-
‘Jèhófà Dáhùn Àdúrà Mi!’Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | October 15
-
-
‘Jèhófà Dáhùn Àdúrà Mi!’
JÁKÈJÁDÒ ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ to mílíọ̀nù márùn-ún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ nínú jíjèrè ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Àní àwọn tí ó jẹ́ ọmọdé láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọmọdékùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joel. Ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn sí Jèhófà, a sì batisí rẹ̀ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Ọdún kan lẹ́yìn náà, ó ní ìrírí yìí:
“Nígbà tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo pàdé obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Candy. Mo fi ìwé pẹlẹbẹ náà, ‘Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun,’ lọ̀ ọ́. Ó ti ní in tẹ́lẹ̀, nítorí náà mo fi ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, lọ̀ ọ́. Ó ti ni ìyẹn pẹ̀lú tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà mo ronú pé, ‘n óò fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ obìnrin yìí.’ Ó gbà bẹ́ẹ̀!
“Arábìnrin Candy, tí àrùn káńsà ń pa kú lọ, wá gbé ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ní àfikún sí i, Candy ń kẹ́kọ̀ọ́ láti di nọ́ọ̀sì. Nítorí náà, fún sáà kan, a dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dúró. Ṣùgbọ́n, èmi àti àwọn òbí mi máa ń kàn sí i nípa fífún òun tàbí ọkọ rẹ̀, Dick, ní ìwé ìròyìn. Ó sọ fún wa pé aya òún máa ń kó àwọn ìwé ìròyìn náà síbi ibùsùn rẹ̀, ó sì máa ń kà wọ́n ní alẹ́.
“Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, arábìnrin Candy kú. Èmi àti Bàbá mi àti Ìyá mi bá Candy sọ̀rọ̀ nípa ipò tí àwọn òkú wà. Ó pinnu láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ní ọjọ́ mìíràn, a béèrè lọ́wọ́ Dick bí yóò bá fẹ́ kí a máa bá òun pẹ̀lú Candy kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ kí a sì sọ ọ́ di ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Ó ronú pé èrò yẹ́n dára. Nítorí náà nísinsìnyí, èmi pẹ̀lú Bàbá mi ń bá Dick àti Candy ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n ń tẹ̀ síwájú dáradára, wọ́n sì fi ìmọrírì hàn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
“Mo ti máa ń gbàdúrà fún níní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, Jèhófà sì dáhùn àdúrà mi!”
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | October 15
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?
Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìwọ́ lè jèrè ayọ̀ láti inú ìmọ̀ pípéye Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni síwájú sí i tàbí kí ẹnì kan kàn sí ọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.
-