ORIN 54
“Èyí Ni Ọ̀nà”
- 1. Ọ̀nà kan wà tó ti - Wà lọ́jọ́ tó ti pẹ́. - Jésù sọ nípa rẹ̀ - Nígbà tó wá sáyé. - Mo kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ti - Wá mọ ọ̀nà yìí gan-an. - Ọ̀nà àlàáfíà yìí - Wà nínú Bíbélì. - (ÈGBÈ) - Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí. - Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì! - Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò; - Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’ 
- 2. Ọ̀nà ìfẹ́ lo wà, - Má ṣe wọ̀tún-wòsì. - Bíbélì fi hàn pé - Jèhófà jẹ́ ìfẹ́. - Ìfẹ́ tó dára, tó - Jinlẹ̀ ló ní sí wa. - Ọ̀nà tí à ń sọ yìí - Kan ìgbé ayé wa. - (Ègbè) - Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí. - Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì! - Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò; - Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’ 
- 3. Ọ̀nà ìyè la wà, - Má ṣe bojú wẹ̀yìn. - Kò sí ibòmíràn - Tá a lè lọ, tá a lè rí - Àlàáfíà àtìfẹ́ - Tí Jáà ṣèlérí rẹ̀. - Ọ̀nà ìyè nìyí, - Ọpẹ́ yẹ Jèhófà. - (Ègbè) - Ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nìyí. - Tẹsẹ̀ mọ́rìn, má ṣe wọ̀tún-wòsì! - Jèhófà ń sọ pé: ‘Má yà kúrò; - Má ṣe wẹ̀yìn, ojú ọ̀nà lo wà.’