-
Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn ÒǹkàwéIlé-Ìṣọ́nà—1992 | August 1
-
-
Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
A ha gbọdọ lóye lati inu Jobu 1:8 pe ni sáà akoko ti Jobu gbé ni ayé, oun nikanṣoṣo ni eniyan ti o jẹ́ oloootọ si Jehofa bi?
Bẹẹkọ. Ipari ero yẹn ni a kò dáláre nipa Jobu 1:8, ti o wi pe:
“Oluwa [“Jehofa,” NW] si sọ fun Satani pe, Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ ni ayé, ọkunrin tii ṣe oloootọ, ti o si duro ṣinṣin, ẹni ti o bẹru Ọlọrun, ti o si koriira iwa buburu?” Ọlọrun pese èrò idiyele ti o farajọ eyi ninu Jobu 2:3, ni bíbi Satani leere pe: “Iwọ ha kiyesi Jobu iranṣẹ mi, pe, kò si ekeji rẹ̀ ni ayé, ọkunrin tii ṣe oloootọ ti o sì duro ṣinṣin, ẹni ti ó bẹru Ọlọrun ti o sì koriira iwa buburu”?
Iwe Jobu funraarẹ tọka pe Jobu kọ́ ni eniyan kanṣoṣo ti o walaaye ti Ọlọrun tẹwọgba gẹgẹ bi aduroṣinṣin. Bẹrẹ ni ori 32, a kà nipa Elihu. Bi o tilẹ jẹ pe o jẹ́ ọdọmọkunrin kan, Elihu tọ́ aṣiṣe oju-iwoye Jobu sọna ti o si gbé Ọlọrun tootọ ga.—Jobu 32:6–33:6, 31-33; 35:1–36:2.
Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, ọ̀rọ̀ Ọlọrun naa pe ‘kò si ekeji Jobu ni ayé’ gbọdọ tumọsi pe Jobu dayatọ ni pataki gẹgẹ bi ẹni aduroṣinṣin. O ṣeeṣe ki o jẹ pe Jobu gbé laaarin akoko iku Josefu ni Egipti ati ibẹrẹ iṣẹ isin Mose gẹgẹ bii wolii Ọlọrun. Laaarin akoko yẹn pupọ awọn ọmọ Israeli ni wọn ń gbé ni Egipti. Kò sí idi lati ronu pe gbogbo wọn jẹ́ alaiduroṣinṣin ati alaiṣetẹwọgba fun Ọlọrun; boya pupọ wà ti wọn ni igbẹkẹle ninu Jehofa. (Eksodu 2:1-10; Heberu 11:23) Sibẹ, eyikeyii ninu wọn kò kó ipa ti o yọrí, gẹgẹ bi Josefu ti ṣe, bẹẹ sì ni awọn olujọsin wọnyẹn kò dayatọ niti ijọsin tootọ, gẹgẹ bi Mose yoo ti ṣe ni didari orilẹ-ede Israeli jade kuro ni Egipti.
Bi o ti wu ki o ri, ọkunrin kan ti iwatitọ rẹ̀ yẹ fun afiyesi ń gbé ni ibomiran. “Ọkunrin kan wà ni ilẹ Usi, orukọ ẹni tii jẹ Jobu; ọkunrin naa si ṣe oloootọ, o duro ṣinṣin, ẹni ti o sì bẹru Ọlọrun, ti o si koriira iwa buburu.”—Jobu 1:1.
Jehofa le tipa bayii mẹnukan Jobu gẹgẹ bi apẹẹrẹ igbagbọ ati ifọkansin ti o hàn gbangba tabi ti o gbafiyesi. Bakan naa, awọn òǹkọ̀wé Bibeli naa Esekieli ati Jakọbu ni sisọrọ nipa ohun ti o ti kọja ya Jobu sọtọ gẹgẹ bi ẹni ti ó fi ilana ododo ati iforiti lelẹ.—Esekieli 14:14; Jakọbu 5:11.
-
-
Ipade Ọdọọdun—October 3, 1992Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | August 1
-
-
Ipade Ọdọọdun—October 3, 1992
IPADE ỌDỌỌDUN ti mẹmba Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a o ṣe ni October 3, 1992, ni Gbọngan Apejọ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ipade àṣeṣaájú ti kìkì awọn mẹmba ni a o pe apejọpọ rẹ̀ ni 9:30 òwúrọ̀, ti ipade ọdọọdun ti gbogbogboo yoo sì tẹle e ni 10:00 òwúrọ̀.
Awọn mẹmba Ajọ-ẹgbẹ nilati fi tó Ọfiisi Akọwe leti nisinsinyi nipa iyipada eyikeyii ninu awọn adirẹsi ifiweranṣẹ wọn ni aarin ọdun ti o kọja ki awọn lẹta ìfitónilétí ti a ń lo deedee ati iwe aṣẹ ìṣojúfúnni ba lè dé ọdọ wọn kété lẹhin August 1.
Awọn iwe aṣẹ ìṣojúfúnni naa, ti a o fi ranṣẹ si awọn mẹmba pẹlu ìfitónilétí nipa ipade ọdọọdun, ni a nilati dá pada ki o baa lè dé Ọfiisi Akọwe Society laipẹ ju August 15 lọ. Mẹmba kọọkan nilati kọ ọrọ kun iwe aṣẹ ìsọfúnni tirẹ̀ ni kíámọ́sá ki ó sì dá a pada ni sisọ yala oun yoo wà ni ibi ipade naa fúnraarẹ̀ tabi bẹẹkọ. Ìsọfúnni ti a fifunni lori iwe aṣẹ ìsọfúnni kọọkan nilati ṣe pàtó lori kókó yii, niwọn bi a o ti gbarale e ni pipinnu awọn wo ni yoo wà nibẹ funraawọn.
A reti pe gbogbo akoko ijokoo naa, titi kan awọn ipade iṣẹ àmójútó eleto àṣà ati awọn irohin, ni a o pari rẹ̀ ni 1:00 ọ̀sán tabi kété lẹhin naa. Kì yoo sí akoko ijokoo ọ̀sán. Nitori ààyè ti o mọniwọn, igbawọle yoo jẹ́ nipasẹ tikẹẹti nikanṣoṣo. Kò sí iṣeto kankan ti a o ṣe fun siso ipade ọdọọdun naa pọ mọ wáyà tẹlifoonu lọ si awọn gbọngan awujọ miiran.
-