-
Kí ni Ìhìn Rere Ìjọba Náà?Ilé Ìṣọ́—2001 | April 1
-
-
ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23.
Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé—ìyẹn ọkùnrin atóbilọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí—Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà. Àkọsílẹ̀ Bíbélì nínú Máàkù 1:14, 15 sọ fún wa pé: “Wàyí o, lẹ́yìn tí a ti fi àṣẹ ọba mú Jòhánù, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run, ó sì ń wí pé: ‘Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé, ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.’”
Àwọn tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Jésù jẹ́, tí wọ́n sì gba ìhìn rere náà gbọ́ rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Jòhánù 1:12 sọ pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n gba [Jésù], àwọn ni ó fún ní ọlá àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run, nítorí pé wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.” Jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n ní ìrètí jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Jòhánù 2:25.
Ṣùgbọ́n àǹfààní rírí àwọn ìbùkún Ìjọba náà gbà kò mọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní. Gẹ́gẹ́ báa ti sọ ṣáájú, gbogbo ilẹ̀ ayé táwọn èèyàn ń gbé la ti ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí. Fún ìdí yìí, àwọn ìbùkún Ìjọba náà ṣì ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó. Kí ni o gbọ́dọ̀ ṣe láti lè rí àwọn ìbùkún náà gbà? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.
-
-
Àwọn Ìbùkún Ìjọba náà Lè Jẹ́ TìrẹIlé Ìṣọ́—2001 | April 1
-
-
Àwọn Ìbùkún Ìjọba náà Lè Jẹ́ Tìrẹ
KRISTẸNI àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ mélòó kan lára àwọn lájorí èdè táwọn èèyàn ń sọ nígbà ayé rẹ̀. Ìwé tó kà bá tẹni tó jáde yunifásítì lóde òní dọ́gba. Gbogbo àǹfààní àti ẹ̀tọ́ táwọn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní lòun náà ní. (Ìṣe 21:37-40; 22:3, 28) Àwọn nǹkan wọ̀nyí ì bá ti sọ ọ́ dọlọ́rọ̀ àti olókìkí. Àmọ́, ó sọ pé: “Àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi . . . mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.” (Fílípì 3:7, 8) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?
Pọ́ọ̀lù, ẹni táa mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù ará Tásù tẹ́lẹ̀, tó tún ṣe inúnibíni sáwọn “tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà,” wá di onígbàgbọ́ lẹ́yìn tó rí ìran Jésù táa jí dìde, táa sì ṣe lógo. (Ìṣe 9:1-19) Ohun tí Pọ́ọ̀lù rí lọ́nà nígbà tó ń lọ sí Damásíkù mú kí ó dá a lójú gbangba pé Jésù ni Mèsáyà, tàbí Kristi, táa ṣèlérí, ẹni tí yóò di alákòóso Ìjọba táa ṣèlérí náà lọ́jọ́ iwájú. Èyí tún fa ìyípadà tó kàmàmà nínú ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ gbígbàfiyèsí tó sọ lókè yìí ṣe fi hàn. Lọ́rọ̀ kan, Pọ́ọ̀lù ronú pìwà dà nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn.—Gálátíà 1:13-16.
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ ìṣe táa sábà máa ń tú sí “ronú pìwà dà,”
-