣe ohun tó fi hàn pé orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́! Nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ yóò “jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́r. 15:28.
“KÍ ÌJỌBA RẸ DÉ”
11, 12. Ìlàlóye wo ni Jèhófà fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ bí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ti ń parí lọ?
11 Kó tó di pé Jésù pa dà sókè ọ̀run, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba náà padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” Ìdáhùn tí Jésù fún wọn fi hàn pé kò tíì tó àkókò fún wọn láti mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ náà, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù. (Ka Ìṣe 1:6-8.) Síbẹ̀, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa retí ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé. Torí náà, láti ọjọ́ àwọn àpọ́sítélì ni àwọn Kristẹni ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé.
12 Nígbà tí àkókò náà tó tí Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Jésù jẹ́ Ọba rẹ̀, máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láti ọ̀run, Jèhófà jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ lóye àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan máa wáyé. Lọ́dún 1876, Arákùnrin Charles Taze Russell gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn Bible Examiner. Àkòrí àpilẹ̀kọ náà ni, “Àwọn Àkókò Kèfèrí: Ìgbà Wo Ni Wọ́n Dópin?,” èyí sì ń tọ́ka sí ọdún 1914 pé ó jẹ́ ọdún mánigbàgbé. Àpilẹ̀kọ náà jẹ́ ká mọ bí “ìgbà méje” tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ṣe kan “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” tí Jésù sọ.a—Dán. 4:16; Lúùkù 21:24.
13. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1914, kí sì ni àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé láti ìgbà yẹn fi ẹ̀rí ẹ̀ múlẹ̀?
13 Lọ́dún 1914, àwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jagun, ogun yẹn sì tàn kárí ayé. Ìgbà tó fi máa kásẹ̀ nílẹ̀ lọ́dún 1918, oúnjẹ ti di góòlù, àrùn gágá sì tún fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò débi pé iye tí àìsàn náà pa ju iye àwọn tí ogun pa lọ. Torí náà, “àmì” tí Jésù sọ pé ó máa jẹ́ ẹ̀rí wíwàníhìn-ín òun tí a kò lè fojú rí gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun, èyí tí yóò ṣàkóso lórí ayé ti bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ. (Mát. 24:3-8; Lúùkù 21:10, 11) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé ọdún 1914 ni ìgbà tí Ọlọ́run “fún” Jésù Kristi Olúwa “ní adé.” Torí náà, ó “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣí. 6:2) Kó lè fọ ọ̀run mọ́, ó bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun, ó sì lé wọn dà nù sí orí ilẹ̀ ayé. Látìgbà yẹn, àwọn ẹ̀dá èèyàn ti gbà pẹ̀lú ohun tí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí sọ, pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣí. 12:7-12.
14. (a) Kí nìdí tó tún fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà kí Ìjọba Ọlọ́run dé? (b) Kí la láǹfààní láti ṣe?
14 Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 12:7-12 ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé ìgbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ bọ́ sí ìgbà kan náà tí àjálù lọ́kan-ò-jọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí í han aráyé léèmọ̀. Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. Títí dìgbà tó fi máa parí ìṣẹ́gun rẹ̀, táá sì mú òpin dé bá ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé, a óò máa bá a nìṣó láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Lẹ́sẹ̀ kan náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ sọ, lọ́nà wo? Ká máa kópa nínú apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú “àmì” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:14.
“KÍ ÌFẸ́ RẸ ṢẸ . . . LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ”
15, 16. Báwo la ṣe lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà wa mu pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé?
15 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ lórí ilẹ̀ ayé. Abájọ tí Jèhófà fi wo àwọn ohun rere tó ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn tó wá sọ pé: “Ó dára gan-an ni.” (Jẹ́n. 1:31) Nígbà tó yá, Sátánì di ọlọ̀tẹ̀, látìgbà yẹn sì rèé, ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ lóde òní, àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń gbé lásìkò tí iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́jọ. Gbogbo wọn ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì tún ń sapá láti gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà náà. Wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n sì ń kópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù.
Ǹjẹ́ ò ń ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé? (Wo ìpínrọ̀ 16)
16 Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1948, tó sì ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà sọ pé: “Tí mo bá fẹ́ gbàdúrà nípa kókó yìí nínú àdúrà àwòṣe, mo sábà máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kí á lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ẹni bí àgùntàn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kó tó pẹ́ jù. Bákan náà, tí mo bá fẹ́ wàásù fún ẹnì kan, mo máa ń béèrè fún ọgbọ́n kí n lè dénú ọkàn ẹni náà. Mo sì tún máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà máa bù kún ìsapá wa ká lè máa bójú tó àwọn ẹni bí àgùntàn tá a ti rí.” Abájọ tí arábìnrin ẹni ọgọ́rin [80] ọdún yìí fi ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn àwọn ará míì, ó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láìsí àní-àní, ìwọ náà lè ronú kan àpẹẹrẹ rere àwọn míì tí wọ́n fi gbogbo okun wọn ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bí ọjọ́ ogbó ò tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀.—Ka Fílípì 2:17.
17. Kí lèrò rẹ̀ nípa ohun tí Jèhófà máa tó ṣe láti fi dáhùn àdúrà wa pé kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé?
17 Títí dìgbà tí Ọlọ́run yóò fi pa àwọn ọ̀tá Ìjọba náà run kúrò lórí ilẹ̀ ayé, a óò máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, a óò rí bí ìfẹ́ Ọlọ́run yóò ṣe nímùúṣẹ lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ nígbà tí bílíọ̀nù àwọn òkú bá jí dìde. Jésù sọ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [mi], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòh. 5:28, 29) Ẹ ò rí i pé àsìkò aláyọ̀ ló máa jẹ́ fún wa nígbà tá a bá ń kí àwọn èèyàn wa tó ti kú káàbọ̀! Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa].” (Ìṣí. 21:4) Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó bá jíǹde nígbà yẹn máa jẹ́ “àwọn aláìṣòdodo,” ìyẹn àwọn tó gbé láyé tí wọ́n sì kú láìmọ òtítọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Àǹfààní ló máa jẹ́ fún wa láti jẹ́ kí àwọn tó bá jíǹde mọ ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tóótun láti jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.”—Ìṣe 24:15; Jòh. 17:3.
18. Kí ni ohun táwa ẹ̀dá èèyàn nílò jù lọ?
18 Ìjọba Ọlọ́run tó máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nìkan ló máa mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan dé bá gbogbo ayé. Torí náà, ìdáhùn sí ìbéèrè mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú àdúrà àwòṣe náà ló máa jẹ́ kí ọwọ́ aráyé tẹ ohun tí wọ́n nílò jù lọ. Àwọn ohun míì ṣì wà tó ṣe pàtàkì tí Jésù mẹ́nu kàn nínú apá mẹ́rin tó kù nínú àdúrà àwòṣe náà. A máa jíròrò wọn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
a Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i lórí bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ ní ọdún 1914, ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀, wo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ojú ìwé 215 sí 218.
-
-
Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà Apá KejìIlé Ìṣọ́—2015 | June 15
-
-
Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà Apá Kejì
“Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní.”—MÁT. 6:8.
1-3. Kí nìdí tó fi dá arábìnrin kan lójú pé Jèhófà mọ ohun tí a nílò?
ARÁBÌNRIN Lana kò jẹ́ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2012 ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Ó mọ̀ pé Jèhófà dáhùn àdúrà méjì kan tí òun gbà. Inú ọkọ̀ ojú irin tó ń lọ sí pápákọ̀ òfuurufú ló ti gbàdúrà àkọ́kọ́ pé kí Jèhófà jẹ́ kí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún òun láti wàásù. Nígbà tó dé pápákọ̀ òfuurufú, ó gbọ́ pé ọkọ̀ òfuurufú tó máa gbé òun kò ní lọ mọ́ lọ́jọ́ yẹn, ó di ọjọ́ kejì. Lana tún gbàdúrà sí Jèhófà, torí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ná owó tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tán, kò sì sí ibi tó máa sùn sí di ọjọ́ kejì.
2 Kódà Lana ò tíì parí àdúrà tó ń gbà tó fi gbọ́ tẹ́nì kan sọ pé, “Lana, ìwọ nìyẹn, kí lò ń ṣe níbí?” Ọkùnrin kan tí òun àti Lana jọ lọ sí ilé ìwé nígbà kan rí ló ń bá a sọ̀rọ̀. Ọkùnrin náà ń lọ sí orílẹ̀-èdè South Africa, ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà sìn ín wá wọ ọkọ̀ òfuurufú. Nígbà tí Lana sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ìyá ọkùnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elke sọ fún Lana pé kó wá sùn sí ilé àwọn. Elke àti ìyá rẹ̀ ṣe Lana lálejò, wọ́n sì ń bi í ní ìbéèrè nípa ohun tó gbà gbọ́ àti iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó ń ṣe.
3 Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ aládùn kan tán, Lana tún bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn àwọn ìbéèrè míì látinú Bíbélì, ó wá gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù wọn kí ó lè ṣètò bí wọ́n á ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lana dé ilé láyọ̀, ó sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà rẹ̀ nìṣó. Ó mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” lọ́wọ́ sí bí gbogbo nǹkan ṣe yọrí sí rere.—Sm. 65:2.
4. Àwọn ohun tá a nílò wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Kì í ṣòro fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà tí a bá ṣàdédé bá ara wa nínú ìṣòro, inú Jèhófà sì máa ń dùn láti gbọ́ irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ gbà. (Sm. 34:15; Òwe 15:8) Àmọ́ tá a bá ronú lórí àdúrà àwòṣe náà, a lè rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì wà tá à ń gbójú fò. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí i pé apá mẹ́ta tó kẹ́yìn nínú àdúrà àwòṣe náà dá lórí àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan ṣì wà tí a lè ṣe ká lè máa gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí apá kẹrin àdúrà náà sọ pé ká bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ òòjọ́ wa?—Ka Mátíù 6:11-13.
“FÚN WA LÓNÌÍ OÚNJẸ WA FÚN ỌJỌ́ ÒNÍ”
5, 6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní, ká tiẹ̀ sọ pé a ní ohun tó pọ̀ tó nípa tara?
5 Ẹ kíyè sí i pé ìbéèrè ara ẹni yìí kì í wulẹ̀ ṣe pé fún “mi” ní oúnjẹ fún ọjọ́ òní, àmọ́ fún “wa” ní oúnjẹ fún ọjọ́ òní. Alábòójútó àyíká kan nílẹ̀ Áfíríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victor sọ pé: “Mo sábà máa ń fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti ìyàwó mi kì í dààmú lórí ohun tá a máa jẹ tàbí bá a ṣe máa rí owó ilé san. Àwọn ará ló máa ń fìfẹ́ bójú tó wa lójoojúmọ́. Àmọ́, mo máa ń gbàdúrà pé kí àwọn tó ń ràn wá lọ́wọ́ lè rí ọ̀nà láti bójú tó ìṣúnná owó wọn.”
6 Tá a bá ní oúnjẹ tó pọ̀ tó láti jẹ fáwọn ìgbà kan, a lè ronú kan àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ṣaláìní tàbí àwọn tí ìjábá ti ba nǹkan ìní wọn jẹ́. Kì í ṣe pé ká kàn gbàdúrà fún wọn nìkan, àmọ́ ká tún ṣe ohun tó bá àdúrà náà mu. Bí àpẹẹrẹ, a lè fún àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí wọ́n ṣaláìní látinú ohun tá a ní. Bákan náà, a lè máa fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé déédéé, bá a ṣe mọ̀ pé a máa ń lo irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó yẹ.—1 Jòh. 3:17.
7. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣàpèjúwe ìmọ̀ràn tó fún wa pé ká “má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la”?
7 Nígbà tí Jésù mẹ́nu kan oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ohun tá a nílò lójú ẹsẹ̀ ló ní lọ́kàn. Torí náà, ó sọ̀rọ̀ lórí bí Ọlọ́run ṣe ń wọ àwọn òdòdó pápá láṣọ, ó wá sọ pé: “Òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré? Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, . . . ‘Kí ni a ó wọ̀?’” Ó fún wa ní ìmọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì láti fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la.” (Mát. 6:30-34) Èyí fi hàn pé, kàkà tá a fi máa to àwọn nǹkan ìní tara jọ, ńṣe ló yẹ ká ní ìtẹ́lọ́rùn tá a bá ti ní àwọn ohun kòṣeémáàní ojoojúmọ́. Lára rẹ̀ ní ilé tó bójú mu, iṣẹ́ táá jẹ́ ká lè máa pèsè fún àwọn ìdílé wa àti bá a ṣe lè máa fọgbọ́n lo ìlera wa. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan ìní tara yẹn nìkan lá ń sọ nínú àdúrà wa, á jẹ́ pé tara wa nìkan la mọ̀ nìyẹn. Àmọ́ o, àwọn nǹkan kan wà tá a nílò nípa tẹ̀mí tí wọ́n ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ.
8. Ohun pàtàkì tá a nílò wo ni Jésù rán wa létí rẹ̀ bó ṣe mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ oúnjẹ òòjọ́ wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
8 Bí Jésù ṣe mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ oúnjẹ òòjọ́ wa yẹ kó rán wa létí pé a nílò oúnjẹ tẹ̀mí. Jésù Ọ̀gá wa sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún wa.
“DÁRÍ ÀWỌN GBÈSÈ WA JÌ WÁ”
9. Ọ̀nà wo ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà jẹ́ “gbèsè”?
9 Kí nìdí tí Jésù fi lo ọ̀rọ̀ náà “gbèsè,” nígbà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” ló lò nígbà míì tó ń sọ̀rọ̀? (Mát. 6:12; Lúùkù 11:4) Ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin Ọlọ́run mú ká jẹ Ọlọ́run ní gbèsè. . . . Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, Ọlọ́run lè gba ẹ̀mí wa. . . . Ó lè mú àlááfíà rẹ̀ kúrò lára wa, kó sì já gbogbo àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ kúrò. . . . A jẹ ẹ́ ní gbèsè ìfẹ́, ìgbọ́ràn wa ló sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀; tí a bá wá dá ẹ̀ṣẹ̀, a ti kùnà láti san gbèsè ìfẹ́ wa fún un nìyẹn, kò sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí a bá ń dá ẹ̀ṣẹ̀.”—1 Jòh. 5:3.
10. Kí ló lè mú kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí rí lára wa?
10 Nítorí pé a ní láti máa tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lójoojúmọ́, Ọlọ́run pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù tó jẹ́ ìlànà kan ṣoṣo tó bá òfin mu tí Jèhófà lè fi pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún tí ìràpadà náà ti wáyé, ó yẹ ká mọrírì rẹ̀ bí ẹni pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i gbà lónìí. “Iye owó ìtúnràpadà” tí Jésù san “ṣe iyebíye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” tó fi jẹ́ pé kò sí ohunkóhun tí ẹ̀dá èèyàn aláìpé èyíkéyìí lè ṣe fún wa tó lè sún mọ́ àtisan ìràpadà náà. (Ka Sáàmù 49:7-9; 1 Pétérù 1:18, 19.) Torí náà, ńṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn bàǹtàbanta yìí nígbà gbogbo. Bákan náà, gbólóhùn náà “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,” dípò “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi” yẹ kó máa rán wa létí pé gbogbo àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ni ìpèsè onífẹ̀ẹ́ yìí wúlò fún. Ó ṣe kedere pé, Jèhófà kò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ipò tẹ̀mí tara wa nìkan jẹ wá lógún, ó fẹ́ ká ro ti àwọn ẹlòmíì náà, títí kan àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣẹ̀ wá. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í tó nǹkan. Torí náà, àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa àti pé a múra tán láti dárí jì wọ́n, bí Ọlọ́run náà ṣe ń fi àánú hàn sí wa tó sì ń dárí jì wá.—Kól. 3:13.
Tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì ẹ́, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn ẹlòmíì (Wo ìpínrọ̀ 11)
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ẹ̀mí ìdáríjini?
11 Torí a jẹ́ aláìpé, ó ṣeni láàánú pé nígbà míì a máa ń di àwọn èèyàn sínú. (Léf. 19:18) Tá a bá lọ ro ẹjọ́ fáwọn ẹlòmíì, wọ́n lè gbè sẹ́yìn wa, ìyẹn sì lè fa ìpínyà nínú ìjọ. Tí a bá fàyè gba irú ẹ̀mí yìí, ńṣe là ń fi hàn pé a kò mọrírì àánú Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ìràpadà náà nìyẹn. Tí a kò bá ní ẹ̀mí ìdáríjini, Baba wa kò ní jẹ́ kí ìtóye ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ fún wa mọ́. (Mát. 18:35) Jésù túbọ̀ ṣàlàyé lórí kókó yìí ní gbàrà tó sọ àdúrà àwòṣe náà tán. (Ka Mátíù 6:14, 15.) Paríparí rẹ̀, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa kí á má ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì dàṣà. Ní báyìí, tó ti wù wá láti máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀, àdúrà ẹ̀bẹ̀ míì ló tún kàn.—1 Jòh. 3:4, 6.
“MÁ SÌ MÚ WA WÁ SÍNÚ ÌDẸWÒ”
12, 13. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù kété tó ṣèrìbọmi tán? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí á máa di ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíì tó bá ṣẹlẹ̀ pé a kó sínú ìdẹwò? (d) Kí ni Jésù fi hàn bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú?
12 Tá a bá ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù kété tó ṣèrìbọmi tán, a óò lóye ìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà pé: “Má . . . mú wa wá sínú ìdẹwò.” Ẹ̀mí Ọlọ́run ṣamọ̀nà Jésù lọ sínú aginjù. Kí nìdí? “Kí Èṣù lè dẹ ẹ́ wò.” (Mát. 4:1; 6:13) Ǹjẹ́ ó yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu? Kò ní yà wá lẹ́nu tá a bá lóye ìdí tí Ọlọ́run fi rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé. Ìdí rẹ̀ ni pé kó wá yanjú ọ̀ràn tó jẹ yọ nígbà tí Ádámù àti Éfà kọ Ọlọ́run ní Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn ìbéèrè kan yọjú tó máa gba àkókò kó tó lè níyanjú. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àṣìṣe kankan wà nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá èèyàn ni? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dá èèyàn pípé fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, kódà bí “ẹni burúkú náà” tiẹ̀ ń fínná mọ́ ọn? Àti pé, gẹ́gẹ́ bí Sátánì ṣe sọ, ṣé nǹkan máa sàn fáwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n ò bá sí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:4, 5) Ó máa gba àkókò ká tó lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, àmọ́ ìdáhùn wọn máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì mọ̀ pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ.
13 Jèhófà jẹ́ mímọ́, torí náà, kò lè fi ibi dán ẹnikẹ́ni wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, Èṣù ni “Adẹniwò náà.” (Mát. 4:3) Èṣù lè hùmọ̀ àwọn ipò tó lè fi dẹ wá wò. Síbẹ̀, ó kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan, yálà a máa gbà kí Sátánì mú wa wá sínú ìdẹwò tàbí a ò ní gbà. (Ka Jákọ́bù 1:13-15.) Ní ti Jésù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu láti kọ ìdẹwò kọ̀ọ̀kan tí Sátánì gbé síwájú rẹ̀. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àmọ́ Sátánì ò jáwọ́ o. Ó dúró “títí di àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Síbẹ̀, Jésù ń bá a nìṣó láti máa dènà gbogbo ìsapá Sátánì láti mú kó di aláìṣòótọ́. Kristi fìdí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ múlẹ̀, ó sì fi hàn pé ẹ̀dá èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ kódà lójú àdánwò tó le koko jù lọ. Àmọ́ ṣá o, Sátánì ń dá gbogbo ọgbọ́n kó lè dẹkùn mú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, kò sì yọ ìwọ náà sílẹ̀.
14. Kí ló yẹ ká ṣe tí a kò bá fẹ́ kó sínú ìdẹwò?
14 Torí àríyànjiyàn tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ipò Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, Jèhófà fàyè gba Adẹniwò náà pé kó lo ayé yìí láti fi dẹ wá wò. Ọlọ́run kọ́ ló ń mú wa wá sínú ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fọkàn tán wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́ o, torí pé Jèhófà fún wa lómìnira láti yan òun tó wù wá, kì í dédé yọ wá ká máa bàa kó sínú ìdẹwò. A ní láti ṣe ohun méjì kan. Àkọ́kọ́ ni pé ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Ìkejì sì ni pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa?
Máa fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà, má sì jẹ́ kí ìtara rẹ jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù (Wo ìpínrọ̀ 15)
15, 16. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdẹwò tá a ní láti sá fún? (b) Ta ló yẹ ká dá lẹ́bi tí ẹnì kan bá kó sínú ìdẹwò?
15 Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára, tó lè fún wa nígboyà kó sì mú ká yàgò fún ìdẹwò. Ọlọ́run tún ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ láti kìlọ̀ fún wa ká lè mọ àwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún, irú bíi ká máa lo okun wa, owó àti àkókò tó pọ̀ jù lórí àwọn nǹkan ìní tara tí kò pọn dandan. Espen àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Janne ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù nílẹ̀ Yúróòpù. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní ibì kan lórílẹ̀-èdè náà tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bí àkọ́bí wọn, wọ́n fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀, wọ́n sì ti bí ọmọ kejì báyìí. Arákùnrin Espen sọ pé: “A máa ń gbàdúrà ní gbogbo ìgbà sí Jèhófà pé ká má ṣe kó sínú ìdẹwò ní báyìí tó jẹ́ pé a ò lè lo àkókò tó pọ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi ti ìgbà kan. A máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀, kí ìtara wa má sì jó rẹ̀yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.”
16 Ìdẹwò míì tó tún gbòde kan lóde òní ni wíwo àwòrán, fídíò tàbí gbígbọ́ àwọn orin tó ń mú kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe. Ǹjẹ́ a lè dá Sátánì lẹ́bi tá a bá kó sínú ìdẹwò yìí? Rárá o. Kí nìdí? Ìdí ni pé Sátánì àti ayé yìí ò lè fipá mú wa ṣe ohun tí kò wù wá. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìdẹwò yìí dẹkùn mú wọn torí pé wọ́n fàyè gba èròkerò lọ́kàn wọn. Àmọ́, ó dájú pé a lè sá fún un. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 10:12, 13.
“DÁ WA NÍDÈ KÚRÒ LỌ́WỌ́ ẸNI BURÚKÚ NÁÀ”
17. (a) Báwo la ṣe lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí Ọlọ́run dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà? (b) Ìtura wo ló dé tán?
17 Tí a bá fẹ́ gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àdúrà náà mu pé kí Ọlọ́run “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti má ṣe jẹ́ “apá kan ayé [Sátánì].” A kò gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ yálà ayé [Sátánì] tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” (Jòh. 15:19; 1 Jòh. 2:15-17) Èyí kì í ṣe ohun tá à ń ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo o, a gbọ́dọ̀ máa ṣe é ní gbogbo ìgbà. Ìtura gbáà ló máa jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá dáhùn àdúrà yìí tó sì mú Sátánì àti ayé rẹ̀ kúrò! Àmọ́, ẹ jẹ́ ká rántí pé nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, ó mọ̀ pé àkókò tí òun ní kéré gan-an. Pẹ̀lú ìbínú ló fi ń jà fitafita kó lè ba ìṣòtítọ́ wa jẹ́. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀.—Ìṣí. 12:12, 17.
18. Tá a bá fẹ́ la òpin ayé Sátánì yìí já, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe?
18 Ǹjẹ́ ó wù ọ́ kírú àsìkò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣojú rẹ? Tó bá wù ẹ́, máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kó sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó pèsè àwọn ohun tó o nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara fún ọ. Torí náà, pinnu pé wàá máa gbé ìgbé ayé rẹ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà àwòṣe náà.
-