ORIN 43
Àdúrà Ìdúpẹ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Bàbá aláàánú, jọ̀ọ́ gbọ́ àdúrà wa. - Jèhófà, a dúpẹ́, a sì yìn ọ́. - A gbẹ́kẹ̀ lé ọ, à ń sìn ọ́ látọkàn - Torí a mọ̀ pé ò ń ṣìkẹ́ wa gan-an. - Àìpé ń jẹ́ ká ṣàṣìṣe lójoojúmọ́. - Jọ̀ọ́, dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. - A dúpẹ́ gan-an pé o ti rà wá pa dà, - Tó o sì tún mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. 
- 2. A mọrírì ìfẹ́ àti àánú rẹ - Àti bí o ṣe tún ń fà wá mọ́ra. - Jẹ́ ká lè máa sìn ọ́, kọ́ wa ká mọ̀ ọ́, - Ká jẹ́ olóòótọ́, ká dúró ṣinṣin. - A dúpẹ́ pé ò ń fẹ̀mí rẹ darí wa. - Ò ń fún wa nígboyà ká lè wàásù. - A dúpẹ́ pé o máa ń ṣojúure sí wa. - A ó máa fayọ̀ àtìrẹ̀lẹ̀ sìn ọ́.