ORIN 75
“Èmi Nìyí! Rán Mi!”
- 1. Aráyé ń pẹ̀gàn Ọlọ́run. - Wọ́n ń b’orúkọ mímọ́ rẹ̀ jẹ́. - Wọ́n tún ń sọ pé ọ̀dájú ni. - Wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé, “Kò s’Ọ́lọ́run.” - Ta ló máa mẹ́gàn yìí kúrò, - Tó máa gbèjà orúkọ rẹ̀? - (ÈGBÈ 1) - Olúwa, èmi rèé! Rán mi! - Màá ròyìn iṣẹ́ rẹ fáyé. - Ọlá ńlá lo dá mi, Olúwa. - Èmi rèé! Rán mi, rán mi. 
- 2. Àwọn èèyàn kan ń bọ̀rìṣà. - Ọba ayé ló ń darí wọn. - Wọ́n sọ pé Jáà ń fi nǹkan falẹ̀; - Wọn kò níbẹ̀rù Ọlọ́run. - Ta ló máa kìlọ̀ fẹ́ni ‘bi - Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán? - (ÈGBÈ 2) - Olúwa, èmi rèé! Rán mi! - Màá fìgboyà kìlọ̀ fún wọn. - Ọlá ńlá lo dá mi, Olúwa. - Èmi rèé! Rán mi, rán mi. 
- 3. Onírẹ̀lẹ̀ ń kérora gan-an - Torí ìwà ibi ń pọ̀ sí i. - Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń wá - Òtítọ́ tó ń fọkàn balẹ̀. - Ta ló máa lọ tù wọ́n nínú, - Táá kọ́ wọn lọ́nà òdodo? - (ÈGBÈ 3) - Olúwa, èmi rèé! Rán mi! - Màá fi sùúrù kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. - Ọlá ńlá lo dá mi, Olúwa. - Èmi rèé! Rán mi, rán mi.