ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Wà ni Ilera Ninu Igbagbọ!
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | February 15
    • Ẹ Wà ni Ilera Ninu Igbagbọ!

      Awọn Koko Itẹnumọ Lati Inu Titu

      AWỌN ijọ Kristian ni erékùsù Mediterranean ti Krete nfẹ àfiyèsí nipa tẹmi. Ta ni o lè ràn wọn lọwọ? Họwu, Titu alábàáṣiṣẹ́pọ̀ apọsteli Pọọlu ni! Oun ni ìgboyà, o tóótun lati kọ́ni, ó ní ìtara fun awọn iṣẹ rere, ó sì wà ni ilera ninu igbagbọ.

      Pọọlu bẹ Krete wo láàárín ìfisẹ́wọ̀n rẹ̀ akọkọ ati èkejì ni Roomu. O fi Titu silẹ lẹhin ni erékùsù naa lati ṣàtúnṣe awọn ohun kan ati lati yan awọn alàgbà ìjọ. A o tun késí Titu lati bá awọn olùkọ́ èké wí ati lati fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀. Gbogbo eyi ni a ṣipaya ninu lẹta Pọọlu si Titu, ti o ṣeeṣe ki a fi ranṣẹ lati Masedonia láàárín 61 si 64 C.E. Fifi ìmọ̀ràn apọsteli naa sílò lè ran awọn alábòójútó òde-òní ati awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn lọwọ lati jẹ onígboyà, onítara, ati onílera nipa tẹ̀mí.

      Ki Ni A Bèèrè fún Lọ́dọ̀ awọn Alábòójútó?

      O pọndandan lati yan awọn alábòójútó lati bójútó awọn iṣoro wíwúwo. (1:1-16) Fun ìyànsípò gẹgẹbi alábòójútó kan, ọkunrin kan nilati jẹ́ aláìlẹ́sùn, àwòfiṣàpẹrẹ gẹgẹ bi ẹnikan ati ninu igbesi-aye ìdílé rẹ̀, olufẹ àlejò ṣiṣe, ẹni ti o wàdéédé, ki o sì ní ìkóra-ẹni nijaanu. Oun nilati kọni ní oun ti o jẹ́ òtítọ́ ki o sì gbaniníyànjú ki o si fi ibawi tọ́ awọn wọnni ti wọn nsọ ojú-ìwòye títakora jade sọna. Ìgboyà ni a nilo nitori pe awọn eniyan oniwa ewèlè ninu ijọ ni a nilati pa lẹ́nu mọ́. Ni pataki ni eyi ri bẹẹ niti awọn wọnni ti wọn ńtòròpinpin mọ ìkọlà, nitori ti wọn ti ṣojú gbogbo agbo ile dé. Ìbáwí mímúná ni yoo pọndandan bi awọn ijọ ba nilati wà ni ilera nipa tẹ̀mí. Lonii, awọn alábòójútó Kristian tun nílò ìgboyà lati baniwi ki wọn sì gbaniníyànjú, pẹlu ete gbígbé ijọ naa ró.

      Fi Ẹkọ Onílera Sílò

      Titu nilati fi ẹkọ onílera nipa tẹmi kọni. (2:1-15) Awọn àgbà ọkunrin nilati jẹ àwòfiṣàpẹẹrẹ niti ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ìwà àgbà, èrò-inú yíyèkooro, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ati ìpamọ́ra. Awọn àgbà obinrin ni wọn nilati jẹ́ “ẹni ọ̀wọ̀ ni ìwà.” Gẹgẹ bi “olùkọ́ni ní ohun rere,” wọn le ran awọn ọdọbinrin lọwọ lati ni oju-iwoye títọ̀nà nipa iṣẹ́ wọn gẹgẹbi aya ati ìyá. Awọn ọ̀dọ́kùnrin nilati ni èrò-inú yíyèkooro, awọn ẹrú sì nilati tẹriba fun awọn olówó wọn ni ọna ti yoo ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun lọ́ṣọ̀ọ́. Gbogbo awọn Kristian ni wọn nilati kọ àìwà-bí-Ọlọ́run silẹ kí wọn sì gbe pẹlu èrò-inú yíyèkooro ninu ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nnkan yìí nigba ti wọn ńdúró de ìfarahàn ológo ti Ọlọrun ati Jesu Kristi, “ẹni ti o fi ara rẹ fun wa, ki oun ki o le ra wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo, ki o si lè wẹ awọn eniyan kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ìní oun tikalaraarẹ awọn onitara [fun] iṣẹ rere.” Nipa fifi iru ìmọ̀ràn onilera bẹẹ silo, ẹ jẹ ki awa pẹlu ‘ṣe ẹkọ Ọlọrun lọ́sọ̀ọ́.’

      Ìmọ̀ràn ìparí ọ̀rọ̀ Pọọlu gbe ìlera tẹmi larugẹ. (3:1-15) O pọndandan lati fi ìtẹríba ti o tọna han fun awọn oluṣakoso ati lati mu ìlọ́gbọ́n nínú dàgbà. Awọn Kristian ni ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, awọn ọrọ Pọọlu sì ni a nilati tẹnumọ lati fun wọn niṣiiri lati maa pa ọkan pọ̀ sori awọn iṣẹ rere. Awọn ibeere òmùgọ̀ ati ìjà lori Ofin ni a nilati yẹra fun, olùṣagbátẹrù ẹ̀ya isin ni a si nilati ṣátì lẹhin ti a bá ti ṣi i leti lẹ́ẹ̀mejì. Bi awọn alagba ba ti nfi iru ìmọ̀ràn bẹẹ silo loni, awọn ati awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn yoo wà ni lera ninu igbagbọ.

  • Ìfẹ́ Ará Jẹ́ Agbékánkánṣiṣẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | February 15
    • Ìfẹ́ Ará Jẹ́ Agbékánkánṣiṣẹ́

      Awọn Koko Itẹnumọ Lati inu Filemoni

      JESU KRISTI fun awọn ọmọlẹhin rẹ ni “ofin titun” pe ki wọn nifẹẹ ara wọn ẹnikinni ẹnikeji gan-an gẹgẹbi oun ti nifẹẹ wọn. (Johanu 13:34, 35) Nitori ìfẹ́ yẹn, wọn yoo tilẹ kú fun ara wọn ẹnikinni ẹnikeji. Bẹẹni, ìfẹ́ ará lágbára tobẹẹ o si ńgbékánkánṣiṣẹ́.

      Apọsteli Pọọlu ni idaniloju pe ìfẹ́ ara yoo sún Filemoni, Kristian kan ti o ndarapọ mọ ijọ ti o wà ni Kolose, ilu nla kan ni Asia Kekere. Ìfẹ́ ti sún Filemoni lati ṣi ile rẹ silẹ fun lilo gẹgẹbi ibi ipade Kristian. Onesimọsi ẹrú Filemoni ti salọ, o ṣeeṣe ki o jí owo ti yoo fi wọ ọkọ oju omi lọ si Roomu, nibi ti o ti pade Pọọlu nikẹhin ti o si tẹwọgba isin Kristian.

      Nigba ti a fi sẹwọn ni Roomu ni nnkan bi 60 si 61 C.E., Pọọlu kọ lẹta kan ti a dari si Filemoni ni ipilẹ. O bẹ Filemoni lati gba Onesimọsi ti npada bọ pẹlu ẹmi ara. Ka lẹta yii, iwọ yoo si ri pe o jẹ apẹẹrẹ rere ti ìfẹ́ni ati ọgbọn ẹ̀wẹ́—ọkan ti awọn eniyan Jehofa le ṣafarawe daradara.

      Ọ̀rọ̀ Ìwúrí fun Ìfẹ́ ati Ìgbàgbọ́

      Ni biba Filemoni ati awọn miiran sọrọ, Pọọlu kọkọ funni ni ọ̀rọ̀ ìwúrí (ẹsẹ 1-7) Apọsteli naa ngbọ leralera nipa ìfẹ́ ti Filemoni ni fun Kristi ati gbogbo awọn eniyan mimọ ati nipa igbagbọ rẹ. Eyi sún Pọọlu lati dupẹ lọwọ Jehofa o si mu ayọ ati ìtùnú pupọ wá fun un. Njẹ awa gẹgẹ bi ẹnikan maa ńsọ̀rọ̀ ìwúrí fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ti wọn jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu ìfẹ́ ati igbagbọ bi? Awa nilati maa ṣe bẹẹ.

      Ọ̀rọ̀-ìyànjú ti a gbé kari ìfẹ́ ni a nfẹ nigba gbogbo ninu biba awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa lo, gẹgẹbi awọn ọrọ Pọọlu ti fihan. (ẹsẹ 8-14) Lẹhin ìyọsíni ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, apọsteli naa wipe bi o tilẹ jẹ pe oun le paṣẹ “ohun ti o yẹ” fun Filemoni, kàkà bẹ́ẹ̀ oun yàn lati gbà á niyanju. Lati ṣe ki ni? Họ́wù, lati gba ẹrú naa Onesimọsi pada ni ọna oníyọ̀ọ́nú! Pọọlu ìbá ti fẹ lati dá Onesimọsi duro fun iṣẹ-isin wiwulo rẹ, ṣugbọn oun ko ni ṣe eyi laisi ìfọwọ́sí Filemoni.

      Awọn ohun ti wọn jẹyọ lọna ti o jọ bi aláìbáradé saba maa njasi àǹfààní, gẹgẹbi Pọọlu ti fihan tẹle e. (Ẹsẹ 15-21) Niti tootọ, sisalọ Onesimọsi ti yọrisi rere. Eeṣe? Nitori pe Filemoni le gbà á pada nisinsinyi gẹgẹbi alailabosi arakunrin Kristian kan, ti o ti muratan, kii ṣe gẹgẹbi ẹrú alábòsí ti ko muratan. Pọọlu sọ fun Filemoni lati fọyaya tẹwọgba Onesimọsi àní gẹgẹ bi a o ti fọyaya tẹwọgba Pọọlu paapaa. Bi Onesimọsi ba ti ṣẹ Filemoni ni ọna eyikeyii, apọsteli naa yoo ṣe ìsanfidípò. Lati mu ki Filemoni tubọ muratan lati gbà, Pọọlu ran an leti pe oun funraarẹ jẹ apọsteli naa ni gbese fun didi Kristian kan. Fun idi yii, Pọọlu ni idaniloju pe Filemoni yoo ṣe ani ju ohun ti a ni ki o ṣe lọ. Iru ifọranlọ ọlọgbọn ẹ̀wẹ́ ati onifẹẹ wo ni eyi jẹ! Niti tootọ, eyi ni ọna ti awa nilati gba ba awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa lò.

      Pọọlu pari lẹta rẹ pẹlu ìrètí, awọn ìkíni, ati awọn idaniyan rere. (Ẹsẹ 22-25) Oun ṣereti pe nipasẹ adura awọn ẹlomiran nitori oun, a o tú oun silẹ kuro ninu túbú. (Gẹgẹ bi lẹta Pọọlu keji si Timoti ti fihan, awọn adura wọnni ni a dahun.) Ni mimu lẹta rẹ wa si ipari, Pọọlu fi awọn ìkíni ranṣẹ o si sọ idaniyan naa pe ki inurere ailẹtọọsi ti Jesu Kristi wa pẹlu ẹmi ti Filemoni ati awọn olùjọsìn Jehofa ẹlẹgbẹ rẹ fihan jade.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́