ORIN 107
Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa
- 1. Àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Jèhófà kọ́ wa - Ló yẹ ká máa tẹ̀ lé. - Gbogbo ‘hun tó ṣe fẹ̀rí hàn pó fẹ́ wa, - Ká fara wé e; ká fìfẹ́ hàn. - Ó fún wa lọ́mọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo; - Ó kú fẹ́ṣẹ̀ wa kí a lè rí ìyè. - Kò sóhun tá a lè fi wé ìfẹ́ ńlá yìí! - Ìfẹ́ yìí ga; Bàbá nífẹ̀ẹ́ wa. 
- 2. Tá a bá fara wé e, ìfẹ́ wa yóò jinlẹ̀, - Yóò máa tuni lára. - Yóò jẹ́ ká lè máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo - Ẹgbẹ́ ará, tàgbà tèwe. - Ó ṣe pàtàkì ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, - Ká sì tún rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa. - Yóò jẹ́ ká lè máa dárí ji ara wa; - Ìyẹn fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ tòótọ́. 
- 3. Ìfẹ́ òtítọ́ tá a ní ló so wá pọ̀ - Bí ọmọ ìyá kan. - Bàbá wa ọ̀run fìfẹ́ ké sí wa pé: - “Tọ́ ọ wò kóo rí ìfẹ́ tòótọ́.” - Ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ - Ṣèrànwọ́ fún wa, ká lè wà níṣọ̀kan. - Ìfẹ́ àárín wa sì ń rán wa létí pé - Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́. 
(Tún wo Róòmù 12:10; Éfé. 4:3; 2 Pét. 1:7.)