Títan Òtítọ́ Bibeli Kálẹ̀ Ní Ilẹ̀ Potogí
LÁTI Caminha ní àríwá, sí Vila Real de Santo Antônio ní gúúsù, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkọ̀ ojú omi, aláwọ̀ mèremère, tí a fi ń pẹja gba gbogbo ilẹ̀ tí ó tó 800 kìlómítà ní Etíkun Atlantic ilẹ̀ Potogí. Àwọn apẹja ti “sọ̀ kalẹ̀ lọ sí òkun nínú ọkọ̀” fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ní sísọ ẹja di olórí oúnjẹ ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ilẹ̀ Potogí.—Orin Dafidi 107:23.
Fún 70 ọdún sẹ́yìn, irú ẹja pípa mìíràn ti ń wáyé ní ilẹ̀ Potogí. Ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti dí fún mímú ìhìn rere tọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹja ìṣàpẹẹrẹ lọ. (Matteu 4:19) Ní May 1995, wọ́n dé góńgó 44,650 akéde Ìjọba—ìṣirò ìfiwéra ènìyàn 1 sí nǹkan bí 210 olùgbé. Ní àwọn ìlú ńlá kan ìpíndọ́gba náà jẹ́ ìdajì ìyẹn.
Pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀, àgbègbè tí a ti ń wàásù ní ọ̀pọ̀ àdúgbò ni a ń kárí ní nǹkan bí ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Nípa báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Potogí ní ìtara ọkàn nínú lílo oríṣiríṣi ọ̀nà ìgbàyọsíni kí wọ́n baà ṣàjọpín ìrètí wọn tí a gbé karí Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n mọrírì ìjẹ́pàtàkì sísọ òtítọ́ Bibeli di mímọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ó bá ṣeé ṣe.—1 Korinti 9:20-23.
Ríran Àwọn Tí Wọ́n Nífẹ̀ẹ́ Sí Ìsìn Lọ́wọ́
Ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìkànìyàn ti 1991, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ láti 18 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ilẹ̀ Potogí ni wọ́n sọ pé àwọ́n jẹ́ onísìn Roman Kátólíìkì. Láìka èyí sí, ìmọ̀ Bibeli ti jó rẹ̀yìn láàárín àwọn ènìyàn náà. Ìwé agbéròyìnjáde náà, Jornal de Notícias, ṣàkíyèsí pé: “Èyí ni ọ̀kan lára ohun ìbànújẹ́ tí ó burú jù lọ láàárín àwọn Kátólíìkì: Àìmọ Bibeli!” Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Potogí náà, Expresso, tọ́ka sí ìdáhùn náà. Nígbà tí ó ń ròyìn ìpàdé àwọn 500 àlùfáà ní Fátima, ìwé náà sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí bíṣọ́ọ̀bù ti sọ, ó pọn dandan kí àlùfáà yọ ara rẹ̀ kúrò nínú àìníye àwọn ìgbòkègbodò tí kò kàn án, kí ó baà tún fìdí ipò rẹ̀ tí ó kàn án gbọ̀ngbọ̀n múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘olùpòkìkí.’ . . . Bí àlùfáà bá fi ara rẹ̀ jin wíwàásù Ìròyìn Rere náà, kì yóò ní àyè fún àwọn ìgbòkègbodò míràn.”
Ní ìyàtọ̀ gédégbé, ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ilẹ̀ Potogí dí fún sísọ òtítọ́ Bibeli di mímọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ó bá ṣeé ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn Kátólíìkì olóòótọ́ inú ń rí ìmọ̀ Bibeli gbà.
Carlota jẹ́ Kátólíìkì olùfọkànsìn, ó sì jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ abẹ́ ìsìn kan. Ó tún jẹ́ olùkọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi, níbi tí Antônio, tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ti ń ṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ní gbogbo ìgbà ni Antônio máa ń gbìyànjú láti bá àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Bibeli ní àkókò ìjẹun. Ní ọjọ́ kan, Carlota bi í léèrè nípa ìgbàgbọ́ nínú ọ̀run àpáàdì àti ìjọsìn Maria. Antônio fi ohun tí Bibeli kọ́ni lórí kókó wọ̀nyí hàn án, báyìí sì ni ọ̀pọ̀ ìjíròrò Bibeli ṣe bẹ̀rẹ̀. Nígbà àkọ́kọ́ tí Carlota lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò, èyí wú u lórí púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àkókò ìpàdé forí gbárí pẹ̀lú àwọn àkókò ìpàdé ti ìsìn tí ó ń dara pọ̀ mọ́. Ó rí i pé, òún ní láti ṣe ìpinnu. Kí ni ohun tí yóò ṣe?
Carlota pe gbogbo ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ náà jọ, ó sì fi Bibeli ṣàlàyé ìdí tí ó fi ń yọwọ́ nínú ẹgbẹ́ náà. Gbogbo wọn ta ko ìpinnu rẹ̀, àyàfi ọ̀dọ́mọbìnrin kan Stela, tí ó tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Nígbà tí Carlota bá a sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà, Stela béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ète ìwàláàyè. Carlota fún un ní ìwé náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?a ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Láàárín àkókò náà, Carlota tẹ̀ síwájú dáradára nípa tẹ̀mí, ó ṣe batisí ní June 1991, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà. Ní May 1992, òun àti Antônio ṣègbéyàwó, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà nìṣó pa pọ̀ ní ìjọ alámùúlégbè kan níbi tí àìní ti pọ̀. Stela ń kọ́? Ó ṣe batisí ní May 1993, ó sì ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé nísinsìnyí.
Ọ̀dọ́mọkùnrin Francisco jẹ́ ẹnì kan tí ó nífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí ìsìn. Ní gbogbo ọjọ́ Sunday, ó máa ń pésẹ̀ fún Máàsì ní òwúrọ̀ àti kíka Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà ní ọ̀sán. Ó ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alu-agogo-ṣọ́ọ̀ṣì, ní ríran àlùfáà lọ́wọ́ nígbà Máàsì. Ó tilẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọrun pé, kí o sọ òun di “ẹni mímọ́” ní ọjọ́ kan!
Ó wu Francisco láti ní Bibeli ní ti gidi, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan sì fún un ní ọ̀kan ní ọjọ́ kan. Ó yà á lẹ́nu láti rí i pé Ọlọrun ní orúkọ, Jehofa. (Eksodu 6:3; Orin Dafidi 83:18) Nígbà tí ó kà á nínú Eksodu 20:4, 5 pé Ọlọrun ka lílo ère nínú ìjọsìn léèwọ̀, èyí túbọ̀ yà á lẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀! Nígbà tí ó rí i pé ṣọ́ọ̀ṣì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ère, ó gbàdúrà pẹ̀lú ìgbóná ọkàn sí Ọlọrun láti ràn án lọ́wọ́ láti lóye gbogbo ìdàrúdàpọ̀ yìí. Ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà, ó pàdé ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí kan ó sì bi í pé kí ni ìdí tí o fi pa ilé ẹ̀kọ́ ìrọ̀lẹ́ tì.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dáhùn pé: “Ilé ẹ̀kọ́ ìrọ̀lẹ́ tí ó dára ju ìyẹn lọ ni mo ń lọ nísinsìnyí.”
Francisco béèrè pé: “Ilé ẹ̀kọ́ wo nìyẹn, kí sì ni ẹ̀ ń kọ́?” Ìdáhùn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yà á lẹ́nu púpọ̀.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ wí fún un pé: “Mo ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti lọ bí?”
Ohun tí Francisco rí nígbà àkọ́kọ́ tí ó lọ sí ìpàdé yà á lẹ́nu púpọ̀—àwọn ènìyàn tí wọ́n láyọ̀, tí wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́; tí wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀yàyà, bí i ti ọ̀rẹ́; àwọn ọmọ tí wọ́n jókòó ti àwọn òbí wọn, tí wọ́n ń fetí sílẹ̀ sí ohun tí wọ́n ń sọ.
Francisco sọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu pé: “Èmi tí mo jẹ́ àlejò pátápátá nìyí láàárín wọn, ti mo sì nímọ̀lára pé mo jẹ́ apá kan ìdílé náà!” Láti ìgbà náà wa ni ó ti ń lọ sí ìpàdé déédéé. Nísinsìnyí, Francisco ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ, òun pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì ń yọ̀ nínú àwọn ìlérí títayọ lọ́lá ti Ìjọba náà, tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
Ṣíṣàjọpín Òtítọ́ Náà Pẹ̀lú Àwọn Ìbátan
Manuela, tí ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní àgbègbè Lisbon, ti mú ọ̀pọ̀ yanturu ẹja nítorí ìforítì rẹ̀ ní fífi ẹ̀mí inú rere jẹ́rìí fún gbogbo ènìyàn, títí kan àwọn ìbátan rẹ̀. Lára wọn ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ José Eduardo wa, ẹni tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfìjàdáàbòbo-ara-ẹni. Ó ti tẹ òfin lójú ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín a fi ẹ̀sùn 22 kàn án, a sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n 20 ọdún. Ó jẹ́ oníwà ipá débi pé, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bẹ̀rù rẹ̀, a sì fi í sí yàrá ẹ̀wọ̀n tí ó jẹ́ àdádó.
Manuela fi sùúrù bẹ José Eduardo wò fun ọdún méje, ṣùgbọ́n ó sáà máa ń kọ ìhìn iṣẹ́ Bibeli ni. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nígbà tí a tẹ ìwé náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? jáde, ó tẹ́wọ́ gbà á, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Lójú ẹsẹ̀, ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe nínú ìwà rẹ̀. Ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, ó fúnra rẹ̀ jẹ́rìí fún 200 ẹlẹ́wọ̀n, àti fún àwọn 600 mìíràn ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà. Ó tilẹ̀ gba àṣẹ láti bẹ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà ní yàrá ẹ̀wọ̀n míràn wò. Nítorí ìyípadà pípẹtẹrí nínú ìwà rẹ̀, àkókò ẹ̀wọ̀n náà ni a dín kù sí ọdún 15. Lẹ́yìn lílo ọdún 10, a dá a sílẹ̀ lórí àyẹ̀wò káṣìmáawòó. Láti ìgbà náà wá, ọdún márùn-ún ti kọjá, José Eduardo sì ti di Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí ó ti ṣe batisí, ó sì ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìjọ àdúgbò. Ní tòótọ́ ọ̀ràn ‘ìkokò tí ń bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé pọ̀’ ni!—Isaiah 11:6.
Nítorí ìsapá rẹ̀ tí ń tẹ̀ síwájú ní jíjẹ́rìí fún ìdílé rẹ̀, Manuela ti ní ayọ ríran ọkọ rẹ̀ àti àwọn mẹ́rin mìíràn nínú ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti di ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa. Ọkọ rẹ̀ ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nísinsìnyí.
“N Óò Fi Ìpá àti Pàṣán Lé Wọn Jáde”
Maria do Carmo ń gbé ní ìgbèríko Lisbon nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí kàn sí i. Ó nífẹ̀ẹ́ ohun tí ó gbọ́, ó sì béèrè lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀, Antônio, bí òún bá lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nínú ilé. Ọkọ rẹ̀ dáhùn pé: “Má wulẹ̀ gbé ìyẹn wá rárá! Bí mo bá rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ilé wa pẹ́nrẹ́n, n óò fi ìpá àti pàṣán lé wọn jáde.” Ó ṣe tán, olùkọ́ni ní ìjà kàréètì ni Antônio, ó sì jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onípò kẹta nínú àwọn tí ń fi ìjà gbèjà ara wọn. Nítorí náà, Maria do Carmo pinnu láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ ní ibòmíràn.
Nígbà tí ó yá, Antônio ní láti lọ sí England fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́jọ nínú ìjà kàréètì, Maria do Carmo sì fi tìṣọ́ratìṣọ́ra fi ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi, sínú àpamọ́wọ́ rẹ̀.b Níwọ̀n bí Antônio ti ní àyè púpọ̀ nígbà ìrìn àjò rẹ̀, ó ka ìwé náà. Nígbà tí ó ń padà bọ̀ wá sílé, ìjì mi ọkọ̀ òfuurufú náà kíkankíkan, ó sì ṣòro fún un láti balẹ̀. Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, Antônio gbàdúrà sí Jehofa.
Nígbà tí Antônio padà délé, Ẹlẹ́rìí tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ ké sí i wá sí ìpàdé. Ó gbà, ó sì rí i pé gbogbo ènìyàn ní ń hùwà bí ọ̀rẹ́. A ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, àti láìpẹ́, Antônio rí i pé òún ní láti ṣe àwọn ìpinnu kan. Àbárèbábọ̀ náà ni pé, ó fi kíkọ́ni ní kàréètì sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbésí ayé alálàáfíà nísinsìnyí àti títí láé. Ọ̀kan lára wọn, tí òun pẹ̀lú jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú àwọn tí ń fi ìjà gbèjà ara wọn, ti di Kristian tí a ti batisí nísinsìnyí.
Ní ti Antônio, ó ti ṣe batisí ní April 1991. Ọjọ́ kejì tí ó ṣe batisí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, àti láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli 12 nínú ilé. Ní July 1993, a yàn án gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.
Ní Àwọn Agbègbè Ìpínlẹ̀ Tí A Ń Ṣe Lemọ́lemọ́
Ní ọ̀pọ̀ àdúgbò ní orílẹ̀-èdè náà, agbègbè ìpínlẹ̀ náà ni a máa ń ṣe ní nǹkan bí ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìgbòkègbodò “ẹja pípa” wọn lọ́nà tí ń mú èrè wá?
João ń gbìyànjú láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn ní gbogbo ilé. Nígbà tí ó ń bẹ obìnrin kan wò, ó béèrè bí àwọn ènìyàn míràn bá ń gbé inú ilé náà. Obìnrin náà dáhùn pé ọkọ òun àti àwọn ọmọkùnrin méjì ń gbé níbẹ̀, ṣùgbọ́n kò ní rọrùn láti rí wọn nítorí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́, àti pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni wọ́n lè wà nílé. Nítorí náà João tẹ̀ síwájú láti bẹ àwọn yòókù ní àdúgbò náà wò. Ní nǹkan bíi wákàtí kan àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan tọ̀ ọ́ wá.
Ọkùnrin náà wí fún João pé: “O sọ pé o fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́ sọ ohun tí o fẹ́ fún mi.”
João dáhùn pẹ̀lú ìyàlẹ́nu pé: “Mo tọrọ gáfárà, èmi kò mọ̀ ọ́. Ta ni ọ́?”
“Antônio ni orúkọ mi, mo sì ń gbé òkè níbẹ̀ yẹn. O sọ fún màmá mi pé o fẹ́ láti bá àwọn yòókù nínú ìdílé sọ̀rọ̀, nítorí náà mo wá láti wádìí ohun tí o fẹ́.”
João jẹ́rìí fún Antônio lọ́nà tí ó múná dóko, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́ẹ̀kejì, Antônio béèrè bí wọ́n bá lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Ní kìkì oṣù mẹ́rin péré, ó dara pọ̀ mọ́ João, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere náà ní òpópónà tirẹ̀ fúnra rẹ̀. Ó ṣe batisí ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà. Láìpẹ́ yìí, màmá rẹ̀ pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti gbìyànjú láti bá gbogbo mẹ́ḿbà agboolé sọ̀rọ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa!
Irú àwọn ìrírí amọ́kànyọ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ẹja pípa nípa tẹ̀mí ṣì kù láti ṣe nínú àwọn omi ilẹ̀ Potogí. Jehofa ti fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ń tẹ̀ síwájú bù kún àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń ṣiṣẹ́ kára níbẹ̀. Bí wọ́n ti ń bá a nìṣó láti wá ọ̀nà púpọ̀ sí i láti sọ òtítọ́ Bibeli di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn, àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu sí àwọn Kristian ní Filippi ń ní ìmúṣẹ ní tòótọ́ ní ilẹ̀ Potogí lónìí pé: “Ní gbogbo ọ̀nà, . . . Kristi ni a ń kéde gbangba.”—Filippi 1:18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
SPAIN
ILẸ̀ POTOGÍ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ilẹ̀ Potogí ń lo gbogbo àǹfààní láti sọ òtítọ́ Bibeli di mímọ̀