-
‘Ọkọ Tó Láyọ̀ Nítorí Tí Ó Ní Aya Rere’Ilé Ìṣọ́—1999 | September 1
-
-
‘Ọkọ Tó Láyọ̀ Nítorí Tí Ó Ní Aya Rere’
LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN, àwọn kan máa ń fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé túlétúlé ni wọ́n. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó tó ti kẹ́sẹ járí níbi tó jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀kan nínú àwọn tọkọtaya náà ti fi hàn pé irọ́ gbáà ni. Kíkọbi ara sí àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì nínú ìgbésí ayé ìdílé máa ń mú kí ayọ̀ wà nínú ìgbéyàwó, ohun tí lẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí, tí a kọ sínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé, fi hàn nìyẹn.
Ó ti ń lọ sí ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n báyìí tí mo ti jẹ́ ọkọ tó láyọ̀ nítorí tí mo ní aya rere tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọmọ mi márààrún ló bá mi tọ́jú, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ rèé, òun kọ́ ló bí méjì nínú wọn, àmọ́, ọwọ́ tó fi mú àwọn ọmọ tirẹ̀ náà ló fi mú àwọn tó kù, kò sì fẹ́ràn ìkan jù ìkan lọ. Bí mo ti jẹ́ olùdarí ilé iṣẹ́ kan báyìí tí mo sì ní àwọn òṣìṣẹ́ márùndínláàádọ́ta lọ́dọ̀, mo lè fi ìdánilójú sọ fún un yín pé òun ló jẹ́ kí n ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ mi. Ìdí nìyẹn tó jẹ́ pé bí mo ṣe rí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn tí mo máa ń kà déédéé tó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ewu sí àgbègbè Lot-et-Garonne, ni mo bá pinnu láti fún un yín ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro.”
Lẹ́tà náà tún sọ pé: “Wọn kì í mu sìgá tàbí kí wọ́n mutí yó. Ṣé ewu lèyí jẹ́ ni? Wọ́n jẹ́ Kristẹni tó ń rára gba nǹkan, tí kì í fagbára mú ẹnikẹ́ni láti tẹ̀ lé ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni wọ́n ti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. . . . A kì í gbọ́ pé wọ́n kówó jẹ tàbí pé wọ́n ń ta oògùn olóró. Wọn kì í jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, mo sì lè mú un dá yín lójú pé àwọn pẹ̀lú ń gbé ìgbésí ayé bíi ti gbogbo ènìyàn. . . .
“Ẹ lè wá bi mí pé: Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tíwọ náà ò fi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ìdí ni pé wọn ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìgbàgbọ́ Kristẹni, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò gba gbẹ̀rẹ́ lórí ọ̀ràn ìwà rere, ìwọ̀nyí ò sì rọrùn fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.”
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?Ilé Ìṣọ́—1999 | September 1
-
-
Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?
Àní nínú ayé onídààmú yìí, o lè jèrè ayọ̀ láti inú ìmọ̀ pípéye Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ète àgbàyanu rẹ̀ fún aráyé. Bí o bá fẹ́ gba ìsọfúnni síwájú sí i tàbí kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.
-