-
Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn SíKí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
-
-
Ẹ̀kọ́ 8
Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí
Kí ni ipò ọkọ nínú ìdílé? (1)
Báwo ni ó ṣe yẹ kí ọkọ bá aya rẹ̀ lò? (2)
Kí ni ẹrù iṣẹ́ bàbá? (3)
Kí ni ojúṣe aya nínú ìdílé? (4)
Kí ni Ọlọrun ń béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí àti àwọn ọmọ? (5)
Kí ni ojú ìwòye Bibeli nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀? (6, 7)
1. Bibeli sọ pé ọkọ ni olórí ìdílé rẹ̀. (1 Korinti 11:3) Aya kan péré ni ọkọ kan gbọ́dọ̀ ní. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó bí ó ti tọ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin.—1 Timoteu 3:2; Titu 3:1.
2. Ọkọ́ ní láti nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀. Ó ní láti bá a lò ní ọ̀nà tí Jesu gbà bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò. (Efesu 5:25, 28, 29) Kò gbọdọ̀ lu aya rẹ̀ tàbí ṣìkà sí i lọ́nàkọnà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fi ọlá àti ọ̀wọ̀ hàn sí i.—Kolosse 3:19; 1 Peteru 3:7.
3. Bàbá ní láti ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó ìdílé rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé fún aya àti àwọn ọmọ rẹ̀. Bàbá tún gbọ́dọ̀ pèsè àwọn àìní tẹ̀mí fún ìdílé rẹ̀. (1 Timoteu 5:8) Ó ń mú ipò iwájú nínú ríran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun àti àwọn ète Rẹ̀.—Deuteronomi 6:4-9; Efesu 6:4.
4. Aya gbọ́dọ̀ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rere fún ọkọ rẹ̀. (Genesisi 2:18) Ó ní láti ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ nínú kíkọ́ àti títọ́ àwọn ọmọ wọn. (Owe 1:8) Jehofa ń béèrè pé kí aya bójú tó ìdílé rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. (Owe 31:10, 15, 26, 27; Titu 2:4, 5) Ó gbọ́dọ̀ ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.—Efesu 5:22, 23, 33.
5. Ọlọrun ń béèrè pé kí àwọn ọmọ gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu. (Efesu 6:1-3) Ó retí pé kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ lo àkókò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn, ní bíbójú tó àwọn àìní wọn tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára. (Deuteronomi 11:18, 19; Owe 22:6, 15) Àwọn òbí kò gbọdọ̀ bá àwọn ọmọ wọn wí ní ọ̀nà líle koko tàbí rírorò láé.—Kolosse 3:21.
6. Nígbà tí tọkọtaya bá ní ìṣòro gbígbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n ní láti gbìyànjú láti lo ìmọ̀ràn Bibeli. Bibeli rọ̀ wá láti fi ìfẹ́ hàn, kí á sì máa dárí jini. (Kolosse 3:12-14) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò fún ìpínyà níṣìírí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti yanjú àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ṣùgbọ́n, aya lè yàn láti fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ bí (1) ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ jálẹ̀jálẹ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé rẹ̀, bí (2) ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ oníwà ipá, tí ìwàláàyè aya àti ìlera rẹ̀ sì wà nínú ewu, tàbí bí (3) àtakò àṣerégèé ọkọ rẹ̀ kò bá jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún aya láti jọ́sìn Jehofa.—1 Korinti 7:12, 13.
7. Àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ sí ara wọn. Panṣágà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun àti sí ẹnì kejì ẹni. (Heberu 13:4) Ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó nìkan ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìkọ̀sílẹ̀, tí ó yọ̀ǹda fún fífẹ́ ẹlòmíràn. (Matteu 19:6-9; Romu 7:2, 3) Jehofa kórìíra rẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá kọ ara wọn sílẹ̀ láìsí ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, tí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíràn.—Malaki 2:14-16.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Bàbá onífẹ̀ẹ́ máa ń pèsè fún ìdílé rẹ̀ nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọlọrun retí pé kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà
-
-
Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Gbọ́dọ̀ Mọ́ TónítóníKí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
-
-
Ẹ̀kọ́ 9
Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Gbọ́dọ̀ Mọ́ Tónítóní
Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní ní gbogbo ọ̀nà? (1)
Kí ni ó túmọ̀ sí láti mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí? (2) mọ́ tónítóní ní ti ìwà híhù? (3) mọ́ tónítóní ní ti èrò orí? (4) mọ́ tónítóní nípa ti ara? (5)
Irú àwọn èdè àìmọ́ wo ni ó yẹ kí a yẹra fún? (6)
1. Jehofa Ọlọrun mọ́ tónítóní, ó sì jẹ́ mímọ́. Ó retí pé kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní—nípa tẹ̀mí, ní ti ìwà híhù, ní ti èrò orí, àti nípa ti ara. (1 Peteru 1:16) Ó gba ìsapá gidigidi láti wà ní mímọ́ tónítóní ní ojú Ọlọrun. A ń gbé nínú ayé aláìmọ́. A tún ní ìjàkadì lòdì sí àwọn ìtẹ̀sí wa láti ṣe ohun tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n a kò gbọdọ̀ juwọ́ sílẹ̀.
2. Ìmọ́tónítóní Nípa Tẹ̀mí: Bí a bá fẹ́ẹ́ sin Jehofa, a kò lè máa bá ẹ̀kọ́ tàbí àṣà ìsìn èké èyíkéyìí nìṣó. A gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú ìsìn èké, kí a má sì ṣe tì í lẹ́yìn lọ́nàkọnà. (2 Korinti 6:14-18; Ìṣípayá 18:4) Níwọ̀n bí a bá ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọrun, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí àwọn ènìyàn tí ń kọni ní ohun tí kì í ṣe òtítọ́, má baà ṣì wá lọ́nà.—2 Johannu 10, 11.
3. Ìmọ́tónítóní Ní Ti Ìwà Híhù: Jehofa ń fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ hùwà gẹ́gẹ́ bíi Kristian tòótọ́ ní gbogbo ìgbà. (1 Peteru 2:12) Ó ń rí gbogbo ohun tí a bá ṣe, kódà ní kọ́lọ́fín pàápàá. (Heberu 4:13) A gbọ́dọ̀ yẹra fún ìwà pálapàla àti àwọn àṣà àìmọ́ mìíràn ti ayé yìí.—1 Korinti 6:9-11.
4. Ìmọ́tónítóní Ní Ti Èrò Orí: Bí a bá fi àwọn èrò tí ó mọ́ tónítóní, tí ó dára kún èrò inú wa, ìwà wa pẹ̀lú yóò mọ́ tónítóní. (Filippi 4:8) Ṣùgbọ́n, bí a bá ń ronú lórí àwọn ohun tí kò mọ́, yóò yọrí sí àwọn ìṣe búburú. (Matteu 15:18-20) A gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn eré ìnàjú tí ó lè sọ èrò inú wa di ẹlẹ́gbin. A lè fi àwọn èrò tí ó mọ́ tónítóní kún èrò inú wa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
5. Ìmọ́tónítóní Nípa Ti Ara: Nítorí pé wọ́n ń ṣojú fún Ọlọrun, àwọn Kristian ní láti mú kí ara àti aṣọ wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní. A gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ wa nígbà tí a bá lọ sí ilé ìyàgbẹ́, a sì gbọ́dọ̀ fọ̀ wọ́n kí á tó jẹun tàbí fọwọ́ kan oúnjẹ. Bí ẹ kò bá ní ilé ìyàgbẹ́ tí ó bójú mu, ẹ gbẹ́ kòtò bo ìgbẹ́ mọ́lẹ̀. (Deuteronomi 23:12, 13) Wíwà ní mímọ́ tónítóní nípa ti ara máa ń dá kún ìlera pípé. Ilé Kristian ní láti bójú mu, kí ó sì mọ́ tónítóní nínú àti lóde. Ó ní láti dá yàtọ̀ ní àdúgbò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ rere.
6. Èdè Mímọ́ Tónítóní: Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo. Àwọn òpùrọ́ kì yóò wọ Ìjọba Ọlọrun. (Efesu 4:25; Ìṣípayá 21:8) Àwọn Kristian kì í lo èdè rírùn. Wọn kì í tẹ́tí sí tàbí sọ àwọn ọ̀rọ̀ àpárá rírùn tàbí ìtàn rírùn. Nítorí èdè mímọ́ tónítóní tí ń jáde lẹ́nu wọn, wọ́n dá yàtọ̀ ní ibi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ àti ládùúgbò.—Efesu 4:29, 31; 5:3.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní ní gbogbo ọ̀nà
-
-
Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun KórìíraKí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
-
-
Ẹ̀kọ́ 10
Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun Kórìíra
Báwo ni ó ṣe yẹ kí o nímọ̀lára nípa àwọn nǹkan tí Ọlọrun sọ pé ó burú? (1)
Irú ìbálòpọ̀ wo ni kò tọ̀nà? (2)
Ojú wo ni ó yẹ kí Kristian fi wo irọ́ pípa? (3) tẹ́tẹ́ títa? (3) olè jíjà? (3) ìwà ipá? (4) ìbẹ́mìílò? (5) ìmùtípara? (6)
Báwo ni ẹnì kan ṣe lè fi àwọn àṣà búburú sílẹ̀? (7)
1. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ohun rere. Ṣùgbọ́n wọ́n tún gbọ́dọ̀ kọ́ láti kórìíra ohun búburú. (Orin Dafidi 97:10) Ìyẹ́n túmọ̀ sí yíyẹra fún àwọn àṣà kan tí Ọlọrun kórìíra. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣà wọ̀nyẹn?
2. Àgbèrè: Ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, panṣágà, ìbẹ́rankolòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, àti ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo lòdì sí Ọlọrun. (Lefitiku 18:6; Romu 1:26, 27; 1 Korinti 6:9, 10) Bí tọkọtaya kan kò bá ṣègbéyàwó, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń gbé pọ̀, wọ́n ní láti pínyà tàbí kí wọ́n ṣègbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú òfin.—Heberu 13:4.
3. Irọ́ Pípa, Tẹ́tẹ́ Títa, Olè Jíjà: Jehofa Ọlọrun kò lè purọ́. (Titu 1:2) Àwọn ènìyàn tí ń wá ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ gbọ́dọ̀ yẹra fún irọ́ pípa. (Owe 6:16-19; Kolosse 3:9, 10) Gbogbo onírúurú tẹ́tẹ́ títa ní ìwọra nínú. Nítorí náà, àwọn Kristian kì í lọ́wọ́ nínú irú tẹ́tẹ́ títa èyíkéyìí, irú bíi tẹ́tẹ́ oríire, tẹ́tẹ́ eré ẹṣin, àti bíńgò. (Efesu 5:3-5) Àwọn Kristian kì í sì í jalè. Wọn kì í mọ̀-ọ́nmọ̀ ra ọjà tí a jí gbé tàbí mú nǹkan láìgba àṣẹ.—Eksodu 20:15; Efesu 4:28.
4. Ìrufùfù Ìbínú, Ìwà Ipá: Ìbínú tí a kò kápá lè ṣamọ̀nà sí àwọn ìṣe oníwà ipá. (Genesisi 4:5-8) Oníwà ipá kan kò lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọrun. (Orin Dafidi 11:5; Owe 22:24, 25) Ó lòdì láti gbẹ̀san tàbí láti fi ibi san búburú tí àwọn ẹlòmíràn lè ṣe sí wa.—Owe 24:29; Romu 12:17-21.
5. Oògùn Onídán àti Ìbẹ́mìílò: Àwọn ènìyàn kan ń lo agbára àwọn ẹ̀mí láti lè wo àrùn sàn. Àwọn mìíràn ń sà sí àwọn ọ̀tá wọn láti mú wọn ṣàìsàn tàbí láti pa wọ́n pàápàá. Satani ni agbára tí ó wà lẹ́yìn gbogbo àwọn àṣà wọ̀nyí. Nítorí náà, àwọn Kristian kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ nínú èyíkéyìí lára wọn. (Deuteronomi 18:9-13) Sísún mọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí ni ààbò dídára jù lọ kúrò lọ́wọ́ oògùn tí àwọn ẹlòmíràn lè sà sí wa.—Owe 18:10.
6. Ìmùtípara: Kò lòdì láti mu wáìnì, ọtí bíà, tàbí ọtí líle mìíràn, níwọ̀nba. (Orin Dafidi 104:15; 1 Timoteu 5:23) Ṣùgbọ́n, ìmukúmu àti ìmùtípara lòdì lójú Ọlọrun. (1 Korinti 5:11-13; 1 Timoteu 3:8) Ọtí àmujù lè ba ìlera rẹ jẹ́, kí ó sì da ìdílé rẹ rú. Ó tún lè jẹ́ kí o tètè ṣubú sínú àwọn àdánwò míràn.—Owe 23:20, 21, 29-35.
7. Àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọrun sọ pé ó burú “kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (Galatia 5:19-21) Bí o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ní tòótọ́, tí o sì fẹ́ láti mú inú rẹ̀ dùn, o lè fi àwọn àṣà wọ̀nyí sílẹ̀. (1 Johannu 5:3) Kọ́ láti kórìíra ohun tí Ọlọrun sọ pé ó burú. (Romu 12:9) Kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìwà-bí-Ọlọ́run. (Owe 13:20) Àwọn Kristian alábàákẹ́gbẹ́, tí wọ́n dàgbà dénú, lè jẹ́ orísun ìrànwọ́. (Jakọbu 5:14) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbára lé ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ àdúrà.—Filippi 4:6, 7, 13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Ọlọrun kórìíra ìmùtípara, olè jíjà, tẹ́tẹ́ títa, àti àwọn ìṣe oníwà ipá
-
-
Àwọn Èrò Ìgbàgbọ́ àti Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Tí Inú Ọlọrun Kò Dùn SíKí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
-
-
Ẹ̀kọ́ 11
Àwọn Èrò Ìgbàgbọ́ àti Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Tí Inú Ọlọrun Kò Dùn Sí
Irú àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wo ni ó lòdì? (1)
Ó ha yẹ kí Kristian gbà gbọ́ pé Ọlọrun jẹ́ Mẹ́talọ́kan? (2)
Èé ṣe tí àwọn Kristian tòótọ́ kì í fi í ṣayẹyẹ Keresimesi, Easter, tàbí ọjọ́ ìbí? (3, 4)
Òkú ha lè pa alààyè lára bí? (5)
Jesu ha kú sórí àgbélébùú bí? (6)
Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì tó láti mú inú Ọlọrun dùn? (7)
1. Kì í ṣe gbogbo èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ni ó burú. Ṣùgbọ́n, Ọlọrun kò tẹ́wọ́ gbà wọ́n bí wọ́n bá wá láti inú ìsìn èké tàbí bí wọ́n bá lòdì sí àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli.—Matteu 15:6.
2. Mẹ́talọ́kan: Jehofa ha jẹ́ Mẹ́talọ́kan—ẹni mẹ́ta nínú Ọlọrun kan ṣoṣo bí? Rárá o! Jehofa, Baba, ni “Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo.” (Johannu 17:3; Marku 12:29) Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin Rẹ̀ àkọ́bí, ó sì wà ní ìtẹríba fún Ọlọrun. (1 Korinti 11:3) Baba tóbi ju Ọmọkùnrin lọ. (Johannu 14:28) Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan; ó jẹ́ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun.—Genesisi 1:2; Ìṣe 2:18.
3. Keresimesi àti Easter: Kì í ṣe December 25 ni a bí Jesu. A bí i ní nǹkan bí October 1, àkókò kan nínú ọdún nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń da àwọn agbo ẹran wọn lọ sínú pápá ní òru. (Luku 2:8-12) Jesu kò pàṣẹ fún àwọn Kristian rí láti ṣayẹyẹ ìbí rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ṣèrántí, tàbí rántí, ikú rẹ̀. (Luku 22:19, 20) Keresimesi àti àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀ wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì. Ohun kan náà jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Easter, irú bíi lílo ẹyin àti ehoro. Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣayẹyẹ Keresimesi tàbí Easter, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn Kristian tòótọ́ lónìí kì í ṣe wọ́n.
4. Ọjọ́ ìbí: Àwọn ènìyàn tí kò jọ́sìn Jehofa ni ó ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì péré tí a ròyìn nínú Bibeli. (Genesisi 40:20-22; Marku 6:21, 22, 24-27) Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì. Àwọn Kristian tòótọ́ ń fi ẹ̀bùn tọrẹ, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ní àwọn àkókò míràn láàárín ọdún.
5. Ìbẹ̀rù Àwọn Òkú: Àwọn òkú kò lè ṣe ohunkóhun tàbí nímọ̀lára ohunkóhun. A kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́, wọn kò sì lè pa wá lára. (Orin Dafidi 146:4; Oniwasu 9:5, 10) Ọkàn ń kú; kì í wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. (Esekieli 18:4) Ṣùgbọ́n nígbà míràn, àwọn áńgẹ́lì búburú, tí a ń pè ní ẹ̀mí èṣù, máa ń díbọ́n bí ẹ̀mí àwọn òkú. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ èyíkéyìí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rù tàbí ìjọsìn àwọn òkú lòdì.—Isaiah 8:19.
6. Àgbélébùú: Jesu kò kú sórí àgbélébùú. Orí òpó, tàbí igi dídúró ṣánṣán kan, ni ó kú sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “àgbélébùú” nínú ọ̀pọ̀ Bibeli túmọ̀ sí ẹyọ igi kan ṣoṣo. Àmì àgbélébùú wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì. Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò lo àgbélébùú tàbí jọ́sìn rẹ̀. Nítorí náà, ìwọ́ ha rò pé yóò tọ̀nà láti lo àgbélébùú nínú ìjọsìn bí?—Deuteronomi 7:26; 1 Korinti 10:14.
7. Ó lè ṣòro gan-an láti kọ díẹ̀ nínú àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọ̀nyí sílẹ̀. Àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ lè gbìyànjú láti yí ọ lérò padà láti má ṣe yí àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ padà. Ṣùgbọ́n, mímú inú Ọlọrun dùn ṣe pàtàkì ju mímú inú ènìyàn dùn.—Owe 29:25; Matteu 10:36, 37.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ọlọrun kì í ṣe Mẹ́talọ́kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Keresimesi àti Easter wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kò sí ìdí láti jọ́sìn àwọn òkú tàbí láti bẹ̀rù wọn
-
-
Fífọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè àti Ẹ̀jẹ̀Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
-
-
Ẹ̀kọ́ 12
Fífọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè àti Ẹ̀jẹ̀
Ojú wo ni ó yẹ kí á fi wo ìwàláàyè? (1) ìṣẹ́yún? (1)
Báwo ni àwọn Kristian ṣe ń fi hàn pé ààbò jẹ wọ́n lọ́kàn? (2)
Ó ha lòdì láti pa ẹranko bí? (3)
Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣà tí kò fí ọ̀wọ̀ hàn fún ìwàláàyè? (4)
Kí ni òfin Ọlọrun lórí ẹ̀jẹ̀? (5)
Èyí ha kan ìfàjẹ̀sínilára bí? (6)
1. Jehofa ni Orísun ìwàláàyè. Gbogbo ohun abẹ̀mí jẹ Ọlọrun ní gbèsè ìwàláàyè wọn. (Orin Dafidi 36:9) Ìwàláàyè jẹ́ mímọ́ fún Ọlọrun. Ìwàláàyè ọmọ tí a kò tí ì bí, tí ó wà nínú ìyá rẹ̀ pàápàá, ṣeyebíye fún Jehofa. Láti mọ̀-ọ́nmọ̀ pa ọmọ inú jòjòló, tí ń dàgbà, lòdì lójú Ọlọrun.—Eksodu 21:22, 23; Orin Dafidi 127:3.
2. Àwọn Kristian tòótọ́ máa ń jẹ́ kí ààbò jẹ wọ́n lọ́kàn. Wọ́n ń rí i dájú pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àti ilé wọn kò fa ewu. (Deuteronomi 22:8) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun kì í fi ẹ̀mí wọn wewu láìnídìí nítorí ìgbádùn tàbí ìmóríyá lásán. Nítorí náà, wọn kì í lọ́wọ́ nínú àwọn eré ìdárayá oníwà ipá, tí ń mọ̀-ọ́nmọ̀ ṣe ìpalára fún àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ń yẹra fún eré ìnàjú tí ń fún ìwà ipá níṣìírí.—Orin Dafidi 11:5; Johannu 13:35.
3. Ìwàláàyè ẹranko pẹ̀lú jẹ́ mímọ́ fún Ẹlẹ́dàá. Kristian lè pa ẹranko láti pèsè oúnjẹ àti aṣọ tàbí láti dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àìsàn àti ewu. (Genesisi 3:21; 9:3; Eksodu 21:28) Ṣùgbọ́n, ó lòdì láti ṣe ẹranko níkà tàbí láti pa wọ́n fún eré ìdárayá tàbí ìgbádùn lásán.—Owe 12:10.
4. Mímu sìgá, jíjẹ ẹ̀pà beteli, àti lílo oògùn fún ìmóríyá kò yẹ fún Kristian. Àwọn àṣà wọ̀nyí lòdì nítorí pé (1) wọ́n ń sọ wá di ẹrú wọn, (2) wọ́n ń pa ara wa lára, àti pé (3) wọ́n jẹ́ aláìmọ́. (Romu 6:19; 12:1; 2 Korinti 7:1) Ó lè ṣòro gan-an láti fi àwọn ìwà wọ̀nyí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láti mú inú Jehofa dùn.
5. Ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọrun. Ọlọrun sọ pé ẹ̀mí, tàbí ìwàlááyè, ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀. Nítorí náà, ó lòdì láti jẹ ẹ̀jẹ̀. Ó lòdì pẹ̀lú láti jẹ ẹran tí a kò ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dànù dáradára. Bí a bá lọ́ ẹranko kan lọ́rùn pa tàbí bí ó bá kú sí ojú pàkúté, a kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́. Bí a bá gún un ní ọ̀kọ̀ tàbí bí a bá yin ìbọn pa á, a gbọ́dọ̀ dúńbú rẹ̀ kíákíá, bí a óò bá jẹ ẹ́.—Genesisi 9:3, 4; Lefitiku 17:13, 14; Ìṣe 15:28, 29.
6. Ó ha lòdì láti gba ẹ̀jẹ̀ sára? Rántí pé, Jehofa béèrè pé kí á ta kété sí ẹ̀jẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé, lọ́nàkọnà tí ó wù kí ó jẹ́, a kò gbọdọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹ̀jẹ̀ ti àwa fúnra wa pàápàá, tí a tọ́jú pamọ́, sára. (Ìṣe 21:25) Nítorí náà, àwọn Kristian tòótọ́ kì yóò gba ẹ̀jẹ̀ sára. Wọn yóò gba oríṣi ìtọ́jú ìṣègùn míràn, irú bíi fífa àwọn èròjà tí kò ní ẹ̀jẹ̀ nínú sára. Wọ́n fẹ́ wà láàyè, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbìyànjú láti du ẹ̀mí wọn nípa rírú òfin Ọlọrun.—Matteu 16:25.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Láti mú inú Ọlọrun dùn, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ìfàjẹ̀sínilára, àwọn àṣà àìmọ́, àti ìfẹ̀mí-ara-ẹni-wewu láìnídìí
-