-
Kí Ló Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Tòótọ́ Láàárín Àwọn Kristẹni Ṣeé Ṣe?Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2003 | December
-
-
Kí Ló Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Tòótọ́ Láàárín Àwọn Kristẹni Ṣeé Ṣe?
1 Kí lohun náà tó lè mú kó ṣeé ṣe fún mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn láti igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ tí wọ́n ń sọ nǹkan bí okòó dín nírínwó [380] èdè láti wà ní ìṣọ̀kan? Àfi ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú kí èyí ṣeé ṣe. (Míkà 2:12; 4:1-3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ látinú ìrírí tiwọn fúnra wọn pé ìṣọ̀kan tòótọ́ láàárín àwọn Kristẹni kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lónìí. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ “agbo kan” lábẹ́ ‘olùṣọ́ àgùntàn wa kan,’ a ti pinnu láti yàgò fún ẹ̀mí ayé yìí tí ń fa ìpínyà.—Jòhánù 10:16; Éfé. 2:2.
2 Ète Ọlọ́run tí kò lè kùnà ni pé kí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ láyé àti lọ́run wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́. (Ìṣí. 5:13) Nítorí pé Jésù mọ bí èyí ṣe ṣe pàtàkì tó, ó gbàdúrà gidigidi pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun lè wà níṣọ̀kan. (Jòh. 17:20, 21) Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè mú kí ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni máa bá a nìṣó?
3 Ohun Tó Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Ṣeé Ṣe: Láìsí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀, ìṣọ̀kan Kristẹni kò lè ṣeé ṣe rárá. Fífi àwọn ohun tí à ń kà nínú Bíbélì ṣèwà hù ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ lọ fàlàlà nínú ìgbésí ayé wa. Èyí ń jẹ́ ká lè “máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3) Ó ń jẹ́ ká lè máa fara dà á fún ara wa nínú ìfẹ́. (Kól. 3:13, 14; 1 Pét. 4:8) Ṣé ò ń mú kí ìṣọ̀kan yìí máa bá a nìṣó nípa ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́?
4 Iṣẹ́ wíwàásù àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí a gbé lé wa lọ́wọ́ náà tún ń mú ká wà níṣọ̀kan. Nígbà tá a bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, tí à “ń làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere,” à o di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.” (Fílí. 1:27; 3 Jòh. 8) Bá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìdè ìfẹ́ tó ń mú ká wà níṣọ̀kan láàárín ìjọ á máa di èyí tó lágbára sí i. Oò ṣe ké sí ẹnì kan tó ti pẹ́ díẹ̀ tẹ́ ẹ ti jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láti bá ọ jáde lọ́sẹ̀ yìí?
5 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ fún wa láti jẹ́ apákan ẹgbẹ́ ará tòótọ́ kan ṣoṣo tó kárí ayé, lórí ilẹ̀ ayé lónìí! (1 Pétérù 5:9) Láìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló fojú ara wọn rí ìṣọ̀kan tó kárí ayé yìí ní àwọn Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run.” Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa mú kí ìṣọ̀kan oníyebíye yìí máa bá a nìṣó nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, nípa fífi ìfẹ́ yanjú aáwọ̀ àti nípa wíwàásù ìhìn rere náà “pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan.”—Róòmù 15:6.
-
-
Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ RíIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2003 | December
-
-
Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Rí
1 Àwọn ìtọ́ni tí Jésù fún wa nípa bí a óò ṣe ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà ń mú ìpèníjà wá. Ó sọ pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” (Mát. 10:11) Ní àkókò yìí tí àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ sí nílé mọ́, ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo la lè gbà wá àwọn ẹni yíyẹ rí?
2 Gbé Ìpínlẹ̀ Rẹ Yẹ̀ Wò Dáadáa: Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbé ìpínlẹ̀ rẹ yẹ̀ wò dáadáa. Ìgbà wo ló ṣeé ṣe jù lọ pé kí àwọn èèyàn wà nílé? Ibo la ti lè rí wọn lójú mọmọ? Ǹjẹ́ ọjọ́ kan wà láàárín ọ̀sẹ̀ tàbí àkókò kan wà lóòjọ́ tí wọ́n á lè tẹ́tí gbọ́ wa dáadáa tá a bá kàn sí wọn? Mímú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ bá ìgbòkègbodò àti ipò àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ mu lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí púpọ̀.—1 Kọ́r. 9:23, 26.
3 Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ti rí i pé àwọ́n máa ń bá àwọn èèyàn nílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Lásìkò yẹn, ara àwọn onílé kan máa ń balẹ̀ dáadáa, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti tẹ́tí sílẹ̀. Ṣíṣiṣẹ́ láwọn àgbègbè okòwò àti láwọn ibi táwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà jẹ́ kí àwọn èèyàn gbọ́ nípa ìhìn rere náà.
4 Nínú oṣù kan tó jẹ́ oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò, ìjọ kan ṣètò ìjẹ́rìí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ láwọn ọjọ́ Sátidé àti Sunday wọ́n sì tún ṣètò ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ láwọn ọjọ́ Wednesday àti Friday. Bákan náà, wọ́n ṣètò fún ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù, wọ́n sì tún ṣètò láti ṣiṣẹ́ láwọn àgbègbè okòwò. Àwọn ìṣètò wọ̀nyí mú kí ìtara àwọn ará fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i débi pé ìjọ náà pinnu láti máa bá àwọn ìṣètò náà lọ.
5 Jẹ́ Aláápọn Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò: Bí kò bá rọrùn ní ìpínlẹ̀ rẹ láti bá àwọn èèyàn nílé nígbà tó o bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò, gbìyànjú láti rí i pé gbogbo ìgbà tó o bá lọ bẹ̀ wọ́n wò lẹ jọ máa ń fohùn ṣọ̀kan lórí ìgbà kan pàtó tí wàá padà wá, títí kan ìgbà àkọ́kọ́ tó o bá bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, rí i dájú pé o padà lọ. (Mát. 5:37) Bí onílé náà bá ní tẹlifóònù, o lè ní kó fún ọ ní nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Èyí tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tún kàn sí ẹni náà.
6 Ó dájú pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa aláápọn láti wá àwọn ẹni yíyẹ rí àti láti padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò.—Òwe 21:5.
-