ORIN 17
“Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọmọ Ọlọ́run wá sáyé - Láti fẹ̀rí hàn pó fẹ́ wa. - Ó fi ọ̀run sílẹ̀ - Ká lè rígbàlà, - Ó fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. - Aláàánú ni Jésù Kristi, - Ó fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. - Ẹ̀rí fi hàn pé onínúure ni - Nígbà tó sọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” 
- 2. Àǹfààní ńlá lèyí fún wa - Pá a lè tẹ̀ lápẹẹrẹ Jésù; - Ká jẹ́ onínúure, - Ká máa fìfẹ́ hàn, - Ní ojoojúmọ́ ayé wa. - Táwọn opó bá wá bá ọ - Tàbí àwọn tó sorí kọ́, - Fẹ̀rí hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn dénú; - Kíwọ náà sọ pé, “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” 
(Tún wo Jòh. 18:37; Éfé. 3:19; Fílí. 2:7.)