ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìjẹ́wọ́ Tí Ń Yọrí sí Ìwòsàn
    Ilé Ìṣọ́—2001 | June 1
    • pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ ẹni, lè múni bọ̀ sípò. Bẹ́ẹ̀ ni o, lórí ìpìlẹ̀ ìràpadà Kristi, ẹni tó ronú pìwà dà lè wá rí “ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—Éfésù 1:7.

      “Ọkàn-Àyà Mímọ́ Gaara” àti “Ẹ̀mí Tuntun”

      Nínú Sáàmù 51, lẹ́yìn tí Dáfídì jẹ́wọ́, kò wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé òun ò wúlò fún nǹkan kan mọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn sáàmù tó kọ nípa ìjẹ́wọ́ rẹ̀ fi hàn pé ara tù ú àti pé ó pinnu láti máa fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, wo Sáàmù 32. Ní ẹsẹ kìíní, a kà pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.” Bó ti wù kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wúwo tó, ó bà ni, kò tíì bà jẹ́, bí onítọ̀hún bá fi tọkàntọkàn ronú pìwà dà. Ọ̀nà kan téèyàn lè gbà fi hàn pé tọkàntọkàn lòun fi ronú pìwà dà ni pé kí ó gbà, bí Dáfídì ti gbà, pé ẹ̀bi òun ni gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:13) Dáfídì kò bẹ̀rẹ̀ sí wá àwáwí níwájú Jèhófà tàbí kí ó gbìyànjú láti di ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíì. Ẹsẹ karùn-ún sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀. Mo wí pé: ‘Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.’ Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” Ìjẹ́wọ́ àtọkànwá ń mú ìtura wá, kò sì ní jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn máa na onítọ̀hún ní pàṣán mọ́ nítorí àwọn ìwà àìtọ́ tó hù sẹ́yìn.

      Lẹ́yìn tí Dáfídì tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Jèhófà, ó wá bẹ̀bẹ̀ pé: “Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sáàmù 51:10) Bíbéèrè “ọkàn-àyà mímọ́ gaara” àti “ẹ̀mí tuntun” fi hàn pé Dáfídì gbà pé ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun, òun sì nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti wẹ ọkàn-àyà òun mọ́, kí òun sì wá bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Dípò kí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí káàánú ara rẹ̀, ó pinnu láti máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run nìṣó. Ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, kí o ṣí ètè tèmi yìí, kí ẹnu mi lè máa sọ ìyìn rẹ jáde.”—Sáàmù 51:15.

      Kí ni Jèhófà ṣe sí ìrònúpìwàdà àtọkànwá Dáfídì àti akitiyan rẹ̀ láti sìn ín? Ó sọ ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí fún Dáfídì pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Èyí fini lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò kọbi ara sí ìmọ̀lára àti àìní ẹni tó ronú

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2001 | June 1
    • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

      Níwọ̀n bí Jèhófà ti múra tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini nípasẹ̀ ìtóye ẹbọ ìràpadà, èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì kí àwọn Kristẹni jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fáwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ?

      Gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú ọ̀ràn ti Dáfídì àti Bátí-ṣébà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì wúwo gan-an, síbẹ̀ Jèhófà dárí jì í nítorí pé Dáfídì ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Nígbà tí Nátánì wòlíì tọ Dáfídì wá, ó jẹ́wọ́ ní tààràtà pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.”—2 Sámúẹ́lì 12:13.

      Àmọ́ o, kì í ṣe kìkì pé Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba ìjẹ́wọ́ àtọkànwá, tó sì ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún máa ń ṣe ètò onífẹ̀ẹ́ láti ran ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lọ́wọ́ láti padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí. Nínú ọ̀ràn ti Dáfídì, ìrànlọ́wọ́ náà wá nípasẹ̀ Nátánì wòlíì. Lónìí, àwọn àgbà ọkùnrin, tàbí àwọn alàgbà tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí ń bẹ nínú ìjọ Kristẹni. Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn ṣàlàyé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn [nípa tẹ̀mí] láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.”—Jákọ́bù 5:14, 15.

      Àwọn alàgbà onírìírí lè ṣe púpọ̀ láti pẹ̀rọ̀ sí àròdùn ọkàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ti ronú pìwà dà. Wọ́n

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́