ORIN 102
Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Gbogbo wa pátá la ní - Ibi tá a kù sí. - Síbẹ̀, Jèhófà ń fìfẹ́ - Ṣèrànwọ́ fún wa. - Bàbá aláàánú ni; - Ó nífẹ̀ẹ́ wa púpọ̀. - Ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jáà; - Ká máa ṣèrànwọ́. 
- 2. Lójú tiwa, àwọn kan - Lè má níṣòro. - Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn lè - Má tó bá a ṣe rò. - Ó yẹ ká gbé wọn ró, - Ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. - Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà - Yóò tún ṣèrànwọ́. 
- 3. Àwọn tó j’áláìlera - Nílò ìrànwọ́. - Ká má ṣe dá wọn lẹ́bi, - Ká mára tù wọ́n. - Ká máa kíyè sí wọn, - Ká lè máa gbé wọn ró. - Tí a bá ń ràn wọ́n lọ́wọ́, - A ó rí ‘bùkún gbà. 
(Tún wo Àìsá. 35:3, 4; 2 Kọ́r. 11:29; Gál. 6:2.)