-
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Lóye Bíbélì?Ilé Ìṣọ́—2015 | December 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Lóye Bíbélì?
“Bíbélì gbayì gan-an nínú àwọn ìwé ìsìn. Àmọ́ ìwé àjèjì ni, kò sì wúlò fún àwa ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà.”—LIN, ṢÁÍNÀ.
“Mi ò lóye ohun tó wà nínú ìwé ìsìn Híńdù tí mò ń ṣe. Báwo ni màá ṣe wá lóye Bíbélì?”—AMIT, INDIA.
“Mo gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì, torí ó lọ́jọ́ lórí, ó sì ń tà gan-an. Àmọ́, mi ò ríkan rí.”—YUMIKO, JAPAN.
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló gbà pé ọba ìwé ni Bíbélì. Síbẹ̀, wọn ò mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ tàbí kó jẹ́ díẹ̀ ni ohun tí wọ́n mọ̀ níbẹ̀. Ìṣòro yìí wọ́pọ̀ láàárín àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Éṣíà, ó sì tún wà láwọn àgbègbè tí Bíbélì pọ̀ sí pàápàá.
O lè máa ronú pé, ‘Kí nìdí tó fi yẹ kí n lóye Bíbélì?’ Tó o bá lóye ohun tó wà nínú Bíbélì:
Wàá ní ìtẹ́lọ́rùn, wàá sì láyọ̀
Wàá lè kojú àwọn ìṣòro ìdílé
Wàá lè gbé àwọn àníyàn ìgbésí ayé kúrò lọ́kàn
Àárín ìwọ àtàwọn èèyàn máa túbọ̀ gún
Wàá mọ bí èèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná
Wo àpẹẹrẹ Yoshiko tó ń gbé ní Japan. Ó ti máa ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó wà nínú Bíbélì, ló bá pinnu láti kà á. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó sọ pé: “Bíbélì ti jẹ́ káyé mi nítumọ̀, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.” Ó wá fí kún un pé: “Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀.” Amit tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá sọ pé: “Ohun tí mo bá nínú rẹ̀ yà mí lẹ́nu. Mo rí i pé àwọn nǹkan tó máa ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní ló wà nínú Bíbélì.”
Bíbélì ti tún ayé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ṣe kárí ayé. Ìwọ náà lè yẹ̀ ẹ́ wò, kó o sì rí bó ṣe máa ṣe ẹ́ láǹfààní.
-
-
Ìwé Kan Tó Yẹ Ká Mọ̀ DunjúIlé Ìṣọ́—2015 | December 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ
Ìwé Kan Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dunjú
Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti kọ Bíbélì. Báwo ló ṣe pẹ́ tó? Wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn. Ìyẹn jẹ́ àkókò kan náà pẹ̀lú ìjọba Shang tọ́jọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ nínú ìtàn ilẹ̀ Ṣáínà, ó sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ọdún kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀sìn Búdà lórílẹ̀-èdè Íńdíà. —Wo àpótí náà “Ìsọfúnni Nípa Bíbélì.”
Bíbélì fún wa ní àwọn ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé
Tí ìwé kan bá máa ṣe wá láǹfààní, tó sì máa ṣamọ̀nà wa, a gbọ́dọ̀ lóye ohun tó wà nínú rẹ̀, ká sì rí i pé lóòótọ́ ló wúlò fún wa. Irú ìwé tí Bíbélì jẹ́ gan an nìyẹn. Ó fún wa ní àwọn ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé.
Bí àpẹẹrẹ, ṣé o máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí la wá ṣe láyé?’ Kì í ṣòní kì í ṣàná táwọn èèyàn ti ń béèrè ìbéèrè yìí, títí di báyìí ọ̀pọ̀ ló ṣì ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà. Síbẹ̀, ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú orí méjì tó ṣáájú nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì. Níbẹ̀, Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,” ìyẹn ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún sẹ́yìn nígbà tí Ọlọ́run dá àgbáálá ayé wa, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ó tún ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe sọ ayé di ibi tó ṣe é gbé, tó sì dá àwọn ewéko àti onírúurú ẹranko. Lẹ́yìn náà ló sọ bó ṣe dá àwa èèyàn, tó sì ṣàlàyé ìdí tó fi dá wa.
WỌ́N KỌ BÍBÉLÌ LỌ́NÀ TÓ MÁA GBÀ YÉNI
Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká lè borí àwọn ìṣòro tá a sábà máa ń kojú. Àwọn ìmọ̀ràn yìí rọrùn láti lóye. Ohun méjì ló mú kí èyí rí bẹ́ẹ̀.
Àkọ́kọ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe tààràtà, kò lọ́jú pọ̀, ó sì tuni lára. Dípò kí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì tó ṣòro lóye, ńṣe ni wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa tètè yéni. Bíbélì máa ń lo àwọn nǹkan tí kò ṣàjèjì sí wa láti ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ta kókó ká lè lóye wọn.
Bí àpẹẹrẹ, Jésù lo àwọn àpèjúwe tó dá lórí nǹkan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa kó lè fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. A máa rí ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe yìí nínú ìwàásù kan táwọn èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè tó wà nínú ìwé Mátíù orí 5 sí 7. Ọgbẹ́ni alálàyé kan pè é ní “ìwàásù tó ṣeé múlò.” Ó wá fi kún un pé kì í ṣe pé Jésù “kàn rọ́ ìsọfúnni kalẹ̀ fún wa, àmọ́ ó fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa tọ́ wa sọ́nà nígbèésí ayé.” O lè ka àwọn orí yẹn láàárín ogún ìṣẹ́jú, á sì yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i bí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣe wúlò tó.
Ohun míì tó jẹ́ kí Bíbélì rọrùn láti lóye ni ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ lé lórí. Kì í ṣe ìtàn àròsọ ló wà nínú rẹ̀. Ìwé The World Book Encyclopedia sọ pé, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “onírúurú àwọn èèyàn,” ó sì sọ “ìlàkàkà wọn, ìrètí wọn, àṣìṣe wọn àtàwọn àṣeyọrí wọn.” Torí èèyàn bíi tiwa làwọn wọ̀nyí, ó rọrùn láti lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn.—Róòmù 15:4.
Ó WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN
Kí ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé kan tó lè yé ẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ ọ ní èdè tó o mọ̀ ọ́n kà. Lóde òní, ó ṣeé ṣe kí Bíbélì wà ní èdè tó o mọ̀ láìka ibi tí ò ń gbé tàbí ẹ̀yà tó o ti wá. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó mú kí èyí ṣeé ṣe.
Iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè. Èdè Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì ni wọ́n fi kọ Bíbélì láyé àtijọ́. Àmọ́, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ àwọn èdè yìí. Àwọn atúmọ̀ èdè wá ṣe iṣẹ́ takuntakun kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sí ọ̀pọ̀ àwọn èdè míì. Ọpẹ́lọpẹ́ wọn, Bíbélì ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tí ó tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje [2,700]. Èyí fi hàn pé ohun tó ju ìdá mẹ́sàn nínú mẹ́wàá àwọn èèyàn kárí ayé ló lè ka Bíbélì ní èdè abínibí wọn.
Iṣẹ́ ìtẹ̀wé. Orí àwọn nǹkan tó lè tètè bà jẹ́ irú bí awọ àti òrépèté ni wọ́n kọ Bíbélì sí láyé àtijọ́. Èyí gbà pé kí wọ́n máa ṣe àdàkọ rẹ̀ lóòrèkóòrè. Àmọ́ àwọn àdàkọ yìí wọ́n gan-an, àwọn tó bá sì jẹun kánú ló lè rà á. Ṣùgbọ́n àtìgbà tí wọ́n ti ṣe ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé Gutenberg ní ohun tó lé ní àádọ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [550] ọdún sẹ́yìn, ó ti túbọ̀ rọrùn gan-an láti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dà Bíbélì jáde. Àwọn kan tiẹ̀ fojú bù ú pé, ohun tó ju bílíọ̀nù márùn-ún Bíbélì bóyá lódindi tàbí lápá kan ni wọ́n ti pín káàkiri.
Kò sí ìwé ìsìn míì tó dà bíi Bíbélì láwọn ọ̀nà wọ̀nyí. Èyí fi hàn gbangba pé a lè lóye ohun tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́ nígbà míì, ó lè dà bíi pé ó ṣòro láti lóye rẹ̀. Fọkàn balẹ̀, ohun tó o lè ṣe wà. Ibo lo ti lè rí ìrànlọ́wọ́ yìí? Èrè wo lo máa rí tó o bá lóye Bíbélì? Wà á rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
-
-
Ohun Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Lóye BíbélìIlé Ìṣọ́—2015 | December 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ
Ohun Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì
Ká sọ pé o lọ sí orílẹ̀-èdè míì fún ìgbà àkọ́kọ́. O wá rí i pé gbogbo nǹkan ní ilẹ̀ yẹn ló yàtọ̀ sí tìẹ, bí owó tí wọ́n ń ná, àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀, àṣà wọn, àti oúnjẹ wọn. Kò sí àní-àní pé gbogbo nǹkan á tojú sú ẹ.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe máa rí nìyẹn nígbà àkọ́kọ́ tó o ka Bíbélì. Ó máa dà bíi pé o pa dà sáyé àtijọ́, tí gbogbo nǹkan ti ṣàjèjì sí ẹ. Níbẹ̀, wàá rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń pè ní àwọn Filísínì, wàá tún rí àwọn àṣà wọn tó máa yà ẹ́ lẹ́nu bíi ‘gbígbọn ẹ̀wù ya,’ àti oúnjẹ tí wọ́n ń pè ní mánà tàbí ẹyọ owó tí wọ́n mọ̀ sí dírákímà. (Ẹ́kísódù 16:31; Jóṣúà 13:2; 2 Sámúẹ́lì 3:31; Lúùkù 15:9) Ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó o kà máà yé ẹ. Àmọ́, bíi ti ẹni tó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, ṣé inú rẹ kò ní dùn tó o bá rí ẹni tó máa ṣàlàyé àwọn nǹkan wọ̀nyí fún ẹ?
OHUN TÓ RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ LÁTI LÓYE BÍBÉLÌ LÁYÉ ÀTIJỌ́
Láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe máa lóye ohun tó wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Mósè tó jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ‘ṣe àlàyé’ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀.—Diutarónómì 1:5.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó wà nínú Bíbélì. Ní ọdún 455 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ àwọn Júù, títí kan àwọn ọmọdé ló kóra jọ pọ̀ sí ojúde ìlú ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì tó wà níbẹ̀ ń ‘ka [ìwé mímọ́ náà] sókè.’ Kò tán síbẹ̀ o. ‘Wọ́n tún ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.’—Nehemáyà 8:1-8.
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn èyí, Jésù Kristi náà ṣe irú iṣé ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Kódà, olùkọ́ ni àwọn èèyàn mọ Jésù sí. (Jòhánù 13:13) Ó máa ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn pa pọ̀, nígbà míì ó tún máa ń kọ́ wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó tiẹ̀ nígbà kan tó bá ogunlọ́gọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀, nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè. Lẹ́yìn ìwàásù náà, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 5:1, 2; 7:28) Nígbà ìrúwé lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ méjì sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà tó lọ sí abúlé kan ní ìtòsí Jerúsálẹ́mù, ó “ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wọn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́,” tàbí ṣàlàyé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ fún wọn.—Lúùkù 24:13-15, 27, 32.
Àwọn ọmọ ẹ̀yin Jésù náà máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìgbà kan wà tí òṣìṣẹ́ láàfin kan láti ilẹ̀ Etiópíà ń ka apá kan nínú Ìwé Mímọ́. Ọ̀kan lára ọmọ ẹ̀yin Jésù tó ń jẹ́ Fílípì sún mọ́ ọn, ó sì bi í pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ará Etiópíà náà dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Fílípì wá ṣàlàyé ohun tí ibi tó kà túmọ̀ sí fún un.—Ìṣe 8:27-35.
ÌRÀNLỌ́WỌ́ TÓ WÀ LÓNÌÍ
Bíi tàwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láyé àtijọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní igba ó lé mọ́kàndínlógójì ilẹ̀ [239] kárí ayé lónìí. (Mátíù 28:19, 20) Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, à ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Púpọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni kì í ṣe Kristẹni. Ọ̀fẹ́ ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, o sì lè ṣe é ní ilé rẹ tàbí ibi tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Àwọn kan máa ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lórí fóònù tàbí kí wọ́n ṣe é lórí íńtánẹ́ẹ̀tì.
Jọ̀wọ́ kàn sí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá rí, kó lè ṣàlàyé bó o ṣe lè jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ yìí. Wàá rí i pé Bíbélì kì í ṣe ìwé tó ṣòro lóye, kàkà bẹ́ẹ̀, ó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo,” kí o lè tóótun pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.—2 Tímótì 3:16, 17.
-