ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
    • ń jọ́sìn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá máa ń lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn, àwọn Kèfèrí sì máa ń lò ó nínú àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìbálòpọ̀ lárugẹ.

      Kí wá nìdí tí wọ́n fi gbé àgbélébùú tó jẹ́ àmì ìjọsìn àwọn Kèfèrí ayé ọjọ́un lárugẹ? Ó jọ pé ìdí tí wọ́n fi gbé e lárugẹ ni kó bàa lè rọrùn fáwọn Kèfèrí láti yí padà sí “ìsìn Kristẹni” táwọn èèyàn náà gbà pé àwọn ń ṣe. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ ọ́, ó là á, pé jíjọ́sìn ohunkóhun tó jẹ́ àmì ìjọsìn Kèfèrí kò tọ̀nà. (2 Kọ́ríńtì 6:14-18) Ìwé Mímọ́ tún ka onírúurú ìbọ̀rìṣà léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; 1 Kọ́ríńtì 10:14) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lo àgbélébùú nínú ìjọsìn.a

  • Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ń Ṣe Láti Bọlá fún Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
    • ÀFIKÚN

      Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ń Ṣe Láti Bọlá fún Ọlọ́run

      ÀṢẸ kan tó wà fáwọn Kristẹni ni pé kí wọ́n máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Èyí la tún ń pè ní “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:20) Kí ló mú kó ṣe pàtàkì gan-an? Ìgbà wo ló yẹ ká máa ṣe é, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa ṣe é?

      Alẹ́ ọjọ́ táwọn Júù máa ń ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ni Jésù Kristi dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún làwọn Júù máa ń ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá, ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn ló sì máa ń bọ́ sí lórí kàlẹ́ńdà àwọn Júù. Káwọn Júù bàa lè ṣírò ìgbà tí ọjọ́ yìí á bọ́ sí, ó jọ pé ńṣe ni wọ́n máa ń dúró di ọjọ́ tí ọ̀sán àti òru máa ń gùn dọ́gba nígbà ìrúwé. Ọjọ́ yìí ni ọ̀sán máa ń jẹ́ wákátì méjìlá, tí òru sì máa ń jẹ́ wákátì méjìlá. Òṣùpá tó bá lé kó tó di ọjọ́ tí ọ̀sán àti òru máa ń gùn dọ́gba ni wọ́n máa fi ń ka ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Nísàn. Ọjọ́ mẹ́rìnlá lẹ́yìn náà ni wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.

      Jésù ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, lẹ́yìn náà ó jẹ́ kí Júdásì Ísíkáríótù jáde, ó sì fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀. Òun ló rọ́pò ayẹyẹ Ìrékọjá àwọn Júù, nítorí náà, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún la ní láti máa ṣe é.

      Ìhìn Rere Mátíù ròyìn pé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’”—Mátíù 26:26-28.

      Èrò àwọn kan ni pé Jésù sọ búrẹ́dì náà di ẹran ara rẹ̀ tó sì sọ wáìnì náà di ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ nǹkan kan ò tíì ṣe Jésù lára lákòókò tó fún wọn ní búrẹ́dì yìí. Ṣé ara Jésù gan-an làwọn àpọ́sítélì jẹ ni, ṣe ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gan-an sì ni wọ́n mu? Rárá o, nítorí pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ èèyàn nìyẹn, èyí ò sì bá òfin Ọlọ́run mu. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Léfítíkù 17:10) Bó ṣe wà nínú Lúùkù 22:20, Jésù sọ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.” Ṣé ife yẹn gan-an ló di “májẹ̀mú tuntun” ni? Ko lè rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àdéhùn ni májẹ̀mú jẹ́, tí kì í ṣe ohun téèyàn lè fojú rí.

      Nítorí náà, ohun ìṣàpẹẹrẹ ni búrẹ́dì àti wáìnì wulẹ̀ jẹ́. Búrẹ́dì ṣàpẹẹrẹ ara pípé Kristi. Búrẹ́dì tó ṣẹ́ kù nígbà tí wọ́n ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá ni Jésù lò. Wọn ò sì fi ohun tí ń mú nǹkan wú sínú búrẹ́dì yìí. (Ẹ́kísódù 12:8) Nínú Bíbélì, ìwúkàrà máa ń dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdíbàjẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ara pípé Jésù tí Jésù fi rúbọ fún wa ni búrẹ́dì tí wọn kò fi ohun tí ń mú nǹkan wú sí yẹn dúró fún. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ kankan lára Jésù.—Mátíù 16:11, 12; 1 Kọ́ríńtì 5:6, 7; 1 Pétérù 2:22; 1 Jòhánù 2:1, 2.

      Wáìnì pupa náà ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù. Ẹ̀jẹ̀ yẹn ló jẹ́ kí májẹ̀mú tuntun ṣeé ṣe. Jésù sọ pé ẹ̀jẹ̀ òun ni a ta sílẹ̀ ‘fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.’ Èyí ló mú kí àwọn èèyàn lè di mímọ́ lójú Ọlọ́run kí wọ́n sì bá Jèhófà wọ májẹ̀mú. (Hébérù 9:14; 10:16, 17) Májẹ̀mú tàbí àdéhùn yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] láti lọ sí ọ̀run. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti ṣàkóso bí ọba àti àlùfáà láti bù kún gbogbo aráyé.—Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Jeremáyà 31:31-33; 1 Pétérù 2:9; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-3.

      Àwọn wo ló yẹ kó jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi? Bó ṣe yẹ kó rí, àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun tí wọ́n ní ìrètí láti lọ sọ́run nìkan ló yẹ kó jẹ búrẹ́dì kí wọ́n sì mu wáìnì. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló fi ń dá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú pé Ọlọ́run ti yàn wọ́n láti jẹ́ ọba ní ọ̀run. (Róòmù 8:16) Jésù tún bá wọn dá májẹ̀mú Ìjọba.—Lúùkù 22:29.

      Àwọn tí wọ́n nírètí àtiwà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Àwọn náà máa ń pa àṣẹ Jésù mọ́ nípa lílọ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Àmọ́, ńṣe ni wọ́n kàn máa ń lọ síbẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọn kì í jẹ búrẹ́dì, wọn kì í sì í mu wáìnì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kóra jọ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, lẹ́yìn tóòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé jákèjádò ayé, ìwọ̀nba ẹgbẹ̀rún èèyàn díẹ̀ ló sọ pé àwọn ní ìrètí àtilọ sọ́run, gbogbo Kristẹni ni Ìrántí Ikú Kristi ṣe pàtàkì fún. Ó jẹ́ àkókò tí gbogbo wa ti lè ronú lórí ìfẹ́ tí kò lẹ́gbẹ́ tí Jèhófà àti Jésù Kristi fi hàn sí wa.—Jòhánù 3:16.

  • Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
    • ÀFIKÚN

      Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?

      TÓ O bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” àti “ẹ̀mí,” kí lo máa ń rò pé wọ́n túmọ̀ sí? Èrò àwọn kan ni pé “ọkàn” tàbí “ẹ̀mí” jẹ ohun tí kò lè kú tó wà nínú èèyàn. Wọ́n rò pé téèyàn bá kú, ohun tí kò ṣeé fojú rí tó wà nínú ara yìí yóò fi ara sílẹ̀ yóò sì máa wà láàyè lọ níbòmíràn. Nítorí pé ìgbàgbọ́ yìí wọ́pọ̀, ó máa ń ya àwọn kan lẹ́nu tí wọ́n bá gbọ́ pé kì í ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni rárá. Nígbà náà, kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ọkàn jẹ́, kí ló sì sọ pé ẹ̀mí jẹ́?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́