ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2004 | July 15
    • kúrò lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni pípèsè tó pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.a (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 2:1, 2) Nígbà wo la dá àwọn Kristẹni nídè kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀? Nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù darí rẹ̀ sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ní: “Òfin ẹ̀mí yẹn, èyí tí ń fúnni ní ìyè ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.” (Róòmù 8:2) Àwọn tí wọ́n ní ìrètí ìyè lókè ọ̀run gba òmìnira yìí nígbà tá a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n tí wọ́n sì jẹ́ aláìpé, Ọlọ́run polongo wọn ní olódodo ó sì sọ wọ́n di ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí. (Róòmù 3:24; 8:16, 17) Ní ti àwọn ẹni àmì òróró, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, Júbílì ti Kristẹni bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Tiwa.

      Àwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? (Jòhánù 10:16) Ní ti àwọn àgùntàn mìíràn, Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi á jẹ́ ìgbà ìmúbọ̀sípò àti ìdáǹdè. Lákòókò Júbílì Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún yìí, Jésù á lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà rẹ̀ fún gbogbo aráyé tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run yóò sì mú ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ ń ní lórí aráyé kúrò. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ní ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, aráyé á ti di ẹ̀dá pípé a ó sì ti dá wọn nídè pátápátá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá àti ikú. (Róòmù 8:21) Lẹ́yìn tí èyí bá ti rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Júbílì Kristẹni ti parí nìyẹn.

  • “Gbogbo Ẹni Tí Ó Jẹ́ Afọgbọ́nhùwà Yóò Fi Ìmọ̀ Hùwà”
    Ilé Ìṣọ́—2004 | July 15
    • “Gbogbo Ẹni Tí Ó Jẹ́ Afọgbọ́nhùwà Yóò Fi Ìmọ̀ Hùwà”

      ÌTỌ́SỌ́NÀ tó bá wá láti inú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ‘yẹ ní fífẹ́ ju wúrà, àní, ju ọ̀pọ̀ wúrà tí a yọ́ mọ́.’ (Sáàmù 19:7-10) Kí nìdí tó fi yẹ ní fífẹ́? Nítorí pé “òfin ọlọ́gbọ́n [Jèhófà] jẹ́ orísun ìyè, láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” (Òwe 13:14) Nígbà tá a bá fi ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ sílò, kì í wulẹ̀ ṣe pé á mú kí ìgbésí ayé wa sàn sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n á tún ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìdẹkùn tó lè fẹ̀mí wa wewu. Ẹ ò wá rí i bó ṣe ṣe kókó tó láti wá ìmọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ká sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tá à ń kọ́!

      Gẹ́gẹ́ bó ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Òwe 13:15-25, Sólómónì, ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, fún wa ní àmọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ hùwà kí ayé wa lè dára kí ẹ̀mí wa sì gùn.a Nípa lílo àwọn òwe ṣókí ṣókí, ó jẹ́ ká rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ojú rere àwọn ẹlòmíì, bá a ṣe lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, bá a ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo ìbáwí àti bá a ṣe lè fọgbọ́n yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa. Lára ohun tó tún gbé yẹ̀ wò ni ọgbọ́n tó wà nínú fífi ogún sílẹ̀ fáwọn ọmọ wa àti bá a ṣe lè máa fi ìfẹ́ bá wọn wí.

      Ìjìnlẹ̀ Òye Rere Ń Múni Rí Ojú Rere

      Sólómọ́nì sọ pé, “ìjìnlẹ̀ òye rere ń fúnni ní ojú rere, ṣùgbọ́n págunpàgun ni ọ̀nà àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè.” (Òwe 13:15) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé èdè tí wọ́n pilẹ̀ máa ń lò fún “ìjìnlẹ̀ òye rere,” tàbí òye rere, “ṣàpèjúwe agbára tí ẹnì kan ní láti lo agbára ìmòye rere, ìrònú yíyè kooro àti èrò ọlọgbọ́n.” Kì í ṣòro fún ẹnì kan tó nírú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ láti rí ojúure àwọn ẹlòmíràn.

      Ìwọ wo ìjìnlẹ̀ òye tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bá Fílémónì tó jẹ́ Kristẹni bíi tiẹ̀ lò nígbà tó ń rán Ónẹ́símù, ẹrú rẹ̀ tó sá kúrò nílé ṣùgbọ́n tó ti di Kristẹni, padà sí i. Pọ́ọ̀lù gba Fílémónì níyànjú pé kó finú rere gba Ónẹ́símù padà, bí yóò ṣe gba òun tọwọ́ tẹsẹ̀. Kódà, Pọ́ọ̀lù sọ pé bí Ónẹ́símù bá jẹ Fílémónì ní ohunkóhun, òun ṣe tán láti san án. Pọ́ọ̀lù lágbára láti lo ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì kó sì pàṣẹ fún Fílémónì pé kó ṣe ohun tó tọ́. Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì náà yàn láti fi ìfẹ́ àti ọgbọ́n bójú tó ọ̀ràn náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Fílémónì ò ní kọ̀rọ̀ sí òun lẹ́nu, kódà á ṣe kọjá ohun tí òun ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lò lọ́nà yìí?—Fílémónì 8-21.

      Àmọ́, ní ti àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè, ńṣe ni ọ̀nà wọ́n rí págunpàgun, ìyẹn ni pé ó le koko. Lọ́nà wo? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣe sọ, èyí túmọ̀ sí ohun tó “lágbára tàbí tó le koránkorán, ó sì ń sọ nípa ìwà ọ̀dájú táwọn èèyàn búburú máa ń hù. . . . Bí ọkùnrin kan bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú ibi ṣíṣe, tó dájú gbáú tí kò sì bìkítà nípa ìtọ́ni ọlọgbọ́n táwọn ẹlòmíì ń fún un, ọ̀nà ìparun ló forí lé yẹn.”

      Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ arìndìn yóò tan ìwà òmùgọ̀ káàkiri.” (Òwe 13:16) Afọgbọ́nhùwà tá à ń sọ níbí kì í ṣe alárèékérekè ẹ̀dá o. Ìfọgbọ́nhùwà tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ọlọgbọ́n èèyàn tó máa ń ro nǹkan kó tó ṣe é ló sì máa ń ní in. Bí wọ́n bá ń ṣe lámèyítọ́ ẹni tó jẹ́ afọgbọ́nhùwà láìtọ́ tàbí tí wọ́n ń bú u, ńṣe ló máa kó ahọ́n ara rẹ̀ níjàánu. Á gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ kó bàa lè lo èso ẹ̀mí mímọ́ kí inú má bàa bí i sódì. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹni tó gbọ́n kì í jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì tàbí bí ipò nǹkan ṣe rí darí òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìkáwọ́ rẹ̀ ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ wà, ó sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún èdè àìyedè tó máa ń wáyé bí ẹnì kan bá tètè máa ń fara ya nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ ẹ́.

      Ọlọgbọ́n èèyàn tún máa ń fi ìmọ̀ hùwà nígbà tó bá ń ṣe ìpinnu. Ó mọ̀ pé ṣíṣe ohun tó mọ́gbọ́n dání kì í ṣe ọ̀ràn èyí-jẹ́-èyí-ò-jẹ, kì í wáyé nípa wíwulẹ̀ ṣe ohun tó bá ṣáà ti sọ síni lọ́kàn, tàbí wíwulẹ̀ ṣe ohun táwọn ẹlòmíì bá ń ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń fara balẹ̀ yẹ ipò tó bá bá ara rẹ̀ wò dáadáa. Ó máa ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo nǹkan tó bá yí ọ̀rọ̀ kan ká, á sì pinnu onírúurú ọ̀nà tí òun lè gbé nǹkan gbà. Lẹ́yìn náà, á ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, á sì pinnu àwọn òfin tàbí ìlànà Bíbélì tí òun lè lò. Ipa ọ̀nà irú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa tọ́ ni lọ́jọ́ gbogbo.—Òwe 3:5, 6.

      “Olùṣòtítọ́ Aṣojú Jẹ́ Ìmúniláradá”

      Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìkáwọ́ wa ni Ọlọ́run fi pípolongo ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ sí. Ọ̀rọ̀

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́