ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Àkọlé Sí/Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Orúkọ Òǹṣèwé sí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
    • Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Àkọlé Sí/Ojú Ìwé Tí Wọ́n Kọ Orúkọ Òǹṣèwé sí

      Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé

      A Tún Un Tẹ̀ ní Ọdún 2006

      A tẹ ìwé yìí jáde gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tí à ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹ́yìn fún.

      Awọn ẹsẹ Bibeli ti a fayọ ninu iwe yii jẹ lati inu ­Bibeli Mimọ ni èdè Yoruba, itẹjade ti 1960, ayafi bi a bá ­fihan pe omiran ni. Nibi ti a bá ti fi NW han tẹle ẹsẹ Bibeli kan ti a fayọ, o ń fihan pe a ti tumọ ẹsẹ naa lati inu Bibeli èdè Gẹẹsi, itumọ ­ode-oni ti New World Translation of the Holy Scriptures ​—With References, Ẹ̀dà ti 1984

  • Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
    • ORÍ KÌÍNÍ

      Àṣírí Kan Ha Wà fún Ayọ̀ Ìdílé Bí?

      1. Èé ṣe tí àwọn ìdílé tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin fi ṣe pàtàkì nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn?

      ÌDÍLÉ ni ìgbékalẹ̀ tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń kó ipa pàtàkì nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Jálẹ̀ ìtàn, àwọn ìdílé tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ti mú àwùjọ tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin jáde. Ìdílé ni ètò tí ó dára jù lọ fún títọ́ àwọn ọmọdé di àgbàlagbà tí ó dàgbà dénú.

      2-5. (a) Ṣàpèjúwe ìfọkànbalẹ̀ tí ọmọ máa ń nímọ̀lára rẹ̀ nínú ìdílé aláyọ̀. (b) Àwọn ìṣòro wo ni a ròyìn rẹ̀ nínú àwọn ìdílé kan?

      2 Ìdílé aláyọ̀ jẹ́ ibi ààbò àti ìfọkànbalẹ̀. Fi ọkàn yàwòrán ìdílé rere kan, fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Lákòókò oúnjẹ alẹ́ wọn, àwọn òbí tí ó bìkítà jókòó ti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì jíròrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ náà. Inú àwọn ọmọ ń dùn ṣìnkìn bí wọ́n ti ń sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ fún bàbá àti ìyá wọn. Àkókò ìdẹ̀ra, tí wọ́n jọ lò pa pọ̀, tu gbogbo wọn lára láti lè kojú ọjọ́ mìíràn lẹ́yìn òde ìdílé.

      3 Nínú ìdílé aláyọ̀, ọmọ́ mọ̀ pé bàbá àti ìyá òun yóò tọ́jú òun nígbà tí òún bá ń ṣàìsàn, bóyá kí wọ́n tilẹ̀ pín dídúró ti òun láàárín ara wọn, títí tí ilẹ̀ yóò fi mọ́. Ó mọ̀ pé òún lè mú àwọn ìṣòro ìgbà èwe òun tọ ìyá tàbí bàbá òun lọ, kí wọ́n sì fún òun ní ìmọ̀ràn àti ìṣírí. Bẹ́ẹ̀ ni, ọkàn ọmọ náà balẹ̀, láìka bí ipò ayé lẹ́yìn òde ìdílé ti lè kún fún rúkèrúdò tó sí.

      4 Nígbà tí àwọn ọmọdé bá dàgbà, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ṣègbéyàwó, wọ́n sì máa ń ní ìdílé tiwọn. Òwe Ìlà Oòrùn ayé kan sọ pé: “Ẹnì kan ń mọ bí òún ti jẹ àwọn òbí òun ní gbèsè tó, nígbà tí ó bá bí ọmọ tirẹ̀.” Pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀, àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ń gbìyànjú láti mú kí ìdílé tiwọn náà láyọ̀, wọ́n sì tún ń bójú tó àwọn òbí wọn tí ń darúgbó, tí ń láyọ̀ láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wọn.

      5 Bóyá o ń ronú níbi tí a dé yìí pé: ‘Họ́wù, mo nífẹ̀ẹ́ ìdílé mi, ṣùgbọ́n kò rí bí irú èyí tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ júwe tán yìí. Àkókò iṣẹ́ mi yàtọ̀ sí ti alábàáṣègbéyàwó mi pátápátá, a kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ríra. Ìṣòro owó ni àwọn ọ̀rọ̀ wa sábà máa ń dá lé lórí.’ Tàbí o ha sọ pé, ‘Ìlú mìíràn ni àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ mi ń gbé, ó sì ti pẹ́ tí mo ti rí wọn kẹ́yìn’? Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́pọ̀ ìgbà, fún àwọn ìdí tí ó ré kọjá agbára àwọn tí ọ̀rán kàn, ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ ìdílé kò dára tó. Síbẹ̀, àwọn kan ń gbé ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Báwo? Àṣírí kan ha wà fún ayọ̀ ìdílé bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn náà. Ṣùgbọ́n, ṣáájú jíjíròrò ohun tí ó jẹ́, ó yẹ kí a dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan.

      KÍ NI ÌDÍLÉ?

      6. Irú ìdílé wo ni a óò jíròrò nínú ìwé yìí?

      6 Ní àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn, lọ́pọ̀ ìgbà, bàbá, ìyá, àti àwọn ọmọ ní ń para pọ̀ jẹ́ ìdílé. Àwọn òbí àgbà lè gbé ní ilé tiwọn fúnra wọn, títí dìgbà tí kò bá ṣeé ṣe fún wọn mọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ ń ní ìbáṣe pẹ̀lú àwọn ìbátan jíjìnnà réré, ìwọ̀nba ni ojúṣe wọn sí àwọn wọ̀nyí. Ní pàtàkì, irú ìdílé yìí ni a óò jíròrò nínú ìwé yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìdílé mìíràn ti ń wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí​—ìdílé olóbìí kan, ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe, àti ìdílé tí àwọn òbí kì í ti í gbé pa pọ̀, fún ìdí kan tàbí òmíràn.

      7. Kí ni ìdílé amẹ́bí-múbàátan?

      7 Ìdílé amẹ́bí-múbàátan wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ kan. Nínú ìṣètò yìí, níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, àwọn ọmọ ń pín títọ́jú àwọn òbí àgbà láàárín ara wọn, a sì ń nawọ́ ìbáṣe tímọ́tímọ́ àti ojúṣe sí àwọn ìbátan jíjìnnà réré. Fún àpẹẹrẹ, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣèrànwọ́ nínú ṣíṣètìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ àbúrò, ọmọ ẹ̀gbọ́n, tàbí àwọn ìbátan jíjìnnà réré, nípa títọ́ wọn dàgbà, tàbí rírán wọn lọ sí ilé ẹ̀kọ́ pàápàá. Àwọn ìlànà tí a óò jíròrò nínú ìtẹ̀jáde yìí kan àwọn ìdílé amẹ́bí-múbàátan pẹ̀lú.

      ÌDÍLÉ LÁBẸ́ MÁSÙNMÁWO

      8, 9. Àwọn ìṣòro wo ní àwọn ilẹ̀ kan ni ó fi hàn pé ìdílé ń yí padà?

      8 Lónìí, ìdílé ń yí padà​—ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe sí rere. Àpẹẹrẹ kan ni ti India, níbi tí aya ti lè máà gbé pẹ̀lú ìdílé ọkọ rẹ̀, kí ó sì máa ṣiṣẹ́ nínú ilé lábẹ́ ìdarí àwọn àna rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lóde òní, ó wọ́pọ̀ fún àwọn aya ní India láti wáṣẹ́ síta. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé, a ṣì retí pé kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìbílẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a gbé ìbéèrè dìde pé, Ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù, báwo ni ó ṣe yẹ kí iṣẹ́ tí a retí pé kí obìnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ lóde ṣe nínú ilé ti pọ̀ tó?

      9 Nínú àwọn àwùjọ Ìlà Oòrùn ayé, ìbáṣepọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin láàárín ìdílé amẹ́bí-múbàátan jẹ́ àṣà ìbílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ agbára ìdarí àṣà Ìwọ̀ Oòrùn ayé ti oníkóńkó-jabele àti másùnmáwo ìṣòro ìṣúnná owó, àṣà ìbílẹ̀ ìdílé amẹ́bí-múbàátan ti ń di ahẹrẹpẹ. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ ka títọ́jú àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ó ti darúgbó sí ẹrù ìnira, dípò wíwò ó gẹ́gẹ́ bí ojúṣe tàbí àǹfààní kan. A ń ṣìkà sí àwọn òbí àgbàlagbà kan. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí ni a ti ń hùwà ìkà sí àwọn arúgbó, tí a sì ń pa wọ́n tì.

      10, 11. Àwọn òtítọ́ wo ni ó fi hàn pé ìdílé ń yí padà ní àwọn ilẹ̀ Europe?

      10 Ìkọ̀sílẹ̀ ti ń wọ́pọ̀ gan-an. Ní Spain, iye ìkọ̀sílẹ̀ ti ròkè dé ìgbéyàwó 1 nínú 8, ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tí ó kẹ́yìn ọ̀rúndún ogún yìí​—ìlọsókè pípabambarì láti orí ìgbéyàwó 1 nínú 100 ní kìkì ọdún 25 ṣáájú. Britain, tí a ròyìn pé ó ní àròpọ̀ iye ìkọ̀sílẹ̀ tí ó ga jù lọ ní Europe (a retí pé kí ìgbéyàwó 4 nínú 10 forí ṣánpọ́n), ti rí ìbísí ńlá nínú iye ìdílé olóbìí kan.

      11 Ó jọ pé ọ̀pọ̀ ní Germany ń kọ ìdílé àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀ pátápátá. Àwọn ọdún 1990 ti rí ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn agbo ilé Germany tí ó jẹ́ kìkì ẹnì kan ṣoṣo, tí ìpín 31 nínú ọgọ́rùn-ún sì jẹ́ kìkì ènìyàn méjì. Àwọn ará Faransé pẹ̀lú kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣègbéyàwó mọ́, àwọn tí ó sì ń ṣègbéyàwó tètè máa ń kọ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lemọ́lemọ́ ju bí ó ti máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i yàn láti máa gbé pọ̀ láìsí àwọn ojúṣe ìgbéyàwó. A ń rí àwọn ìtẹ̀sí tí ó jọ èyí kárí ayé.

      12. Báwo ni àwọn ọmọ ṣe ń jìyà nítorí àwọn ìyípadà nínú ìdílé òde òní?

      12 Àwọn ọmọ ńkọ́? Ní United States àti ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ míràn, a ń bí àwọn ọmọ púpọ̀ sí i lẹ́yìn òde ìgbéyàwó, àwọn ọ̀dọ́langba sì ni òbí àwọn kan. Ọ̀pọ̀ ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba ń bí àwọn ọmọ fún àwọn bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìròyìn kárí ayé ń sọ nípa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ kékeré, tí kò nílé, tí ń ráre ká ìgboro; ọ̀pọ̀ ń sá lọ kúrò nílé tí a ti ń hùwà ìkà sí wọn, tàbí àwọn ìdílé tí kò lè gbọ́ bùkátà lórí wọn mọ́ ń tì wọ́n síta.

      13. Àwọn ìṣòro títàn kálẹ̀ wo ní ń du ìdílé láyọ̀?

      13 Bẹ́ẹ̀ ni, ìdílé wà nínú yánpọnyánrin. Ní àfikún sí àwọn ohun tí a ti mẹ́nu kàn ṣáájú, ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba, ìhùwà ìkà sí ọmọdé, ìwà ipá alábàáṣègbéyàwó, ìmukúmu, àti àwọn ìṣòro abaninínújẹ́ mìíràn, ń du ọ̀pọ̀ ìdílé láyọ̀. Fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọdé àti àgbà, ìdílé kì í ṣe ibi tí ń fi ọkàn ènìyàn balẹ̀ rárá.

      14. (a) Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, kí ni okùnfà yánpọnyánrin ìdílé? (b) Báwo ni amòfin kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe ṣàpèjúwe ayé òde òní, ipa wo sì ni ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní lórí ìgbésí ayé ìdílé?

      14 Kí ni ó fa yánpọnyánrin ìdílé? Àwọn kan di ẹ̀bi yánpọnyánrin ìdílé, tí a ń rí lónìí, ru wíwọ̀ tí àwọn obìnrin ń wọṣẹ́. Àwọn mìíràn tọ́ka sí ìwólulẹ̀ ìwà rere. A tún mẹ́nu kan àwọn ìdí mìíràn. Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, amòfin kan tí a mọ̀ bí ẹní mowó sọ tẹ́lẹ̀ pé ìkìmọ́lẹ̀ púpọ̀ yóò yọ ìdílé lẹ́nu, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ní awọn ọjọ́ ìkẹyìn awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò yoo wà níhìn-ín. Nitori awọn ènìyàn yoo jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀-òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹlu ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun.” (2 Timoteu 3:​1-4) Ta ni yóò ṣiyè méjì pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti ń ní ìmúṣẹ lónìí? Nínú ayé tí ó kún fún irú àwọn ipò bí ìwọ̀nyí, ó ha yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ìdílé wà nínú yánpọnyánrin bí?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́