ORIN 59
Jẹ́ Ká Yin Jáà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jẹ́ ká yin Jáà; - Ká kọrin sí i. - Ó fún wa lẹ́mìí àtohun rere. - Ojoojúmọ́ - Là ń fìyìn fún un. - Alágbára ni, ìfẹ́ rẹ̀ pọ̀ gan-an. - À ń kéde orúkọ rẹ̀ fáráyé. 
- 2. Jẹ́ ká yin Jáà; - Olùpèsè - Tó ń gbọ́ àdúrà wa, tó ń tọ́jú wa. - A ó máa ròyìn - Agbára rẹ. - Ò ń fún àwọn aláìlera lókun. - Ò ń fẹ̀mí mímọ́ rẹ ràn wá lọ́wọ́. 
- 3. Jẹ́ ká yin Jáà; - Olóòótọ́ ni. - Ó ńt ù wá nínú, a lè gbọ́kàn lé e. - Ìjọba rẹ̀ - Yóò mú nǹkan tọ́. - Yóò mú ìtura bá gbogbo ayé. - Ẹ jẹ́ ká fayọ̀ àt’ìtara yìn ín. 
(Tún wo Sm. 94:18, 19; 145:21; 147:1; 150:2; Ìṣe 17:25.)