ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Yin Jèhófà Lógo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | September
    • Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Yin Jèhófà Lógo

      1 Ìhìn pàtàkì kan wà tí à ń polongo jákèjádò ayé. Ìhìn náà ni: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” (Ìṣí. 14:6, 7) A láǹfààní láti máa kópa nínú pípolongo ìhìn yìí. Kí ló yẹ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Jèhófà kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì máa jọ́sìn rẹ̀?

      2 Orúkọ Rẹ̀: Ó yẹ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, kí wọ́n lè fi ìyàtọ̀ sáàárín òun àti ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́run èké tí wọ́n ń jọ́sìn lónìí. (Diu. 4:35; 1 Kọ́r. 8:5, 6) Ká sòótọ́, àwọn tó kọ Bíbélì lo orúkọ ọlọ́lá ńlá Jèhófà ní iye ìgbà tó ju ẹgbẹ̀rún méje lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká lo ìfòyemọ̀ ní ti ìgbà tá a máa sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, a kò gbọ́dọ̀ fi pa mọ́ fún wọn tàbí ká kùnà láti lò ó. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ìran èèyàn mọ orúkọ òun.—Sm. 83:18.

      3 Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀: Láti yin Jèhófà lógo, ó yẹ káwọn èèyàn mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́. A ní láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó ní ìfẹ́ títayọ, ọgbọ́n tó ga jù lọ, ìdájọ́ òdodo tó pé pérépéré, àti agbára tó ju gbogbo agbára lọ, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àánú rẹ̀, inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àtàwọn ànímọ́ àgbàyanu mìíràn tó ní. (Ẹ́kís. 34:6, 7) Wọ́n tún ní láti mọ bí wọ́n ṣe lè ní ìbẹ̀rù àtọkànwá fún Ọlọ́run, àti bí wọ́n ṣe lè máa fi ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ hàn fún un, kí wọ́n sì mọ̀ pé ìwàláàyè wọn sinmi lórí rírí ojú rere Jèhófà.—Sm. 89:7.

      4 Sísúnmọ́ Ọlọ́run: Bí àwọn èèyàn bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbà wọ́n là nígbà ìdájọ́ rẹ̀ tó ń bọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Jèhófà. (Róòmù 10:13, 14; 2 Tẹs. 1:8) Èyí kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn mímọ orúkọ Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ nìkan. A ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé e. (Òwe 3:5, 6) Bí wọ́n bá ṣe ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, tí wọ́n ń gba àdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń rí ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fún wọn nínú ìgbésí ayé wọn, ìgbàgbọ́ wọn yóò pọ̀ sí i, wọ́n á sì lè sún mọ́ Jèhófà.—Sm. 34:8.

      5 Ẹ jẹ́ ká máa fi tìtaratìtara polongo orúkọ Ọlọ́run, ká sì máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé e, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. A ṣì láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn sí i lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, kí wọ́n sì máa yìn ín lógo gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run ìgbàlà” wọn.—Sm. 25:5.

  • Máa Náání Àwọn Ohun Ìní Ètò Àjọ Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2002 | September
    • Máa Náání Àwọn Ohun Ìní Ètò Àjọ Ọlọ́run

      1 Nígbà tí ètò ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì, Jòsáyà Ọba gbóríyìn fún àwọn tí a yanṣẹ́ náà fún nípa sísọ pé: “Kí a má ṣe ṣírò owó tí ó wà lọ́dọ̀ wọn sí ọwọ́ ẹni tí a ń fi í sí, nítorí pé ìṣòtítọ́ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́.” (2 Ọba 22:3-7) Ìmọrírì tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn ní fún àwọn nǹkan tẹ̀mí fara hàn kedere nínú bí wọ́n ṣe bójú tó ohun tá a fi síkàáwọ́ wọn. Lónìí, bá a ṣe ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run, ó yẹ kí àwa náà máa fi ìṣòtítọ́ hàn nínú bí a ṣe ń bójú tó àwọn ohun tí a pèsè fún wa.

      2 Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Pápá: Tí a bá ń náání àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa àti iye tó ń ná wa láti tẹ̀ wọ́n jáde èyí á máa sún wa láti mọyì wọn gidigidi. Kò yẹ ká máa pín àwọn ìwé wa fún irú-wá-ògìrì-wá, ìyẹn àwọn ẹni tí kò ní ojúlówó ìmọrírì fún ìhìn Bíbélì. Bí ẹnì kan kò bá fi bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn nínú ìhìn rere náà, a lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú dípò tí a ó fi fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.

      3 Máa pín àwọn ìwé wa lọ́nà tó máa fi hàn pé o mọyì ìjẹ́pàtàkì wọn. Má kàn máa kó wọn sílẹ̀ ní gbangba, níbi tí atẹ́gùn á ti máa gbá wọn káàkiri. Láti yẹra fún ìfiṣòfò, yẹ àwọn ìwé tó o ní lọ́wọ́ nílé wò kó o tó gba àfikún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀dà ìwé ìròyìn bá sábà máa ń ṣẹ́ jọ sí ọ lọ́wọ́, o lè dín iye tó ò ń gbà kù.

      4 Àwọn Ìtẹ̀jáde Tí A Fẹ́ Lò Fúnra Wa: Àwọn ìtẹ̀jáde tá a dìídì nílò nìkan ló yẹ ká béèrè fún. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nígbà tá a bá fẹ́ béèrè fún àwọn ìtẹ̀jáde àkànṣe, irú bíi Bíbélì olómi góòlù (deluxe), Bíbélì atọ́ka lédè Gẹ̀ẹ́sì (Reference Bible), àtàwọn ìtẹ̀jáde ńlá mìíràn bí ìwé Concordance, ìwé Index, àwọn ìdìpọ̀ Insight, àti ìwé Proclaimers, nítorí pé owó gọbọi ló ń ná wa láti tẹ̀ wọ́n jáde.

      5 Ṣé o máa ń rántí láti kọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ sínú àwọn ẹ̀dà ìtẹ̀jáde tó jẹ́ tìrẹ? Bó o bá ń ṣe èyí, kò ní fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan láti máa gba àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn láti fi rọ́pò àwọn tó o ṣèèṣì sọ síbì kan. Bó o bá sọ ìwé orin, Bíbélì, tàbí ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ nù, ó ṣeé ṣe kó o rí i láàárín àwọn nǹkan tó sọ nù tí wọ́n sì rí he ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní ilẹ̀ àpéjọ.—Lúùkù 15:8, 9.

      6 Ẹ jẹ́ ká sapá láti rí i pé à ń fi ọgbọ́n lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Èyí jẹ́ ọ̀nà kan láti fi ìṣòtítọ́ wa hàn nínú bí a ṣe ń bójú tó àwọn ohun ìní Ìjọba náà tí Jèhófà ti fi sí ìkáwọ́ wa.—Lúùkù 16:10.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́