ORIN 154
Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀
- 1. Nínú ayé yìí; - Ìfẹ́ ṣọ̀wọ́n púpọ̀, - Àmọ́ ìfẹ́ tiwa jinlẹ̀! - Àwọn olóòótọ́ - Èèyàn ló yí wa ká, - A kì í fara wé ayé yìí. - (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ) - Ìfẹ́ kò ní yẹ̀ rárá. - Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé! - Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni - Ìfẹ́ ti ń wá. - Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé - Ó ń mú káyé wa dùn. - Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀, - Kó má ṣe yẹ̀ rárá. - Ìfẹ́ kì í yẹ̀. 
- 2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé - Ìṣòro pọ̀ láyé - Ó sì lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, - A máa láyọ̀ gan-an - Tí a bá ń ṣe oore - Tá a sì ń tu àwọn míì nínú. - (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ) - Ìfẹ́ kò ní yẹ̀ rárá. - Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé! - Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni - Ìfẹ́ ti ń wá. - Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé - Ó ń mú káyé wa dùn. - Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀, - Kó má ṣe yẹ̀ rárá. - (ÈGBÈ) - Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé! - Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni - Ìfẹ́ ti ń wá. - Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé - Ó ń mú káyé wa dùn. - Ìfẹ́ wa tó jinlẹ̀, - Kó má ṣe yẹ̀ rárá. - Ìfẹ́ kì í yẹ̀, - Ìfẹ́ kì í yẹ̀, - Ìfẹ́ kì í yẹ̀.