-
Àwọn Èèyàn Mọ Òfin Pàtàkì Náà—Kárí AyéIlé Ìṣọ́—2001 | December 1
-
-
èèyàn fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí, kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ mi dù mí, kí wọ́n má sì rẹ́ mi jẹ? Ṣé màá fẹ́ gbé nínú ayé tí kò ti sí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìwà ọ̀daràn àti ogun? Ṣé màá fẹ́ wà nínú ìdílé tí gbogbo mẹ́ńbà rẹ̀ ti ń bìkítà nípa ìmọ̀lára àti ire ẹnì kìíní kejì?’ Ká sòótọ́, ta ló máa sọ pé òun ò fẹ́ nǹkan dáadáa wọ̀nyẹn? Ohun tó kàn ń báni nínú jẹ́ ni pé bóyá la rí ẹni tó ń gbádùn ipò wọ̀nyí lónìí. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, bí ẹní ń gbéra ẹni gẹṣin aáyán ni ríretí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.
Wọ́n Ti Rú Òfin Pàtàkì Náà
Kì í ṣòní kì í ṣàná làwọn èèyàn ti ń hùwà ibi séèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìkejì wọn lójú. Lára ìwà ibi wọ̀nyí ni òwò ẹrú ní Áfíríkà, àwọn àgọ́ ìfikúpani ti ìjọba Násì, àṣà fífi agbára mú àwọn ògo wẹẹrẹ ṣiṣẹ́ àti ìwà ìkà pípa odindi ẹ̀yà run ní àwọn ibi púpọ̀. Tá a bá ní ká máa ka gbogbo ìwà láabi táwọn èèyàn ń hù, ilẹ̀ á kún.
Ayé anìkànjọpọ́n layé onímọ̀ ẹ̀rọ tí à ń gbé lónìí. Ṣàṣà làwọn tó ń gba ti ẹlòmíì rò, àfi tí kò bá ní í ná wọn ní nǹkan kan, tí kò sì ní tẹ ohun tí wọ́n pè ní ẹ̀tọ́ tiwọn lójú. (2 Tímótì 3:1-5) Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ya onímọtara-ẹni-nìkan, òǹrorò, aláìlójú àánú àti anìkànjọpọ́n? Kì í ha í ṣe nítorí pé àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ti pa Òfin Pàtàkì náà tì, tí wọ́n kà á sí ìlànà tí kò bóde mu mọ́ ni bí? Ó mà ṣe o, nítorí pé àwọn kan tó sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ pàápàá wà lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Níbi tí nǹkan sì ń bá a lọ yìí, ńṣe làwọn èèyàn á túbọ̀ máa di anìkànjọpọ́n.
Nítorí náà, àwọn ìbéèrè tó ṣe kókó, tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni: Kí ni títẹ̀lé Òfin Pàtàkì yìí wé mọ́? Ǹjẹ́ a ṣì rí àwọn tó ń tẹ̀ lé e? Ǹjẹ́ àkókò kan máa wà tí gbogbo aráyé yóò tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì yìí? Tó o bá fẹ́ mọ ìdáhùn tòótọ́ sí ìbéèrè wọ̀nyí, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
-
-
Òfin Pàtàkì Náà—Ṣì Bóde MuIlé Ìṣọ́—2001 | December 1
-
-
Òfin Pàtàkì Náà—Ṣì Bóde Mu
Lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn, Jésù ló ṣe Òfin Pàtàkì náà kí ó lè fi ìwà rere kọ́ni, àmọ́ ohun tí òun alára sọ ni pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 7:16.
BẸ́Ẹ̀ ni o, ẹni tó rán Jésù, èyíinì ni Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe Ẹlẹ́dàá, ni Orísun àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni, títí kan èyí tí a wá mọ̀ sí Òfin Pàtàkì.
Ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni pé kí gbogbo èèyàn máa ṣe sáwọn ẹlòmíì bí wọ́n ṣe fẹ́ káwọn ẹlòmíì máa ṣe sáwọn. Bí a bá wo bó ṣe dá ènìyàn, a óò rí i pé ó fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ ní ti bíbìkítà fún ire àwọn ẹlòmíràn. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé títí dé àyè kan, Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ fún àwọn èèyàn ní àwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ, kí wọ́n lè wà ní àlàáfíà, ayọ̀ àti ìṣọ̀kan—ète rẹ̀ sì ni pé kí wọ́n máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí ayé fáàbàdà. Bí wọ́n bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wọn
-