ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fífi Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí Lọni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—1995 | December
    • Fífi Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí Lọni

      1 December jẹ́ oṣù àtàtà tí a lè fi ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí lọni. Àwọn aláfẹnujẹ́ Kristian máa ń ronú nípa Jesu ní oṣù yìí ju ìgbàkígbà lọ láàárín ọdún. Ó yẹ kí gbogbo wa lo àǹfààní tí oṣù yìí ṣí sílẹ̀ fún wa láti fi ìwé dáradára yìí, tí ó kún fún àwòrán nípa Jesu Kristi, lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Ohun tí a nílò lè má ju ìgbékalẹ̀ rírọrùn kan láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú ìwé náà.

      2 Lẹ́yìn kíkí onílé, o lè sọ ohun kan bí èyí:

      ◼ “Ayé ti mú àwọn ènìyàn ńlá tí ìtàn kò lè gbàgbé jáde. A ń díwọ̀n àwọn ènìyàn ńlá nípa ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ láti gbèrú lẹ́yìn wọn, tí ó ń bá a lọ lẹ́yìn ikú wọn. Nínú èrò tìrẹ, ta ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Nígbà kan rí, ọba kan sọ nípa Jesu Kristi pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin naa!’ (Joh. 19:5) Nígbà ayé rẹ̀, a mọ̀ ọ́n sí ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Ṣùgbọ́n, ní àkókò wa yìí ńkọ́? A ha ṣì mọ̀ ọ́n sí ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí bí?” Ṣí ìwé náà sí ìbẹ̀rẹ̀, kí o sì ka ìpínrọ̀ 2 àti 3. Ṣàlàyé pé, àwọn òpìtàn àti àwọn ọba ńlá jẹ́rìí sí i pé, Jesu ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Kí onílé náà baà lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìdí tí Jesu fi jẹ́ irú ènìyàn ńlá bẹ́ẹ̀, fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún iye owó tí a ń fi síta. Ṣètò láti padà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.

      3 Lẹ́yìn sísọ ẹni tí o jẹ́, o lè sọ pé:

      ◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń ronú nípa Jesu Kristi. A mọrírì rẹ̀, a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ fún oore rẹ̀. Kí ni èrò rẹ—ká ní Jesu Kristi ni olùṣàkóso ayé yìí, kò ha ní jẹ́ ibi tí ó sunwọ̀n láti gbé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Yóò ha ṣeé ṣe láé fún Jesu Kristi láti ṣàkóso wa ní tààràtà bí? [Ka Isaiah 9:6, 7.] A sọ tẹ́lẹ̀ pé Jesu Kristi ni ẹni tí yóò mú àlàáfíà tòótọ́, tí ó wà pẹ́ títí, wá fún aráyé. Ìwé yìí, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, yóò mú un dá ọ lójú pé àkóso Jesu yóò sọ ilẹ̀ ayé di ibi rírẹwà kan láìpẹ́.” Tọ́ka sí orí 132, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta.

      4 O lè yàn láti lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí:

      ◼ “A fẹ́ mọ èrò àwọn aládùúgbò wa lórí ọ̀ràn yìí: Àwọn ọ̀nà ha wà tí a lè gbà sún mọ́ Kristi bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó pọn dandan láti ní ìmọ̀ kíkún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ẹlòmíràn, láti lè bá wọn ṣọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ohun tí ó ń béèrè lọ́wọ́ wa láti sún mọ́ Jesu Kristi tímọ́tímọ́ kò kéré sí èyí. A ní láti mọ irú ènìyàn tí ó jẹ́, àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ ojoojúmọ́, ìyà tí ó jẹ ẹ́, ìmọ̀lára rẹ̀, àti gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa Jesu Kristi pọn dandan bí a óò bá jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. [Ka Johannu 17:3.] Ìwé yìí, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, jẹ́ àkópọ̀ ìròyìn kíkún rẹ́rẹ́ nípa Jesu, tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jèrè irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀ nípa rẹ̀.” Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta, kí o sì ṣètò gúnmọ́ fún ìpadàbẹ̀wò.

      5 O lè lo ọ̀nà ìgbàyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, pẹ̀lú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kúkúrú yìí:

      ◼ “A ń fi ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yìí han àwọn aládùúgbò wa. Ó dá lórí Jesu Kristi. O ha ti rí i rí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] N óò fẹ́ láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀, láti fi bí o ṣe lè lò ó pẹ̀lú Bibeli rẹ hàn ọ́.” Ṣí i sí orí 59, kí o sì jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 4. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́.

      6 Bí a bá múra sílẹ̀ dáradára, yóò ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ìmọrírì wọn fún Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, jinlẹ̀ sí i. Lo gbogbo àǹfààní tí o ní láti fi ìwé Ọkunrin Titobilọla lọni, ní oṣù December tí a wà nínú rẹ̀ yìí.

  • Mímúra Sílẹ̀ fún Ìpadàbẹ̀wò Tí Ó Gbéṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—1995 | December
    • Mímúra Sílẹ̀ fún Ìpadàbẹ̀wò Tí Ó Gbéṣẹ́

      1 Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.” (Matt. 28:19, 20) A ń ṣàṣeparí kíkọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó ṣeé ṣe pé àwọn tí ó fìfẹ́ hàn nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla, nígbà tí o kọ́kọ́ ké sí wọn, yóò láyọ̀ láti tún rí ọ. Bí o bá wéwèé ṣáájú, tí o múra sílẹ̀ dáadáa, tí o sì ṣètò láti ṣèpadàbẹ̀wò tí ó gbéṣẹ́, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti bẹ̀rẹ̀, kí o sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé déédéé.

      2 Bí o bá ti sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 2 àti 3 ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé “Ọkunrin Titobilọla,” o lè sọ pé:

      ◼ “Nígbà tí mo wábí kẹ́yìn, a sọ̀rọ̀ lórí bí Jesu Kristi ṣe jẹ́ ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Àwọn ọba ńlá àti àwọn òpìtàn pẹ̀lú jẹ́rìí sí i pé Jesu ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Ṣùgbọ́n, kí ni ó sọ ọ́ di ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jesu ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Baba rẹ̀, Ọlọrun Olódùmarè, ì bá ti ṣe. [Ka Johannu 14:9, 10.] Ṣíṣàfarawé Ọlọrun lọ́nà pípé pérépéré sọ ọ́ di ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ. Ṣùgbọ́n, àwọn ànímọ́ Ọlọrun wo ni Kristi fi hàn?” Ṣí i sí ìbẹ̀rẹ̀, kí o sì gbé àwọn kókó díẹ̀ yẹ̀ wò lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ohun Tí Ó Mú Kí Ó Tobilọla Julọ.” Ṣètò fún ìbẹ̀wò rẹ tí yóò tẹ̀ lé e.

      3 Bí o bá padà lọ láti mú ìjíròrò lórí àkóso Jesu Kristi tẹ̀ síwájú, o lè sọ pé:

      ◼ “A fohùn ṣọ̀kan nínú ìjíròrò wa tí ó kọjá pé, a ti yan Jesu Kristi láti ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jesu yóò fi jẹ́ alákòóso tí ó dára jù lọ tí ayé lè ní? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó kórìíra àìṣèdájọ́ òdodo, ó sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere. [Ka Heberu 1:9.] Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi ohun tí yóò ṣàṣeparí gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí ilẹ̀ ayé hàn, ní ìwọ̀n ṣékélé. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó sì tún jí àwọn òkú dìde pàápàá. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó tún ní agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ láti kápá àwọn ìjábá. Alákòóso kankan ha wà tí ó lè faga gbága pẹ̀lú rẹ̀ bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] A lè kọ́ púpọ̀ sí i nípa alákòóso tí ó ju ẹ̀dá ènìyàn lọ yìí, ní orí 53.” Lẹ́yìn náà, jíròrò àwọn ìpínrọ̀ díẹ̀, kí o sì ṣèlérí láti padà wá.

      4 O lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí ó nífẹ̀ẹ́ sí níní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jesu, ní ọ̀nà yìí:

      ◼ “Nígbà tí mo wábí kẹ́yìn, a ka Johannu 17:3. A lóye ìdí tí ó fi yẹ kí a ní ìmọ̀ pípéye, kí a baà lè ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jesu Kristi àti Baba rẹ̀ ọ̀run. Fún àpẹẹrẹ, o ha mọ ìdí tí Jesu fi ti ọ̀run wá sí ayé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọ̀pọ̀ yóò sọ pé, ó wá sí ayé láti rà wá padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Òótọ́ ni! Ṣùgbọ́n, ìdí pàtàkì mìíràn tún wà tí Jesu fi wá sí ayé. [Ka Luku 4:42, 43.] Ó wá, ní pàtàkì láti wàásù àti láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọrun.” Gbé àwọn kókó díẹ̀ ípa Ìjọba náà yẹ̀ wò, ní orí 133. Bí ó bá ṣeé ṣe, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.

      5 Bí o bá ń padà lọ sọ́dọ̀ ẹni tí o lo ọ̀nà ìgbàyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ ní ọ̀nà yìí:

      ◼ “Ní ìgbà tí mo ké sí ọ kẹ́yìn, a jíròrò orí 59, ‘Ta Ni Jesu Jẹ́ Niti Gidi?’ nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Ìwọ yóò rántí pé Jesu fúnra rẹ̀ ni ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìbéèrè yìí. Ìdí tí mo fi wá nísinsìnyí ni láti jíròrò apá tí ó kẹ́yìn nínú orí náà pẹ̀lú rẹ. Ó ṣí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ẹni tí Jesu jẹ́ ní ti gidi payá síwájú sí i.” O lè máa bá ìjíròrò rẹ nìṣó pẹ̀lú onílé náà.

      6 Lẹ́yìn tí ó ti ka ìwé náà, ẹnì kan fi ìtara sọ pé: “Òun ni ìwé tí ó dára jù lọ tí mo tíì kà rí! Ó yí ìgbésí ayé mi padà.” Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò tí ó gbéṣẹ́ sọ́dọ̀ àwọn tí ó fìfẹ́ hàn nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla, lè sèso àtàtà ní ìpínlẹ̀ rẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́