ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́—2015 | April 1
    • Ọkùnrin kan ń ṣàyẹ̀wò Bíbélì níbi ìkówèésí rẹ̀

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?

      Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

      • Kí nìdí tá a fi wà láyé?

      • Kí nìdí tá a fi ń jìyà tá a sì ń kú?

      • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la?

      • Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa mi?

      Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ ní irú àwọn ìbéèrè yìí rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé kì í ṣe ìwọ nìkan lo ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Kárí ayé làwọn èèyàn ti ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. Ǹjẹ́ o lè rí ìdáhùn?

      Ọ̀pọ̀ èèyàn máa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn nínú Bíbélì. Ṣé wàá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ máa ṣe ẹ́ láǹfààní.a

      Tó bá kan pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn kan máa ń sọ pé: “Mi ò kì í ráyè.” “Ó ti le jù.” “Mi ò fẹ́ràn kí n máa ṣàdéhùn.” Àmọ́, èrò àwọn míì yàtọ̀ síyẹn. Wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan:

      • “Mo ti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì, mo lọ sí tẹ́ńpìlì àwọn ẹlẹ́sìn Sikh, mo ṣe ẹ̀sìn Búdà, mo sì lọ kẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní yunifásítì. Àmọ́, mi ò rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn. Lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sí ilé mi. Bó ṣe fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè mi wú mi lórí. Èyí sì mú kí n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”—Gill, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

      • “Mo ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìgbésí ayé, àmọ́ pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì mi kò fún mi ní ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn. Àmọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi Bíbélì nìkan dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Nígbà tó béèrè bóyá máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i, tayọ̀tayọ̀ ni mo gbà.”—Koffi, Benin.

      • “Mo fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Mo gbà pé àwọn òkú lè ṣe àwọn èèyàn ní jàǹbá, àmọ́ ó wù mí láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—José, Brazil.

      • “Mo ka Bíbélì, àmọ́ ohun tí mo kà kò yé mi. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mélòó kan fún mi. Èyí mú kó wù mí láti mọ̀ sí i.”—Dennize, Mẹ́síkò.

      • “Mo máa ń ronú pé bóyá ni Ọlọ́run bìkítà nípa mi. Torí náà, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní ọjọ́ kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé mi, mo sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”—Anju, Nepal.

      Àwọn ìrírí yìí rán wa létí ohun tí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ká sòótọ́, ó máa ń wù wá láti mọ Ọlọ́run. Ọlọ́run nìkan sì lẹni tó lè mú ká mọ òun nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

      Báwo la ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ọ̀nà wo ni ẹ̀kọ́ yìí máa gbà ṣe ẹ́ láǹfààní? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

      a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

      Ìsọfúnni Nípa Bíbélì

      Bíbélì tí wọ́n ṣí sílẹ̀
      • ORÚKỌ: Látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà bi·bliʹa, tó túmọ̀ sí “àwọn ìwé kéékèèké”

      • OHUN TÓ WÀ NÍNÚ RẸ̀: Ìwé 39 ní èdè Hébérù (pẹ̀lú ojú ìwé mélòó kan ní èdè Árámáíkì) àti ìwé 27 ní èdè Gíríìkì

      • BÍ WỌ́N ṢE KỌ Ọ́: Nǹkan bíi 40 èèyàn ló kọ ọ́, ó sì gbà ju 1,600 ọdún lọ, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1513 Ṣ.S.K. sí nǹkan bí ọdún 98 S.K.b

      • IYE ÈDÈ: Ó ti wà lápá kan tàbí lódindi ní èdè tó lé ní 2,500

      • ÌPÍNKIRI: Wọ́n ti tẹ nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́rin Bíbélì, èyí mú kó jẹ́ ìwé tí wọ́n tíì pín kiri jù lọ kárí ayé

      b Ìkékúrú yìí Ṣ.S.K. túmọ̀ sí “Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.” S.K. sì túmọ̀ sí “Sànmánì Kristẹni.”

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fún Gbogbo Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́—2015 | April 1
    • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?

      Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fún Gbogbo Èèyàn

      Àwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé a tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé?

      Ọkùnrin kan ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ibiṣẹ́

      Lọ́dún 2014, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè òjìlérúgba [240] tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Iye àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [9,500,000].a Ká sòótọ́, iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ju iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogóje [140]!

      Kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a máa ń tẹ Bíbélì, àwọn ìwé, àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje (700) èdè! Iṣẹ́ ìtẹ̀wé tí kò lẹ́gbẹ́ yìí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè tí wọ́n bá fẹ́.

      “Nígbà tí mo wà níléèwé, mi ò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn kí n máa kẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí yàtọ̀. Àwọn ohun tí mo kọ́ tù mí nínú gan-an!”—Katlego, South Africa.

      “Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dáhùn gbogbo ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn àtàwọn míì.”—Bertha, Mẹ́síkò.

      “Ilé mi la ti ń sẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní àkókò tó rọrùn fún mi. Kí ni mo tún ń fẹ́!”—Eziquiel, Brazil.

      “Nígbà míì, mo máa ń lo nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú láti fi kẹ́kọ̀ọ́, nígbà míì sì rèé, a lè lò jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí tó bá ti rọrùn fún mi ni.”—Viniana, Ọsirélíà.

      “Ọ̀fẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an!” —Aimé, Benin.

      “Ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ onísùúrù àti onínúure. Èyí mú ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.” —Karen, Northern Ireland.

      “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọn ò sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” —Denton, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

      ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPA ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ TÁ À Ń ṢE

      Báwo lẹ ṣe máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?

      A máa ń yan onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì, a sì máa ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bá àwọn ẹ̀kọ́ náà mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè, bíi: Ta ni Ọlọ́run? Irú ẹni wo ni Ọlọ́run jẹ́? Ṣé ó ní orúkọ? Ibo ló ń gbé? Ǹjẹ́ a lè sún mọ́ ọn? Ohun tó máa ń jẹ́ ìṣòro ni béèyàn ṣe máa rí ìdáhùn nínú Bíbélì.

      Kó lè ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti rí ìdáhùn, a máa ń lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tó ní ojú ìwé igbà ó lé mẹ́rìnlélógún [224].b Ńṣe la dìídì ṣe ìwé yìí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì. Ìwé náà ní àwọn ẹ̀kọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, Jésù Kristi, ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, àjíǹde, àdúrà àtàwọn ẹ̀kọ́ míì.

      Ìgbà wo ni èèyàn lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ibo ló sì ti máa ṣe é?

      Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè wáyé ní àkókò tó bá rọrùn fún ẹ àti ní ibi tó bá wù ẹ́.

      Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa gùn tó?

      Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo nǹkan bíi wákátì kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò pọn dandan kó gùn tó bẹ́ẹ̀. A máa ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó máa bá ipò rẹ mu. Àwọn kan kì í lò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

      Èló lẹ máa ń gbà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà?

      Ọ̀fẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Èyí sì bá ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mu pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.

      Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa pẹ́ tó?

      Ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu bó ṣe máa pẹ́ tó. Ẹ̀kọ́ mọ́kàndínlógún [19] ló wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè ka èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀kọ́ náà, o sì lè ka gbogbo rẹ̀ bí àkókó bá ṣe wà fún ẹ tó.

      Ṣé ó pọn dandan kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      Rárá. A gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó máa gbà gbọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó bá ti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ló máa ń fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe.

      Ibo ni mo ti lè rí ìsọfúnni síwájú sí i?

      Wàá rí ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ìkànnì jw.org/yo.

      Báwo ni mo ṣe lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

      • Àwọn tó ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónírúurú ọ̀nà: lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, kíkọ̀wé, àti nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí

        Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.

      • Kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó sún mọ́ ẹ jù lọ lára àwọn tá a kọ sí ojú ìwé kejì nínú ìwé ìròyìn yìí.

      • O tún lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè rẹ.

      a A sábà máa ń kọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwùjọ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

      b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. A sì ti tẹ ẹ̀dá tó lé ní mílíọ̀nù igba ó lé ọgbọ̀n [230,000,000] jáde ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgọ́ta [260] èdè.

      Ó ń mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan

      Eziquiel

      “Nígbà tí ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo kíyè sí pé àwọn ìwà rẹ̀ yí pa dà. Èyí mú kí ìrẹ́pọ̀ wà láàárín wa. Mo wá fẹ́ mọ nǹkan tó ń kọ́, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí mo kọ́ wá jẹ́ kí ìwà tèmi náà dára sí i. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mú kí ìdílé mi wà ní ìṣọ̀kan.”—Eziquiel.

      Karen

      “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, ọtí àmujù, mo sì tún kọ́ bí máa ṣe ṣàkóso ìbínú mi. Ní báyìí, inú ilé mi ṣeé rí, ó sì wà létòlétò. Mo túbọ̀ wá mọyì ìdílé mi, mo sì gbádùn kí n máa ṣe nǹkan tó máa múnú wọn dùn. Èmi fúnra mi sì láyọ̀ gan-an.”—Karen.

      Viniana

      “Àwọn kan ń bú mi torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ọkọ mi tì mí lẹ́yìn, ó ni: ‘Ohun tó bá wu ẹlẹ́nu ló lè fẹnu ẹ̀ sọ. Ohun tó ṣe pàtàkì sí mi ni pé ohun tó ò ń kọ́ tí jẹ́ kí ìwà rẹ dára sí i. Máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́.’ Kò tíì sígbà tí ìdílé wa ṣọ̀kan báyìí rí!”—Viniana.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́