ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì Gbádùn Rẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2006 | February
    • Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì Gbádùn Rẹ̀

      1 Ọ̀kan lára ohun tó dùn mọ́ni jù ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” ni ìmújáde ìwé Kí Ní Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? A máa tó bẹ̀rẹ̀ sí lò ó ní pẹrẹu nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, pàápàá nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Nítorí náà, ó yẹ ká mọ ìwé tuntun yìí tinú tẹ̀yìn. A sì máa mọ̀ ọ́n, torí, a máa tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti ọ̀sẹ̀ April 17, 2006.

      2 Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ á darí àfiyèsí àwọn ará sí àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ló máa wá fi àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ ojú ìwé náà darí ìkẹ́kọ̀ọ́. A ó máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣe kókó, a ó sì máa jíròrò wọn. Lẹ́yìn tá a bá ti parí orí kọ̀ọ̀kan, a ó máa jíròrò àpótí náà, “Ohun Tí Bíbélì Fí Kọ́ni,” èyí yóò sì ṣèrànwọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ náà torí pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpótí yìí ló jẹ́ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí náà. Á wù ẹ́ láti máa dáhùn níwọ̀n bí ìwé yìí ti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, tó rọrùn, tó sì fani mọ́ra.

      3 Àfikún inú ìwé yìí ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí onírúurú kókó ẹ̀kọ́. A ó lè lo ìsọfúnni yìí nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ bá nílò àlàyé sí i lórí kókó kan pàtó. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ó máa jíròrò àwọn ibi pàtó kan nínú àfikún náà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ẹni tó ń kàwé ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa ka gbogbo àlàyé tó wà lábẹ́ kókó kan nínú àfikún náà, àmọ́ tó bá jẹ́ àpilẹ̀kọ tó gùn ni, ṣe la máa dá a sí ìsọ̀rí ìsọ̀rí. Àfikún kì í ní ìbéèrè tá a fi máa jíròrò rẹ̀. Ṣùgbọ́n alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ náà lè béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwùjọ lè ṣàlàyé táá fa kókó ibẹ̀ yọ.

      4 Kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa yá kánmọ́kánmọ́. Àmọ́, a ò retí pé ká máa ṣe é kánmọ́kánmọ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, pàápàá tí òye wọn nípa Bíbélì ò bá tó nǹkan tàbí tí wọn ò bá tiẹ̀ ní in rárá. (Ìṣe 26:28, 29) Nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, a máa ní láti jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ibẹ̀ kúnnákúnná, ká ṣàlàyé àwọn àkàwé àtàwọn nǹkan míì tó wà níbẹ̀ bó ṣe yẹ. Nítorí náà, rí i dájú pé ò ń pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó o lè kópa kíkún nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

  • Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2006 | February
    • Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

      Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ọ̀sẹ̀ April 17, 2006, sí January 1, 2007.

      Ọ̀SẸ̀ ORÍ ÌPÍNRỌ̀ ÀFIKÚN

      Apr. 17 1* 1 sí 13

      Apr. 24 1 14 sí 24 ojú ìwé 195 sí 7

      May 1 2 1 sí 17

      May 8 2 18 sí 20 ojú ìwé 199 sí 201

      May 15 3 1 sí 12

      May 22 3 13 sí 24

      May 29 4 1 sí 11 ojú ìwé 197 sí 9

      June 5 4 12 sí 22 ojú ìwé 201 sí 4

      June 12 5 1 sí 13 ojú ìwé 204 sí 6

      June 19 5 14 sí 22 ojú ìwé 206 sí 8

      June 26 6 1 sí 6 ojú ìwé 208 sí 11

      July 3 6 7 sí 20

      July 10 7 1 sí 15

      July 17 7 16 sí 25 ojú ìwé 212 sí 15

      July 24 8 1 sí 17

      July 31 8 18 sí 23 ojú ìwé 215 sí 18

      Aug. 7 9 1 sí 9 ojú ìwé 218 sí 19

      Aug. 14 9 10 sí 18

      Aug. 21 10 1 sí 9

      Aug. 28 10 10 sí 19

      Sept. 4 11 1 sí 11

      Sept. 11 11 12 sí 21

      Sept. 18 12 1 sí 16

      Sept. 25 12 17 sí 22

      Oct. 2 13 1 sí 9

      Oct. 9 13 10 sí 19

      Oct. 16 14 1 sí 13

      Oct. 23 14 14 sí 21

      Oct. 30 15 1 sí 14

      Nov. 6 15 15 sí 20 ojú ìwé 219 sí 20

      Nov. 13 16 1 sí 10 ojú ìwé 221 sí 2

      Nov. 20 16 11 sí 19 ojú ìwé 222 sí 3

      Nov. 27 17 1 sí 11

      Dec. 4 17 12 sí 20

      Dec. 11 18 1 sí 13

      Dec. 18 18 14 sí 25

      Dec. 25 19 1 sí 14

      Jan. 1 19 15 sí 23

      Ẹ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí kẹ́ ẹ sì jíròrò wọn bí àkókò bá ṣe wà sí. Ẹ rí i pé ẹ ka gbogbo ìpínrọ̀ tá a yàn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti àfikún tá a bá yàn síbẹ̀. Ẹ jíròrò àpótí náà “Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni” lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn nínú orí náà.

      * Fi ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó wà ní ojú ìwé 3 sí 7 kún un.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́