-
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Gbàdúrà?Ilé Ìṣọ́—2015 | October 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Gbàdúrà?
“Tẹ́tẹ́ títa ti di mọ́líkì sí mi lára. Mo sì máa ń gbàdúrà pé kí n rí owó ńlá jẹ. Àmọ́ mi ò rí i jẹ rí.”—Samuel,a Kenya.
“Nígbà tí mo wà nílé ìwé, ohun tá a kàn máa ń ṣe ni pé ká gba àdúrà àkọ́sórí.”—Teresa, Philippines.
“Mo máa ń gbàdúrà tí mo bá ní ìṣòro. Mo máa ń gbàdúrà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti pé kí n lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tínú ẹ̀ dùn sí.”—Magdalene, Gánà.
Ohun tí Samuel, Teresa àti Magdalene sọ fi hàn pé onírúurú nǹkan làwọn èèyàn máa ń gbàdúrà fún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn kan ń béèrè ṣe pàtàkì ju tàwọn míì lọ. Àdúrà àwọn kan máa ń tọkàn wá, ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán sì ni tàwọn míì. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbàdúrà nípa ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, bíi kí wọ́n yege ìdánwò nílé ìwé, kí ẹgbẹ́ eléré ìdárayá tí wọ́n fẹ́ràn borí ìdíje tàbí fún ààbò Ọlọ́run lórí ìdílé wọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwádìí tiẹ̀ fi hàn pé àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn pàápàá máa ń gbàdúrà.
Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo máa ń tọrọ nínú àdúrà rẹ? Yálà o máa ń gbàdúrà tàbí o kì í gbàdúrà, o lè máa ronú pé: ‘Ǹjẹ́ àdúrà tiẹ̀ máa ń ṣeni láǹfààní kankan? Ṣé ẹnì kan wà tó ń gbọ́ àdúrà?’ Òǹkọ̀wé kan gbà pé ńṣe ni ẹni tó ń gbàdúrà kàn ń dá ara rẹ̀ nínú dùn. Àwọn oníṣègùn kan tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni àdúrà dà bí ìgbà tí èèyàn ń tu ara rẹ̀ nínú lásán. Ṣé ẹni tó ń gbàdúrà kàn ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò, àbí ńṣe ló kàn ń dánú ara rẹ̀ dùn?
Ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn, ó jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ tí àdúrà ń ṣe kọjá pé kó kàn tù wá nínú. Ó fi dá wa lójú pé ẹnì kan wà tó ń gbọ́ àdúrà tá a bá gbà lọ́nà tó yẹ, tí ohun tá a bá béèrè bá tọ̀nà. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
-
-
Ṣé Ẹnì Kan Wà Tó Ń Gbọ́ Àdúrà?Ilé Ìṣọ́—2015 | October 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ
Ṣé Ẹnì Kan Wà Tó Ń Gbọ́ Àdúrà?
Àwọn kan gbà pé bí ẹni fàkókò ṣòfò ni kéèyàn máa gbàdúrà torí kò sẹ́ni tó ń gbọ́ àdúrà. Àwọn míì máa ń gbàdúrà, àmọ́ ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé Ọlọ́run kò gbọ́ àdúrà wọn. Ọ̀gbẹ́ni kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sọ èrò rẹ̀ nípa Ọlọ́run, ó ní òun bẹ Ọlọ́run pé: “Tiẹ̀ kàn sọ nǹkan kan fún mi.” Àmọ́, òun kò gbọ́ nǹkan kan rárá.
Síbẹ̀, Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ń gbọ́ àdúrà wa. Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn kan láyé àtijọ́, ó ní: “Láìkùnà, [Ọlọ́run] yóò fi ojú rere hàn sí ọ ní gbígbọ́ ìró igbe ẹkún rẹ; gbàrà tí ó bá gbọ́ ọ, yóò dá ọ lóhùn ní tòótọ́.” (Aísáyà 30:19) Ẹsẹ Bíbélì míì tún sọ pé: “Àdúrà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 15:8.
Jésù gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀, “a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere.”—Hébérù 5:7
Bíbélì tún sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn. Ẹsẹ Bíbélì kan sọ nípa Jésù pé ó ṣe “ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là . . . a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere.” (Hébérù 5:7) Àpẹẹrẹ àwọn míì tí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn wà nínú Dáníẹ́lì 9:21 àti 2 Kíróníkà 7:1.
Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí tàwọn kan fi rò pé Ọlọ́run kì í gbọ́ àdúrà wọn? Ohun kan tó ṣe pàtàkì ni pé, Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìkan la gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí, ìyẹn Jèhófà.a A kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí ọlọ́run míì tàbí àwọn baba ńlá tó ti kú. Ọlọ́run tún sọ pé a gbọ́dọ̀ gbàdúrà “ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ [òun],” ìyẹn ni pé, ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí ló yẹ ká máa gbà ládùúrà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé òun máa “gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì mọ ohun tó fẹ́.
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àdúrà kì í kàn ṣe ààtò ìsìn kan lásán, ṣùgbọ́n Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà, ó sì máa ń dáhùn wọn. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Isaac lórílẹ̀-èdè Kenya sọ pé: “Mo gbàdúrà kí n lè lóye ohun tí mò ń kà nínú Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ẹnì kan wá sọ́dọ̀ mi, kó lè ràn mí lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀.” Obìnrin kan tó ń jẹ́ Hilda lórílẹ̀-èdè Philippines fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ṣùgbọ́n, pàbó ni gbogbo akitiyan rẹ̀ já sí. Ọkọ rẹ̀ wá dábàá pé, “O ò ṣe gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́?” Hilda tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọkọ rẹ̀, ó wá sọ pé: “Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ràn mí lọ́wọ́ yà mí lẹ́nu gan-an. Ńṣe ni sìgá bẹ̀rẹ̀ sí í rùn sí mi. Mo sì jáwọ́ ńbẹ̀.”
Tí àdúrà rẹ bá bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu, ṣé o rò pé Ọlọ́run kò ní ràn ẹ́ lọ́wọ́?
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
-
-
Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí ÒunIlé Ìṣọ́—2015 | October 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ
Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun
Ọlọ́run fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.
Bí ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa, àárín wọ́n máa gún. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.” (Jeremáyà 29:12) Bó o ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, wàá “sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ [ẹ].” (Jákọ́bù 4:8) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Bí a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ máa túbọ̀ gún régé.
“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”—Sáàmù 145:18
Ọlọ́run fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Jésù sọ pé: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì, òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹja, òun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Mátíù 7:9-11) Torí náà, Ọlọ́run fẹ́ kó o gbàdúrà sí òun torí pé ‘ó bìkítà fún ẹ,’ ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Pétérù 5:7) Kódà, ó fẹ́ kó o sọ gbogbo ìṣòro rẹ fún òun. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.
Ó máa ǹ wu àwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run.
Àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ẹ̀dá kíyè sí i pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa ń fẹ́ gbàdúrà. Títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà.a Èyí fi hàn pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi máa wù wá láti sún mọ́ ọn. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká máa gbàdúrà sí i déédéé.
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run?
a Lọ́dún 2012, iléeṣẹ́ ìwádìí kan tó ń jẹ́ Pew Research Center ṣe ìwádìí kan nípa àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwádìí náà fi hàn pé ẹnì kan nínú mẹ́wàá lára wọn máa ń gbàdúrà ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóṣù.
-
-
Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú ÀdúràIlé Ìṣọ́—2015 | October 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ
Àǹfààní Tó O Máa Rí Nínú Àdúrà
Ká tó dáwọ́ lé ohun kan, a lè ronú pé, ‘Àǹfààní wo ni máa rí níbẹ̀?’ Ṣé ìmọtara ẹni nìkan ni tá a bá ní irú èrò yìí nípa àdúrà? Rárá o. Ìdí ni pé a máa ń fẹ́ mọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá gbàdúrà. Kódà, ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù béèrè pé: “Bí mo bá pè é, òun yóò ha dá mi lóhùn?”—Jóòbù 9:16.
Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àdúrà ju ohun téèyàn fi ń dánú ara rẹ̀ dùn tàbí ààtò ẹ̀sìn kan lásán. Ọlọ́run tòótọ́ máa ń gbọ́ àdúrà wa. Tá a bá gbàdúrà lọ́nà tó yẹ, tá a sì ń béèrè ohun tó tọ́, ó dájú pé ó máa gbọ́ tiwa. Kódà, ó rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. (Jákọ́bù 4:8) Kí wá ni àǹfààní tí àdúrà máa ń ṣe láyé wa? Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ nínú rẹ̀ yẹ̀ wò.
Ìbàlẹ̀ ọkàn.
Nígbà tá a bá kojú onírúurú ìṣòro ní ìgbésí ayé wa, àníyàn sábà máa ń gbà wá lọ́kàn. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa “gbàdúrà láìdabọ̀,” ká sì máa sọ àwọn ohun tá à ń “tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 5:17; Fílípì 4:6) Bíbélì fi dá wa lójú pé tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa].” (Fílípì 4:7) Ọkàn wa máa balẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan tá a bá sọ àwọn ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Bàbá wa ọ̀run. Kódà, òun fúnra rẹ̀ fẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé Sáàmù 55:22 sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”
“Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22
Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ti jàǹfààní àlàáfíà ọkàn tí Bíbélì sọ yìí. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Hee Ran lórílẹ̀-èdè South Korea sọ pé: “Bí mo tiẹ̀ ní ìṣòro ńlá, tí mo bá ṣáà ti gbàdúrà nípa rẹ̀, ńṣe lara máa ń tù mí, mo sì máa ń lókun láti fara dà á.” Obìnrin míì lórílẹ̀-èdè Philippines tó ń jẹ́ Cecilia sọ pé: “Torí pé abiyamọ ni mí, mo máa ń ṣàníyàn gan-an nípa àwọn ọmọ mi àti ìyá mi tí àìsàn kò jẹ́ kó dá mi mọ̀ mọ́. Àmọ́, àdúrà máa ń jẹ́ kí n gbọ́kàn kúrò lórí àwọn ìṣòro náà, torí mo mọ̀ pé Jèhófà máa bá mi tọ́jú wọn.”
Ó ń tù wá nínú, ó sì ń fún wa lókun nígbà ìṣòro.
Ṣé kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lò ń bá fà á tàbí àwọn ìṣòro tó le koko míì? Àdúrà sí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” lè mú kára tù ẹ́. Bíbélì sọ pé ó máa ń “tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Àpẹẹrẹ kan ni ìgbá tí Jésù ní ẹdùn ọkàn, ńṣe ló “tẹ eékún rẹ̀ ba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà.” Kí ni àbájáde rẹ̀? “Áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:41, 43) Àpẹẹrẹ míì ni ti ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Nehemáyà. Àwọn èèyàn burúkú halẹ̀ mọ́ ọn kó lè dá iṣẹ́ Ọlọ́run tó ń ṣe dúró. Ló bá gbàdúrà pé: “Nísinsìnyí, fún ọwọ́ mi lókun.” Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fi hàn pé Ọlọ́run fún un lókùn, ó sì parí iṣẹ́ náà. (Nehemáyà 6:9-16) Ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè Gánà tó ń jẹ́ Reginald sọ àǹfààní tí àdúrà máa ń ṣe fún un, ó ní: “Tí mo bá gbàdúrà, pàápàá jù lọ nígbà tí ìṣòro kan bá kọjá agbára mi, ó máa ń ṣe mí bíi pé mo ti sọ ìṣòro náà fún ẹni tó lè ràn mí lọ́wọ́, tó sì fi mi lọ́kàn balẹ̀ pé kí n má ṣe bẹ̀rù, kò séwu.” Kò sí àní-àní pé Ọlọ́run máa ń tù wá nínú tá a bá gbàdúrà sí i.
Ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Àwọn ìpinnu kan wà tó lè yí ìgbésí ayé wa àti tàwọn èèyàn wa pa dà. Báwo la ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó dáa? Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n [ní pàtàkì láti kojú ìṣòro], kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Jákọ́bù 1:5) Tá a bá béèrè fún ọgbọ́n, Ọlọ́run lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa ká lè ṣe ìpinnu tó dáa. Kódà, a lè dìídì béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ torí Jésù mú un dá wa lójú pé, “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:13.
“Mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà kí n lè ṣe ìpinnu tó tọ́.”—Kwabena, Gánà
Jésù pàápàá rí i pé ó pọn dandan kí òun gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà tó fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù fẹ́ yan àwọn ọkùnrin méjìlá tó máa jẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀, ‘ó fi gbogbo òru gbàdúrà sí Ọlọ́run.’—Lúùkù 6:12, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.
Bíi ti Jésù, ọ̀pọ̀ lónìí ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa, ìgbàgbọ́ wọn sì lágbára sí i nígbà tí wọ́n rí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà wọn. Obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Philippines tó ń jẹ́ Regina sọ onírúurú ìṣòro tó ń dojú kọ, òun ló ń dá gbọ́ bùkátà ìdílé lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú. Iṣẹ́ tún bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kò sì rọrùn fún un láti tọ́ àwọn ọmọ. Ọgbọ́n wo ló dá sí i? Ó sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì dá mi lójú pé ó máa ràn mí lọ́wọ́.” Ọkùnrin kan láti Gánà tó ń jẹ́ Kwabena sọ ìdí tí òun fi gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ní: “Iṣẹ́ ìkọ́lé ni mò ń ṣe, ó sì ń mówó wọlé dáadáa fún mi. Àmọ́, iṣẹ́ náà bọ́ lọ́wọ́ mi lójijì.” Nígbà tó ń ronú lórí ohun tó máa ṣe, ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà kí n lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Ó sì dá mi lójú pé Jèhófà dáhùn àdúrà mi ní ti pé mo rí iṣẹ́ tó fún mi láyè láti jọ́sìn Ọlọ́run, mo sì tún ráyè gbọ́ tara mi.” Tó o bá ń gbàdúrà nípa àwọn ohun tó kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run, ó dájú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà rẹ.
A ti mẹ́nu kan díẹ̀ lára nǹkan tí àdúrà lè ṣe fún wa. (Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpótí náà “Àǹfààní Tí Àdúrà Ń Ṣe.”) Ṣùgbọ́n kó o tó lè rí àwọn àǹfààní wọ̀nyí, o ní láti kọ́kọ́ mọ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́. Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, kí wọ́n lè kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.a Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á jẹ́ pé o ti gbé ìgbésẹ̀ kan tó máa jẹ́ kó o sún mọ́ “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sáàmù 65:2.
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì, www.jw.org/yo.
-