Jíjẹ́rìí—Títí Dé Òpin Ilẹ̀ Ayé
Àwọn wo ló ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti máa wo fídíò náà, To the Ends of the Earth láwòtúnwò? Àwọn tó ń gbèrò láti di míṣọ́nnárì àtàwọn tó fẹ́ láti rí i pé àwọn mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn gbòòrò sí i ni. Fídíò yìí la fi ṣe àyájọ́ àádọ́ta ọdún ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, tí a dá sílẹ̀ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù tàn kálẹ̀ títí dé “gbogbo òpin ilẹ̀ ayé.” (Sm. 22:27) Wíwo fídíò yìí á jẹ́ kí o túbọ̀ mọ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà, á sì tún sún ọ láti túbọ̀ kópa tó jọjú nínú rẹ̀. Ronú lórí àwọn kókó wọ̀nyí: (1) Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940 sí 1949, kí ni lájorí ohun tó ń jẹ ètò àjọ Jèhófà lọ́kàn? (Ìṣe 1:8) (2) Ní ọdún 1942, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yíyanilẹ́nu wo ló ń ní ìmúṣẹ, báwo sì ni a kò ṣe darí àfiyèsí síbi tí gbogbo ayé lápapọ̀ darí àfiyèsí wọn sí? (Ìṣí. 17:8; w89-YR 4/15 ojú ewé 14 ìpínrọ̀ 12) (3) Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo la ṣe láti lo àǹfààní àsìkò àlàáfíà tí kò sógun èyí tí a ń fojú sọ́nà fún pé á dé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì? ( jv-E ojú ìwé 522 ìpínrọ̀ 1 àti 2) (4) Kí làwọn ànímọ́ tó wú ọ lórí lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì àkọ́kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì? (5) Ní àádọ́ta ọdún àkọ́kọ́ látìgbà tí a ti dá ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mélòó ló ti gboyè jáde, orílẹ̀-èdè mélòó la sì rán wọn lọ? (6) Báwo ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì dójú àmì tó? (7) Kí ló ń sọ ẹnì kan di míṣọ́nnárì tó dáńgájíá àti olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó péye? (8) Irú ìgbésí ayé wo ni àwọn míṣọ́nnárì ń gbé, kí sì làwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú? (9) Kí ni èrò àwọn míṣọ́nnárì nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lo ìgbésí ayé wọn, ayọ̀ tó pabanbarì wo sì ni ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn ń mú kí wọ́n ní? (10) Kí ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún míṣọ́nnárì ti gbé ṣe láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá? Sọ àwọn àpẹẹrẹ. (11) Èrò wo lo ní nípa àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin tí wọ́n ti lọ sí “òpin ilẹ̀ ayé” láti wàásù? (12) Kí làpẹẹrẹ tí àwọn míṣọ́nnárì fi lélẹ̀ sún ọ láti ṣe, èé sì ti ṣe tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?