-
Mú Kí Ìfẹ́ Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé Jinlẹ̀ Sí IIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | May
-
-
Mú Kí Ìfẹ́ Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé Jinlẹ̀ Sí I
1. Báwo la ṣe mú kí ìfẹ́ ẹnì tá à ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé jinlẹ̀ sí i?
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn tá à ń bá pàdé ló máa ń fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa, inú wọn sì máa ń dùn láti gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ wa ṣùgbọ́n wọn kì í nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé ká máa mú ìwé ìròyìn lọ fún wọn déédéé. Tó o bá fún ẹnì kan ní ìwé ìròyìn, kọ orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni yẹn sílẹ̀, kọ ọjọ́ tó o fún un níwèé náà, kọ ẹ̀dà ìwé ìròyìn tó o fún un àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ jíròrò tó fi mọ́ ohunkóhun tó o kíyè sí pé ó lè fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o bá a sọ. Gbàrà tí ìwé ìròyìn tuntun bá ti dé, wo àwọn kókó tó o rí i pé ó máa wọ àwọn tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn lọ́kàn, kó o sì mú un lọ fún wọn nígbà tó o bá padà lọ sọ́dọ̀ wọn. (1 Kọ́r. 9:19-23) Nígbà tó bá yá, ohun tí wọ́n kà nínú àwọn ìwé ìròyìn wa á mú kí wọ́n fẹ́ láti mọ̀ sí i.
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn wá Jèhófà lásìkò yìí, nǹkan míì wo la tún lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?
2 Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè tipasẹ̀ dídá ka àwọn ìwé ìròyìn wa nìkan di ìránṣẹ́ Jèhófà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó ti di kánjúkánjú fáwọn èèyàn láti wá Jèhófà lásìkò yìí, kí la tún lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? (Sef. 2:2, 3; Ìṣí. 14:6, 7) A lè mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ohun tá à ń bá wọn sọ tá a bá ń ka ó kéré tán ẹsẹ Bíbélì kan tá a ti yẹ̀ wò dáadáa ní gbogbo ìgbà tá a bá mú ìwé ìròyìn lọ fún wọn.
3. (a) Báwo la ṣe lè múra onírúurú ìjíròrò téèyàn á fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣe? (b) Kí lohun tó jẹ́ olórí àníyàn àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ?
3 Bó O Ṣe Lè Lo Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Kan Ṣoṣo Láti Fi Báni Sọ̀rọ̀: Ronú nípa àwọn tó o máa ń mú ìwé ìròyìn lọ fún kó o sì múra onírúurú ìjíròrò tó o lè fi ẹsẹ Bíbélì kan ṣe, tó máa lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́. (Fílí. 2:4) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan wà téèyàn rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, o lè máa lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ láti máa bá a jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò táwọn òkú wà àti ìrètí àjíǹde. O lè lo àlàyé tó wà lábẹ́ àkòrí náà “Death” (Ikú) àti “Resurrection” (Àjíǹde) nínú ìwé Reasoning láti fi múra ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo tó o máa fi bá a sọ̀rọ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, o lè ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ fún un lórí àwọn kókó míì tó jẹ mọ́ ọn, irú bí àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú ṣe máa pòórá títí láé. Ohun tá á jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe ni pé kó o wá kókó tí ẹni yẹn á nífẹ̀ẹ́ sí kó o sì máa fi ẹ̀kọ́ Bíbélì yé e ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé.
4. Tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ látinú Ìwé Mímọ́, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kóhun tí wọ́n ń kọ́ yé wọn báwo la sì ṣe lè ṣe é?
4 La Ohun Kan Yé Wọn: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa jù ni pé kí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ rọrùn láti lóye kó sì tún ṣe ṣókí, nǹkan míì tún wà tó ṣe pàtàkì ju kéèyàn kàn ka Ìwé Mímọ́ nìkan. Sátánì ti fọ́ èrò inú àwọn èèyàn sí ìhìn rere. (2 Kọ́r. 4:3, 4) Kódà àwọn tó mọ Bíbélì pàápàá ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ kó tó lè yé wọn. (Ìṣe 8:30, 31) Nípa bẹ́ẹ̀, ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì náà kó o sì lo àpẹẹrẹ tó máa mú kó yé wọn, bí ìgbà tó ò ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Iṣe 17:3) Rí i dájú pé ẹni yẹn mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa wúlò tó nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
5. Ọ̀nà wo ni ẹni tó ò ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé lè gbà di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
5 Bí ẹ̀kọ́ tí ẹni náà ń kọ́ bá ń gbádùn mọ́ ọn, jẹ́ kí ẹsẹ Bíbélì tẹ́ ẹ̀ ǹ jíròrò di méjì tàbí mẹ́ta ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nígbà ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan. Wá ọ̀nà tó o lè fi mú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ wọnú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Lọ́nà yìí, ẹni tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé lè di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
-
-
Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé ÌròyìnIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | May
-
-
Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ May 15
“Ǹjẹ́ o kò rò pé ìgbà kan á wà tí ò ní sí tálákà láyé mọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwọ gbọ́ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí. [Ka Aísáyà 65:21.] Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé bí ìlérí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí ṣe máa ṣẹ.” Sọ fún un pé wàá padà wá láti dáhùn ìbéèrè yìí: Ìgbà wo ni ìlérí ìyípadà náà máa ṣẹ?
Ile Iṣọ June 1
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ló ń sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà, ìṣọ̀kan ṣì jẹ́ àléèbá fún aráyé. Àbí o kò rò pé ó lè ṣeé ṣe kí arayé wà níṣọ̀kan? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ nípa ìjọba kan tó lè mú ayé wà ní ìṣọ̀kan.” Ka Sáàmù 72:7, 8, kẹ́ ẹ sì jọ ṣe àdéhùn ìgbà tó o máa padà lọ ṣàlàyé bí ìṣọ̀kan ṣe máa wà fún un.
Jí June 8
“Ọ̀pọ̀ ló ti gbọ́ pé eré ìmárale ṣe pàtàkì béèyàn bá fẹ́ kí ara gbé kánkán, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé àwọn kì í ṣe eré ìmárale tó. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ṣe eré ìmárale déédéé, ó sì tún dábàá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà wá àyè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ dí.”
-