ORIN 4
“Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
(Sáàmù 23)
- 1. Jèhófà ni Olùṣọ́ mi; - Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. - Ìfẹ́ tòótọ́ tó fi hàn sí mi - Ló mú mi wà lálàáfíà. - Oúnjẹ tẹ̀mí rẹ̀ gbé mi ró, - Ó fún mi lókun tó yẹ. - Ó mú mi mọ ọ̀nà òtítọ́ rẹ̀, - Kí nlè máa gbénú ‘lé rẹ̀. - Ó mú mi mọ ọ̀nà òtítọ́, - Kí n lè máa gbénú ‘lé rẹ̀. 
- 2. Ìtura àìlẹ́gbẹ́ lèyí; - Ọ̀nà òdodo Rẹ̀ pọ̀. - Olùṣọ́ Àgbà ni Jèhófà, - Kò ní jẹ́ kí n ṣáko lọ. - B’Éṣù tilẹ̀ halẹ̀ mọ́ mi, - ‘Jáà ń fọ̀pá rẹ̀ darí mi’ - Síbi tí kò ní sí ìbẹ̀rù mọ́, - Tí kò ní sípayà mọ́; - Síbi tí kò ní síbẹ̀rù mọ́, - Tí kò ní sípayà mọ́. 
- 3. Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, - Ẹni tó ṣeé fi yangàn. - Ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ dá mi lójú; - Kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. - Bàbá aláàánú ni Jáà jẹ́, - Tí kì í fọ̀rọ̀ mi ṣeré. - Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ máa ṣamọ̀nà mi - Sípa ọ̀nà òdodo. - Jẹ́ kífẹ̀ẹ́ rẹ máa ṣamọ̀nà mi - Sípa ọ̀nà òdodo.