ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ṣé Lóòótọ́ Ló Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 2
    • Wọ́n gbé òkú Jésù kúrò lórí òpó igi, àwọn ọmọlẹ́yìn sì ń wò ó látọ̀ọ́kán

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÍ JÉSÙ FI JÌYÀ TÓ SÌ KÚ?

      Ṣé Lóòótọ́ Ló Ṣẹlẹ̀?

      Wọ́n pa Jésù ará Násárétì nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án ni pé ó dìtẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì lù ú ní àlùbami kí wọ́n tó kàn án mọ́gi. Ikú oró ló kú. Àmọ́, Ọlọ́run jí i dìde, ó sì pa dà sí ọ̀run lẹ́yìn ogójì [40] ọjọ́ tó jíǹde.

      Inú ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù ni ìtàn yìí wà. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló ṣẹlẹ̀? Ìbéèrè pàtàkì lèyí jẹ́, torí pé tí kò bá ṣẹlẹ̀, á jẹ́ pé alá tí kò lè ṣe ni ìrètí tí àwa Kristẹni ní pé ayé máa di Párádísè, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa. (1 Kọ́ríńtì 15:14) Lọ́wọ́ kejì, tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bá wáyé lóòótọ́, á jẹ́ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa fún àwa èèyàn, a sì máa ní láti sọ nípa rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Torí náà, ṣé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù àbí ìtàn àròsọ lásán ni?

      OHUN TÍ Ẹ̀RÍ FI HÀN

      Àwọn ìwé Ìhìn Rere yìí kò dà bí àwọn ìwé ìtàn àròsọ, torí pé ó ṣe àwọn àkọsílẹ̀ tó péye àti àwọn àlàyé tó kún rẹ́rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ orúkọ oríṣiríṣi ìlú tó ṣì wà títí dòní. Wọ́n tún sọ nípa àwọn èèyàn tó gbé ayé nígbà yẹn, tí àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ náà sì sọ̀rọ̀ nípa wọn.—Lúùkù 3:1, 2, 23.

      Àwọn òǹkọ̀wé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti ìkejì pàápàá sọ̀rọ̀ nípa Jésù.a Ohun tí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ nípa bí wọ́n ṣe pa Jésù bá ọ̀nà tí àwọn ará Róòmù máa ń gbà pa àwọn èèyàn nígbà yẹn mu. Láfikún sí i, kò sí àbùmọ́ tàbí àyọkúrò èyíkéyìí nínú ohun tí wọ́n kọ. Kódà, wọ́n sọ ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fúnra wọn hù. (Mátíù 26:56; Lúùkù 22:24-26; Jòhánù 18:10, 11) Gbogbo èyí fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù, ó sì péye.

      ÀJÍǸDE JÉSÙ WÁ Ń KỌ́?

      Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ gbà pé Jésù gbáyé ó sì kú, síbẹ̀ àwọn kan ò gbà pé Jésù jíǹde. Kódà, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kò kọ́kọ́ gbà gbọ́ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jésù ti jíǹde. (Lúùkù 24:11) Àmọ́ wọ́n kò ṣiyèméjì mọ́ nígbà tí wọ́n rí Jésù ní àsìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. Ó tiẹ̀ nígbà kan tí Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ.—1 Kọ́ríńtì 15:6.

      Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ pé àwọn lè fẹ̀wọ̀n gbára tàbí kí wọ́n pa àwọn, síbẹ̀ wọ́n fi ìgboyà sọ nípa àjíǹde Jésù fún gbogbo èèyàn, kódà fún àwọn tó ṣekú pa Jésù. (Ìṣe 4:1-3, 10, 19, 20; 5:27-32) Ṣé ó máa ṣeé ṣe fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ní irú ìgboyà bẹ́ẹ̀ tí kò bá dá wọn lójú pé Jésù ti jíǹde? Torí pé Jésù jíǹde lóòótọ́ ló mú kí ẹ̀sìn Kristẹni lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nígbà yẹn àti lóde òní.

      Àwọn ẹ̀rí fi hàn pé òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni àwọn àkọsílẹ̀ nípa ikú àti àjíǹde Jésù tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Tá a bá fara balẹ̀ ka àwọn ìwé Ìhìn Rere yìí, ó máa dá wa lójú pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Ìgbàgbọ́ tá a sì ní máa túbọ̀ lágbára sí i tá a bá mọ ìdí tí wọ́n fi ṣẹlẹ̀. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé èyí.

      a Tacitus, tí wọ́n bí ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Kristẹni kọ̀wé pé “Kristi táwọn Kristẹni fi sọ ara wọn lórúkọ ni Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn baálẹ̀ wa dájọ́ ikú fún tí wọ́n sì pa nígbà ìjọba Tìbéríù.” Àwọn míì tó tún mẹ́nu kan Jésù ni Suetonius tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní; òpìtàn Júù náà Josephus tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti Pliny Kékeré tó jẹ́ gómìnà Bítíníà tó gbáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì.

      Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Ọ̀pọ̀ Ìwé Míì Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Jésù?

      Kárí ayé láwọn èèyàn ti mọ Jésù, ṣé ó tún yẹ ká máa retí pé kí àwọn ìwé míì tí wọ́n kọ lásìkò yẹn tó yàtọ̀ sí Bíbélì sọ nípa ìtàn Jésù? Ó lè má pọn dandan. Ìdí ni pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn ni wọ́n kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ìwọ̀nba díẹ̀ nínú ìwé tí wọ́n kọ lásìkò yẹn ló ṣì wà títí dòní. (1 Pétérù 1:24, 25) Àti pé Jésù ni àwọn ọ̀tá tó pọ̀, kò sì dájú pé àwọn wọ̀nyí máa kọ ohun táá mú kí àwọn èèyàn gba Jésù gbọ́.

      Nígbà tí Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì ń sọ nípa àjíǹde Jésù, ó ní: “Ọlọ́run gbé Ẹni yìí dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì yọ̀ǹda fún un láti fara hàn kedere, kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọ́run ti yàn ṣáájú, fún àwa, tí a bá a jẹ, tí a sì bá a mu lẹ́yìn tí ó dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 10:40, 41) Kí nìdí tí Jésù kò fi fara han gbogbo èèyàn? Ìwé Ìhìn Rere Mátíù sọ pé nígbà táwọn ọ̀tá Jésù gbọ́ pé ó ti jíǹde, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa bo ìròyìn náà mọ́lẹ̀.—Mátíù 28:11-15.

      Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jésù kò fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa àjíǹde rẹ̀ ni? Rárá o, torí Pétérù sọ pé: “Ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná pé ẹni tí Ọlọ́run ti fàṣẹ gbé kalẹ̀ nìyí pé kí ó jẹ́ onídàájọ́ alààyè àti òkú.” Ohun táwọn Kristẹni tòótọ́ ti ṣe látìgbà náà títí dòní nìyẹn.—Ìṣe 10:42.

  • Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó sì Kú?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 2
    • Onírúurú àwọn èèyàn ń gbádùn ní Párádísè

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

      Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó Sì Kú?

      “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.”​—Róòmù 5:12

      Ádámù àti Éfà ń wo èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀; Ádámù àti Éfà ní ọjọ́ ogbó wọn; wọ́n ń gbé pósí lọ sí sàréè

      Kí lo máa sọ tí wọ́n bá bi ẹ́ pé, “Ṣé o fẹ́ wà láàyè títí lọ fáàbàdà?” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé àwọn fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bí ohun tí kò ṣeé ṣe nírú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa jọ lójú wọn. Wọ́n máa ń sọ pé awáyé máà kú ò sí.

      Ká sọ pé wọ́n bi ẹ́ ní ìbéèrè yẹn lọ́nà míì, pé, “Ṣé o ti ṣe tán tó o fẹ́ kú?” Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa dáhùn pé rárá o. Kí ni èyí fi hàn? Èyí jẹ́ ká rí i pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti wà láàyè láìka ìṣòro yòówù ká máa kojú. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà táá fi wù wá láti máa wà láàyè. Kódà ó sọ pé, “àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.”—Oníwàásù 3:11.

      Àmọ́ ní báyìí, àwa èèyàn ń kú. Kí ló fà á? Ǹjẹ́ Ọlọ́run ti ṣe ohunkóhun láti gbà wá lọ́wọ́ ikú? Bíbélì fún wa láwọn ìdáhùn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, àwọn ìdáhùn náà sì jẹ́ ká mọ ìdí tí Jésù fi jìyà tó sì kú.

      BÍ NǸKAN ṢE DOJÚ RÚ

      Orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ó sì sọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó. Àkọsílẹ̀ náà sọ bí wọ́n ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì pàdánù àǹfààní yẹn. Torí pé Bíbélì kàn sọ ìtàn náà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, àwọn kan sọ pé ìtàn àròsọ lásán ni. Àmọ́, bí àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere ṣe jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé.a

      Kí wá ni àbájáde àìgbọràn Ádámù? Bíbélì dáhùn pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ádámù di ẹlẹ́ṣẹ̀ torí pé ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ó tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tó ní láti wà láàyè títí láé, ó sì kú nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá, a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀. Èyí sì máa ń mú ká ṣàìsàn, ká darúgbó, ká sì kú. Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ìdí tá a fi ń kú bá ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ mu, ìyẹn ni pé ohun tí àwọn òbí bá ní ni ọmọ máa jogún. Àmọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti ṣe ohunkóhun láti gbà wá lọ́wọ́ ikú?

      OHUN TÍ ỌLỌ́RUN TI ṢE

      Ọlọ́run ṣètò láti ra ohun tí Ádámù gbé sọnù pa dà fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ìyẹn ni àǹfààní láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣe èyí?

      Ìwé Róòmù 6:23 sọ pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” Èyí fi hàn pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi kú. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ìdí sì nìyẹn tá a fi ń kú. Àmọ́, kì í ṣe ẹ̀bi wa pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ torí pé ńṣe la jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ kó lè wá san ‘owó ọ̀yà ẹ̀ṣẹ̀’ náà nítorí wa. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe?

      Onírúurú àwọn èèyàn ń gbádùn ní Párádísè

      Ikú Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà, ká sì láyọ̀

      Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé ṣàìgbọràn, èyí ló fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Torí náà, ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, a nílò ẹni pípé tó máa jẹ́ onígbọràn títí dójú ikú. Bíbélì ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà yìí: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” (Róòmù 5:19) Jésù ni ẹnì kejì tí Bíbélì yìí ń tọ́ka sí. Ó fi ọ̀run sílẹ̀, ó di èèyàn tí kò lẹ́ṣẹ̀b, ó sì kú fún wa. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti rí ojúure Ọlọ́run, ká sì nírètí láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà.

      ÌDÍ TÍ JÉSÙ FI JÌYÀ TÓ SÌ KÚ

      Kí wá nìdí tó fi pọn dandan kí Jésù kú kó tó lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? Ṣé Ọlọ́run ò kàn lè sọ pé kí àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù máa wà láàyè títí lọ? Ó kúkú lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ èyí máa ta ko òfin tó sọ pé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Òfin yìí kì í sì ṣe òfin tó ṣeé fọwọ́ rọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tàbí tó ṣeé yí pa dà nígbàkigbà. Títẹ̀lé òfin yìí máa fi hàn pé Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ òdodo.—Sáàmù 37:28.

      Tí Ọlọ́run bá gbójú fo ìdájọ́ òdodo nínú ọ̀rọ̀ yìí, èyí lè mú ká máa ronú pé bóyá ni Ọlọ́run ò ni gbójú fo ìdájọ́ òdodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ míì tó ṣe pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, ṣé Ọlọ́run máa ṣe ìdájọ́ tó yẹ tó bá fẹ́ pinnu àwọn tó máa wà láàyè títí láé nínú àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù? Ṣé ọkàn wa máa balẹ̀ pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Àmọ́, Ọlọ́run ò gbójú fo ìdájọ́ òdodo nínú bó ṣe ṣètò ìgbàlà fún wa. Èyí sì jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ṣe ohun tó tọ́.

      Nípasẹ̀ ikú Jésù, Ọlọ́run ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wa ká lè wà láàyè títí lọ fáàbàdà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ nínú ìwé Jòhánù 3:16 pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Ikú Jésù jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kì í bo ìdájọ́ òdodo mọ́lẹ̀, àmọ́ ní pàtàkì ó jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni Ọlọ́run ní fún àwa èèyàn.

      Ṣùgbọ́n, kí nìdí tí Jésù fi jẹ adúrú ìyà tó jẹ láyé tó sì tún wá kú ikú oró bí àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe sọ? Sátánì Èṣù sọ pé kò sẹ́ni tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tó bá rí àdánwò, àmọ́ bí Jésù ṣe jẹ adúrú ìyà yẹn títí tó fi kú fi hàn pé irọ́ gbuu ni Èṣù pa. (Jóòbù 2:4, 5) Ohun tí Sátánì sọ yìí jọ òótọ́ nígbà tó tan Ádámù tó jẹ́ ẹni pípé láti dẹ́ṣẹ̀. Àmọ́, Jésù tóun náà jẹ́ ẹni pípé bíi ti Ádámù jẹ́ olóòótọ́ láìka adúrú ìyà tó jẹ. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Ádámù náà lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ká sọ pé ó pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí Jésù ṣe fara da àdánwò jẹ́ àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé lónìí. (1 Pétérù 2:21) Ọlọ́run wá san ọmọ rẹ̀ lẹ́san torí ìgbọràn rẹ̀ nípa fífún un ní àìleèkú ní ọ̀run.

      BÓ O ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ

      Lóòótọ́ ni Jésù kú. Ní báyìí, ọ̀nà ìyè ayérayé ti ṣí sílẹ̀. Ṣé ó wù ẹ́ láti wà láàyè títí lọ fáàbàdà? Jésù sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

      Àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí ń rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ àti Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. O sì tún lè rí ìsọfúnni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org/yo.

      a Wo àkòrí tá a pè ní “The Historical Character of Genesis,” nínú ìwé Insight on the Scriptures, Apá kìíní, ojú ìwé 922. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

      b Ọlọ́run fi ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ sínú Màríà, ó sì lóyún. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì dáàbò bo Jésù kó máa bàa jogún ẹ̀ṣẹ̀ látara Màríà.—Lúùkù 1:31, 35.

      Wọ́n ń pín àkàrà aláìwú

      “Ẹ Máa Ṣe Èyí”

      Ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù kó àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ, ó si fi Ìrántí Ikú rẹ̀ lélẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ọdọọdún ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pé jọ láti pa àṣẹ yìí mọ́ ní àyájọ́ ọjọ́ tí Jésù kú. Lọ́dún tó kọjá, àwọn 19,862,783 ló wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

      Lọ́dún yìí, ọjọ́ Wednesday, March 23 la máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. À ń fi àsìkò yìí ké sí ìwọ, àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kó o lè wá gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí Bíbélì. Àsọyé náà máa ṣàlàyé ìdí tó fi pọn dandan kí Jésù kú àti bí ikú rẹ̀ ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní. Ọ̀fẹ́ ni ìjókòó, a kò sì ní gbégbá owó. Jọ̀wọ́, béèrè aago tí wọ́n máa ṣe é àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe é lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá wà ládùúgbò rẹ. O sì lè wò ó lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org/yo.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́