ORIN 125
“Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Aláàánú ni Ọlọ́run wa, - Ó ń yọ́nú síni látọkàn, - Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣoore; - Kì í fi ohun tá a fẹ́ dù wá. - Ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá yí pa dà - Mọ̀ pé Ó máa yọ́nú sáwọn. - Tor’ó mọ̀ páláìpé ni wá, - Olóore ni, olóòótọ́ ni. 
- 2. Bàbá, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ wa; - Ẹ̀ṣẹ̀ mú ọkàn wa gbọgbẹ́. - K’Ọ́lọ́run lè dárí jì wá, - Kristi kọ́ wa lóhun tá ó ṣe: - Pé ká bẹ̀bẹ̀ fún àánú rẹ̀, - Ká sì lẹ́mìí ìdáríjì. - Tá a kò bá dira wa sínú, - A ó máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn. 
- 3. Ká jẹ́ ẹlẹ́mìí ọ̀làwọ́, - Kí àánú jẹ́ ká máa fúnni, - Kì í ṣe lọ́nà ṣekárími; - Ìyẹn máa jẹ́ ká lè láyọ̀. - Ọlọ́run ń rí wa kedere, - Yóò san wá lẹ́san ní gbangba. - Aláyọ̀ làwọn aláàánú; - Wọ́n lẹ́wà lójú Ọlọ́run. 
(Tún wo Mát. 6:2-4, 12-14.)