-
Nígbà Tí Ẹnì Tó O Nífẹ̀ẹ́ Bá KúIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Nígbà Tí Ẹni Tó O Nífẹ̀ẹ́ Bá Kú
“Ọlọ́run ló yé, ọmọ. Yéé sunkún.”
Ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ fún obìnrin kan tó ń jẹ́ Bebe nìyẹn níbi tí wọ́n ti lọ sin bàbá rẹ̀ tó kú nínú ìjàǹbá ọkọ̀.
Mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ ìdílé Bebe bí iṣan ọrùn ló sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Bebe. Àmọ́ kàkà kí ọ̀rọ̀ náà tù ú nínú, ńṣe ló tún dá kún ọgbẹ́ ọkàn rẹ̀ torí pé òun àti bàbá rẹ̀ sún mọ́ ara wọn gan-an. Gbogbo ìgbà ni Bebe máa ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ikú bàbá mi yìí ò dáa.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ó kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sínú ìwé kan, èyí sì fi hàn pé ọgbẹ́ ọkàn rẹ̀ kò tíì sàn.
Bíi ti Bebe, ó máa ń pẹ́ kéèyàn tó lè gbé ìbànújẹ́ tí ikú ń fà kúrò lára, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ló kú. Bíbélì tiẹ̀ dìídì pé ikú ní “ọ̀tá ìkẹyìn.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ìgbà téèyàn kò ronú rẹ̀ ni ikú máa ń ṣọṣẹ́, kò sì sí ohun tá a lè ṣe tí ikú bá dé. Ó máa ń dà bíi pé àwọn tá a fẹ́ràn jù ló ń pa. Kò sì sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ ikú. Torí náà, ó lè má rọrùn láti gbé e kúrò lọ́kàn nígbà tẹ́ni tá a fẹ́ràn bá kú.
Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé: ‘Báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó kéèyàn tó lè gbé ìbànújẹ́ náà kúrò lọ́kàn? Báwo lèèyàn ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn yìí? Báwo ni mo ṣe lè tu ẹni téèyàn rẹ̀ kú nínú? Ṣé ìrètí kankan wà fún àwọn èèyàn wa tó ti kú?’
-
-
Ṣé Ó Burú Kéèyàn Ṣọ̀fọ̀?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ
Ṣé Ó Burú Kéèyàn Ṣọ̀fọ̀?
Ṣé àìsàn ti dá ẹ gúnlẹ̀ rí? Àìsàn náà lè lọ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, tí wàá sì gbàgbé ohun tí àìsàn náà fojú ẹ rí. Àmọ́, ẹ̀dùn ọkàn tí ikú ń fà kì í lọ bọ̀rọ̀. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Alan Wolfelt sọ nínú ìwé rẹ̀ tó ń jẹ́ Healing a Spouse’s Grieving Heart pé, “ìbànújẹ́ náà kì í kúrò lọ́kàn.” Ó wá fi kún un pé: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn èèyàn, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ẹ̀dùn ọkàn yẹn máa fúyẹ́.”
Bí àpẹẹrẹ, wo bí Ábúráhámù ṣe hùwà nígbà tí ìyàwó rẹ̀ kú. Bíbélì sọ pé: “Ábúráhámù sì wọlé láti pohùn réré ẹkún Sárà àti láti sunkún lórí rẹ̀.” Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé ó pẹ́ díẹ̀ kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ tó fúyẹ́.a Àpẹẹrẹ míì ni ti Jékọ́bù, tí wọ́n parọ́ fún pé ẹranko kan ti pa Jósẹ́fù ọmọ rẹ̀ jẹ. “Ọ̀pọ̀ ọjọ́” ni ó fi ṣọ̀fọ̀, kò sì sí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kankan tó lè tù ú nínú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ikú ọmọkùnrin rẹ̀ Jósẹ́fù ṣì wúwo lọ́kàn rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 23:2; 37:34, 35; 42:36; 45:28.
Ábúráhámù ṣọ̀fọ̀ nígbà tí Sárà ìyàwó rẹ̀ kú
Bó ṣe máa ń rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí nìyẹn tí ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn bá kú. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.
“Robert ọkọ mi kú ní July 9, 2008. Àárọ̀ ọjọ́ tí ìjàǹbá burúkú yìí ṣẹlẹ̀ kò yàtọ̀ sí àwọn ọjọ́ míì lójú mi. Lẹ́yìn tá a jẹun tán, a fi ẹnu ko ara wa lẹ́nu, a dì mọ́ra bá a ṣe máa ń ṣe lárààárọ̀ kó tó lọ sí ibiṣẹ́, a sì sọ fún ara pé ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ.’ Ó ti lé lọ́dún mẹ́fà báyìí tí ọkọ mi ti kú, síbẹ̀ ọgbẹ́ ọkàn yẹn kò tíì kúrò lọ́kàn mi. Mi ò sì rò pé ìbànújẹ́ náà lè tán lára mi.”—Gail, ẹni ọgọ́ta [60] ọdún.
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pé ọdún méjìdínlógún [18] tí ìyàwó mi ti kú, mo ṣì ń ṣàárò rẹ̀, mi ò tíì gbé àdánù náà kúrò lára mi. Nígbàkigbà tí mo bá rí ohun tó rẹwà, mo máa ń rántí ìyàwó mi, mo sì máa ń ronú bí inú rẹ̀ ì bá ṣe dùn tó ká sọ pé òun náà rí ohun tí mo rí.”—Etienne, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84].
Òótọ́ kan ni pé ó máa ń dùn wá wọra tí a bá pàdánù ẹnì kan, kì í sì í kúrò lọ́kàn wa bọ̀rọ̀. Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ṣe máa ń fi ẹ̀dùn ọkàn hàn yàtọ̀ síra, torí náà kò bọ́gbọ́n mu ká máa ṣàríwísí àwọn míì torí bí wọ́n ṣe ṣe nígbà tí èèyàn wọn kú. Lẹ́sẹ̀ kan náà, kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi tá a bá bara jẹ́ gan-an nígbà téèyàn wa bá kú. Báwo la ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn yìí?
a Ísákì ọmọkùnrin Ábúráhámù náà ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Bí a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” nínú ìwé ìròyìn yìí, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ísákì ṣì ń ṣọ̀fọ̀ ikú Sárà ìyá rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 24:67.
-
-
Bó O Ṣe Lè Fara Da Ọgbẹ́ ỌkànIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ
Bó O Ṣe Lè Fara Da Ọgbẹ́ Ọkàn
Ọ̀pọ̀ ìsọfúnni làwọn èèyàn ti tẹ̀ jáde lórí kókó yìí. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo rẹ̀ ló wúlò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan á sọ pé o kò gbọ́dọ̀ sunkún tàbí kó o bara jẹ́ lọ́nàkọnà. Àwọ́n míì á sọ pé àfi kó o sun ẹkún àsun-ùn-dákẹ́ kó lè hàn pé ó dùn ẹ́. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ bá a ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn, ìwádìí táwọn èèyàn sì ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé òótọ́ ni Bíbélì sọ.
Láwọn ilẹ̀ kan, wọ́n gbà pé ọ̀lẹ ọkùnrin ló máa ń sunkún. Àmọ́, ṣé ó yẹ kójú máa ti èèyàn láti sunkún, kódà tó bá jẹ́ ní gbangba? Àwọn onímọ̀ nípa ọpọlọ gbà pé sísunkún jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn ń gbà fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn. Tó o bá sì fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn, ó máa jẹ́ kó o lè gbé ọ̀ràn náà kúrò lọ́kàn, láìka bí ikú ẹni náà ṣe dùn ẹ́ tó. Tá a bá pa ẹ̀dùn ọkàn náà mọ́ra, ńṣe ló máa dá kún ìbànújẹ́ náà. Bíbélì kò fara mọ́ èrò àwọn kan pé kò dáa kéèyàn sunkún tàbí pé ọ̀lẹ ọkùnrin ló máa ń sunkún. Wo àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú, Jésù sunkún ní gbangba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lágbára láti jí i dìde.—Jòhánù 11:33-35.
Nígbà míì, ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ lè máa kanra, àgàgà tó bá jẹ́ pé ńṣe lẹni náà kú láìròtẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ máa kanra. Irú bí ìgbà tí ẹnì kan tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún bá sọ ọ̀rọ̀ láìronú tàbí sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́. Ọkùnrin kan lórílẹ̀ èdè South Africa tó ń jẹ́ Mike sọ pé: “Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni mí nígbà tí bàbá mi kú. Lọ́jọ́ ìsìnkú, òjíṣẹ́ ìjọ Anglican kan sọ pé, Ọlọ́run nílò àwọn èèyàn rere, ó sì máa ń yára mú wọn lọ.a Èyí múnú bí mi gan-an torí pé a ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ bàbá mi. Ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] ti kọjá báyìí, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ náà ṣì ń dùn mí.”
Àwọn míì máa ń dá ara wọn lẹ́bi, pàápàá tó bá jẹ́ ikú òjijì lẹni náà kú. Ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà lè máa sọ léraléra pé, ‘Ká ní mo ti ṣe báyìí ni, ì bá máà kú.’ Tàbí kó jẹ́ pé ìjà ni ìwọ àti ẹni tó kú náà fi túká nígbà tẹ́ ẹ ríra kẹ́yìn. Èyí lè dá kún bó o ṣe ń dá ara rẹ lẹ́bi.
Tó o bá ń kanra tàbí tí ò ń dá ara rẹ lẹ́bi, ó máa dáa kó o má ṣe pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fọ̀rọ̀ náà lọ ọ̀rẹ́ rẹ tó máa fara balẹ̀ gbọ́ ẹ tó sì máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ló máa ń ronú bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
Ọ̀rẹ́ tó dáa jù tí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ lè ní ni Ẹlẹ́dàá wa, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. O lè tú ọkàn rẹ jáde sí Ọlọ́run nínú àdúrà nítorí pé ‘ó bìkítà fún ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Bákan náà, Ọlọ́run ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó bá gbàdúrà sí òun fún ìrànlọ́wọ́ máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:6, 7) Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ kí ọkàn wa lè fúyẹ́ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. O lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń tuni nínú. (Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀.) O tiẹ̀ lè há díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Bíbélì náà sórí. Irú àwọn ẹsẹ Bíbélì báyìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ pàápàá tó o bá dá wà lọ́wọ́ alẹ́, tí o kò sì rí oorun sùn.—Aísáyà 57:15.
Ẹni ogójì [40] ọdún ni ọkùnrin kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Jack. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àrùn jẹjẹrẹ pa ìyàwó rẹ̀. Jack sọ pé nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Àmọ́ gbígbàdúrà ti ràn án lọ́wọ́. Ó ní: “Tí mo bá ti gbàdúrà sí Jèhófà, kì í ṣe mí bíi pé mo dá wà mọ́. Nígbà míì tí oorun bá dá lójú mi láàárín òru, mo máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú nínú Bíbélì, màá sì ronú lé wọn lórí. Lẹ́yìn náà, màá wá sọ ẹdùn ọkàn mi fún Ọlọ́run, ìyẹn sì máa ń mú kí ọkàn mi tutù pẹ̀sẹ̀. Ara mi á wá balẹ̀, èyí sì máa ń jẹ́ kí n rí oorun sùn pa dà.”
Àìsàn kan gbẹ̀mí ìyá ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Vanessa. Àdúrà ló ran òun náà lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Nígbà tí nǹkan bá le koko, mo máa ń ké pe orúkọ Ọlọ́run, màá sì bú sẹ́kún. Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà mi, ó sì máa ń fún mi lókun tí mo nílò.”
Àwọn tó máa ń gba àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nímọ̀ràn sọ pé ó máa ń dáa kí àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn aráàlú lọ́wọ́. Àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ kó o láyọ̀, á sì mú kí ọkàn rẹ fúyẹ́. (Ìṣe 20:35) Ọ̀pọ̀ Kristẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ti rí i pé ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ti mú kí ara túbọ̀ tù wọ́n.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
a Bíbélì kò fi irú ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni. Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ ohun mẹ́ta tó máa ń fa ikú.—Oníwàásù 9:11; Jòhánù 8:44; Róòmù 5:12.
-
-
Bá A Ṣe Lè Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ NínúIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ
Bá A Ṣe Lè Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí pé o kò mọ ohun tó o máa ṣe nígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ? Nígbà míì o lè má mọ ohun tó o máa sọ, kó o wá kúkú dákẹ́ láìṣe ohunkóhun. Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nílò kò ju pé kó o wà lọ́dọ̀ wọn, kó o sì kí wọn pé “Ẹ pẹ̀lẹ́ o, ẹ kú ọ̀rọ̀ èèyàn.” Láwọn ilẹ̀ kan, gbígbá ẹni náà mọ́ra tàbí kéèyàn rọra fọwọ́ kàn án máa fi hàn pé ò ń bá a kẹ́dùn. Tí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà bá fẹ́ sọ̀rọ̀, fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Ohun tó wá dáa jù ni pé kó o bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ ilé kan, bóyá àwọn tí wọn ò lè ṣe fúnra wọn lásìkò yẹn. Irú bíi síse oúnjẹ, títọ́jú àwọn ọmọ tàbí kó o bá wọn ṣètò ìsìnkú tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣe wọ́n láǹfààní ju kéèyàn kàn máa sọ̀rọ̀ ṣáá.
Bí àkókò ti ń lọ, o lè sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó kú náà, irú bí ìwà rere tẹ́ni náà ní àti àkókò alárinrin tẹ́ ẹ jọ gbádùn. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè mú kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà tújú ká. Bí àpẹẹrẹ, Pam tí ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Ian kú lọ́dún mẹ́fà sẹ́yìn sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ ohun rere tí lan ṣe tí mi ò tiẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ rárá, èyí sì máa ń múnú mi dùn.”
Àwọn olùṣèwádìí ròyìn pé àwọn èèyàn máa ń rọ́ lọ kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ gbàrà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá wáyé. Àmọ́ kì í pẹ́ táwọn èèyàn á fi pa ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ tì. Torí náà, sapá láti máa kàn sí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà lóòrèkóòrè lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.a Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń mọ rírì rẹ̀ táwọn èèyàn bá kàn sí wọn kí ẹdùn ọkàn wọn lè fúyẹ́.
Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kaori lórílẹ̀-èdè Japan. Ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò nígbà tí ìyá rẹ̀ kú, tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà sì tún kú ní nǹkan bí ọdún kan àti oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà. Àmọ́, ó rí ìtìlẹyìn látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tó dúró tì í. Ritsuko jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Ritsuko dàgbà ju Kaori lọ dáadáa. Ó sọ fún Kaori pé kó jẹ́ káwọn jọ máa ṣọ̀rẹ́. Kaori sọ pé: “Kí n má parọ́, inú mi ò dùn sí i. Mi ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni gba ipò ìyá mi, mi ò tiẹ̀ rò pé ẹnikẹ́ni lè ṣe bí ìyá fún mi. Àmọ́, torí bí màmá yìí ṣe ń ṣe sí mi, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ ọn. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la jọ máa ń lọ wàásù, tá a sì jọ máa ń lọ sí ìpàdé Kristẹni. Ó máa ń pè mí pé kí n wá mu tíì lọ́dọ̀ òun, ó máa ń gbé oúnjẹ wá fún mi, ó sì máa ń fi lẹ́tà àti káàdì ránṣẹ́ sí mi. Ìwà rere tí màmá yìí ń hù ní ipa rere lórí mi.”
Ó ti lé lọ́dún méjìlá báyìí tí ìyá Kaori ti kú. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, òun àti ọkọ rẹ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Kaori sọ pé: “Màmá yìí kò fọ̀rọ̀ mi ṣeré rárá. Tí mo bá lọ sílé, mó máa ń lọ kí i, mo sì máa ń gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìṣírí tó máa ń sọ.”
Ẹlòmíì tó jàǹfààní látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ adúrótini ni Poli, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Cyprus. Èèyàn dáadáa ni ọkọ Poli, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sozos. Ọwọ́ pàtàkì ló fi mú ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ. Ó sábà máa ń pe àwọn ọmọ aláìlóbìí àtàwọn opó láti wá bá wọn ṣeré kí wọ́n sì jọ jẹun. (Jákọ́bù 1:27) Àmọ́, kókó kan tó yọ nínú ọpọlọ rẹ̀ ṣekú pa á lẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta [53]. Poli sọ pé: “Mo pàdánù ọkọ mi tá a ti jọ gbé pa pọ̀ fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33].”
Wá ọ̀nà tó o lè gbà ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́
Lẹ́yìn ìsìnkú, Poli àti Daniel ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kó lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Poli sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ wa ní ìjọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa tàbí ipò tá a wà. Síbẹ̀ wọ́n máa ń sún mọ́ wa, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ tútù fún wa, wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Ìrànlọ́wọ́ ńlá gbáà ni èyí jẹ́ fún ọmọ mi lákòókò tó nílò bàbá rẹ̀ gan-an yìí. Àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ kò fọ̀rọ̀ Daniel ṣeré rárá. Ọ̀kan tiẹ̀ wà lára wọn tó máa ń mú Daniel jáde tó bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí nígbà tó bá fẹ́ lọ gbá bọ́ọ̀lù.” Nǹkan ti ń lọ dáadáa fún Poli àti ọmọ rẹ̀ báyìí.
Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ ká sì tù wọ́n nínú. Àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nípa ọjọ́ ọ̀la tó wà nínú Bíbélì pẹ̀lú máa ń tuni nínú.
a Àwọn kan tiẹ̀ máa ń kọ déètì ọjọ́ tí ẹni náà kú sórí kàlẹ́ńdà wọn, kí wọ́n lè rántí láti tu ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà nínú nígbà tó nílò ìtùnú. Bóyá ní àyájọ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tàbí lọ́jọ́ míì tó sún mọ́ ọn.
-
-
Àwọn Òkú Máa Jíǹde!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 3
-
-
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ
Àwọn Òkú Máa Jíǹde!
Ṣé o rántí Gail tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó ń rò ó pé bóyá ni òun máa lè gbé ikú ọkọ òun kúrò lọ́kàn. Àmọ́, ó ń retí ọjọ́ tó máa rí Rob ọkọ rẹ̀ nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Gail sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì tí mo fẹ́ràn jù ni Ìṣípayá 21:3, 4.” Ó kà pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”
Gail sọ pé: “Ìlérí yìí tuni nínú. Mo káàánú àwọn kan tí èèyàn wọn ti kú, àmọ́ tí wọn kò mọ̀ pé àwọn ṣì tún lè rí wọn pa dà nígbà àjíǹde.” Gail wá ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ohun tó gbà gbọ́, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Ó ń sọ ìlérí Ọlọ́run fún àwọn aládùúgbò rẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú kan tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’
Ó dá Jóòbù lójú pé òun máa jíǹde
Ó ṣeé ṣe kí èyí yà ẹ́ lẹ́nu! Ṣùgbọ́n jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù yẹ̀ wò. Àìsàn burúkú kan kọ lù ú. (Jóòbù 2:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ronú pé ó sàn kí òun kú, síbẹ̀ ó ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run lágbára láti jí òun dìde pa dà sí ayé. Ó fi ìdánilójú sọ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù [Sàréè] . . . Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:13, 15) Ó dá Jóòbù lójú pé Ọlọ́run kò ní gbàgbé òun, á sì fẹ́ láti jí òun dìde.
Láìpẹ́, Ọlọ́run máa jí Jóòbù àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì dìde, nígbà tó bá sọ ayé yìí di Párádísè. (Lúùkù 23:42, 43) Bíbélì mú un dá wa lójú nínú ìwé Ìṣe 24:15 pé: “Àjíǹde . . . yóò wà.” Jésù fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Jóòbù máa rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí wọ̀nyẹn. Nígbà tó bá rí i pé òun pa dà ní “okun inú ti ìgbà èwe” tí “ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe.” (Jóòbù 33:24, 25) Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó bá fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè fún wa, ìyẹn ni bó ṣe máa jí àwọn òkú dìde pa dà sí ayé.
Tí ìwọ náà bá ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn rẹ kan tó kú, àwọn ohun tá a ti jíròrò yìí lè má gbé ìbànújẹ́ náà kúrò lọ́kàn rẹ pátápátá. Àmọ́ tó o bá ń ronú lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì, wà á nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, wàá sì lókun láti máa fara dà á nìṣó.—1 Tẹsalóníkà 4:13.
Ṣé wà á fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè fara da ìbànújẹ́? Tàbí o ní àwọn ìbéèrè míì tó fara pẹ́ ẹ, irú bí “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi àti ìjìyà?” Jọ̀ọ́ lọ sórí ìkànnì wa, www.jw.org/yo, kó o sì rí bí Bíbélì ṣe fún wa ní ìdáhùn tó tuni nínú, tó sì gbéṣẹ́ lónìí.
-