ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | February
    • 3. Kí ni àǹfààní tó wà nínú fífi ìwé ìròyìn méjèèjì lọni pa pọ̀?

      3 Fi Méjèèjì Lọni Pa Pọ̀: Àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí jẹ́ ká rí i pé a ò lè sọ pé ẹni báyìí ló máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa tàbí ẹni báyìí ni ò ní kà á, àti pé a ò lè mọ ohun táwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú wọn. (Oníw. 11:6) Nítorí náà, ńṣe ló yẹ ká máa fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan lára wọn la máa sọ̀rọ̀ lé lórí tá a bá ń fi wọ́n lọni. Láwọn ìgbà míì, ó máa dára ká fi oríṣiríṣi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

      4. Ètò wo la lè ṣe ká lè máa lọ pín ìwé ìròyìn?

      4 Ó dára ká máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a ó fi máa lọ pín ìwé ìròyìn. Nínú kàlẹ́ńdà ọdún yìí, 2005 Calendar of Jehovah’s Witnesses, gbogbo ọjọ́ Saturday la pè ní “Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn.” Síbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lágbègbè kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, àti pé ohun tó rọrùn fún ẹnì kan lè má rọrùn fún ẹlòmíràn, àwọn akéde kan lè ya ọjọ́ mìíràn sọ́tọ̀ láti fi pín àwọn ìwé ìròyìn wa. Ǹjẹ́ iṣẹ́ pínpín ìwé ìròyìn wà lára ohun tó o máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?

      5. Àwọn àǹfààní wo la lè lò láti fi ìwé ìròyìn lọni, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo àǹfààní wọ̀nyí?

      5 Pinnu Iye Ìwé Ìròyìn Tó O Fẹ́ Máa Fi Síta: Bí a bá pinnu iye ìwé ìròyìn tá a fẹ́ máa fi síta lóṣooṣù, a ó lè túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn fífi ìwé ìròyìn síta. Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé? Ǹjẹ́ o máa ń fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn tó o bá bá pàdé lóde ẹ̀rí? Ǹjẹ́ o lè máa fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn nígbà tó o bá ń wàásù ní òpópónà, níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, tàbí láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí? Ǹjẹ́ o máa ń kó ìwé ìròyìn dání nígbà tó o bá ń rìnrìn àjò, nígbà tó o bá ń lọ rajà, tàbí nígbà tó o bá ń lọ sáwọn ibòmíràn? Lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!

      6. Báwo la ṣe lè lo àwọn ìwé ìròyìn wa tí ọjọ́ wọn ti pẹ́?

      6 Síwájú sí i, a lè pinnu pé a fẹ́ máa fi àwọn ìwé ìròyìn wa tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tá a bá ní lọ́wọ́ síta. Kódà bí kò bá ṣeé ṣe láti fi ìwé ìròyìn síta láàárín oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn tá a ti tẹ̀ ẹ́ jáde, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣì wúlò. Ẹ jẹ́ ká fún àwọn olùfìfẹ́hàn wa láwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí. “Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́” ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. (Òwe 25:11) Ẹ jẹ́ ká lò wọ́n láti fi túbọ̀ ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sí i lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì wá sìn ín.

  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | February
    • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

      Ile Iṣọ Feb. 15

      “Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń gbọ́ pé àwọn kan ṣe iṣẹ́ ìyanu. [Sọ àpẹẹrẹ kan.] Àwọn èèyàn kan máa ń gba àwọn ìròyìn wọ̀nyí gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn máa ń ṣiyèméjì. Ìwé ìròyìn yìí á jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ wáyé àti pé bóyá irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ ṣì ń ṣẹlẹ̀ lónìí.” Ka Jeremáyà 32:21.

      Ile Iṣọ Mar. 1

      “Ǹjẹ́ o rò pé ayé yóò dára ju bó ṣe wà yìí lọ bí gbogbo èèyàn bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí? [Ka Róòmù 12:17, 18. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ó ṣeni láàánú pé, nígbà míì èdèkòyédè máa ń wáyé. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro tó bá wà láàárín àwa àtàwọn èèyàn kí àlàáfíà lè jọba.”

      Jí Mar. 8

      áyé ìgbàanì, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ máa bọlá fún ìyá wọn àti bàbá wọn. [Ka Ẹ́kísódù 20:12.] Ǹjẹ́ o rò pé àwọn èèyàn ń bọlá fún àwọn ìyá bó ṣe yẹ lóde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ojú àwọn ìyá ń rí ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ojúṣe wọn ní àṣeyege.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́