Ẹ̀KỌ́ 3
Pípe Ọ̀rọ̀ Bó Ṣe Tọ́
KÌ Í ṣe gbogbo Kristẹni ló fi bẹ́ẹ̀ kàwé lọ títí. Àní wọ́n tiẹ̀ ṣàpèjúwe àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn gbáàtúù èèyàn tí kò gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti àwọn rábì.’ (Ìṣe 4:13) Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí o yàgò fún jíjẹ́ kí ṣíṣi ọ̀rọ̀ pè bu òtítọ́ Bíbélì tí ò ń kéde kù.
Àwọn Kókó Tó Yẹ Kí O Gbé Yẹ̀ Wò. Kò sí ọ̀wọ́ ìlànà ọ̀rọ̀ pípè kan ṣoṣo tó ṣeé lò fún gbogbo èdè pátá. Ọ̀pọ̀ èdè ló ń lo ìlànà ìkọ̀wé onílẹ́tà bíi ti a, b, d. Yàtọ̀ sí ìlànà ìkọ̀wé onílẹ́tà a, b, d, tó tinú èdè Látìn wá, onírúurú ìlànà ìkọ̀wé ní àwọn lẹ́tà mìíràn tún wà, irú bíi ti èdè Lárúbáwá, àwọn èdè ilẹ̀ Rọ́ṣíà, èdè Gíríìkì, àti ti Hébérù. Bí àwọn ará Ṣáínà bá fẹ́ kọ̀wé, àwòrán tí a sín pọ̀ mọ́ra ni wọ́n máa ń yà dípò ìlànà ìkọ̀wé onílẹ́tà a, b, d. Àwọn àwòrán tí a sín pọ̀ mọ́ra yìí ló sábà máa ń dúró fún ọ̀rọ̀ kan tàbí apá kan ọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlànà ìkọ̀wé ti àwọn ará Ṣáínà yìí làwọn ará Japan àti Korea gbà lò, ìró tí àwọn àwòrán wọn dúró fún lè máà bára mu kí ìtumọ̀ wọn sì yàtọ̀.
Ní àwọn èdè tó ń lo lẹ́tà a, b, d, pípe ọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́ wé mọ́ fífi ìró tó yẹ pe lẹ́tà kan tàbí àpapọ̀ àwọn lẹ́tà kan. Bí irú èdè bẹ́ẹ̀ bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó mú ọ̀nà kan ṣoṣo, bíi ti èdè Gíríìkì, èdè àwọn ará Sípéènì, àti ti Súlù, kò ní ṣòro fúnni láti máa pe ọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́. Àmọ́ ṣá, bí a ṣe ń pe àyálò ọ̀rọ̀ tó tinú èdè kan bọ́ sínú èdè mìíràn sábà máa ń bá ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pè é nínú èdè tó ti wá mu. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè ju ọ̀nà kan tí à ń gbà pe lẹ́tà kan tàbí àpapọ̀ àwọn lẹ́tà kan, tàbí nígbà mìíràn kí á má tiẹ̀ pe lẹ́tà yìí sókè rárá nínú ọ̀rọ̀. Èyí lè béèrè pé kí o kọ́ àwọn tó yàtọ̀ yẹn sórí, kí o sì máa lò wọ́n déédéé tí o bá ń sọ̀rọ̀. Nínú èdè àwọn ará Ṣáínà, ó máa ń gba pé kéèyàn kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwòrán tí a sín pọ̀ mọ́ra sórí kí onítọ̀hún tó lè máa pe ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́. Ní àwọn èdè kan, tí a bá yí ìró ọ̀rọ̀ padà, ó lè mú kí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn yí padà. Béèyàn bá kùnà láti fún pípe ọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́ ní àfiyèsí tó yẹ, ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè máa gbin èrò ọ̀tọ̀ sí àwọn èèyàn lọ́kàn.
Bó bá jẹ́ pé ìlànà gígé ọ̀rọ̀ sí sílébù la fi ń pe ọ̀rọ̀ nínú èdè kan, ó ṣe pàtàkì pé kó jẹ́ sílébù tó tọ́ là ń tẹnu mọ́. Ọ̀pọ̀ èdè tó ń fi gígé ọ̀rọ̀ sí sílébù pe ọ̀rọ̀ sábà máa ń ní ìlànà ìtẹnumọ́ ọ̀rọ̀ tí kì í yẹ̀. Níbi tí àyàfi bá ti wà nínú pípè ọ̀rọ̀ kan, àmì bí a ó ṣe pe ọ̀rọ̀ yìí yóò wà lórí rẹ̀ bí a bá kọ ọ́ sílẹ̀. Èyí máa ń jẹ́ kó rọrùn láti mọ ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà pè é. Àmọ́ tó bá di pé ìlànà fún títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ kò bára mu délẹ̀ nínú èdè kan, ó lè fúnni níṣòro. Yóò gba pé kéèyàn kọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ sórí kí o lè máa pè wọ́n bó ṣe tọ́.
Nínú èdè Yorùbá, ó ṣe pàtàkì gidi láti kíyè sí àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀. Èyí ni àmì orí àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ tí a fi yán àwọn lẹ́tà, bíi: à, ẹ, ọ́, ṣ. A lè ti fi àmì wọ̀nyí sí ọ̀rọ̀ tí a kọ tàbí kí á retí pé kí òǹkàwé fúnra rẹ̀ fi sí i níbàámu pẹ̀lú ohun tí òye àlàyé ọ̀rọ̀ tó ń kà bọ̀ bá fi hàn pé ó yẹ kó jẹ́. Bó bá di pé a kò yán ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, yóò gba pé kí o fara balẹ̀ múra sílẹ̀ dáadáa tí a bá yàn ọ́ láti kàwé fún àwùjọ. Ẹ̀wẹ̀, a tún ní láti ṣàkíyèsí àwọn sílébù tó jẹ́ fáwẹ̀lì àti kọ́ńsónáǹtì àránmúpè bí: an, ẹn, in, ọn, un, m àti n.
Ní ti pípe ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀fìn kan wà tó yẹ kéèyàn yẹra fún. Béèyàn bá ti ń yun ẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ jù, ó lè mú kó dà bíi pé ńṣe ló ń sín ẹlòmíràn jẹ, tàbí pé ó fi ń ṣe fọ́rífọ́rí. Bákan náà ló ṣe rí tá a bá ń pe ọ̀rọ̀ lọ́nà tí a kì í sábà pè é mọ́ lédè ọ̀hún. Èyí á kàn máa pe àfiyèsí sí olùbánisọ̀rọ̀ fúnra rẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ó tún yẹ kéèyàn yẹra fún àṣejù lọ́nà kejì, ìyẹn ni jíjá ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ra bó o bá ń sọ̀rọ̀ tàbí bó o bá ń pe ọ̀rọ̀. A ti jíròrò nípa ọ̀ràn yìí ṣáájú lábẹ́ ẹ̀kọ́ “Sísọ̀rọ̀ Ketekete.”
Ọ̀nà tí a gbà pé ó tọ́ láti máa pe àwọn ọ̀rọ̀ ní èdè kan lè yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn, kódà ó lè yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíràn nínú orílẹ̀-èdè kan náà. Ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn lè máa fi ohùn ìlú rẹ̀ tó yàtọ̀ sọ èdè àdúgbò ibi tó ń gbé. Àwọn ìwé atúmọ̀ èdè lè to oríṣiríṣi ọ̀nà tó ju ẹyọ kan lọ tí ó tọ́ láti gbà pe ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo. Ẹ̀wẹ̀, bí ẹnì kan kò bá fi bẹ́ẹ̀ kàwé, tàbí pé kì í ṣe èdè àbínibí rẹ̀ ló ń sọ nísinsìnyí, yóò jàǹfààní dáadáa tó bá fetí sí bí àwọn tó mọ èdè ọ̀hún sọ dáadáa ṣe ń sọ ọ́, kí ó sì máa pe ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń pè é. Àwa tí a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò buyì kún iṣẹ́ tí à ń jẹ́, àti lọ́nà tí yóò mú kó tètè yé àwọn èèyàn tó wà ládùúgbò wa.
Nínú ọ̀rọ̀ sísọ wa ojoojúmọ́, ó sábà máa ń dára jù lọ pé ká máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ dunjú. Ọ̀nà tí à ń gbà pe ọ̀rọ̀ kò ní jẹ́ ìṣòro tó bá ṣe pé à ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ ni. Àmọ́, tó bá di pé kí a kàwé sókè, a lè bá àwọn ọ̀rọ̀ kan tí a kì í lò nínú ọ̀rọ̀ wa ojoojúmọ́ pàdé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó jẹ́ ìṣe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa kàwé sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn. A máa ń ka Bíbélì sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn nígbà tí a bá ń wàásù. A máa ń sọ pé kí àwọn arákùnrin kan ka ìpínrọ̀ fún àwùjọ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tàbí nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ó ṣe pàtàkì pé kí á kàwé bó ṣe tọ́ kí a má sì fi àṣìpè ọ̀rọ̀ tàbùkù sí ìsọfúnni tí à ń kà.
Ǹjẹ́ àwọn orúkọ inú Bíbélì máa ń ṣòro fún ọ láti pè? Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Yorùbá, a ti fi àmì ohùn àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ tí a fi máa pe orúkọ wọ̀nyí bó ṣe yẹ sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí a ṣe máa pe S nínú Síbólẹ́tì yàtọ̀ sí bí a ṣe máa pe Ṣ nínú Ṣíbólẹ́tì. Iwájú ahọ́n àti èrìgì la fi ń pe S tó jẹ́ pé kò lọ́mọ nídìí. Ṣùgbọ́n iwájú ahọ́n, àárín àjà ẹnu àti èrìgì la fi ń pe Ṣ tó lọ́mọ nídìí. Yóò dára kí á sapá láti má ṣe gbé àwọn lẹ́tà yìí fúnra wọn. Bákan náà, bí a bá fẹ́ pe àwọn orúkọ tí H bẹ̀rẹ̀ wọn, irú bíi Hágáì, a kò ní pa lẹ́tà H ìbẹ̀rẹ̀ yìí jẹ kí á wá pè é ní Ágáì. Àlàfo tán-án-ná ọ̀nà ọ̀fun ni a fi ń pe H.
Ọ̀nà Tí O Lè Gbà Ṣàtúnṣe. Ọ̀pọ̀ ló níṣòro ọ̀rọ̀ pípè ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ̀ rárá. Bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ bá mẹ́nu kan apá ibi tó ti yẹ kó o ṣàtúnṣe nínú ọ̀rọ̀ pípè, fi ìmọrírì hàn fún inú rere rẹ̀. Bí o bá ti wá mọ ìṣòro yẹn, ọ̀nà wo ni wàá gbà ṣàtúnṣe rẹ̀?
Lákọ̀ọ́kọ́, bí a bá fún ọ ní iṣẹ́ ìwé kíkà, wá àyè láti ṣàyẹ̀wò nínú ìwé atúmọ̀ èdè kan. Wo àwọn ọ̀rọ̀ tí o kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ níbẹ̀. Bí o kò bá fi bẹ́ẹ̀ mọ bí a ṣe ń lo ìwé atúmọ̀ èdè, wo àwọn ojú ewé apá ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ fún àlàyé nípa ohun tí àwọn àmì inú rẹ̀ túmọ̀ sí, tàbí kí o ní kí ẹnì kan ṣàlàyé rẹ̀ fún ọ. Ìwé atúmọ̀ èdè yẹn á sọ ibi tí àmì ohùn àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ wà, ìyẹn yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pe ọ̀rọ̀ náà bó ṣe yẹ. Kó o rántí pé ṣíṣi àmì ohùn ọ̀rọ̀ pè lè mú kí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí nǹkan mìíràn. Bí o bá sì ti yẹ ọ̀rọ̀ kan wò nínú ìwé atúmọ̀ èdè, pe ọ̀rọ̀ náà sókè ní àpètúnpè kí o tó pa ìwé yẹn dé.
Ọ̀nà kejì tó o lè gbà ṣàtúnṣe nínú pípe ọ̀rọ̀ ni pé kí o ka ìwé sétígbọ̀ọ́ ẹnì kan tí òun fúnra rẹ̀ máa ń pe ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́, kí o sọ fún un pé kó sọ bí o ṣe máa pe àwọn tó o bá ṣì pè fún ọ.
Ọ̀nà kẹta tó o lè gbà ṣàtúnṣe ni pé kí o fetí sílẹ̀ dáadáa sí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dá-ń-tọ́. Bí kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí tí a ka Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tàbí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! sínú rẹ̀ bá wà lédè tí o fẹ́ fi kàwé, tẹ́tí sí ìwọ̀nyí dáadáa. Bí o ṣe ń gbọ́ ọ, ṣàkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ tí a pè yàtọ̀ sí bí ìwọ ṣe ń pè wọ́n. Kọ wọ́n sílẹ̀, kí o sì máa fi bí a ṣe ń pè wọ́n dánra wò. Bí àkókò ti ń lọ, wàá bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣi ọ̀rọ̀ pè nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀, ìyẹn á sì mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ lárinrin.