ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 2/15 ojú ìwé 24-25
  • Ìdí Tí Ijọsin Kristian Fi Galọ́lájù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Ijọsin Kristian Fi Galọ́lájù
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kristi Galọ́lá Ju awọn Angẹli ati Mose
  • Awọn Kristian Wọnu Isinmi Ọlọrun
  • Oyè-àlùfáà ati Majẹmu Onípò Gígajù
  • Ìgbàgbọ́ Ṣe Pàtàkì!
  • Àwọn Àgùntàn Míràn àti Májẹ̀mú Tuntun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìbùkún Púpọ̀ Sí I Nípasẹ̀ Májẹ̀mú Tuntun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ẹgbẹ́ Àlùfáà Aládé Tó Máa Ṣe Gbogbo Aráyé Láǹfààní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 2/15 ojú ìwé 24-25

Ìdí Tí Ijọsin Kristian Fi Galọ́lájù

Awọn Koko Itẹnumọ Lati inu Lẹta si Awọn Heberu

JEHOFA ỌLỌRUN nasẹ awọn apa-ẹka ìjọsìn gigalọlaju nigba ti o ran Ọmọkunrin rẹ, Jesu Kristi, wa sori ilẹ-aye. Iyẹn jẹ́ bẹẹ nitori pe Jesu, Olùdásílẹ̀ isin Kristian, galọ laju awọn angẹli ati Wolii Mose lọ. Oyè àlùfáà Kristi jẹ́ gigalọlaju lọna titobi nigba ti a ba fiwe ti awọn ọmọ Lefi ni Israẹli igbaani. Ẹbọ Jesu sì fi pupọpupọ galọ́lá ju ti awọn ẹran ti a fi rubọ labẹ Ofin Mose.

Awọn kókó wọnyi ni a mú ṣe kedere ninu lẹta si awọn Heberu. O hàn gbangba pe a kọ ọ́ lati ọwọ apọsteli Pọọlu ni Roomu ni nnkan bi 61 C.E. a sì fi ranṣẹ si awọn onigbagbọ Heberu ni Judea. Lati akoko ìjímìjí, awọn Kristian ti wọn jẹ Giriiki ati ara Asia gbà pe Pọọlu ni ẹni ti o kọ ọ́, eyi ni a si tilẹhin nipasẹ mímọ̀ ti onkọwe naa mọ̀ Iwe Mimọ lede Heberu dunju ati ọna gbigbooro ti o gba ṣe igbeyọ ọrọ ti o ba ọgbọn ironu mu, eyi ti a mọ̀ mọ apọsteli naa. Oun ti le ṣai fi orukọ rẹ kún un nitori ẹ̀tanú awọn Juu si i ati nitori pe a mọ̀ ọ́n gẹgẹ bi “apọsteli awọn orilẹ-ede.” (Roomu 11:13, NW) Nisinsinyi ẹ jẹ ki a wo awọn apá-ẹ̀ka gígalọ́lájù ti isin Kristian, gẹgẹbi a ti ṣipaya rẹ ninu lẹta Pọọlu si awọn Heberu.

Kristi Galọ́lá Ju awọn Angẹli ati Mose

Ohun ti a kọkọ fihan ni ipo gígalọ́láju ti Ọmọkunrin Ọlọrun. (1:1–3:6) Awọn Angẹli ńwárí fun un, ìṣàkóso ọlọba rẹ si sinmi le Ọlọrun. Nitori naa awa nilati fun ohun ti Ọmọkunrin naa sọ ni àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, awa nilati ranti pe àní bi o tilẹ jẹ pe eniyan naa Jesu rẹlẹ̀ ju awọn angẹli lọ, oun ni a gbéga rekọja wọn a sì fun un ni aṣẹ akoso lori ilẹ aye gbígbé ti nbọ.

Jesu Kristi tun galọlá ju Mose lọ. Bawo ni o ṣe jẹ bẹẹ? Ó dara, Mose wulẹ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ ninu ile Ọlọrun Israẹli. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa gbé Jesu ga ju gbogbo ile yẹn, tabi ijọ awọn eniyan Ọlọrun lodidi.

Awọn Kristian Wọnu Isinmi Ọlọrun

Lẹhin naa apọsteli naa tọkasi i pe o ṣeeṣe lati wọnu isinmi Ọlọrun. (3:7–4:13) Awọn ọmọ Israẹli ti a fun lominira kuro ninu ìsìnrú awọn ara Íjíbítì kùnà lati wọlé sinu rẹ̀ nitori pe wọn jẹ aláìgbọràn wọn si ṣaláìní ìgbàgbọ́. Ṣugbọn ǹjẹ́ awa lè wọle sinu ìsinmi yẹn bi awa ba lo ìgbàgbọ́ ninu Ọlọrun ti a sì fi pẹlu ìgbọràn tẹle Kristi bi? Nigba naa, dipo wiwulẹ pa ọjọ Isinmi ọ̀lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́, awa yoo maa gbadun ibukun ti o galọ́lájù lojoojumọ fun sisinmi kuro lọwọ gbogbo awọn iṣẹ onimọtara-ẹni-nikan.

Wiwọnu isinmi Ọlọrun jẹ ileri ọ̀rọ̀ rẹ kan, eyi ti “o mú ju idàkídà oloju meji lọ, o si ńgúnni ani titi de pinpin ọkàn ati ẹ̀mí niya.” O ṣe bẹẹ niti pe ó ńwọnilọ́kàn ṣinṣin lati mọ awọn ete ìsúnniṣe ati ẹmi-ironu, lati fi iyatọ sáàárín ìfẹ́ ẹran-ara ati ibi ti èrò-orí tẹ̀ sí. (Fiwe Roomu 7:25.) Bi “ọkàn,” tabi iwalaaye wa gẹgẹ bi ẹnikọọkan, bá papọ̀ pẹlu “ẹmi” tabi ìtẹ̀sí-ọkàn oniwa-bi-Ọlọrun, awa le wọle sinu isinmi Ọlọrun.

Oyè-àlùfáà ati Majẹmu Onípò Gígajù

Pọọlu fi ìgalọ́lájù oyè-àlùfáà ti Kristi ati ti majẹmu titun han tẹle e. (4:14–10:31) Jesu Kristi aláìlẹ́ṣẹ̀ ní ìyọ́nú fun awọn eniyan ẹlẹṣẹ nitori pe, bii tiwa, a ti dan an wò ni gbogbo ọna. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọrun ti yàn án ni “àlùfáà titi lae nipa ti Melikisedeki.” Láìdàbí awọn àlùfáà àgbà ti ọmọ Lefi, Jesu ni ìwàláàyè ti kò lè parun ati nipa bayii kò nilo awọn agbapò ninu iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀. Oun ko nilati pese awọn ẹbọ ẹran, nitori pe oun ti fi ara rẹ aláìlẹ́ṣẹ̀ gigalọlaju rubọ o si ti wọnu ọrun pẹlu ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

Majẹmu titun, ti a fi ẹ̀jẹ̀ Jesu fẹsẹ rẹ múlẹ̀, galọ́lá ju majẹmu Ofin. Awọn wọnni ti wọn wa ninu majẹmu titun ní awọn ofin Ọlọrun ninu ọkan-aya wọn wọn si ngbadun ìdáríjì awọn ẹṣẹ wọn. (Jeremaya 31:31-34) Ìmoore fun eyi sun wọn lati ṣe ipolongo ìrètí wọn ni gbangba ati lati pejọ pẹlu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn. Láìdàbí wọn, awọn amọ̀-ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ ko ni ẹbọ eyikeyii fun ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

Ìgbàgbọ́ Ṣe Pàtàkì!

Lati jèrè lati inu majẹmu titun gígalọ́lájù naa, awa nilo igbagbọ. (10:32–12:29) Ìfaradà ni a tun nilo bi awa bá nilati gbà ohun ti Jehofa ti ṣeleri. Gẹgẹbi iṣiri lati farada, awa ni ‘àwọ̀sánmọ̀ titobi’ ti awọn ẹlẹrii ti wọn wà ṣaaju akoko Kristian ti o yi wa ká. Bi o ti wu ki o ri, o ṣe pataki julọ pe ki awa gbé ipa-ọna aláìlálèébù ti Jesu labẹ ijiya yẹwo. Ijiya eyikeyii ti Ọlọrun ba yọnda ki o ṣubu lù wa ni a le wo lọna kan gẹgẹ bi ibawi kan ti o le mu eso alaafia tii ṣe ododo jade. Ìṣeéfọkantẹ awọn ileri Jehofa yẹ ki o mu ifẹ-ọkan wa pọ sii lati ṣe iṣẹ-isin mimọ-ọlọwọ síi “pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù.”

Pọọlu pari rẹ̀ pẹlu awọn igbani niyanju. (13:1-25) Igbagbọ nilati sun wa lati fi ìfẹ́ ara han, ki a jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣiṣe, ki a ranti awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ti wọn ńjìyà, ki a pa igbeyawo mọ́ ni ọlá, ki a jẹ ‘ki ohun ti a ni ki o to wa.’ Awa nilati ṣafarawe igbagbọ awọn wọnni ti wọn nmu ipò iwaju ninu ijọ ki a si ṣegbọran si wọn. Jù bẹẹ lọ, awa gbọdọ yẹra fun ìpẹ̀hìndà, farada ẹgan ti Jesu farada, “ki a maa rú ẹbọ iyin si Ọlọrun ni igba gbogbo,” ki a si maa baalọ lati ṣe daradara. Iru iwa bẹẹ tun wa laaarin apá-ẹ̀ka isin Kristian tootọ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Oniruuru Baptism: Awọn apá-ẹ̀ka ti ijọsin ni Agọ-isin Israẹli ní í ṣe “pẹlu kiki awọn ounjẹ ati ohun mimu ati oniruuru baptism.” (Heberu 9:9, 10) Awọn baptism wọnyi jẹ ààtò wíwẹ̀nù ti a beere fun nipasẹ Ofin Mose. Awọn koto ti a sọ daláìmọ́ ni a wẹ̀nù, ìwẹ̀nùmọ́ alayẹyẹ si ni fifọ awọn ẹwu ẹni ati wiwẹ ninu. (Lefitiku 11:32; 14:8, 9; 15:5) Awọn àlùfáà wẹ̀, awọn ohun ti o si ní í ṣe pẹlu awọn ọrẹ-ẹbọ sisun ni a fi omi ṣàn nù. (Ẹkisodu 29:4; 30:17-21; Lefitiku 1:13; 2 Kironika 4:6) Ṣugbọn “oniruuru baptism” ko ni ààtò ‘baptism awọn ago, ati awọn ìṣà-omi ati awọn ohun-elo bàbà’ nínú ti awọn Júù nṣe bi àṣà ni akoko ti Mesaya naa de; bẹẹni Heberu 9:10 kò tọka si ìrìbọmi ninu omi ti a mú ṣe lati ọwọ Johanu Arinibọmi tabi si baptism awọn wọnni ti wọn nṣapẹrẹ iyasimimọ wọn si Ọlọrun gẹgẹbi Kristian.—Matiu 28:19, 20; Maaku 7:4; Luuku 3:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́