-
Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?Ilé Ìṣọ́—2015 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?
Tí wọ́n bá bi ẹ́ ní ìbéèrè yìí, kí ni wàá sọ? Ọ̀pọ̀ ronú pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun. Wọ́n sọ pé nínú Bíbélì, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ nígbà àtijọ́ pé kí wọ́n jagun. Àmọ́ àwọn míì sọ pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Mátíù 5:43, 44) Torí náà, wọ́n gbà pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun láyé àtijọ́, àmọ́ kò fẹ́ ká máa jagun mọ́ báyìí.
Kí lèrò tìẹ? Ṣé Ọlọ́run fẹ́ ká máa jagun? Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn wo ni Ọlọ́run máa ń tì lẹ́yìn nígbà ogun? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o ní èrò tó tọ̀nà nípa ogun. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá mọ̀ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun àti pé ẹ̀yìn àwọn tó o fẹ́ kó ṣẹ́gun ni Ọlọ́run wà, ọkàn rẹ máa balẹ̀ pé ẹ̀yin lẹ máa ṣẹ́gun. Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó bá jẹ́ pé ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá yín ni Ọlọ́run wà? Ó dájú pé ọ̀kan rẹ kò ní balẹ̀.
Ohun míì wà tó tún ṣe pàtàkì ju èyí lọ. Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ogun lè pinnu èrò tó o máa ní nípa Ọlọ́run. Tó o bá wà lára ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tí ogun ti fa àdánù ńlá fún, ó máa dáa kó o mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bíi: Ṣé arógunyọ̀ ni Ọlọ́run bí àwọn kan ṣe sọ? Ṣé inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìyà tí ogun ń fà fún àwọn èèyàn? Ṣé ọ̀rọ̀ àwọn tí ogun ń hàn léèmọ̀ kò dun Ọlọ́run ni?
Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò. Láfikún sí i, èrò Ọlọ́run nípa ogun láyé àtijọ́ kò tíì yí pa dà di báyìí. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ lórí èrò Ọlọ́run nípa ogun láyé ìgbàanì àti lẹ́yìn tí Jésù wá sáyé. Ìyẹn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá Ọlọ́run fẹ́ ká máa jagun lóde òní àti bóyá àwọn èèyàn á ṣì máa jagun lọ́jọ́ iwájú.
-
-
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Láyé ÌgbàanìIlé Ìṣọ́—2015 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI ÈRÒ ỌLỌ́RUN NÍPA OGUN?
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Láyé Ìgbàanì
Àwọn ọmọ Íjíbítì jẹ́ orílẹ̀-èdè alágbára, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. Ìyà náà pọ̀ débi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dá àwọn nídè, àmọ́ Ọlọ́run kò dáhùn àdúrà wọn lójú ẹsẹ̀. (Ẹ́kísódù 1:13, 14) Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń rétí pé kí Ọlọ́run gba àwọn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì tó ń fìtínà wọn. Nígbà tó yá, àkókò tó lójú Ọlọ́run láti gbèjà wọn. (Ẹ́kísódù 3:7-10) Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló bá àwọn ọmọ Íjíbítì jagun. Ó fi onírúurú àjálù kọ lu àwọn ọmọ Íjíbítì. Lẹ́yìn náà, ó mú kí ọba Íjíbítì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣègbé sínú Òkun Pupa. (Sáàmù 136:15) Jèhófà Ọlọ́run fi hàn pé òun jẹ́ “akin lójú ogun” nítorí àwọn èèyàn rẹ̀.—Ẹ́kísódù 15:3, 4.
Bí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe bá àwọn ọmọ Íjíbítì jagun fi hàn pé àwọn ogun kan wà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Láwọn ìgbà kan, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n lọ jagun. Bí àpẹẹrẹ, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n bá àwọn ará Kénáánì jagun, torí pé wọ́n ya ìkà lẹ́dàá. (Diutarónómì 9:5; 20:17, 18) Ó tún sọ fún Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì pé kó lọ bá àwọn Filísínì jagun. Kódà, Ọlọ́run kọ́ Dáfídì ní ọgbọ́n tó máa fi ṣẹ́gun wọn.—2 Sámúẹ́lì 5:17-25.
Àwọn ìtàn Bíbélì yìí fi hàn pé bí ìyà tàbí ìnira èyíkéyìí bá dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run máa ń fọwọ́ sí i pé kí wọ́n lọ jagun kó lè dáàbò bò wọ́n, kí ìjọsìn tòótọ́ má sì pa run. Àmọ́, kíyè sí àwọn kókó mẹ́ta yìí nínú àwọn ogun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí.
ỌLỌ́RUN NÌKAN LÓ Ń PINNU ÀWỌN TÓ MÁA LỌ JAGUN. Nígbà kan, Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kì yóò sí ìdí kankan fún yín láti jà nínú ọ̀ràn yìí.” Kí nìdí? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló máa jà fún wọn. (2 Kíróníkà 20:17; 32:7, 8) Bá a ṣe mẹ́nu kàn-án níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni Ọlọ́run jà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Láwọn ìgbà míì, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ja ogun tó fọwọ́ sí. Lára irú àwọn ogun bẹ́ẹ̀ ni èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe máa gba Ilẹ̀ Ìlérí àti bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo ilẹ̀ náà.—Diutarónómì 7:1, 2; Jóṣúà 10:40.
ỌLỌ́RUN NÌKAN LÓ Ń PINNU ÌGBÀ TÍ OGUN MÁA JÀ. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti dúró de àsìkò tí Ọlọ́run bá ni kí wọ́n lọ bá àwọn èèyànkéèyàn tó yí wọn ká jagun. Tí Ọlọ́run kò bá sọ fún wọn pé ó yá, wọn kì í lọ sójú ogun. Tí wọ́n bá wá kù gìrì lọ sojú ogun, Ọlọ́run kì í tì wọ́n lẹ́yìn. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà kan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ ja ogun tí Ọlọ́run kò rán wọn, àbájáde rẹ̀ kò dáa rárá.a
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run gbógun ja àwọn ọmọ Kénáánì, ó dá àwọn kan sí, bíi Ráhábù àti ìdílé rẹ̀
ỌLỌ́RUN KÒ FẸ́ IKÚ ẸNIKẸ́NI, TÍTÍ KAN ÀWỌN ẸNI BURÚKÚ. Jèhófà Ọlọ́run ló fún wa lẹ́mìí torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. (Sáàmù 36:9) Torí náà, kò fẹ́ kí àwa èèyàn máa kú. Àmọ́, ó dunni pé àwọn kan ti jingíri sínú ìwà ìkà débi pé wọ́n máa ń pa àwọn ẹlòmíì. (Sáàmù 37:12, 14) Kí Ọlọ́run lè dáwọ́ irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ dúró, ó fọwọ́ sí i pé kí àwọn èèyàn rẹ̀ gbógun ti àwọn ẹni ibi yẹn. Síbẹ̀, ní gbogbo ìgbà tí Ọlọ́run lo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jagun, ó ṣì máa ń fi hàn pé òun jẹ́ “aláàánú” àti ẹni “tí ń lọ́ra láti bínú” sí àwọn ọ̀tá tó ń gbógun ti àwọn èèyàn rẹ̀. (Sáàmù 86:15) A rí àpẹẹrẹ kan nínú òfin tó fún wọn pé kí wọ́n tó gbógun ja ìlú kan, kí wọ́n kọ́kọ́ “fi ọ̀rọ̀ àlàáfíà lọ̀ ọ́,” kí àwọn aráàlú náà lè láǹfààní láti yíwà pa dà, kí wọ́n má báa bógun lọ. (Diutarónómì 20:10-13) Ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun “kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú, bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó.”—Ìsíkíẹ́lì 33:11, 14-16.b
Àwọn àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé láyé ìgbàanì, Ọlọ́run máa ń lo ogun láti fòpin sí ìwà burúkú táwọn ẹni ibi ń hù. Ọlọ́run nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ìgbà tí ogun máa wáyé àtàwọn tó máa ja ogun náà, kì í ṣe àwọn èèyàn. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé arógunyọ̀ ni Ọlọ́run, tó kàn ń pa èèyàn bí ẹni pa ẹran? Rárá o. Ọlọ́run kórìíra ìwà ipá. (Sáàmù 11:5) Ǹjẹ́ èrò tí Ọlọ́run ní nípa ogun wá yí pa dà nígbà tí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ wá sáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
a Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn ọmọ Kénáánì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ ja ogun náà. (Númérì 14:41-45) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn èyí, Jòsáyà Ọba kù gìrì lọ sójú ogun tí Ọlọ́run kò fọwọ́ sí, ó sì bá ogun náà lọ.— 2 Kíróníkà 35:20-24.
b Kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi fọ̀rọ̀ àlàáfíà lọ àwọn ọmọ Kénáánì kí wọ́n tó gbógun jà wọ́n? Ìdí ni pé irinwó [400] ọdún ni Ọlọ́run fi yọ̀ǹda fún àwọn ọmọ Kénáánì láti jáwọ́ nínú àwọn ìwàkiwà wọn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa gbógun dé, àwọn ọmọ Kénáánì yìí ti jingíri sínú ìwà burúkú wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 15:13-16) Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa wọ́n run pátápátá. Àmọ́, àwọn ọmọ Kénáánì kan ronú pìwà dà, wọ́n sì dá wọn sí.—Jóṣúà 6:25; 9:3-27.
-
-
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lẹ́yìn Tí Jésù Wá SáyéIlé Ìṣọ́—2015 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI ÈRÒ ỌLỌ́RUN NÍPA OGUN?
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lẹ́yìn Tí Jésù Wá Sáyé
Àwọn ará Róòmù ń fìyà jẹ àwọn Júù. Bíi ti àwọn baba ńlá wọn, wọ́n gbàdúrà léraléra pé kí Ọlọ́run gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Nígbà tó yá, wọ́n gbọ́ nípa Jésù. Ṣé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí lóòótọ́? Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù fi “ń retí pé ọkùnrin yìí ni ẹni tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti dá Ísírẹ́lì nídè” lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù tó ń fìyà jẹ wọ́n. (Lúùkù 24:21) Àmọ́ ìṣòro wọn kò yanjú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ run.
Kí ló ṣẹlẹ̀? Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi jà fún àwọn Júù bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀? Kí sì nìdí tí kò fi pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jagun, kí wọ́n lè gba ara wọn sílẹ̀? Ṣé Ọlọ́run ti yí èrò rẹ̀ nípa ogun pa dà ni? Rárá o. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àyípadà ńlá kan ti dé bá àwọn Júù. Wọ́n ti kọ Jésù Ọmọ Ọlọ́run ní Mèsáyà. (Ìṣe 2:36) Torí náà, Ọlọ́run pa orílẹ̀-èdè náà tì.—Mátíù 23:37, 38.
Ọlọ́run kò dáàbò bo àwọn Júù àti Ilẹ̀ Ìlérí náà mọ́, kò bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ogun mọ́, kò sì tì wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ jagun. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn Júù pàdánù àwọn ìbùkún tí wọ́n máa ń rí gbà látàrí bí wọ́n ṣe jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. Ìdí ni pé orílẹ̀-èdè tuntun, tí Bíbélì pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ló ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà báyìí. (Gálátíà 6:16; Mátíù 21:43) Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ló wá di Ísírẹ́lì Ọlọ́run tí à ń sọ yìí. Nígbà yẹn lóhùn-ún, Ọlọ́run mí sí Pétérù láti sọ fún wọn pé: “Nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.”—1 Pétérù 2:9, 10.
Ní báyìí tó jẹ́ pé àwọn Kristẹni ló wá di “ènìyàn Ọlọ́run,” ṣé Ọlọ́run wá bẹ̀rẹ̀ sí í jà fún wọn, kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ìyà táwọn ará Róòmù fi ń jẹ wọ́n? Àbí ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá àwọn ọ̀tá náà jagun? Rárá o, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, tó bá kan ogun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí, òun fúnra rẹ̀ ló máa ń pinnu ìgbà tí irú ogun bẹ́ẹ̀ máa wáyé. Ọlọ́run kò jagun fún àwọn Kristẹni nígbà yẹn lóhùn-ún, kò sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ jagun. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe àkókò yẹn ni Ọlọ́run fẹ́ dá wọn nídè lọ́wọ́ àwọn aninilára.
Torí náà, bíi ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ayé ìgbàanì, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní láti dúró de àkókò tí Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni ibi run. Kó tó di ìgbà yẹn, Ọlọ́run kò fún wọn láṣẹ láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jagun. Jésù Kristi mú kí kókó yìí ṣe kedere sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, kò sọ fún wọn pé kí wọ́n jagun, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó sọ fún wọn ni pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí àwọn ọmọ ogun Róòmù máa gbéjà ko ìlú Jerúsálẹ́mù ayé ìgbà yẹn, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ pé kí wọ́n sá kúrò níbẹ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ bá wọn lọ́wọ́ sí ogun náà. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.—Lúùkù 21:20, 21.
Láfikún sí i, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, . . . nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san,’ ni Jèhófà wí.” (Róòmù 12:19) Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yìí ni Pọ́ọ̀lù ń fà yọ. Ọ̀rọ̀ náà wà nínú Léfítíkù 19:18 àti Diutarónómì 32:35. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń gbà gbẹ̀san fún àwọn èèyàn rẹ ni pé ó máa ń tì wọ́n lẹ́yìn láti bá àwọn ọ̀tá wọn jagun. Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé èrò Ọlọ́run nípa ogun kò tíì yí pa dà. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ṣì rí ogun gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbẹ̀san fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kó sì mú òpin dé bá gbogbo ìnilára àti ìwà burúkú. Àmọ́ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí láyé ìgbàanì, Ọlọ́run nìkan ló ń pinnu ìgbà tí irú ogun bẹ́ẹ̀ máa wáyé àti àwọn tó máa ja ogun náà.
Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò fún àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní láṣẹ láti lọ jagun. Òde òní wá ńkọ́? Ǹjẹ́ Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí àwọn èèyàn kan máa jagun? Àbí àkókò ti tó lójú Ọlọ́run láti dá sí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kó sì jà fún wọn? Kí tiẹ̀ ni èrò Ọlọ́run nípa ogun lóde òní? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
-
-
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde ÒníIlé Ìṣọ́—2015 | November 1
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI ÈRÒ ỌLỌ́RUN NÍPA OGUN?
Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
Lóde òní, àwọn kan máa ń fìtínà àwọn ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ sì ń ké pe Ọlọ́run pé kó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára, àmọ́ kò dá wọn lójú pé ìyà náà máa dópin. Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wọn? Àwọn kan ń jagun kí wọ́n lè gba ara wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń fara ni wọ́n. Àmọ́, ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun bẹ́ẹ̀?
Ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa fòpin sí gbogbo ogun
Òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tó ń tuni nínú ni pé, Ọlọ́run ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn lóde òní, ó sì máa fòpin sí i. (Sáàmù 72:13, 14) Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn tí ojú ń pọ́n máa rí ìtura. Ìgbà wo ni èyí máa ṣẹlẹ̀? Ó máa jẹ́ “nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára . . . bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:7, 8) Ọjọ́ iwájú ni ìṣípayá Jésù yìí máa jẹ́, ní ìgbà ogun tí Bíbélì pè ní “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tí a tún ń pè ní ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣípayá 16:14, 16.
Kì í ṣe àwọn èèyàn ni Ọlọ́run máa lò láti ja ogun yẹn. Jésù Kristi tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run àtàwọn ańgẹ́lì alágbára ni Ọlọ́run máa lò láti gbógun ti àwọn ẹni ibi. Àwọn ọmọ ogun ọ̀run yìí ló máa fòpin sí gbogbo ìnilára.—Aísáyà 11:4; Ìṣípayá 19:11-16.
Èrò Ọlọ́run nípa ogun kò tíì yí pa dà títí dòní. Ó ṣì máa lo ogun láti fòpin sí ìnilára àti ìwà búburú. Àmọ́, bíi tí àwọn àkókò tó ti kọjá sẹ́yìn, Ọlọ́run nìkan ló máa ń pinnu ìgbà tí irú ogun bẹ́ẹ̀ máa wáyé àti àwọn tó máa ja ogun náà. Bá a ṣe sọ, Ọlọ́run ti pinnu pé ọjọ́ iwájú ni Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ máa ja ogun tó máa fòpin sí ìwà ibi, tó sì máa gba àwọn tó ń jìyà sílẹ̀. Èyí fi hàn pé inú Ọlọ́run kò dùn sí ogun tí àwọn èèyàn ń jà lónìí láìka ohun yòówù kí wọ́n máa jà fún.
Wo àpẹẹrẹ yìí: Ká sọ pé àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan ń jà nígbà tí Bàbá wọn kò sí nílé. Nígbà tó yá, wọ́n fi ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì pe bàbá wọn lórí fóònù kí wọ́n lè rojọ́ fún un. Ọ̀kan sọ fún bàbá wọn pé ẹnì kejì ló dá ìjà sílẹ̀. Ẹnì kejì sọ pé ẹni àkọ́kọ́ ló bú òun. Àwọn méjèèjì bẹ bàbá wọn pé kó wá dá sí ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn tí bàbá wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn méjèèjì tán, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má jà mọ́, kí wọ́n sì dúró títí òun máa fi dé láti wá yanjú ìjà wọn. Àwọn ọmọ méjèèjì dúró díẹ̀ de bàbá wọn. Àmọ́, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ ìjà. Nígbà tí bàbá wọn dé, inú rẹ̀ kò dùn sí àwọn méjèèjì, ó sì fìyà jẹ wọ́n torí pé wọn ò gbọ́ràn sí i lẹ́nu.
Lóde òní, àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jà máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí àwọn ṣẹ́gun. Àmọ́ Ọlọ́run kì í gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni nínú ogun táwọn èèyàn ń jà lónìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” Ó sì tún sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín.” (Róòmù 12:17, 19) Síwájú sí í, ó sọ pé kí àwọn èèyàn fi sùúrù ‘dúró de’ òun, kí òun lè gbẹ̀san fún wọn nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. (Sáàmù 37:7) Bí àwọn èèyàn bá kọ̀ láti dúró de àsìkò Ọlọ́run, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jagun, inú Ọlọ́run kì í dùn sí irú ogun bẹ́ẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run máa lo ogun Amágẹ́dọ́nì láti pa gbogbo àwọn tó ń dá wàhálà sílẹ̀ run. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run á “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9; Aísáyà 34:2) Èyí fi hàn pé ogun Amágẹ́dọ́nì ló máa fòpin sí gbogbo ogun.
Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni pé kò ní sí ogun mọ́. Jésù sọ nípa ìjọba yìí nínú àdúrà táwọn èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Kì í ṣe ogun nìkan ni Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí, ó tún máa mú ohun tó ń fa ogun kúrò, ìyẹn ìwà ìkà.a (Sáàmù 37:9, 10, 14, 15) Abájọ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi ń fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá.—2 Pétérù 3:13.
Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí Ìjọba Ọlọ́run tó mú gbogbo ìyà, ìnilára, àti ìwà ibi kúrò? Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ṣe ń ní ìmúṣẹ fi hàn pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé Sátánì. (2 Tímótì 3:1-5)b Láìpẹ́, Ọlọ́run máa lo ogun Amágẹ́dọ́nì láti mú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lọ sí òpin, Ìjọba Ọlọ́run á sì máa ṣàkóso.
Bá a ṣe sọ́ tẹ́lẹ̀, àwọn tó máa pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì ni “àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:8) Rántí pé, Ọlọ́run kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, títí kan àwọn ẹni ibi. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Torí pé “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run” nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, ó ń rí i dájú pé à ń wàásù ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” kí òpin tó dé. (2 Pétérù 3:8, 9; Mátíù 24:14; 1 Tímótì 2:3, 4) Dájúdájú, ìwàásù tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti mọ Ọlọ́run, kí wọn sì máa ṣègbọràn sí ìhìn rere Jésù. Èyí máa jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti gbé nínú ayé tí ogun kò ní sí mọ́.
a Ìjọba Ọlọ́run tún máa fòpin sí ikú tó jé ọ̀tá gbogbo èèyàn. Bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ,” Ọlọ́run máa jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti kú dìde, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn tó ti bógun lọ.
b Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
-