ORIN 150
Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
- 1. Gbogbo ọba ayé, - Wọ́n ń tako Jésù Ọba. - Ìṣàkóso àwọn èèyàn - Máa tó dópin láìpẹ́. - Jáà tí ṣèdájọ́ wọn, - Ìjọba Ọlọ́run dé. - Kò ní pẹ́ mọ́ rárá tí Jésù - Máa pa àwọn ọ̀tá run. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ló lè gbani là, - Fọkàn balẹ̀, kó o gbẹ́kẹ̀ lé e. - Wá òdodo rẹ̀, - Jẹ́ olótìítọ́, - Fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. - Wàá fojú rí bí Jèhófà - Á ṣe gbà ọ́ là. 
- 2. Bá a ṣe ń wàásù òótọ́, - Àwọn kan ń fetí sí wa. - Àwọn mìíràn kò sì fẹ́ gbọ́, - Wọ́n sì tún ń gbéjà kò wá. - Àdánwò wa lè pọ̀, - A ó máa sin Jèhófà lọ. - Jèhófà ń bójú tó èèyàn rẹ̀; - Á gbọ́ wa tá a bá ké pè é. - (ÈGBÈ) - Jèhófà ló lè gbani là, - Fọkàn balẹ̀, kó o gbẹ́kẹ̀ lé e. - Wá òdodo rẹ̀, - Jẹ́ olótìítọ́, - Fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀. - Wàá fojú rí bí Jèhófà - Á ṣe gbà ọ́ là. 
(Tún wo 1 Sám. 2:9; Sm. 2:2, 3, 9; Òwe 2:8; Mát. 6:33.)