-
Ẹ Maa Dúró Ṣinṣin Ninu Ìgbàgbọ́Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | March 15
-
-
Ẹ Maa Dúró Ṣinṣin Ninu Ìgbàgbọ́
Awọn Kókó Itẹnumọ Lati inu Peteru Kìn-ínní
AWỌN Ẹlẹrii Jehofa dojukọ oniruuru awọn adanwo, tabi ìdánwo ìgbàgbọ́ wọn. Ni awọn ilẹ kan, iṣẹ iwaasu Ijọba wọn ni a nṣe loju inunibini nla. Satani Eṣu ni o wa lẹhin iwọnyi ati awọn isapa miiran lati pa ipo ibatan wọn pẹlu Ọlọrun run. Ṣugbọn ohun ki yoo ṣaṣeyọri si rere, nitori Jehofa mu awọn iranṣẹ rẹ̀ duro gbọnyingbọnyin—bẹẹni, duroṣinṣin ninu igbagbọ.
Apọsteli Peteru ni anfaani lati ‘fun awọn arakunrin rẹ̀ lokun’ awọn ti a “ko ẹ̀dùn-ọkàn ba nipa oniruuru awọn adanwo.” (Luuku 22:32; 1 Peteru 1:6, 7, NW) Oun ṣe bẹẹ ninu lẹta rẹ̀ akọkọ, ti a kọ ni nnkan bii 62-64 C.E. lati Babiloni. Ninu rẹ̀ Peteru gba awọn Kristian Juu ati Keferi niyanju, o tù wọn ninu, o sì fun wọn ni iṣiri, ni riran wọn lọwọ lati farada awọn ikọlu Satani ki wọn sì “duroṣinṣin ninu igbagbọ.” (1 Peteru 1:1, 2; 5:8, 9) Nisinsinyi ti akoko Eṣu ti di kukuru ti awọn igbejako rẹ̀ sì rorò tobẹẹ, dajudaju awọn eniyan Jehofa lè janfaani lati inu awọn ọ̀rọ̀ onimiisi Peteru.
Ìwà Ti A Gbekari Awọn Ilana Oniwa-bi-Ọlọrun
Yala ireti wa jẹ ti ọrun tabi ti ilẹ-aye, o nilati ran wa lọwọ lati farada awọn adanwo ki a sì huwa ni ọna oniwa-bi-Ọlọrun. (1:1–2:12) Ireti ogún ti ọ̀run mu ki awọn ẹni-ami-ororo yọ̀ loju awọn adanwo, eyi ti o ńyọ́ igbagbọ wọn mọ́ niti gidi. Gẹgẹ bi ile tẹmi ti a kọ sori ipilẹ Kristi, wọn rú awọn ẹbọ tẹmi ti o ṣetẹwọgba lọdọ Ọlọrun wọn sì dari araawọn ni ọna rere ti o mu ògo wa fun Un.
Awọn ibalo wa pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa ni awọn ilana oniwa-bi-Ọlọrun nilati ṣakoso. (2:13–3:12) Peteru fihan pe awa nilati wà ni ijuwọsilẹ fun awọn oluṣakoso eniyan. Awọn iranṣẹ ile ni wọn nilati wa labẹ awọn oluwa wọn, ati awọn aya si awọn ọkọ wọn. Iwa bi Ọlọrun ti aya Kristian kan lè jere ọkọ rẹ̀ alaigbagbọ wá sinu igbagbọ tootọ. Ọkọ onigbagbọ kan si nilati ‘fi ọla fun aya rẹ̀ gẹgẹ bi ohun-eelo ti ko lagbara.’ Gbogbo awọn Kristian nilati fi imọlara fun ọmọnikeji hàn, ki wọn ni ifẹni ara, ṣe ohun ti o dara, ki wọn sì lepa alaafia.
Ifarada Maa Nmu Awọn Ibukun Wa
Fifi iṣotitọ farada ijiya niha ọ̀dọ̀ Kristian tootọ yoo yọrisi awọn ibukun. (3:13–4:19) Bi awa ba njiya nitori òdodo, awa nilati layọ. Ju bẹẹ lọ, niwọnbi Kristi ti jiya ninu ara lati ṣamọna wa si ọ̀dọ̀ Ọlọrun, awa kò nilati gbe ni ibamu pẹlu awọn ifẹ ti ẹran-ara. Bi awa ba farada awọn adanwo pẹlu iṣotitọ, awa yoo ṣajọpin ninu idunnu nlanla nigba iṣipaya Jesu. Mimu ẹgan mọra nitori orukọ Kristi, tabi gẹgẹ bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nilati mu wa layọ nitori pe o fi ẹri hàn pe awa ni ẹmi Jehofa. Nitori naa gẹgẹ bi awa ti jiya ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun, ẹ jẹ ki a fi araawa si abẹ itọju rẹ̀ ki a sì maa baa lọ lati ṣe rere.
Gẹgẹ bi Kristian, awa nilati mu awọn ojuṣe wa ṣe pẹlu iṣotitọ ki a sì rẹ araawa silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun. (5:1-14) Awọn alagba gbọdọ bojuto agbo Ọlọrun tinutinu, gbogbo wa sì nilati kó gbogbo aniyan wa sori Jehofa, ni mimọ daju pe oun bikita fun wa. Awa tun nilati mu iduro wa lodisi Eṣu ki a ma sì ṣe sọ ireti nu, nitori awọn arakunrin wa ńjìyà lọna kan naa bii tiwa. Maa ranti nigba gbogbo pe Jehofa Ọlọrun yoo mu wa duro gbọnyin yoo sì fun wa lagbara lati maa duro ṣinṣin ninu igbagbọ.
-
-
Ẹ Kiyesi Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Ọlọrun!Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | March 15
-
-
Ẹ Kiyesi Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Ọlọrun!
Awọn Kókó Itẹnumọ Lati Inu Peteru Keji
Ọ̀RỌ̀ alasọtẹlẹ tabi ihin-iṣẹ, Jehofa, dabi fitila ti ntan ninu ibi okunkun, awọn Kristian tootọ sì nilati fiyè gidigidi si i. Iyẹn kò rọrun nigba ti awọn olukọ èké ba gbiyanju lati ṣagbatẹru ipẹhinda. Ṣugbọn a le ṣe e pẹlu iranlọwọ atọrunwa. A sì gbọdọ rọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣinṣin bi awa ba nilati la ọjọ Jehofa ti nsunmọle pẹlu iyara kánkán já.
Lẹta onimiisi keji ti apọsteli Peteru le ran wa lọwọ lati fiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Ọlọrun. Peteru kọ lẹta gigun yii boya lati Babiloni ni nnkan bii 64 C.E. Ninu lẹta rẹ̀ oun gbèjà otitọ Ọlọrun, o kilọ dide ọjọ Jehofa bi olè fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, o sì ran awọn onkawe rẹ̀ lọwọ lati ma jẹ ki a dẹ wọn lọ nipa iṣina awọn eniyan oluṣaya gbangba pofin nija. Niwọnbi ọjọ Jehofa ti fẹrẹẹ deba wa, awa le jere lọna titobi lati inu awọn ọ̀rọ̀ onimiisi Peteru.
Ni Igbẹkẹle ninu Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Naa
Gẹgẹ bi Kristian, awa nilati lo araawa de gongo lati maa fi awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun han a sì gbọdọ fiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ naa. (1:1-21) Lati yẹra fun didi alaiṣiṣẹmọ tabi alaimesojade, awa nilati ‘fi iwa mimọ, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ kun igbagbọ wa.’ Nigba ti Peteru ri Jesu ti a pa a larada ti o sì gbọ ti Ọlọrun sọrọ nipa Kristi nibi iṣẹlẹ yẹn, ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ni a tubọ mu da a loju. (Maaku 9:1-8) O yẹ fun wa lati fiye si ọ̀rọ̀ onimiisi yẹn lati ọrun wa.
Ṣọra Fun Awọn Apẹhinda
Nipa fífiyè gidigidi si ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Ọlọrun, awa lè ṣọra fun awọn apẹhinda ati awọn ẹni oniwa ibajẹ miiran. (2:1-22, NW) Peteru kilọ pe awọn olukọ èké yoo rákòrò wọnu ijọ. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa yoo ṣe idajọ alaibarade fun awọn apẹhinda wọnyi, ani gẹgẹ bi oun ti da awọn angẹli alaigbọran, aye alaiwa-bi-Ọlọrun ti ọjọ Noa, ati awọn ilu-nla Sodomu ati Gomora lẹjọ. Awọn olukọ eke tẹmbẹlu aṣẹ ti Ọlọrun fifunni wọn sì re awọn alailera lọ lati darapọ mọ wọn ninu iwa-aitọ. Ìbá ti daraju fun iru awọn apẹhinda bẹẹ ki wọn ma ti mọ̀ “ipa ọna òdodo ju lẹhin ti wọn ti mọ̀ ọ́n lọna pipeye tan lati yipada kuro ninu aṣẹ mimọ ti a fi lelẹ fun wọn.”
Ọjọ Jehofa Nbọ!
Gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn nfiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi, awa kò gbọdọ yọnda araawa lati jẹ ki awọn apẹ̀gàn ti wọn nfi ihin-iṣẹ nipa wiwanihin-in Jesu ṣẹlẹya lo agbara-idari lori wa. (3:1-18) Wọn gbàgbé pe Ọlọrun ti o ti pete lati pa eto-igbekalẹ awọn nnkan yii run pa aye ti o wà ṣaaju Ikun-omi run. Suuru Jehofa ni a kò nilati wò gẹgẹ bi ìjáfara nitori oun fẹ ki awọn eniyan ronupiwada. Eto-igbekalẹ yii ni a o parun ni “ọjọ Jehofa” ti a o sì rọpo rẹ̀ pẹlu ‘awọn ọ̀run titun ati ilẹ-aye titun kan ninu eyi ti òdodo yoo gbe.’ Nitori naa, awa nilati sa gbogbo ipa wa lati wà “laisi abawọn ati laisi abuku ati ni alaafia.” Dipo didi ẹni ti a ṣìlọ́nà nipasẹ awọn olukọ eke, ẹ jẹ ki a dàgbà ninu imọ Jesu Kristi.
Ẹ jẹ ki a fi awọn ọ̀rọ̀ Peteru sọkan. Ki a maṣe kuna lae lati ṣọra lodisi awọn olukọ èké. Maa gbe igbesi-aye pẹlu mímọ̀ pe ọjọ Jehofa nbọ laipẹ. Maa fiye si ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ti Ọlọrun nigba gbogbo.
-