ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | September 1
    • Obìnrin kan ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń lo kẹ̀kẹ́ tí wọ́n pàtẹ ìwé sí láti wàásù

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

      Ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      “Ó ti pẹ́ díẹ̀ tí mo ti mọ Mike. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Àmọ́ ẹ̀sìn yẹn máa ń jọ mí lójú. Ta ni Jèhófà? Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi ṣe ọdún? Irú ẹgbẹ́ wo ni Mike lọ ń ṣe yìí?”​—Becky, California, U.S.A.

      “Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn aládùúgbò mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo bi ara mi pé: ‘Kí ló ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Orúkọ ẹ̀sìn yẹn pàápàá jọ mí lójú!’”​—Zenon, Ontario, Canada.

      “Ohun tí èmi àti ìyàwó mi rò ni pé ńṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fẹ́ tojú bọ ọ̀rọ̀ wa torí pé a kì í sábà lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. A sì gbà pé tí àwọn ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀ ò bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wa, ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lásánlàsàn ló máa wá lè dáhùn rẹ̀?”​—Kent, Washington, U.S.A.

      “Kí n má parọ́, mi ò mọ nípa wọn, mi ò sì mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”​—Cecilie, Esbjerg, Denmark.

      Ó ṣeé ṣe kó o ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí wọ́n ti ń wàásù láti ilé-dé-ilé, tàbí kó o ti pàdé wọn níbi tí wọ́n pàtẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí, tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ọwọ́ ọ̀kan lára wọn lo ti gba ìwé ìròyìn tó ò ń kà yìí. Àmọ́, o lè máa wò ó pé, ta ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí pàápàá? O sì lè ní irú èrò tí àwọn tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ní.

      Tó o bá ní ìbéèrè tàbí tí ohun kan ń jẹ ẹ́ lọ́kàn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ta ló yẹ kó o bi? Báwo lo ṣe lè mọ ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Ibo ni wọ́n tí ń rí owó tí wọ́n fi ń tẹ ìwé tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ilé ìpàdé wọn? Kí nìdí tí wọ́n fi ń wá àwọn èèyàn lọ ilé wọn kí wọ́n lè wàásù fún wọn? Kí sì nìdí tí wọ́n fi ń pàtẹ ìwé síbi táwọn èèyàn pọ̀ sí?

      Cecilie tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Mo ka ohun tó pọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Oríṣiríṣi nǹkan ni mo ti gbọ́ nípa wọn, tó fi mọ àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn fi ń bà wọ́n jẹ́. Ìyẹn ló jẹ́ kí n máa fi ojú burúkú wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Àmọ́ nígbà tó yá, Cecilie béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìgbà yẹn ló tó mọ òkodoro òtítọ́ nípa wọn.

      Ṣé ìwọ náà fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? A rọ̀ ẹ́ pé kó o wádìí ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. Ó ṣe tán ẹnu oníkàn la ti ń gbọ́ pọ̀n-ún. (Òwe 14:15) A retí pé àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e máa jẹ́ kó o mọ irú ẹni tá a jẹ́ àti ohun tá a gbà gbọ́. Á sì tún jẹ́ kó o mọ ìdí tá a fi ń wàásù.

  • Irú Èèyàn Wo ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | September 1
    • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti onírúurú ẹ̀yà ń kí ara wọn nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

      Irú Èèyàn Wo ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      Ibi gbogbo ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà kárí ayé, a ò sì dara pọ̀ mọ́ àwùjọ ẹ̀sìn èyíkéyìí. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni orílé-iṣẹ́ wa wà, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè míì. Kódà, a ti lẹ́ ní mílíọ̀nù mẹ́jọ báyìí, a sì ń wàásù ní àwọn ilẹ̀ tó lé ní 230 kárí ayé. À ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”​—Mátíù 24:14.

      Ibi yòówù ká máa gbé, tọkàntọkàn la fi ń pa òfin ìlú mọ́. Síbẹ̀, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Ìdí ni pé à ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fún gbogbo Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” Torí náà, a kì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú tàbí ọ̀ràn ogun. (Jòhánù 15:19; 17:16) Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́lé, wọ́n fìyà jẹ àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì pa àwọn míì. Ìdí sì ni pé wọn ò dá sí ọ̀ràn ogun. Ẹnì kan tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù nílẹ̀ Jámánì nígbà kan sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níkàn ló lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn ò dá sí ọ̀ràn ogun nígbà ìjọba Násì.”

      “[Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ní ìwà ọmọlúwàbí. Wọn kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan, torí náà irú wọn là ń fẹ́ kó di ipò pàtàkì mu láwùjọ. Àmọ́, wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. . . . Wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, àmọ́ wọ́n gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro àwa èèyàn.”​—Ìwé ìròyìn Nová Svoboda, lórílẹ̀-èdè Czech Republic.

      Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé à ń dá tara wa ṣe o. Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé.” (Jòhánù 17:15) Torí náà, wàá rí i pé a máa ń lọ sí ibiṣẹ́, a máa ń lọ sí ọjà, a sì máa ń lọ sí ilé ìwé pẹ̀lú àwọn èèyàn tó wà níbi tá a bá ń gbé.

      ÀWỌN ILẸ̀ TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ PỌ̀ SÍ

      • Amẹ́ríkà 1,190,000

      • Mẹ́síkò 800,000

      • Brazil 770,000

      • Nàìjíríà 330,000

      • Ítálì 250,000

      • Japan 220,000

      Ìlú Ísírẹ́lì òde òní

      Wo fídíò yìí, Special Convention in Israel lórí ìkànnì www.jw.org. Nínú fídíò náà, wàá rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti Palẹ́sínì kò ṣe gba ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láyè láàárín wọn. (wo abẹ́ ABOUT US > CONVENTIONS)

  • Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | September 1
    • Tọkọtaya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

      Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́?

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) À ń lo Bíbélì láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá, ìlànà inú rẹ̀ sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.

      Bíbélì sọ pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run nìkan là ń jọ́sìn. À sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ fáwọn èèyàn torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀.​—Aísáyà 43:​10-12.

      Níwọ̀n bá a ti jẹ́ Kristẹni, a gbà gbọ́ pé Jésù “Ọmọ Ọlọ́run”a wá sí ayé, ó sì di Mèsáyà. (Jòhánù 1:​34, 41; 4:​25, 26) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run jí i dìde, ó sì pa dà sí ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:​3, 4) Lẹ́yìn náà, ó di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 11:15) Ìjọba yìí ló sì máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. (Dáníẹ́lì 2:44) Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:​11, 29.

      “Tí wọ́n bá ka Bíbélì, wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló ń bá àwọn sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá ní ìṣòro kan, wọ́n á ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe yanjú ìṣòro náà. . . . Wọ́n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè.”​—Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Benjamin Cherayath, nínú ìwé ìròyìn Münsterländische Volkszeitung lórílẹ̀-èdè, Germany

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ṣàwọn èèyàn láǹfààní láyé àtijọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lè ṣe wá láǹfààní lóde òní. (Aísáyà 48:​17, 18) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọwọ́ pàtàkì la fi mú àwọn ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì kìlọ̀ pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tó máa sọ ara wa di ẹlẹ́gbin, torí náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá, a kì í sì lo oògùn olóró. (2 Kọ́ríńtì 7:1) A tún máa ń yẹra fún àwọn àṣà tí Bíbélì kà léèwọ̀, irú bí ìmutípara, ìṣekúṣe àti olè jíja.​—1 Kọ́ríńtì 6:​9-11.

      a Bíbélì tún sọ pé Jésù ni “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run,” torí pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ dá.​—Jòhánù 3:18; Kólósè 1:​13-15.

      Àwọn obí rẹ́rìn-ín bí ọmọ wọn ṣe ṣí páálí ẹ̀bùn kan

      Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tá a gbà gbọ́ àti ìdí tí a kì í fi í ṣe ọdún tàbí gba ẹ̀jẹ̀ sára, lọ sórí ìkànnì www.jw.org/yo, wo abẹ́ NÍPA WA > ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń BÉÈRÈ.

  • Báwo la ṣe ń rówó bójú tó iṣẹ́ wa?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | September 1
    • Ẹnì kan fi owó sínú àpótí ọrẹ

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

      Báwo la ṣe ń rówó bójú tó iṣẹ́ wa?

      Lọ́dọọdún, a máa ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Bíbélì àti àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, a sì máa ń pín in fún àwọn èèyàn. A máa ń kọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti àwọn ibi ìtẹ̀wé, a sì ń bójú tó iṣẹ́ tó ń lọ níbẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìjọ sì tún máa ń ṣe ìpàdé ní àwọn ibi ìjọsìn tó bójú mu, tó sì mọ níwọ̀n, èyí tí à ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Báwo la ṣe ń rówó ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí?

      Ọrẹ tí àwọn èèyàn fínnú fíndọ̀ ṣe la fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ yìí. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Lọ́dún 1879, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tá à ń pè ní Ilé Ìṣọ́ báyìí sọ pé: “A gbà pé JÈHÓFÀ ni alátìlẹyìn ‘Zion’s Watch Tower,’ torí náà, ìwé ìròyìn yìí kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn fáwọn.” Ìlànà yẹn náà la ṣì ń tẹ̀ lé di báyìí.

      A máa ń fi ọrẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní tààràtà tàbí ká fi sínú àpótí ọrẹ tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́, a kì í gba ìdámẹ́wàá, a kì í gbégbá ọrẹ, a ò sì ń díye lé àwọn ìwé wa. A kì í gba owó fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìpàdé wa kì í gba owó, a ò sì ń gba owó tá a bá lọ kọ́ àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ títí kan àwọn tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í gba owó oṣù fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.

      “Ọrẹ táwọn èèyàn fínnú fíndọ̀ ṣe láwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń bójú tó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa ń pinnu iye tó máa fi ‘ṣètọrẹ’ fún iṣẹ́ Ọlọ́run àti ìgbà tó máa mú un wá.”​—Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, ọdún 2011

      A tún máa ń fi ọrẹ táwọn èèyàn ṣe ran àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Inú àwọn Kristẹni ìjímìjí máa ń dùn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní. (Róòmù 15:26) A máa ń bá àwọn tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí tún ilé àti ibi ìjọsìn wọn ṣe. A máa ń fún wọn lóúnjẹ àti aṣọ, a sì tún máa ń tọ́jú àwọn tó fara pa.

      Ọmọ kékeré kan ń rẹ́rìn-ín

      Wo fídíò yìí, Philippines Typhoon​—Faith Conquers Adversity ní ìkànnì www.jw.org. (Wo abẹ́ ABOUT US > ACTIVITIES)

  • Kí nìdí tá a fi ń wàásù?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | September 1
    • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń wàásù ní àdúgbò táwọn èèyàn ń gbé

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | TA NI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ?

      Kí nìdí tá a fi ń wàásù?

      Ohun tí àwọn èèyàn fi ń dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ yàtọ̀ ni iṣẹ́ ìwàásù wa. A máa ń wàásù láti ilé dé ilé, níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí àti níbikíbi tá a bá ti pàdé àwọn èèyàn. Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wàásù ká lè fi ògo fún Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ rẹ̀. (Hébérù 13:15) A tún ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù Kristi pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”​—Mátíù 28:​19, 20.

      Yàtọ̀ síyẹn, a tún nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa. (Mátíù 22:39) A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní ẹ̀sìn tiwọn àti pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Àmọ́, ó dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ Bíbélì ló máa jẹ́ ká rí ìgbàlà. Ìdí nìyẹn tí a fi ń bá a lọ “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi,” bíi tàwọn Kristẹni ìgbà ìjímìjí.​—Ìṣe 5:​41, 42.

      Ọ̀gbẹ́ni Antonio Cova Maduro, sọ nípa “ìsapá àti akitiyan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń lo gbogbo okun wọn . . . , kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dé ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.”​—Ìwé ìròyìn El Universal, lórílẹ̀-èdè Venezuela

      Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka àwọn ìwé wa kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn tá a sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ní ẹ̀sìn tiwọn. Síbẹ̀, wọ́n mọyì bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń wá sọ́dọ̀ wọn.

      Òótọ́ ni pé o lè ní àwọn ìbéèrè míì nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà nípa ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí:

      • Béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

      • Lọ sórí ìkànnì wa, www.jw.org/yo.

      • Lọ sí àwọn ìpàdé wa. Gbogbo èèyàn ló lè wá, a kì í sì gbégbá owó.

      Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn méjì jáde láti wàásù
      Òkè ńlá tí yìnyín ti bò

      Tó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo fídíò yìí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà​—A Ṣètò Wa Láti Wàásù Ìhìn Rere, lórí ìkànnì www.jw.org/yo. (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN FÍDÍÒ)

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́