ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gbogbo Wa La Nílò Ìtùnú
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 5
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?

      Gbogbo Wa La Nílò Ìtùnú

      Ìyá kan tó ń tu ọmọ rẹ̀ nínú

      Ṣé o rántí ìgbà kan tó o ṣubú ní kékeré? Bóyá tápá rẹ tiẹ̀ kán tàbí tó o fi ojúgun gbá. Ṣé o ṣì lè rántí bí ìyá rẹ ṣe rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún? Ó ṣeé ṣe kí màmá rẹ bá ẹ nu ojú ọgbẹ́ náà, kí wọ́n sì fi nǹkan dè é. Bó o ṣe ń ké ni wọ́n á máa kí ẹ pẹ̀lẹ́, tí wọ́n á sì máa gbá ẹ mọ́ra títí tọ́kàn rẹ á fi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Nígbà yẹn, kò ṣòro fún ẹ láti rẹ́ni tù ẹ́ nínú.

      Àmọ́ ńṣe ni gbogbo nǹkan ń le sí i bá a ṣe ń dàgbà. Bí ìṣòro ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe ń nira sí i láti rẹ́ni tù wá nínú. Ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ ń bá fínra kọjá ká de ojú ọgbẹ́ àti ká gbáni mọ́ra lọ. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

      • Ǹjẹ́ iṣé ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ rí? Julian sọ pé ńṣe lòun ń kanra lódìlódì nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ òun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Báwo ni máa ṣe tọ́jú ìdílé mi? Lẹ́yìn gbogbo ọdún tí mo fi ṣiṣẹ́ àṣekára ní ilé-iṣé yìí, kí ló dé tí wọ́n fi ronú pé mi ò wúlò fún àwọn mọ́?’

      • Lóòótọ́, ọkàn rẹ lè gbọgbẹ́ torí pé ìdílé rẹ ti tú ká. Raque sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi kàn ṣàdédé kúrò nílé ní oṣù méjìdínlógún [18] sẹ́yìn, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n da aṣọ ìbànújẹ́ bò mí. Àfi bíi pé ọkàn mi ya sí méjì. Mò ń jẹ̀rora nínú lọ́hùn, ó sì ń hàn nínú gbogbo ohun tí mò ń ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà mí lẹ́rù gan-an.”

      • Ó lè jẹ́ àìsàn burúkú kan ló ń ṣe ẹ́ tí kò sì sí àmì pé ó máa lọ rárá. Láwọn ìgbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi Jóòbù tó kérora pé: “Mo kọ̀ ọ́; èmi kì yóò wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Jóòbù 7:16) Luis tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n kú kíá jàre.”

      • Ó sì lè jẹ́ pé ikú ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ ló ń mú kó o máa wá ìtùnú. Robert sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ pé ọmọkùnrin mi kú nínú jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú, ó kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé irọ́ ni, kò pẹ́ sásìkò yẹn ni ọgbẹ́ ọkàn ńlá dé bá mi, irú èyí tí Bíbélì fi wé idà gígùn tó ń gúnni lọ́kàn.”​—Lúùkù 2:⁠35.

      Robert, Luis, Raquel àti Julian rí ìtùnú gbà, kódà nínú ipò ìbànújẹ́ tí wọ́n wà yẹn. Wọ́n rí Ẹnì kan tó lè fún wọn ní ìtùnú ìyẹn Ọlọ́run Olódùmarè. Báwo ló ṣe ń tù wá nínú? Ǹjẹ́ ó máa tu ìwọ náà nínú?

  • Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Tù Wá Nínú
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 5
    • Jésù fọwọ́ kan adẹ́tẹ̀ náà kó tó wò ó sàn

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?

      Bí Ọlọ́run Ṣe ń tù Wá Nínú

      Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófàa jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Bíbélì tipa báyìí mú kó dá wa lójú pé gbogbo èèyàn pátá ni Ọlọ́run lè ràn lọ́wọ́, àti pé kò sí ìṣòro tó lè dé bá wa tí Baba wa ọ̀run kò ní lè tù wá nínú.

      Àmọ́ ṣá o, àwa náà ní ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tù wá nínú. Ǹjẹ́ dókítà kan lè ràn wá lọ́wọ́ tí àwa fúnra wa kò bá ṣètò láti rí i? Wòlíì Ámósì béèrè pé: “Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn?” (Ámósì 3:3, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Èyí ló mú kí Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”​—Jákọ́bù 4:8.

      Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run máa sún mọ́ wa? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Ọlọ́run sọ fún wa léraléra pé òun fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. (Wo àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni Ọlọ́run ti tù nínú, lákòókò wa yìí àti nígbà àtijọ́.

      Oríṣiríṣi àjálù ló dé bá Dáfídì Ọba, ó sì bẹ Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run lóde òní. Ìgbà kan wà tí Dáfídì bẹ Jèhófà pé: “Gbọ́ ohùn ìpàrọwà mi nígbà tí mo bá kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́.” Ǹjẹ́ Ọlọ́run dá a lóhùn? Bẹ́ẹ̀ ni. Dáfídì sọ pé: “A sì ti ràn mí lọ́wọ́, tí ó fi jẹ́ pé ọkàn-àyà mi ń yọ ayọ̀ ńláǹlà.”​—Sáàmù 28:2, 7.

      BÍ JÉSÙ ṢE Ń TU ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀ NÍNÚ

      Ọlọ́run fẹ́ kí Jésù náà máa tu àwọn èèyàn nínú. Lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé Jésù lọ́wọ́ ni pé kó “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” kó sì “tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Aísáyà 61:1, 2) Bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jésù fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.”​—Mátíù 11:28-30.

      Jésù tu àwọn èèyàn nínú nípa bó ṣe ń fún wọn ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n, ó máa ń hùwà tó dáa sí wọn, kódà ó mú àwọn míì lára dá. Lọ́jọ́ kan, adẹ́tẹ̀ kan bẹ Jésù pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Jésù káàánú ọkùnrin yìí, ó sì dáhùn pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Máàkù 1:​40, 41) Ara adẹ́tẹ̀ náà sì yá.

      Jésù Ọmọ Ọlọ́run kò sí lórí ilẹ̀ ayé báyìí láti máa fúnra rẹ̀ tù wá nínú. Àmọ́, Bàbá rẹ̀ Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” ṣì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 1:3) Wo ọ̀nà pàtàkì mẹ́rin tí Ọlọ́run ń gbà tu àwọn èèyàn nínú.

      • Bíbélì. “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”​—Róòmù 15:4.

      • Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run. Kété lẹ́yìn tí Jésù kú, gbogbo ìjọ Kristẹni wọ àkókò àlááfíà. Ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé ìjọ náà ń “rìn ní ìbẹ̀rù Jèhófà àti ní ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 9:31) Ẹ̀mí mímọ́, tó jẹ́ agbára Ọlọ́run, máa ń ṣiṣẹ́ gan-an. Ọlọ́run lè lò ó láti tù wá nínú láìka bí ìṣòro wa ṣe le tó.

      • Àdúrà. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun.” Lẹ́yìn náà ó sọ pé, “kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”​—Fílípì 4:6, 7.

      • Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó lè tù wá nínú nígbà ìṣòro. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ òun jẹ́ ìtùnú fún òun nínú gbogbo àìní àti ìpọ́njú òun.​—Kólósè 4:11; 1 Tẹsalóníkà 3:7.

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń tu arákùnrin wọn kan nínú

      Àmọ́ o lè máa ronú pé báwo ni àwọn nǹkan yìí ṣe lè tù ẹ́ nínú nígbà ìṣòro. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ti dojú kọ àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Bíi ti àwọn èèyàn yẹn, ìwọ náà á rí i pé Ọlọ́run ṣì ń mú ìlérí tó tuni nínú yìí ṣẹ, ó ní: “Bí ènìyàn tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú.”​—Aísáyà 66:13.

      a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

      Bá A Ṣe Mọ̀ Pé Ọlọ́run Fẹ́ Tù Wá Nínú

      • “Ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, ti ràn mí lọ́wọ́, o sì ti tù mí nínú.”​—Sáàmù 86:17.

      • “‘Ẹ tu àwọn ènìyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,’ ni Ọlọ́run yín wí.”​—Aísáyà 40:1.

      • “Nítorí pé èyí ni ohun tí Jèhófà wí: . . . ‘Bí ènìyàn tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú.’ ”​—Aísáyà 66:12, 13.

      • “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, níwọ̀n bí a ó ti tù wọ́n nínú.”​—Mátíù 5:4.

      • “Bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.”​—1 Pétérù 5:7.

  • Bá A Ṣe Lè Rí Ìtùnú Lásìkò Wàhálà
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016 | No. 5
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?

      Bá A Ṣe Lè Rí Ìtùnú Lásìkò Wàhálà

      Onírúurú ìṣòro làwa èèyàn máa ń dojú kọ. A ò lè sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ìṣòro náà báyìí, àmọ́ a máa sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin lára àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà. Kó o sì kíyè sí bí àwọn tó ń dojú kọ onírúurú ìṣòro ṣe rí ìtùnú gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

      TÍ IṢẸ́ BÁ BỌ́ LỌ́WỌ́ RẸ

      Jonathan ń fọ wíńdò

      “Mo gbà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú, a sì dín ìnáwó wa kù.”​—Jonathan

      Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Setha sọ pé: “Ìgbà kan náà ni iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èmi àti ìyàwó mi. Owó táwọn mọ̀lẹ́bí ń fún wa àti iṣẹ́ lébìrà la fi gbọ́ bùkátà ara wa fún ọdún méjì gbáko. Èyí kó ẹ̀dùn ọkàn bá Priscilla, ìyàwó mi, èmi náà ò sì já mọ́ nǹkan kan lójú ara mi.

      “Ọgbọ́n wo la wá dá sí i? Gbogbo ìgbà ni Priscilla máa ń ronú lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 6:34. Jésù sọ pé ká má ṣe ṣàníyàn nípa ọ̀la, torí pé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Àdúrà tí ìyàwó mi máa ń gbà látọkànwá sì máa ń fún un lókun láti máa fara dà á. Sáàmù 55:22 ló ran èmi lọ́wọ́. Bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù yẹn, ńṣe ni mo ju gbogbo ẹrù ìnira mi sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ní báyìí mo ti ríṣẹ́, síbẹ̀ à ṣì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó wà ní Mátíù 6:20-22, a ò sì ṣe kọjá agbára wa. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a ti sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, èmi àtìyàwó mi sì tún ti mọ́wọ́ ara wa dáadáa.”

      Jonathan sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí okòwò tí ìdílé wa ń ṣe dẹnu kọlẹ̀. Torí ìṣòro ọrọ̀ ajé tí kò lọ dáadáa, gbogbo ohun tá a ti fi ogún [20] ọdún kó jọ ló lọ láú. Ó wá di pé kémi àti ìyàwó mi máa bára wa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ owó. Ó le débi pé a ò lè lo káàdì tá a fi ń rajà láwìn torí pé ẹ̀rù ń bà wá pé wọ́n lè má tajà fún wa.

      “Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. Mo gbà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú, a sì dín ìnáwó wa kù. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn ará wa tún ràn wá lọ́wọ́. Wọn ò jẹ́ kójú tì wá, wọ́n sì máa ń tì wá lẹ́yìn nígbà tí nǹkan bá le koko.”

      BÍ ÌGBÉYÀWÓ BÁ TÚ KÁ

      Raquel sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi já mi jù sílẹ̀ ní ọ̀sán kan òru kan, ó dùn mí wọra, inú sì bí mi gan-an. Ìbànújẹ́ tó kọjá àfẹnusọ dorí mi kodò. Àmọ́ mo sún mọ́ Ọlọ́run. Ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn.

      “Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lára mi, òun ló jẹ́ kí n lè gbé ìbínú àti ìkórìíra kúrò lọ́kàn. Mo tún máa ń fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, èyí tó wà nínú Róòmù 12:21, tó sọ pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.’

      Raquel ń jíròrò Bíbélì pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀

      “Ìgbà míì wà tó máa gba pé ká gbọ́kàn kúrò lára nǹkan wa tó ‘ti sọnù.’ . . . Mo ti wá ní àwọn nǹkan tuntun tí mò ń lépa báyìí.”​—Raquel

      “Ọ̀rẹ́ mi kan tún jẹ́ kí n rí ìdí tó fi yẹ kí n máa bá ìgbésí ayé mi lọ. Ó fi ohun tó wà nínú Oníwàásù 3:6 hàn mí, ó sì sọ fún mi pé ìgbà míì wà tó máa gba pé ká gbọ́kàn kúrò lára nǹkan wa tó ‘ti sọnù.’ Ìmọ̀ràn yẹn le lójú mi, àmọ́ ohun tí mo nílò gan-an nìyẹn. Mo ti wá ní àwọn nǹkan tuntun tí mò ń lépa báyìí.”

      Elizabeth sọ pé: “Èèyàn máa ń nílò ìtìlẹ́yìn lásìkò tí ìgbéyàwó rẹ̀ bá tú ká. Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fún mi ní irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́. Ó máa ń bá mi sunkún, ó máa ń tù mí nínú, ó sì máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ mi. Ó dá mi lójú pé ńṣe ni Jèhófà lò ó láti wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn.”

      TÍ ÀÌSÀN TÀBÍ ỌJỌ́ OGBÓ BÁ DÉ

      Luis gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun lókun

      “Tí mo bá ti gbàdúrà, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀mí Ọlọ́run fún mi lókun.”​—Luis

      Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Luis, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ní àrùn ọkàn tó lágbára gan-an, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Ní báyìí, ó ní láti lo ẹ̀rọ téèyàn fi ń mí fún wákàtí mẹ́rìndínlógún [16] lójoojúmọ́. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Tí mo bá ti gbàdúrà, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti fún mi lókun. Àdúrà máa ń jẹ́ kí n nígboyà láti má ṣe sọ̀rètí nù, torí mò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, mo sì mọ̀ pé ó bìkítà fún mi.”

      Obìnrin kan tó ń jẹ́ Petra tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń wù mí láti ṣe, àmọ́ agbára mi ò gbé e. Kò rọrùn rárá bí mi ò ṣe lókun mọ́. Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe, oògùn ni mo sì fi ń gbéra. Mo sábà máa ń ronú nípa bí Jésù ṣe bẹ Bàbá rẹ̀ pé kó jẹ́ kí àwọn ìṣòro kan ré òun kọjá, tó bá ṣeé ṣe. Àmọ́, Jèhófà fún Jésù lókun, ó sì ń fún èmi náà lókun. Ojoojúmọ́ ni mò ń gbàdúrà, ara sì máa ń tù mí lẹ́yìn tí mo bá ti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.”—Mátíù 26:39.

      Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Julian náà nìyẹn. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọdún báyìí tí àìsàn sclerosis tó máa ń mú kí iṣan ara le gbagidi, ti ń yọ ọ́ lẹ́nu. Ó sọ pé: “Èmi tí mo máa ń jókòó sórí àga ọlọ́lá tẹ́lẹ̀ wá dẹni tó ń jókòó sórí àga arọ. Àmọ́ ayé yẹ mí torí pé mò ń ṣe ohun tó ń ṣe àwọn míì láǹfààní. Fífún àwọn èèyàn ní nǹkan lè dín ìyà tó ń jẹ wọ́n kù. Jèhófà sì máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á fún wa lókun nígbà ìṣòro. Èmi náà lè sọ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.’”—Fílípì 4:13.

      TÍ ÈÈYÀN RẸ BÁ KÚ

      Antonio sọ pé: “Ńṣe ló dà bí àlá lójú mi nígbà tí bàbá mi kú nínú ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Kó dáa rárá, torí pé jẹ́jẹ́ ni wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn lọ, tí mọ́tò fi yà lọ gbá wọn. Àmọ́ kò sí ohun tí mo lè ṣe sí i. Ọjọ́ márùn-ún ni wọn ò fi mọ nǹkan kan, kí wọ́n tó kú. Mi ò kì í sunkún tí mo bá wà lọ́dọ̀ màmá mi, àmọ́ tí mo bá dá wà, ńṣe ni mo máa ń wa ẹkún mu. Ohun tí mo ṣáà ń bi ara mi ni pé, ‘Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀.’

      “Ní gbogbo àkókò yẹn, mi ò yéé gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn mi, kó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀. Nígbà tó yá, ara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí. Mo rántí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀’ lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lára wa. Ó dá mi lójú pé màá rí bàbá mi pa dà nígbà àjíǹde, torí pé Ọlọ́run kò lè parọ́.”​—Oníwàásù 9:11; Jòhánù 11:25; Títù 1:2.

      Robert àtìyàwó rẹ̀ ń wo fọ́tò

      “Òótọ́ ni pé ìjàǹbá ọkọ̀ òfúrufú náà gba ẹ̀mí ọmọ wa, síbẹ̀ a ṣì ń rántí àwọn àkókò alárinrin tá a ti jọ lò pa pọ̀.”​—Robert

      Èrò yẹn náà ni Robert tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ní. Ó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi ti wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní àlàáfíà Ọlọ́run tí Fílípì 4:​6, 7 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bá a ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Àlàáfíà tó wá látinú ọkàn yìí ló jẹ́ ká lè bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde. Òótọ́ ni pé ìjàǹbá ọkọ̀ òfúrufú náà gba ẹ̀mí ọmọ wa, síbẹ̀ a ṣì ń rántí àwọn àkókò alárinrin tá a ti jọ lò pa pọ̀. Ìyẹn la fi ń tu ara wa nínú.

      “Nígbà tí àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún wa pé àwọn rí wa tí à ń fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, ohun tá a sọ fún wọn ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà tí wọ́n gbà fún wa ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Ó dá mi lójú pé Jèhófà tì wá lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí wọ́n sọ fún wa.”

      Bí àwọn ohun tá a gbé yẹ̀wò yìí ṣe fi hàn, Ọlọ́run lè pèsè ìtùnú fún àwọn èèyàn tó ń dojú kọ onírúurú ìṣòro àti ìpèníjà. Ìwọ ńkọ́? Ìṣòro yòówù kó o dojú kọ nígbèésí ayé, ohun tó lè tù ẹ́ nínú nírú àkókò tó nira bẹ́ẹ̀ wà.b O ò ṣe kúkú yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́? Òun ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”​—2 Kọ́ríńtì 1:3.

      a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

      b Tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kó o sì rí ìtùnú, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó bá sún mọ́ ẹ jù lọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́