ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | April 15
    • Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ

      Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Johanu Keji ati Ikẹta

      ÌMỌ̀ otitọ jẹ ami idanimọ fun awọn olujọsin Jehofa. (Johanu 8:31, 32; 17:17) Ririn ninu otitọ atọrunwa ṣe koko fun igbala. Awọn iranṣẹ Ọlọrun sì gbọdọ jẹ alajumọṣiṣẹpọ ninu otitọ.

      Lẹta keji ati ikẹta apọsteli Johanu ti a misi sọrọ nipa “ririn ninu otitọ.” (2 Johanu 4; 3 Johanu 3, 4) Johanu ikẹta pẹlu fun ifọwọsowọpọ ni iṣiri gẹgẹ bi “awọn alajumọṣiṣẹpọ ninu otitọ.” (3 Johanu 5-8) O ṣeeṣe ki a kọ awọn lẹta mejeeji ni Efesu tabi nitosi rẹ̀ ni nǹkan bii 98 C.E. Ṣugbọn awọn ohun ti wọn sọ lè ṣanfaani fun awọn eniyan Jehofa lonii.

      Johanu Keji Tẹnumọ Otitọ

      Johanu keji kọkọ tẹnumọ otitọ ati ifẹ o sì kilọ lodisi “awọn aṣodisi Kristi.” (Ẹsẹ 1-7) Lẹta naa ni a dari si “ayanfẹ obinrin ọlọla” boya eniyan kan. Ṣugbọn bi a ba ti fi ranṣẹ si ijọ, “awọn ọmọ” rẹ̀ jẹ awọn Kristian ti a fi ẹ̀mí bí “ti a yàn” nipasẹ Ọlọrun fun iye ti ọrun. (Roomu 8:16, 17; Filipi 3:12-14) Johanu yọ̀ pe awọn kan bayii “nrin ninu otitọ” ti wọn tipa bayii dena ipẹhinda. Sibẹsibẹ, aini wà fun wọn lati ṣọra lodisi awọn “aṣodisi Kristi,” ti wọn sẹ́ pe Jesu wá ninu ẹran ara. Awọn Ẹlẹrii Jehofa lonii nkọbiara si iru awọn ikilọ bawọnyi lodisi ipẹhinda.

      Johanu funni ni imọran tẹle e lori biba awọn apẹhinda lo ó sì pari lẹta rẹ̀ lẹhin naa pẹlu idaniyanfẹ ati awọn ikini ti ara-ẹni. (Ẹsẹ 8-13) Nipa iru awọn làálàá gẹgẹ bi wiwaasu, oun ati awọn miiran ti mu eso ti nyọrisi iyilọkan pada awọn wọnni ti oun fi lẹta rẹ̀ ranṣẹ si jade, kiki nipa ‘kikiyesara’ fun ara wọn nipa tẹmi ni wọn yoo to lè “ri èrè kikun gbà,” ti o ni “adé” ti ọrun ninu lọna hihan gbangba eyi ti a pamọ́ fun awọn ẹni ami-ororo oluṣotitọ. (2 Timoti 4:7, 8) Bi ẹnikẹni ‘ti kò duro ninu ẹkọ Kristi’ ba tọ̀ wọn wá, wọn ‘kò nilati gbà á sinu ile wọn tabi kí i’ ki wọn baa lè yẹra fun jijẹ alajumọ kẹgbẹ pọ ninu “awọn iṣẹ́ buburu” rẹ̀. Lẹhin sisọ ireti naa pe oun yoo wá ki oun sì ba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ wọnni sọrọ pọ ni ojukoju, Johanu pari lẹta rẹ̀ pẹlu awọn ikini.

      Johanu Kẹta Tẹnumọ Ifọwọsowọpọ

      Johanu Kẹta ni a dari rẹ̀ si Gayọsi o sì kọkọ ṣakiyesi nǹkan ti oun nṣe fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀. (Ẹsẹ 1-8) Gayọsi “nrin ninu otitọ” nipa didirọ mọ́ gbogbo awọn ẹkọ Kristian pata. Oun tun “nṣe iṣẹ igbagbọ” pẹlu ninu ṣiṣetilẹhin fun awọn arakunrin olubẹwo. Johanu kọwe pe: “Awa . . . wa labẹ aigbọdọmaṣe lati gba iru awọn ẹni bẹẹ pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe, ki awa baa le di alajumọ ṣiṣẹ pọ ninu otitọ.” Awọn Ẹlẹrii Jehofa nnawọ ẹmi alejo ṣiṣe ti o farajọ eyi si awọn alaboojuto arinrin ajo lonii.

      Lẹhin ṣiṣe ifiwera iwa buburu Diotirefe pẹlu ti Demetiriọsi, Johanu pari lẹta rẹ̀. (Ẹsẹ 9-14) Diotirefe tí nwa ògo kò fi ọ̀wọ̀ eyikeyii hàn fun Johanu ani o tilẹ gbiyanju lati le awọn wọnni ti wọn ngba awọn arakunrin pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe kuro ninu ijọ paapaa. Ṣugbọn, Demetiriọsi kan bayii ni a tọkasi gẹgẹ bi apẹẹrẹ rere. Johanu nireti lati ri Gayọsi laipẹ o sì pari rẹ̀ pẹlu ikini ati idaniyanfẹ pe ki Gayọsi gbadun alaafia.

  • Ẹ Ṣọra fun Awọn Apẹhinda!
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | April 15
    • Ẹ Ṣọra fun Awọn Apẹhinda!

      Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Lẹta Juuda

      AWỌN iranṣẹ Jehofa gbọdọ “takété si ohun ti iṣe buburu” ki wọn sì “faramọ́ ohun ti iṣe rere.” (Roomu 12:9) Onkọwe Bibeli naa Juuda ran awọn ẹlomiran lọwọ lati ṣe eyi ninu lẹta rẹ̀ ti o fi ranṣẹ lati Palẹstini o ṣeeṣe ki o jẹ ni nǹkan bii 65 C.E.

      Juuda pe ara rẹ̀ ni “iranṣẹ Jesu Kristi, ati arakunrin Jakọbu.” Jakọbu yii ni a mọ̀ daradara lọna ti o han kedere si ọmọ iya Jesu Kristi. (Maaku 6:3; Iṣe 15:13-21; Galatia 1:19) Juuda funraarẹ nipa bayii jẹ ọmọ iya Jesu. Bi o ti wu ki o ri, o ti lè ronu rẹ̀ bi ohun ti ko yẹ lati mẹnukan isopọ ti ara yii, niwọn bi Kristi ti jẹ ẹni ẹmi ologo kan ninu ọrun nigba naa. Lẹta Juuda ṣe taarata gan-an ninu fifunni ni imọran ti o le ran wa lọwọ lati “faramọ ohun ti iṣe rere” ki a sì ṣọra fun awọn apẹhinda.

      “Ja Ija Lilekoko”

      Bi o tilẹ jẹ pe Juuda nfẹ lati kọwe nipa igbala ti awọn Kristian dìmú ni apapọ, oun ri i pe o pọndandan lati rọ awọn onkawe rẹ̀ lati “ja ija lilekoko fun igbagbọ.” (Ẹsẹ 1-4, NW) Eeṣe? Nitori pe awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun ti yọ́ wọnu ijọ wọn sì ‘nyi inurere ailẹtọọsi Ọlọrun pada si awawi fun iwa ainijaanu.’ Wọn ronu lọna aitọ pe wọn lè rú awọn ofin Ọlọrun sibẹ ki wọn sì wà laaarin awọn eniyan rẹ̀. Njẹ ki awa maṣe juwọsilẹ fun iru ironu buruku bẹẹ lae ṣugbọn ki a lepa ododo nigba gbogbo, ki a kún fun ọpẹ pe nipasẹ ẹ̀jẹ̀ Jesu Ọlọrun wẹ̀ wá nù lọna aanu kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa.—1 Kọrinti 6:9-11; 1 Johanu 1:7.

      Awọn Ikilọ Ti A Gbeka Iwaju Wa

      O pọndandan lati ṣọra lodisi iru awọn ẹmi-ironu, ìwà, ati awọn eniyan kan bayii. (Ẹsẹ 5-16) Nitori pe awọn ọmọ Israẹli melookan ti a gbala kuro ni Ijibiti ṣaini igbagbọ, a pa wọn run. Awọn angẹli ti wọn kọ ipò titọ wọn silẹ ni a ti “pamọ ninu ẹ̀wọ̀n ainipẹkun nisalẹ okunkun [tẹmi] de idajọ ọjọ nla ni.” Iwa palapala biburu lekenka mu “ijiya ina ainipẹkun” wa sori Sodomu ati Gomora. Nitori naa, ẹ jẹ ki a maa tẹ́ Ọlọrun lọrun nigba gbogbo ki a má sì ṣe fi “ipa ọna iye” silẹ lae.—Saamu 16:11.

      Laidabi Maikẹli olori awọn angẹli, ẹni ti kò tilẹ ni mu idajọ wá lodisi Eṣu ni lilo awọn ọ̀rọ̀ eebu, awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun sọrọ lọna eebu si awọn “ẹni ologo,” ti o ṣe kedere pe wọn jẹ awọn wọnni ti a dá lọla pẹlu ògo kan bayii gẹgẹ bi awọn alagba ti a fami ororo yàn lati ọwọ́ Ọlọrun ati Kristi. Ẹ maṣe jẹ ki a fi àìlọ́wọ̀ hàn fun ọla aṣẹ ti Ọlọrun fifunni lae!

      Awọn apẹẹrẹ buburu ti Keeni, Balamu, ati Kora ni awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun tẹle. Wọn gbe ihalẹmọni tẹmi ti o ṣee fiwe awọn okuta ti wọn farasin nisalẹ omi ka iwaju wọn wọ́n sì dabii awọn àwọ̀sánmà alailomi ati awọn òkú igi ti a fàtu tigbongbo tigbongbo, ti kò lè mu eso ti o ṣanfaani kankan jade. Awọn apẹhinda wọnni tun jẹ́ akùnsínú, olùráhùn, ati ‘awọn aṣojúsàájú nitori èrè.’

      Maa Baa Lọ Ní Dídènà

      Lẹhin naa Juuda funni ni amọran lori dídènà awọn agbara idari buburu. (Ẹsẹ 17-25) Awọn apẹgan yoo wà ni “igba ikẹhin,” awọn Kristian tootọ sì gbọdọ farada ati awọn ati ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn wọn lonii. Lati dena iru awọn agbara idari buburu bẹẹ, awa nilati gbé ara wa ró lori ‘igbagbọ wa ti o mọ́ julọ,’ ki a gbadura pẹlu ẹmi mimọ, ki a sì pa ara wa mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, nigba ti a nduro de ifihan sode aanu Jesu.

      Lọna ti o han gbangba ninu ipa ti awọn olukọ eke nko, awọn ọkunrin alaiwa bi Ọlọrun ti mu ki awọn kan ṣiyemeji. (Fiwe 2 Peteru 2:1-3.) Kí sì ni awọn oniyemeji nilo? Họwu, iranlọwọ tẹmi lati já wọn gbà kuro ninu “iná,” iparun ainipẹkun! (Matiu 18:8, 9) Ṣugbọn awọn oniwa bi Ọlọrun ko nilati bẹru kadara yẹn, nitori Jehofa yoo daabobo wọn kuro ninu “ìkọ̀sẹ̀” sinu ẹ̀ṣẹ̀ ati iparun ti o nduro de awọn apẹhinda.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́