ORIN 41
Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Sáàmù 54)
- 1. Jọ̀ọ́, gbọ́ orin tí mò ń kọ, Bàbá. - Ọlọ́run mi, ìwọ ni mò ń sìn. - Orúkọ ńlá rẹ kò láfiwé. - (ÈGBÈ) - Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi. 
- 2. O ṣé Bàbá, tó o jẹ́ n rí òní. - Mo wà láàyè, ò ń tọ́ mi sọ́nà. - Mo mọrírì bó o ṣe ń ṣìkẹ́ mi. - (ÈGBÈ) - Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi. 
- 3. Ohun tó tọ́ ni mo fẹ́ máa ṣe. - Jẹ́ kí n lè máa rìn nínú ‘mọ́lẹ̀. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n lè ní ìfaradà. - (ÈGBÈ) - Jọ̀ọ́ Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi. 
(Tún wo Ẹ́kís. 22:27; Sm. 106:4; Jém. 5:11.)