ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bí Àwọn Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | October
    • 6 Olùṣọ́ Àgùntàn Onífẹ̀ẹ́: Alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ máa ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn tó jẹ́ pé ipa díẹ̀ ni wọ́n lè kó nínú iṣẹ́ ìwàásù nítorí ipò wọn. Ó máa ń rí i dájú pé àwọn tó ní ìṣòro kan pàtó tó ń ṣèdíwọ́ fún wọn, irú bí àwọn arúgbó tàbí àwọn tí kò lè jáde nílé, àtàwọn tí wọ́n ní ìdíwọ́ onígbà kúkúrú nítorí àìsàn lílekoko tàbí ìfarapa, mọ̀ nípa ìṣètò tó fún wọn láǹfààní láti máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá látorí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sókè bí wọn kò bá lè ròyìn odindi wákàtí kan lóṣù. (Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ló máa pinnu ẹni tó tóótun láti jàǹfààní látinú ìṣètò yìí.) Ó tún máa ń fìfẹ́ hàn sí àwọn tí a yàn sí àwùjọ náà tí wọ́n lè ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, nípa sísapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí kópa déédéé nínú ìgbòkègbodò ìjọ.—Lúùkù 15:4-7.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | October
    • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

      Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 14

      Orin 103

      10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tó kọjá, láti múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 7, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ October 15 àti Jí! November 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 7 láti fi Jí! November 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bí “Mo mọ̀ nípa iṣẹ́ yín dáadáa.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.

      15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

      20 min: “Bí Àwọn Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn.” Kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, ṣàlàyé ní ṣókí bí ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ṣe bẹ̀rẹ̀. (jv-E ojú ìwé 237, ìpínrọ̀ 4) Ṣètò ṣáájú pé kí àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta sọ bí wọ́n ti ṣe jàǹfààní látinú ìfẹ́ àtọkànwá tí a fi hàn sí wọn nípasẹ̀ ìṣètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.

      Orin 65 àti àdúrà ìparí.

      Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 21

      Orin 206

      10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

      15 min: “Àwa Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run.” Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Ṣètò láti ka ìpínrọ̀ 5, kí o sì rí i pé àwùjọ lóye kókó náà dáadáa.

      20 min: “Ẹ Bẹ̀rù Ọlọ́run, Kí Ẹ sì Fi Ògo fún Un.” (Ìṣí. 14:7) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká tó kọjá. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n rí kọ́ àti bí ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti fi wọ́n sílò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìdílé. (A lè yan àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ lórí apá kọ̀ọ̀kan ṣáájú.) Jíròrò àwọn apá tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà: (1) “Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” Báwo la ṣe lè ran àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kí wọ́n sì di ògbóṣáṣá ìránṣẹ́ Jèhófà? (2) “Ìbẹ̀rù Jèhófà Túmọ̀ sí Kíkórìíra Ibi.” (w87-YR 4/15 16-18) Báwo ni Òwe 6:16-19 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra—ìgbéraga, irọ́ pípa, lílépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, eré ìnàjú tí kò bójú mu tàbí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́nà tí kò yẹ? (3) “Túbọ̀ Sún Mọ́ Àwọn Tí O Nífẹ̀ẹ́.” A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Jésù, àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa, àtàwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ; báwo ni sísúnmọ́ wọn ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ayé? (4) “Bẹ̀rù Jèhófà, Má Ṣe Bẹ̀rù Èèyàn.” Báwo ni ìbẹ̀rù mímú Jèhófà bínú ti ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí ojo nínú iṣẹ́ ìwàásù, láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run níbi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí láti má ṣe jẹ́ kí ọ̀gá rẹ níbi iṣẹ́ mú ọ pa àwọn ìpàdé ìjọ jẹ, àwọn àpéjọ àyíká, àwọn àpéjọ àkànṣe, àtàwọn àpéjọ àgbègbè? (5) “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run.” (Sm. 119:37; Héb. 4:13) Kí nìdí tó fi yẹ kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run sún wa láti yàgò fún mímu ọtí lámujù, wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tàbí dídá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn níkọ̀kọ̀? (6) “Ẹ Máa Bá A Lọ ní Rírìn Nínú Ìbẹ̀rù Jèhófà.” Ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà bù kún ọ nítorí bó o ṣe gba ẹ̀mí rẹ̀ láyè láti máa ṣiṣẹ́ ní kíkún nínú ìgbésí ayé rẹ?—Sm. 31:19; 33:18; 34:9, 17; 145:19.

      Orin 171 àti àdúrà ìparí.

      Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 28

      Orin 110

      8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tó kọjá, láti múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù October sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 7, jẹ́ kí arábìnrin kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 1 lọni, kí arákùnrin kan sì fi hàn bí a ṣe lè fi Jí! November 8 lọni. Lo àbá kejì ní ojú ìwé 7 láti fi Jí! November 8 lọni. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ní ṣókí, tẹnu mọ́ kókó pàtàkì kan tó gbéṣẹ́ nínú ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà.

      12 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Ké sí àwọn ará láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà, níbi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, nígbà tí wọ́n lọ rajà, àti láwọn ìgbà mìíràn.

      25 min: “Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Fífarasin Tó Wà Nínú Ṣíṣílọ sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn Láìbófinmu.” Kí alàgbà kan tó tóótun bójú tó ìjíròrò yìí lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣètò láti ka ìpínrọ̀ 6, 7, àti 10.

      Orin 67 àti àdúrà ìparí.

      Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 4

      Orin 66

      10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní ṣókí, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá díẹ̀ látinú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002 fún fífi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ lọni. Ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà.

      13 min: Má Ṣe Tijú Ìhìn Rere. (Róòmù 1:16) Ọ̀dọ́ kan lọ fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lọ bàbá rẹ̀. Ọ̀dọ́ náà kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ òun gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ìbẹ̀rù pé káwọn ojúgbà rẹ̀ má bàa fi ṣe ẹlẹ́yà. Bàbá rẹ̀ yìn ín fún bó ṣe sọ tinú rẹ̀ jáde. Ó sọ fún un nípa bí Pétérù ṣe hùwà nígbà kan nítorí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. (Mát. 26:69-74) Bàbá fún un ní ìmọ̀ràn tó tẹ̀ lé e yìí: A kò gbọ́dọ̀ tijú jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni láé. (Máàkù 8:38) Ó ṣàǹfààní láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí ní ilé ẹ̀kọ́. Bó o bá sọ irú ẹni tó o jẹ́ fáwọn olùkọ́, ọ̀pọ̀ lára wọn ni yóò bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ, wọn ò sì ní gbìyànjú láti mú ọ lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tó o mọ̀ pé ó lòdì. Bákan náà làwọn ọ̀dọ́ oníwàkiwà kò ní máa rọ̀ ọ́ láti hùwàkiwà. Á rọrùn fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ yòókù láti tètè lóye ìdí tó o fi pinnu láti má ṣe dájọ́ àjọròde, láti má ṣe kópa nínú àwọn eré ìdárayá ilé ẹ̀kọ́, àti láti má ṣe kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ẹ̀yìn ilé ẹ̀kọ́. Bí àkókò bá ṣe wà sí, kí bàbá àti ọ̀dọ́ náà jíròrò àwọn kókó tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Pipolongo Ibadọrẹẹ Rẹ Pẹlu Ọlọrun Ni Gbangba” látinú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè, ojú ìwé 315 sí 318. Ọ̀dọ́langba náà fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún ìmọ̀ràn àtàtà tó rí gbà náà.

      22 min: Ẹ Fi Ara Yín Sábẹ́ Ọlọ́run—Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù. (Ják. 4:7) Nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí, kí alàgbà kan darí ìjíròrò yìí pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà tó ń tani jí, èyí tí a gbé ka ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tá a ṣe kọjá. Ké sí àwùjọ láti sọ bí wọ́n ṣe fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò. (A lè yan àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ lórí apá kọ̀ọ̀kan ṣáájú.) Jíròrò àwọn apá tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà: (1) “Fífi Ara Ẹni Sábẹ́ Ọlọ́run Nínú Ayé Tó Ti Di Ẹrú Yìí.” Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo ká má bàa kó sínú ìdẹkùn ayé? (2) “Bí Àwọn Tó Wà Nínú Ìdílé Ṣe Lè Fi Ara Wọn Sábẹ́ Ọlọ́run.” Kí nìdí tó fi jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú nínú ètò àjọ Jèhófà pé kí àwọn ìdílé ṣọ̀kan dáadáa? Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (3) “Ran Àwọn Tí Wọ́n Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ọmọ Ẹ̀yìn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-In Sọ́dọ̀ Jèhófà.” Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti borí àwọn ìdènà tó lè dán ìgbàgbọ́ wọn wò? (4) “Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti Kọjú Ìjà sí Èṣù.” Kí lohun pàtàkì tó lè mú wa ṣàṣeyọrí nínú kíkọjú ìjà sí Èṣù? Báwo ni ìhámọ́ra tẹ̀mí tí Éfésù 6:11-18 ṣàpèjúwe ṣe lè dáàbò bò wá? (w92-YR 5/15 21 sí 23) (5) “Àwọn Èwe Tí Wọ́n Ti Kọjú Ìjà sí Èṣù” àti “Àwọn Èwe Tí Wọ́n Ń Jàǹfààní Nínú Fífi Ara Wọn Sábẹ́ Ọlọ́run.” Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọgbọ́n àyínìke Sátánì táwọn ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún? Báwo làwọn èwe ṣe ń rí ìbùkún gbà nítorí fífi ara wọn sábẹ́ Jèhófà? (w90-YR 8/1 13 àti 14, ìpínrọ̀ 15 sí 17) (6) “Bí A Ṣe Lè Jàǹfààní Nínú Títẹríba fún Ọlọ́run.” Ṣàlàyé bí àwọn Kristẹni ṣe lè fi ìtẹríba hàn sí àwọn aláṣẹ ìjọba, sí àwọn ọ̀gá wọn níbi iṣẹ́, nínú agbo ìdílé, àti nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn ànímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?

      Orin 185 àti àdúrà ìparí.

  • Àwọn Ìfilọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | October
    • Àwọn Ìfilọ̀

      ◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí ẹnì kan bá ti fi ìfẹ́ hàn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, o lè fi ìwé kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọ̀ ọ́. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè fi Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. Bí ìjọ kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ìwé tá a lè fi lọni ní àfidípò yìí, ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní púpọ̀ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ẹ kò bá ní èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí, ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni.

      ◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2003” ni àkìbọnú tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, kí ẹ tọ́jú rẹ̀ kí ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún 2003.

      ◼ Bí àwọn àkókò tí ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé yóò bá yí padà ní January 1, kí akọ̀wé ìjọ fi ìyípadà náà tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí nípa fífi fọ́ọ̀mù Congregation Meeting Information and Handbill Request (S-5) ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Bí ẹ bá ń fẹ́ fọ́ọ̀mù yìí tuntun, ẹ lè fi fọ́ọ̀mù ọ̀hún kan náà béèrè fún un. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kọ̀wé béèrè fún fọ́ọ̀mù yìí ní ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ, ó kéré tán, ṣáájú àkókò tí ẹ fẹ́ kó tẹ̀ yín lọ́wọ́.

      ◼ A ò ní jíròrò lórí fídíò Society èyíkéyìí lóṣù October. Ní December, a ó jíròrò lórí fídíò náà, No Blood—Medicine Meets the Challenge.

      ◼ Fídíò Tuntun Tó Wà:

      Faithful Under Trials—Jehovah’s Witnesses in the Soviet Union—Gẹ̀ẹ́sì

      No Blood—Medicine Meets the Challenge—Gẹ̀ẹ́sì

  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | October
    • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

      Ilé Ìṣọ́ Oct. 15

      “Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé fún àwọn ọmọdé tàbí àwọn ẹlòmíràn nípa ìdí tí ọ̀pọ̀ ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀ lónìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì dáhùn ìbéèrè náà, ‘Ta Ní Ń Bẹ Lẹ́yìn Gbogbo Láabi Tí Ń Ṣẹlẹ̀?’ [Ka 1 Jòhánù 5:19.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ olubi ọ̀hún àti bí a ṣe lè kọjúùjà sí i.”

      Ilé Ìṣọ́ Nov. 1

      “Ọ̀pọ̀ lára wa máa ń gbìyànjú láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́, wàá gbà pé èyí kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ṣe. [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀. [Ka Jákọ́bù 3:2.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ bí títọrọ àforíjì ṣe lè jẹ́ kókó pàtàkì kan láti fi mú kí àlàáfíà wà láàárín tọ̀túntòsì.”

      Jí! Nov. 8

      “Ǹjẹ́ o rò pé àdúrà tí àwọn aṣáájú ìsìn tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn ń gbà lè mú àlàáfíà ayé wá? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí àlàáfíà yóò wà kárí ayé. [Ka Aísáyà 9:6, 7.] Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé alákòóso pàtàkì kan ni yóò mú àlàáfíà ayé wá? Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ ẹni tí alákòóso yẹn jẹ́ àti bí yóò ṣe mú ojúlówó àlàáfíà wá.”

      “Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí ẹnì kankan kì yóò sọ pé, ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ [Ka Aísáyà 33:24.] Ǹjẹ́ o ò gbà pé ìyẹn á dára gan-an? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bó ti wù kó rí, lóde òní, aráyé ń dojú kọ oríṣiríṣi àìsàn, títí kan àjàkálẹ̀ àrùn éèdì. Ìtẹ̀jáde Jí! yìí dáhùn ìbéèrè náà, Ǹjẹ́ àrùn Éèdì máa dópin láé?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́